ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: الناس   آية:

سورة الناس - Suuratun-Naas

قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلنَّاسِ
Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn,
التفاسير العربية:
مَلِكِ ٱلنَّاسِ
Ọba àwọn ènìyàn,
التفاسير العربية:
إِلَٰهِ ٱلنَّاسِ
Ọlọ́hun àwọn ènìyàn,¹
1. Ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun àwọn ènìyàn” ni pé, Ẹni tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, tí wọn kò sì gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀.
التفاسير العربية:
مِن شَرِّ ٱلۡوَسۡوَاسِ ٱلۡخَنَّاسِ
níbi aburú (Èṣù) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni tó bá ń dárúkọ Allāhu¹).
1. Ọ̀kan pàtàkì nínú àǹfààní àti oore tí ó wà nínú ath-thikār ṣíṣe ni pé, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóò máa sá sẹ́yìn fún ẹni tí ó bá ń ṣe ath-thikār ní gbogbo ìgbà. Kí á sì rántí wí pé, ọ̀kan pàtàkì jùlọ nínú ohun tí mùsùlùmí yóò máa fi ṣe ath-thikār ni kíké al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé ní ojoojúmọ́ ní díẹ̀ díẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àwọn gbólóhùn ath-thikār èyí tí ó wà nínú ẹ̀gbàwá hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Kí á sì jìnnà tefétefé sí àwọn ìkàkúkà tí wọ́n ń pè ní “wiridi àti waṭḥīfah” èyí tí àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, àwọn ààfáà onibidiah àti àwọn ààfáà onisūfī dáálẹ̀. Bí mùsùlùmí kò bá jìnnà tefétefé sí àwọn irúfẹ́ “wiridi àti waṭḥīfah” bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí pé, ó máa di kèfèrí lórí rẹ̀, àwọn èṣù yóò máa bá onítọ̀ún fínra.
التفاسير العربية:
ٱلَّذِي يُوَسۡوِسُ فِي صُدُورِ ٱلنَّاسِ
(Èṣù ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn.
التفاسير العربية:
مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ
(Èṣù náà) wà nínú àwọn àlùjànnú àti àwọn ènìyàn.”
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: الناس
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق