ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: الزمر   آية:

سورة الزمر - Suuratuz-Zumar

تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀¹ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.
التفاسير العربية:
إِنَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ فَٱعۡبُدِ ٱللَّهَ مُخۡلِصٗا لَّهُ ٱلدِّينَ
Dájúdájú Àwa sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo. Nítorí náà, jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.¹
1. Fífi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Allāhu ni sísin Allāhu, jíjọ́sìn fún Allāhu láti fi wá ojú rere Rẹ̀ nìkan ṣoṣo, tí kò sì níí fi ọ̀nà kan kan ròpọ̀ mọ́ ẹbọ ṣíṣe (ṣirk), ṣekárími (riyā’) àti ìṣọ̀bẹṣèlu (nifāƙ). Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūnus; 10:22.
التفاسير العربية:
أَلَا لِلَّهِ ٱلدِّينُ ٱلۡخَالِصُۚ وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ مَا نَعۡبُدُهُمۡ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَآ إِلَى ٱللَّهِ زُلۡفَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ فِي مَا هُمۡ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ كَٰذِبٞ كَفَّارٞ
Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́.¹ Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): “A kò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé, nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni.” Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.
1. Ẹ̀sìn mímọ́ ni ẹ̀sìn ’Islām tí wọ́n fi wá ojú rere Rẹ̀ nìkan ṣoṣo, tí kò sì níí fi ọ̀nà kan kan ròpọ̀ mọ́ ẹbọ ṣíṣe (ṣirk), ṣekárími (riyā’) àti ìṣọ̀bẹṣèlu (nifāƙ). Nítorí náà, “Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́.” ń já sí pé, bí ’Islām ọwọ́ lágbájá tàbí iṣẹ́ kan nínú àwọn iṣẹ́ ẹ̀sìn náà kò bá ti là kúrò nínú gbogbo àwọn n̄ǹkan tó máa ń́ kó àìmọ́ (ìdọ̀tí àti ẹ̀gbin) bá ẹ̀sìn rẹ̀, ìyẹn ẹbọ ṣíṣe (ṣirk), ṣekárími (riyā’) àti ìṣọ̀bẹṣèlu (nifāƙ), Allāhu kò níí gbà á nítorí pé, kò níí gba ohun tí kì í ṣe tiRẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀dá.
التفاسير العربية:
لَّوۡ أَرَادَ ٱللَّهُ أَن يَتَّخِذَ وَلَدٗا لَّٱصۡطَفَىٰ مِمَّا يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ fi ẹnì kan ṣe ọmọ ni, ìbá ṣẹ̀ṣà ohun tí Ó bá fẹ́ (fi ṣọmọ) nínú n̄ǹkan tí Ó dá. Mímọ́ ni fún Un (níbi èyí). Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí.
التفاسير العربية:
خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۖ يُكَوِّرُ ٱلَّيۡلَ عَلَى ٱلنَّهَارِ وَيُكَوِّرُ ٱلنَّهَارَ عَلَى ٱلَّيۡلِۖ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِي لِأَجَلٖ مُّسَمًّىۗ أَلَا هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفَّٰرُ
Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó ń ti òru bọnú ọ̀sán. Ó sì ń ti ọ̀sán bọnú òru. Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá; ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn fún gbèdéke àkókò kan. Gbọ́! Òun ni Alágbára, Aláforíjìn.
التفاسير العربية:
خَلَقَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ ثُمَّ جَعَلَ مِنۡهَا زَوۡجَهَا وَأَنزَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ ثَمَٰنِيَةَ أَزۡوَٰجٖۚ يَخۡلُقُكُمۡ فِي بُطُونِ أُمَّهَٰتِكُمۡ خَلۡقٗا مِّنۢ بَعۡدِ خَلۡقٖ فِي ظُلُمَٰتٖ ثَلَٰثٖۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ لَهُ ٱلۡمُلۡكُۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُصۡرَفُونَ
Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Lẹ́yìn náà, Ó dá ìyàwó rẹ̀ láti ara rẹ̀. Ó sì sọ mẹ́jọ kalẹ̀ fún yín nínú ẹran-ọ̀sìn ní takọ- tabo. Ó ń ṣẹ̀dá yín sínú ìyá yín, ẹ̀dá kan lẹ́yìn ẹ̀dá kan nínú àwọn òkùnkùn mẹ́ta.¹ Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. TiRẹ̀ ni ìjọba. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
1. Àpò (tán-ánná), ilé ọmọ àti ikùn ni àwọn okùnkùn mẹ́ta náà. Ọlẹ̀ (tàbí ọmọ) máa wà nínú àpò kan tí à ń pè ní “tán-ánná. Tán-ánná wà nínú ilé ọmọ. Ilé ọmọ sì wà nínú ikùn obìnrin. Ọmọ tí a bí tí ó ṣe pé inú àpò ni ó wà láti inú ìyá rẹ̀ ni Yorùbá ń pè ní “ọ̀kẹ́”. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọmọ ló jẹ́ pé, tán-ánná tirẹ̀ máa yọ́ sínú ẹjẹ̀ ìbímọ.
التفاسير العربية:
إِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنكُمۡۖ وَلَا يَرۡضَىٰ لِعِبَادِهِ ٱلۡكُفۡرَۖ وَإِن تَشۡكُرُواْ يَرۡضَهُ لَكُمۡۗ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرۡجِعُكُمۡ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Tí ẹ bá ṣàì moore, dájúdájú Allāhu rọrọ̀ láì sí ẹ̀yin (kò sì ní bùkátà si yín). Kò sì yọ́nú sí àìmoore fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Tí ẹ bá dúpẹ́, Ó máa yọ́nú sí i fún yín. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
التفاسير العربية:
۞ وَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ضُرّٞ دَعَا رَبَّهُۥ مُنِيبًا إِلَيۡهِ ثُمَّ إِذَا خَوَّلَهُۥ نِعۡمَةٗ مِّنۡهُ نَسِيَ مَا كَانَ يَدۡعُوٓاْ إِلَيۡهِ مِن قَبۡلُ وَجَعَلَ لِلَّهِ أَندَادٗا لِّيُضِلَّ عَن سَبِيلِهِۦۚ قُلۡ تَمَتَّعۡ بِكُفۡرِكَ قَلِيلًا إِنَّكَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلنَّارِ
Nígbà tí ìnira kan bá fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pe Olúwa rẹ̀ lẹ́ni tí ó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ó bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ó máa gbàgbé ohun tó ṣe ní àdúà sí (Olúwa rẹ) ṣíwájú. Ó sì máa sọ (àwọn ẹ̀dá kan) di akẹgbẹ́ fún Allāhu nítorí kí ó lè kó ìṣìnà bá (ẹlòmíìràn) ní ojú ọ̀nà ẹ̀sìn Rẹ̀ (’Islām). Sọ pé: “Fi àìgbàgbọ́ rẹ jẹ̀gbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn èrò inú Iná.”
التفاسير العربية:
أَمَّنۡ هُوَ قَٰنِتٌ ءَانَآءَ ٱلَّيۡلِ سَاجِدٗا وَقَآئِمٗا يَحۡذَرُ ٱلۡأٓخِرَةَ وَيَرۡجُواْ رَحۡمَةَ رَبِّهِۦۗ قُلۡ هَلۡ يَسۡتَوِي ٱلَّذِينَ يَعۡلَمُونَ وَٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَۗ إِنَّمَا يَتَذَكَّرُ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Ǹjẹ́ ẹni tí ó jẹ́ olùtẹ̀lé ti Allāhu (tó jẹ́) olùforíkanlẹ̀ àti olùdìdedúró (lórí ìrun kíkí) ní àwọn àkókò alẹ́, tó ń ṣọ́ra fún ọ̀run, tó sì ń ní àgbẹ́kẹ̀lé nínú àánú Olúwa rẹ̀ (dà bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bí?) Sọ pé: “Ǹjẹ́ àwọn tí wọ́n nímọ̀ àti àwọn tí kò nímọ̀ dọ́gba bí? Àwọn onílàákàyè nìkan l’ó ń lo ìrántí.
التفاسير العربية:
قُلۡ يَٰعِبَادِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡۚ لِلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٞۗ وَأَرۡضُ ٱللَّهِ وَٰسِعَةٌۗ إِنَّمَا يُوَفَّى ٱلصَّٰبِرُونَ أَجۡرَهُم بِغَيۡرِ حِسَابٖ
Sọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Ẹ̀san rere wà fún àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí.¹ Ilẹ̀ Allāhu sì gbòòrò.² Àwọn onísùúrù ni Wọ́n sì máa fún ní ẹ̀san (rere iṣẹ́) wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ láì níí ní ìṣírò.”³
1. Ó tún túmọ̀ sí “Àwọn tó ṣe rere ní ilé ayé yìí, ẹ̀san rere wà fún wọn.” Pẹ̀lú ìtúmọ̀ àkọ́kọ́, ẹ̀san rere dúró fún “àlàáfíà àti ìlera nílé ayé yìí”. Pẹ̀lú ìtúmọ̀ kejì, ẹ̀san rere dúró fún “Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ọ̀run”.
2. Ìyẹn ni pé, bí ṣíṣe ẹ̀sìn Allāhu ’Islām, kò bá rọrùn ní àdúgbò tàbí ìlú kan, ẹ kúrò níbẹ̀, kí ẹ lọ máa ṣe ẹ̀sìn yín ní àyè mìíràn tí ó rọrùn.
3. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:212.
التفاسير العربية:
قُلۡ إِنِّيٓ أُمِرۡتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱللَّهَ مُخۡلِصٗا لَّهُ ٱلدِّينَ
Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g jọ́sìn fún Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 2.
التفاسير العربية:
وَأُمِرۡتُ لِأَنۡ أَكُونَ أَوَّلَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ
Wọ́n tún pa mí ní àṣẹ pé kí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ (nínú) àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi).”¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.
التفاسير العربية:
قُلۡ إِنِّيٓ أَخَافُ إِنۡ عَصَيۡتُ رَبِّي عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ
Sọ pé: “Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá, tí mo bá fi lè yapa àṣẹ Olúwa mi.”
التفاسير العربية:
قُلِ ٱللَّهَ أَعۡبُدُ مُخۡلِصٗا لَّهُۥ دِينِي
Sọ pé: “Allāhu ni èmi yóò máa jọ́sìn fún lẹ́ni tí èmi yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn mi fún Un
التفاسير العربية:
فَٱعۡبُدُواْ مَا شِئۡتُم مِّن دُونِهِۦۗ قُلۡ إِنَّ ٱلۡخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَأَهۡلِيهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَا ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡخُسۡرَانُ ٱلۡمُبِينُ
Ẹ̀yin ẹ jọ́sìn fún ohun tí ẹ bá fẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀.”¹ Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ará ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́! Ìyẹn, òhun ni òfò pọ́nńbélé.”
1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀yin ẹ ṣe ohun tí ó bá wù yín. Kò kúkú sí ohun tí kò ní ẹ̀san.
التفاسير العربية:
لَهُم مِّن فَوۡقِهِمۡ ظُلَلٞ مِّنَ ٱلنَّارِ وَمِن تَحۡتِهِمۡ ظُلَلٞۚ ذَٰلِكَ يُخَوِّفُ ٱللَّهُ بِهِۦ عِبَادَهُۥۚ يَٰعِبَادِ فَٱتَّقُونِ
Àwọn àjà Iná máa wà ní òkè wọn. Àwọn àjà yó sì wà ní ìsàlẹ̀ wọn. Ìyẹn ni Allāhu fi ń dẹ́rù ba àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ (báyìí pé:) “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, ẹ bẹ̀rù Mi.”
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ ٱجۡتَنَبُواْ ٱلطَّٰغُوتَ أَن يَعۡبُدُوهَا وَأَنَابُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ لَهُمُ ٱلۡبُشۡرَىٰۚ فَبَشِّرۡ عِبَادِ
Àwọn tí wọ́n takété sí àwọn òrìṣà tí wọn kò jọ́sìn fún un,¹ wọ́n sì ṣẹ́rí padà sí (jíjọ́sìn fún) Allāhu, ìró ìdùnnú ń bẹ fún wọn. Nítorí náà, fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró ìdùnnú.
1. A tún lè túmọ̀ rẹ̀ báyìí pé, “Àwọn tí wọ́n takété sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà”. Ìyẹn ni pé, àwọn tí kò bọ òrìṣà, àwọn tí kì í ṣe ẹlẹbọ́.
التفاسير العربية:
ٱلَّذِينَ يَسۡتَمِعُونَ ٱلۡقَوۡلَ فَيَتَّبِعُونَ أَحۡسَنَهُۥٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ هَدَىٰهُمُ ٱللَّهُۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمۡ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Àwọn tó ń tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé èyí tó dára jùlọ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu fi mọ̀nà. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onílàákàyè.
التفاسير العربية:
أَفَمَنۡ حَقَّ عَلَيۡهِ كَلِمَةُ ٱلۡعَذَابِ أَفَأَنتَ تُنقِذُ مَن فِي ٱلنَّارِ
Ṣé ẹni tí ọ̀rọ̀ ìyà Iná ti kòlé lórí (nípa àìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣé kò níí wọná ni?) Ṣé ìwọ l’ó máa la ẹni tó wà nínú Iná (nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ rẹ̀) ni?
التفاسير العربية:
لَٰكِنِ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ لَهُمۡ غُرَفٞ مِّن فَوۡقِهَا غُرَفٞ مَّبۡنِيَّةٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ لَا يُخۡلِفُ ٱللَّهُ ٱلۡمِيعَادَ
Ṣùgbọ́n àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn, tiwọn ni àwọn ilé gíga, tí àwọn ilé gíga tún wà lókè rẹ̀, àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Àdéhùn Allāhu ni (èyí). Allāhu kò sì níí yẹ àdéhùn náà.
التفاسير العربية:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَسَلَكَهُۥ يَنَٰبِيعَ فِي ٱلۡأَرۡضِ ثُمَّ يُخۡرِجُ بِهِۦ زَرۡعٗا مُّخۡتَلِفًا أَلۡوَٰنُهُۥ ثُمَّ يَهِيجُ فَتَرَىٰهُ مُصۡفَرّٗا ثُمَّ يَجۡعَلُهُۥ حُطَٰمًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
Ṣé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu l’Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, Ó sì mú omi náà wọnú àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú nínú ilẹ̀, lẹ́yìn náà, Ó ń fi mú irúgbìn tí àwọ̀ wọn yàtọ̀ síra wọn jáde, lẹ́yìn náà, (irúgbìn náà) yóò gbẹ, o sì máa rí i ní pípọ́n, lẹ́yìn náà, Ó máa sọ ọ́ di rírún? Dájúdájú ìrántí wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.
التفاسير العربية:
أَفَمَن شَرَحَ ٱللَّهُ صَدۡرَهُۥ لِلۡإِسۡلَٰمِ فَهُوَ عَلَىٰ نُورٖ مِّن رَّبِّهِۦۚ فَوَيۡلٞ لِّلۡقَٰسِيَةِ قُلُوبُهُم مِّن ذِكۡرِ ٱللَّهِۚ أُوْلَٰٓئِكَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
Ǹjẹ́ ẹni tí Allāhu gba ọkàn rẹ̀ láàyè fún ẹ̀sìn ’Islām, tí ó sì wà nínú ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (dà bí aláìgbàgbọ́ bí)? Ègbé ni fún àwọn tí ọkàn wọn le sí ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
التفاسير العربية:
ٱللَّهُ نَزَّلَ أَحۡسَنَ ٱلۡحَدِيثِ كِتَٰبٗا مُّتَشَٰبِهٗا مَّثَانِيَ تَقۡشَعِرُّ مِنۡهُ جُلُودُ ٱلَّذِينَ يَخۡشَوۡنَ رَبَّهُمۡ ثُمَّ تَلِينُ جُلُودُهُمۡ وَقُلُوبُهُمۡ إِلَىٰ ذِكۡرِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُدَى ٱللَّهِ يَهۡدِي بِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٍ
Allāhu l’Ó sọ ọ̀rọ̀ tó dára jùlọ kalẹ̀, (ó jẹ́) Tírà, tí (àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀) jọra wọn ní ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ, tí awọ ara àwọn tó ń páyà Olúwa wọn yó sì máa wárìrì nítorí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, awọ ara wọn àti ọkàn wọn yóò máa rọ̀ níbi ìrántí Allāhu. Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò sí níí sí afinimọ̀nà kan fún un.
التفاسير العربية:
أَفَمَن يَتَّقِي بِوَجۡهِهِۦ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَقِيلَ لِلظَّٰلِمِينَ ذُوقُواْ مَا كُنتُمۡ تَكۡسِبُونَ
Ǹjẹ́ ẹni tí ó máa fojú ara rẹ̀ ko aburú ìyà Iná ní Ọjọ́ Àjíǹde (dà bí ẹni tí ó máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wọ́ọ́rọ́wọ́)? Wọn yó sì sọ fún àwọn alábòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò.”
التفاسير العربية:
كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَأَتَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ
Àwọn tó ṣíwájú wọn pe òdodo ní irọ́. Nítorí náà, ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.
التفاسير العربية:
فَأَذَاقَهُمُ ٱللَّهُ ٱلۡخِزۡيَ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَكۡبَرُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ
Allāhu fún wọn ní àbùkù ìyà tọ́ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọ̀run sì tóbi jùlọ tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ ضَرَبۡنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٖ لَّعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ
A sì ti ṣe gbogbo àkàwé (àpèjúwe àti àpẹ̀ẹrẹ) fún àwọn ènìyàn nínú al-Ƙur’ān yìí nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí
التفاسير العربية:
قُرۡءَانًا عَرَبِيًّا غَيۡرَ ذِي عِوَجٖ لَّعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ
Al-Ƙur’ān (tí A sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú) èdè Lárúbáwá, èyí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò dojú rú nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).
التفاسير العربية:
ضَرَبَ ٱللَّهُ مَثَلٗا رَّجُلٗا فِيهِ شُرَكَآءُ مُتَشَٰكِسُونَ وَرَجُلٗا سَلَمٗا لِّرَجُلٍ هَلۡ يَسۡتَوِيَانِ مَثَلًاۚ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Allāhu fi àkàwé kan lélẹ̀; ẹrúkùnrin kan tó wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gá púpọ̀ tí wọ́n ń ṣe ìfàn̄fà lórí rẹ̀ (kò sì mọ ta ni ó máa dá lóhùn nínú àwọn ọ̀gá rẹ̀) àti (àkàwé) ẹrúkùnrin kan tó dá wà gédégbé lábẹ́ ọ̀gákùnrin kan. Ǹjẹ́ àwọn (ẹrú) méjèèjì dọ́gba ní àkàwé bí? Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
التفاسير العربية:
إِنَّكَ مَيِّتٞ وَإِنَّهُم مَّيِّتُونَ
Dájúdájú ìwọ máa kú. Dájúdájú àwọn náà máa kú.
التفاسير العربية:
ثُمَّ إِنَّكُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عِندَ رَبِّكُمۡ تَخۡتَصِمُونَ
Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bá ara yín ṣe àríyànjiyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín.
التفاسير العربية:
۞ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن كَذَبَ عَلَى ٱللَّهِ وَكَذَّبَ بِٱلصِّدۡقِ إِذۡ جَآءَهُۥٓۚ أَلَيۡسَ فِي جَهَنَّمَ مَثۡوٗى لِّلۡكَٰفِرِينَ
Nítorí náà, ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tó parọ́ mọ́ Allāhu, tó tún pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé kì í ṣe Iná ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِي جَآءَ بِٱلصِّدۡقِ وَصَدَّقَ بِهِۦٓ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُتَّقُونَ
Ẹni tí ó sì mú òdodo wá (ìyẹn, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) àti (àwọn) ẹni tó jẹ́rìí sí òdodo náà; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùbẹ̀rù (Allāhu).
التفاسير العربية:
لَهُم مَّا يَشَآءُونَ عِندَ رَبِّهِمۡۚ ذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn ẹni rere
التفاسير العربية:
لِيُكَفِّرَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ أَسۡوَأَ ٱلَّذِي عَمِلُواْ وَيَجۡزِيَهُمۡ أَجۡرَهُم بِأَحۡسَنِ ٱلَّذِي كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
nítorí kí Allāhu lè bá wọn pa aburú tí wọ́n ṣe níṣẹ́ rẹ́ àti (nítorí) kí Ó lè fi èyí tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n ní ẹ̀san wọn.
التفاسير العربية:
أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِكَافٍ عَبۡدَهُۥۖ وَيُخَوِّفُونَكَ بِٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦۚ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٖ
Ṣé Allāhu kò tó fún ẹrúsìn Rẹ̀ ni? Wọ́n sì ń fi àwọn ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́! Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.
التفاسير العربية:
وَمَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّضِلٍّۗ أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِعَزِيزٖ ذِي ٱنتِقَامٖ
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), kò lè sí aṣinilọ́nà fún un. Ṣé Allāhu kọ́ ni Alágbára, Olùgba-ẹ̀san?
التفاسير العربية:
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۚ قُلۡ أَفَرَءَيۡتُم مَّا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ إِنۡ أَرَادَنِيَ ٱللَّهُ بِضُرٍّ هَلۡ هُنَّ كَٰشِفَٰتُ ضُرِّهِۦٓ أَوۡ أَرَادَنِي بِرَحۡمَةٍ هَلۡ هُنَّ مُمۡسِكَٰتُ رَحۡمَتِهِۦۚ قُلۡ حَسۡبِيَ ٱللَّهُۖ عَلَيۡهِ يَتَوَكَّلُ ٱلۡمُتَوَكِّلُونَ
Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, tí Allāhu bá gbèrò ìnira kan rò mí, ǹjẹ́ wọ́n lè mú ìnira Rẹ̀ kúrò fún mi? Tàbí tí Ó bá gbèrò ìkẹ́ kan sí mi, ǹjẹ́ wọ́n lè dá ìkẹ́ Rẹ̀ dúró bí?” Sọ pé: “Allāhu tó fún mi. Òun sì ni àwọn olùgbáralé ń gbáralé.”
التفاسير العربية:
قُلۡ يَٰقَوۡمِ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنِّي عَٰمِلٞۖ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ
Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣe tiyín ní àyè yín. Èmi náà ń ṣe tèmi. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ
التفاسير العربية:
مَن يَأۡتِيهِ عَذَابٞ يُخۡزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيۡهِ عَذَابٞ مُّقِيمٌ
ẹni tí ìyà tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀ máa dé bá, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí.”
التفاسير العربية:
إِنَّآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ لِلنَّاسِ بِٱلۡحَقِّۖ فَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٍ
Dájúdájú Àwa sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ pẹ̀lú òdodo (kí o lè fi ṣe ìrántí) fún àwọn ènìyàn. Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn.
التفاسير العربية:
ٱللَّهُ يَتَوَفَّى ٱلۡأَنفُسَ حِينَ مَوۡتِهَا وَٱلَّتِي لَمۡ تَمُتۡ فِي مَنَامِهَاۖ فَيُمۡسِكُ ٱلَّتِي قَضَىٰ عَلَيۡهَا ٱلۡمَوۡتَ وَيُرۡسِلُ ٱلۡأُخۡرَىٰٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمًّىۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ
Allāhu l’Ó ń gba àwọn ẹ̀mí ní àkókò ikú wọn àti (àwọn ẹ̀mí) tí kò kú sójú oorun wọn. Ó ń mú (àwọn ẹ̀mí) tí Ó ti pèbùbù ikú lé lórí mọ́lẹ̀. Ó sì ń fi àwọn yòókù sílẹ̀ títí di gbèdéke àkókò kan. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní àròjinlẹ̀.
التفاسير العربية:
أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُفَعَآءَۚ قُلۡ أَوَلَوۡ كَانُواْ لَا يَمۡلِكُونَ شَيۡـٔٗا وَلَا يَعۡقِلُونَ
Tàbí wọ́n mú àwọn olùṣìpẹ̀ mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni? Sọ pé: “(Wọ́n mú wọn ní olùṣìpẹ̀) tó sì jẹ́ pé wọn kò ní agbára kan kan, wọn kò sì níí làákàyè!”
التفاسير العربية:
قُل لِّلَّهِ ٱلشَّفَٰعَةُ جَمِيعٗاۖ لَّهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Sọ pé: “Ti Allāhu ni gbogbo ìṣìpẹ̀ pátápátá. TiRẹ̀ ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.”
التفاسير العربية:
وَإِذَا ذُكِرَ ٱللَّهُ وَحۡدَهُ ٱشۡمَأَزَّتۡ قُلُوبُ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِۖ وَإِذَا ذُكِرَ ٱلَّذِينَ مِن دُونِهِۦٓ إِذَا هُمۡ يَسۡتَبۡشِرُونَ
Nígbà tí wọ́n bá dárúkọ Allāhu nìkan ṣoṣo, ọkàn àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn máa sá kúrò (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Nígbà tí wọ́n bá sì dárúkọ àwọn mìíràn (tí wọ́n ń jọ́sìn fún) lẹ́yìn Rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa dunnú.
التفاسير العربية:
قُلِ ٱللَّهُمَّ فَاطِرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ عَٰلِمَ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ أَنتَ تَحۡكُمُ بَيۡنَ عِبَادِكَ فِي مَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ
Sọ pé: “Allāhu, Olúpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba, Ìwọ l’O máa dájọ́ láààrin àwọn ẹrúsìn Rẹ nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.”
التفاسير العربية:
وَلَوۡ أَنَّ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا وَمِثۡلَهُۥ مَعَهُۥ لَٱفۡتَدَوۡاْ بِهِۦ مِن سُوٓءِ ٱلۡعَذَابِ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَبَدَا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مَا لَمۡ يَكُونُواْ يَحۡتَسِبُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú gbogbo n̄ǹkan tí ó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ ti àwọn alábòsí àti irú rẹ̀ mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ (tún jẹ́ tiwọn ni), wọn ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara wọn) níbi aburú ìyà ní Ọjọ́ Àjíǹde. (Nígbà yẹn) ohun tí wọn kò lérò máa hàn sí wọn ní ọ̀dọ̀ Allāhu;
التفاسير العربية:
وَبَدَا لَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُواْ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Àwọn aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ máa hàn sí wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà tó máa yí wọn po.
التفاسير العربية:
فَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ضُرّٞ دَعَانَا ثُمَّ إِذَا خَوَّلۡنَٰهُ نِعۡمَةٗ مِّنَّا قَالَ إِنَّمَآ أُوتِيتُهُۥ عَلَىٰ عِلۡمِۭۚ بَلۡ هِيَ فِتۡنَةٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ
Nígbà tí ìnira kan ba fọwọ́ ba ènìyàn, ó máa pè Wá. Lẹ́yìn náà, nígbà tí A bá fún un ní ìdẹ̀ra kan láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa wí pé: “Wọ́n fún mi pẹ̀lú ìmọ̀ ni.”¹ Kò sì rí bẹ́ẹ̀, àdánwò ni, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.
1. Ìyẹn ni pé, òun mọ̀ ọ́n ṣe ni tòun fi gún. Dípò kí ó moore sí Allāhu, kí ó dúpẹ́ fún Un, kí ó sì mọ̀ pé Allāhu fẹ́ bẹ́ẹ̀ fún un ni nínú kádàrá Rẹ̀ lórí rẹ̀.
التفاسير العربية:
قَدۡ قَالَهَا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú wí (irú) rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀.
التفاسير العربية:
فَأَصَابَهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُواْۚ وَٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡ هَٰٓؤُلَآءِ سَيُصِيبُهُمۡ سَيِّـَٔاتُ مَا كَسَبُواْ وَمَا هُم بِمُعۡجِزِينَ
Aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ sì bá wọn. Àwọn alábòsí nínú àwọn wọ̀nyí náà, aburú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ yóò bá wọn. Wọn kò sì níí mórí bọ́.
التفاسير العربية:
أَوَلَمۡ يَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
التفاسير العربية:
۞ قُلۡ يَٰعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ أَسۡرَفُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ لَا تَقۡنَطُواْ مِن رَّحۡمَةِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَغۡفِرُ ٱلذُّنُوبَ جَمِيعًاۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Sọ pé: “Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ sí ẹ̀mí ara yín lọ́rùn, ẹ má ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń ṣàforíjìn gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
التفاسير العربية:
وَأَنِيبُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ وَأَسۡلِمُواْ لَهُۥ مِن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلۡعَذَابُ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ
Ẹ ṣẹ́rí padà (ní ti ìronúpìwàdà) sí ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Kí ẹ sì juwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Un ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín. (Bí bẹ́ẹ̀ kọ́) lẹ́yìn náà, A kò níí ràn yín lọ́wọ́.
التفاسير العربية:
وَٱتَّبِعُوٓاْ أَحۡسَنَ مَآ أُنزِلَ إِلَيۡكُم مِّن رَّبِّكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلۡعَذَابُ بَغۡتَةٗ وَأَنتُمۡ لَا تَشۡعُرُونَ
Kí ẹ sì tẹ̀lé ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ṣíwájú kí ìyà náà tó wá ba yín ní òjijì, nígbà tí ẹ̀yin kò níí fura.”
التفاسير العربية:
أَن تَقُولَ نَفۡسٞ يَٰحَسۡرَتَىٰ عَلَىٰ مَا فَرَّطتُ فِي جَنۢبِ ٱللَّهِ وَإِن كُنتُ لَمِنَ ٱلسَّٰخِرِينَ
Nítorí kí ẹ̀mí kan má baà wí pé: “Mo ká àbámọ̀ lórí bí mo ṣe jáfara lórí àìtẹ̀lé àṣẹ Allāhu. Àti pé èmi wà nínú àwọn tó ń fi (ọ̀rọ̀ Rẹ̀) ṣe yẹ̀yẹ́.”
التفاسير العربية:
أَوۡ تَقُولَ لَوۡ أَنَّ ٱللَّهَ هَدَىٰنِي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُتَّقِينَ
Tàbí kí ó má baà wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu fi ọ̀nà mọ̀ mí ni, dájúdájú èmi ìbá wà nínú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).”
التفاسير العربية:
أَوۡ تَقُولَ حِينَ تَرَى ٱلۡعَذَابَ لَوۡ أَنَّ لِي كَرَّةٗ فَأَكُونَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Tàbí nígbà tí ó bá rí Iná kí ó má baà wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ìpadàsáyé wà fún mi ni, èmi ìbá sì wà nínú àwọn olùṣe-rere.”
التفاسير العربية:
بَلَىٰ قَدۡ جَآءَتۡكَ ءَايَٰتِي فَكَذَّبۡتَ بِهَا وَٱسۡتَكۡبَرۡتَ وَكُنتَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Bẹ́ẹ̀ ni! Àwọn āyah Mi kúkú ti dé bá ọ. O pè é ní irọ́. O tún ṣègbéraga. O sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́. ¹
1. Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (58 àti 59) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:99 - 100.
التفاسير العربية:
وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ تَرَى ٱلَّذِينَ كَذَبُواْ عَلَى ٱللَّهِ وُجُوهُهُم مُّسۡوَدَّةٌۚ أَلَيۡسَ فِي جَهَنَّمَ مَثۡوٗى لِّلۡمُتَكَبِّرِينَ
Àti pé ní Ọjọ́ Àjíǹde, o máa rí àwọn tó parọ́ mọ́ Allāhu tí ojú wọn máa dúdú. Ṣé inú iná Jahnamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn onígbèéraga ni?
التفاسير العربية:
وَيُنَجِّي ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ بِمَفَازَتِهِمۡ لَا يَمَسُّهُمُ ٱلسُّوٓءُ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
Allāhu yóò gba àwọn tó bẹ̀rù (Rẹ̀) là sínú ilé ìgbàlà wọn (ìyẹn, Ọgbà Ìdẹ̀ra). Aburú náà kò níí fọwọ́ bà wọ́n. Wọn kò sì níí banújẹ́.
التفاسير العربية:
ٱللَّهُ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٞ
Allāhu ni Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
التفاسير العربية:
لَّهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ilé-ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.
التفاسير العربية:
قُلۡ أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَأۡمُرُوٓنِّيٓ أَعۡبُدُ أَيُّهَا ٱلۡجَٰهِلُونَ
Sọ pé: “Ṣé n̄ǹkan mìíràn yàtọ̀ sí Allāhu l’ẹ̀ ń pa mí lásẹ pé kí n̄g máa jọ́sìn fún, ẹ̀yin aláìmọ̀kan?”
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ أُوحِيَ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ لَئِنۡ أَشۡرَكۡتَ لَيَحۡبَطَنَّ عَمَلُكَ وَلَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ
Dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ (pé) “Dájúdájú tí o bá ṣẹbọ, iṣẹ́ rẹ máa bàjẹ́. Dájúdájú o sì máa wà nínú àwọn ẹni òfò.”
التفاسير العربية:
بَلِ ٱللَّهَ فَٱعۡبُدۡ وَكُن مِّنَ ٱلشَّٰكِرِينَ
Rárá (má ṣẹbọ). Allāhu nìkan ni kí o jọ́sìn fún. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un).
التفاسير العربية:
وَمَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦ وَٱلۡأَرۡضُ جَمِيعٗا قَبۡضَتُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَٱلسَّمَٰوَٰتُ مَطۡوِيَّٰتُۢ بِيَمِينِهِۦۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Wọn kò bu iyì fún Allāhu bí ó ṣe tọ́ láti bu iyì fún Un. Gbogbo ilẹ̀ pátápátá sì ni (Allāhu) máa fọwọ́ ara Rẹ̀ gbámú ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa fi ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ká àwọn sánmọ̀ kóróbójó. Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
التفاسير العربية:
وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَصَعِقَ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا مَن شَآءَ ٱللَّهُۖ ثُمَّ نُفِخَ فِيهِ أُخۡرَىٰ فَإِذَا هُمۡ قِيَامٞ يَنظُرُونَ
Wọ́n á fọn fèrè oníwo (fún ikú). Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ sì máa kú àfi ẹni tí Allāhu bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fọn ọ́n ní ẹ̀ẹ̀ kejì, nígbà náà wọ́n máa wà ní ìdìde. Wọn yó sì máa wò sùn.
التفاسير العربية:
وَأَشۡرَقَتِ ٱلۡأَرۡضُ بِنُورِ رَبِّهَا وَوُضِعَ ٱلۡكِتَٰبُ وَجِاْيٓءَ بِٱلنَّبِيِّـۧنَ وَٱلشُّهَدَآءِ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Àti pé ilẹ̀ náà yóò máa tàn yànrànyànràn pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ Olúwa rẹ̀. Wọ́n máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá lélẹ̀. Wọ́n sì máa mú àwọn Ànábì àti àwọn ẹlẹ́rìí wá. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wọn. A kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
التفاسير العربية:
وَوُفِّيَتۡ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا عَمِلَتۡ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِمَا يَفۡعَلُونَ
Àti pé Wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
التفاسير العربية:
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِلَىٰ جَهَنَّمَ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا فُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَآ أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ رُسُلٞ مِّنكُمۡ يَتۡلُونَ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِ رَبِّكُمۡ وَيُنذِرُونَكُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَاۚ قَالُواْ بَلَىٰ وَلَٰكِنۡ حَقَّتۡ كَلِمَةُ ٱلۡعَذَابِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Wọn yó sì da àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lọ sínú iná Jahanamọ níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: “Ǹjẹ́ àwọn Òjíṣẹ́ kan kò wá ba yín láti ààrin ara yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Olúwa yín fún yín, tí wọ́n sì ń kìlọ̀ ìpàdé ọjọ́ yín òní yìí fún yín?” Wọ́n wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (wọ́n wá bá wa).” Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ìyà kò lé àwọn aláìgbàgbọ́ lórí ni.
التفاسير العربية:
قِيلَ ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ
A óò sọ pé: “Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀nà iná Jahanamọ. Olùṣegbére (ni yín) nínú rẹ̀. Ibùgbé àwọn onígbèéraga sì burú.
التفاسير العربية:
وَسِيقَ ٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ رَبَّهُمۡ إِلَى ٱلۡجَنَّةِ زُمَرًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوهَا وَفُتِحَتۡ أَبۡوَٰبُهَا وَقَالَ لَهُمۡ خَزَنَتُهَا سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡ طِبۡتُمۡ فَٱدۡخُلُوهَا خَٰلِدِينَ
Àti pé A óò kó àwọn tó bẹ̀rù Olúwa wọn lọ sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra níjọníjọ, títí di ìgbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọ́n máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ (fún wọn). Àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ yó sì sọ fún wọn pé: “Kí àlàáfíà máa ba yín. Ẹ̀yin dára (nítorí iṣẹ́ yín tó dára). Nítorí náà, ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, (kí ẹ di) olùṣegbére(nínú rẹ̀).”¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé āyah wọ̀nyí, āyah 71 títí dé āyah 73, tako sūrah Mọryam; 19:71. Èsì rẹ̀ ti wà nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 71 yẹn nínú sūrah Mọryam.
التفاسير العربية:
وَقَالُواْ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي صَدَقَنَا وَعۡدَهُۥ وَأَوۡرَثَنَا ٱلۡأَرۡضَ نَتَبَوَّأُ مِنَ ٱلۡجَنَّةِ حَيۡثُ نَشَآءُۖ فَنِعۡمَ أَجۡرُ ٱلۡعَٰمِلِينَ
Wọ́n á sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó mú àdéhùn Rẹ̀ ṣẹ fún wa. Ó tún jogún ilẹ̀ náà fún wa, tí à ń gbé níbikíbi tí a bá fẹ́ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere mà sì dára.
التفاسير العربية:
وَتَرَى ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ حَآفِّينَ مِنۡ حَوۡلِ ٱلۡعَرۡشِ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡۚ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡحَقِّۚ وَقِيلَ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
O sì máa rí àwọn Mọlāika tí wọ́n ń rọkiriká ní àyíká Ìtẹ́-ọlá. Wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. A máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin àwọn ẹ̀dá. Wọ́n sì máa sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: الزمر
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق