ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: غافر   آية:

سورة غافر - Suuratu Gaafir

حمٓ
Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
التفاسير العربية:
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Onímọ̀,
التفاسير العربية:
غَافِرِ ٱلذَّنۢبِ وَقَابِلِ ٱلتَّوۡبِ شَدِيدِ ٱلۡعِقَابِ ذِي ٱلطَّوۡلِۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ إِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ
Aláforíjìn-ẹ̀ṣẹ̀, Olùgba-ìronúpìwàdà, Ẹni líle níbi ìyà, Ọlọ́rẹ, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni àbọ̀ ẹ̀dá.
التفاسير العربية:
مَا يُجَٰدِلُ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَا يَغۡرُرۡكَ تَقَلُّبُهُمۡ فِي ٱلۡبِلَٰدِ
Kò sí ẹni tí ó máa ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu àfi àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ìgbòkègbodò wọn nínú ìlú kó ẹ̀tàn bá ọ.
التفاسير العربية:
كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ وَٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۖ وَهَمَّتۡ كُلُّ أُمَّةِۭ بِرَسُولِهِمۡ لِيَأۡخُذُوهُۖ وَجَٰدَلُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّ فَأَخَذۡتُهُمۡۖ فَكَيۡفَ كَانَ عِقَابِ
Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Àwọn ìjọ (mìíràn) lẹ́yìn wọn (náà ṣe bẹ́ẹ̀). Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló gbèrò láti ki Òjíṣẹ́ wọn mọ́lẹ̀. Wọ́n fi irọ́ ja òdodo níyàn nítorí kí wọ́n lè fi wó òdodo lulẹ̀. Mo sì gbá wọn mú. Nítorí náà, báwo ni ìyà (tí Mo fi jẹ wọ́n) ti rí (lára wọn ná)!
التفاسير العربية:
وَكَذَٰلِكَ حَقَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ
Àti pé báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe kò lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ pé: “Dájúdájú àwọn ni èrò inú Iná.”
التفاسير العربية:
ٱلَّذِينَ يَحۡمِلُونَ ٱلۡعَرۡشَ وَمَنۡ حَوۡلَهُۥ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيُؤۡمِنُونَ بِهِۦ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْۖ رَبَّنَا وَسِعۡتَ كُلَّ شَيۡءٖ رَّحۡمَةٗ وَعِلۡمٗا فَٱغۡفِرۡ لِلَّذِينَ تَابُواْ وَٱتَّبَعُواْ سَبِيلَكَ وَقِهِمۡ عَذَابَ ٱلۡجَحِيمِ
Àwọn tó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): “Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.
التفاسير العربية:
رَبَّنَا وَأَدۡخِلۡهُمۡ جَنَّٰتِ عَدۡنٍ ٱلَّتِي وَعَدتَّهُمۡ وَمَن صَلَحَ مِنۡ ءَابَآئِهِمۡ وَأَزۡوَٰجِهِمۡ وَذُرِّيَّٰتِهِمۡۚ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Olúwa wa, fi wọ́n sínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére èyí tí Ó ṣe ní àdéhùn fún àwọn àti ẹni tó ṣe iṣẹ́ rere nínú àwọn bàbá wọn, àwọn aya wọn àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
التفاسير العربية:
وَقِهِمُ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ وَمَن تَقِ ٱلسَّيِّـَٔاتِ يَوۡمَئِذٖ فَقَدۡ رَحِمۡتَهُۥۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
Ṣọ́ wọn nínú àwọn aburú. Ẹnikẹ́ni tí O bá ṣọ́ níbi àwọn aburú (ìyà) ní ọjọ́ yẹn, dájúdájú O ti kẹ́ ẹ. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá.”
التفاسير العربية:
إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُنَادَوۡنَ لَمَقۡتُ ٱللَّهِ أَكۡبَرُ مِن مَّقۡتِكُمۡ أَنفُسَكُمۡ إِذۡ تُدۡعَوۡنَ إِلَى ٱلۡإِيمَٰنِ فَتَكۡفُرُونَ
Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò pè wọ́n (láti sọ fún wọn nínú Iná pé): “Dájúdájú ìbínú ti Allāhu tóbi ju ìbínú tí ẹ̀ ń bí síra yín (nínú Iná, ṣebí) nígbà tí wọ́n ń pè yín síbi ìgbàgbọ́ òdodo, ńṣe ni ẹ̀ ń ṣàì gbàgbọ́.”
التفاسير العربية:
قَالُواْ رَبَّنَآ أَمَتَّنَا ٱثۡنَتَيۡنِ وَأَحۡيَيۡتَنَا ٱثۡنَتَيۡنِ فَٱعۡتَرَفۡنَا بِذُنُوبِنَا فَهَلۡ إِلَىٰ خُرُوجٖ مِّن سَبِيلٖ
Wọ́n wí pé: “Olúwa wa, O pa wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì. O sì ji wá ní ẹ̀ẹ̀ méjì.¹ Nítorí náà, a jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà láti jáde (padà sí ilé ayé) bí?”
1. Àwọn kan lérò pé, ìtúmọ̀ āyah yìí ni pé, ènìyàn máa wáyé ní ẹ̀ẹ̀ méjì, ó sì máa kú ní ẹ̀ẹ̀ méjì. Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. Ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, ènìyàn wà ní ipò òkú nígbà tí ó jẹ́ aláìsí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ìyẹn ṣíwájú ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ìyẹn ni ikú àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa wà ní ipò alààyè nígbà tí ó bá délé ayé. Ìyẹn ni ìṣẹ̀mí àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó máa di aláìsí nígbà tí ó bá parí òǹkà àkókò tí Allāhu pèbùbù fún un láti lò nílé ayé. Ìyẹn sì ni ikú kejì. Lẹ́yìn náà, ó máa di alààyè ní ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí kú mọ́. Ìyẹn sì ni ìṣẹ̀mí kejì. Èyí ni ìtúmọ̀ āyah náà. Irú āyah yìí sì kúkú ti ṣíwájú nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:28.
التفاسير العربية:
ذَٰلِكُم بِأَنَّهُۥٓ إِذَا دُعِيَ ٱللَّهُ وَحۡدَهُۥ كَفَرۡتُمۡ وَإِن يُشۡرَكۡ بِهِۦ تُؤۡمِنُواْۚ فَٱلۡحُكۡمُ لِلَّهِ ٱلۡعَلِيِّ ٱلۡكَبِيرِ
(Ẹ wà nínú Iná) yẹn nítorí pé dájúdájú nígbà tí wọ́n bá pe Allāhu nìkan ṣoṣo, ẹ̀yin ṣàì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹbọ sí I, ẹ sì máa gbàgbọ́ (nínú ẹbọ). Nítorí náà, ìdájọ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱلَّذِي يُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُنَزِّلُ لَكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ رِزۡقٗاۚ وَمَا يَتَذَكَّرُ إِلَّا مَن يُنِيبُ
Òun ni Ẹni tó ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Ó sì ń sọ arísìkí kalẹ̀ fún yín láti sánmọ̀. Kò sí ẹni tó ń lo ìrántí àfi ẹni tó ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).
التفاسير العربية:
فَٱدۡعُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Nítorí náà, ẹ pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.¹ àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira Rẹ̀.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:29.
التفاسير العربية:
رَفِيعُ ٱلدَّرَجَٰتِ ذُو ٱلۡعَرۡشِ يُلۡقِي ٱلرُّوحَ مِنۡ أَمۡرِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ لِيُنذِرَ يَوۡمَ ٱلتَّلَاقِ
(Allāhu) Ẹni tó ni gbogbo ipò àjùlọ, Olúwa Ìtẹ́-ọlá, Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀¹ nítorì kí ó lè fi ṣèkìlọ̀ nípa Ọjọ́ ìpàdé náà.
1. Kíyè sí n̄ǹkan kan tó lágbára nínú āyah yìí nítorí kí o má baà di kèfèrí. Gbólóhùn yìí, “Ó ń fi ìmísí mímọ́ ránṣẹ́ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ sí ẹni = = tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀”, ìṣe yìí ti dópin nípasẹ̀ bí Allāhu ti ṣe fi Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe òpin gbogbo àwọn tí ó gba ìmísí mímọ́ náà. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-’Ahzāb; 33:40. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tún sọ pé, òun náà wà nínú ẹni tí Allāhu fẹ́ fún rírí ìmísí mímọ́ gbà, òpùrọ́ asòòkùn sẹ́sìn ni onítọ̀ún.
التفاسير العربية:
يَوۡمَ هُم بَٰرِزُونَۖ لَا يَخۡفَىٰ عَلَى ٱللَّهِ مِنۡهُمۡ شَيۡءٞۚ لِّمَنِ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَۖ لِلَّهِ ٱلۡوَٰحِدِ ٱلۡقَهَّارِ
Ní ọjọ́ tí wọn yóò yọ jáde (láti inú sàréè), kiní kan kò sì níí pamọ́ nípa wọn fún Allāhu. (Allāhu yó sì sọ pé): “Ti ta ni ìjọba ní ọjọ́ òní?” Ti Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí ni.
التفاسير العربية:
ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا كَسَبَتۡۚ لَا ظُلۡمَ ٱلۡيَوۡمَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ
Ní òní ni A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Kò sì sí àbòsí kan ní òní. Dájúdájú Allāhu ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.
التفاسير العربية:
وَأَنذِرۡهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡأٓزِفَةِ إِذِ ٱلۡقُلُوبُ لَدَى ٱلۡحَنَاجِرِ كَٰظِمِينَۚ مَا لِلظَّٰلِمِينَ مِنۡ حَمِيمٖ وَلَا شَفِيعٖ يُطَاعُ
Àti pé ṣèkìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó súnmọ́ (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde). Nígbà tí àwọn ọkàn bá ga dé gògòńgò, tí ó máa kún fún ìbànújẹ́, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ àti olùṣìpẹ̀ kan tí wọ́n máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí (ọ̀rọ̀) àwọn alábòsí.
التفاسير العربية:
يَعۡلَمُ خَآئِنَةَ ٱلۡأَعۡيُنِ وَمَا تُخۡفِي ٱلصُّدُورُ
(Allāhu) mọ ojú ìjàǹbá àti ohun tí àwọn ọkàn fi pamọ́.¹
1. Ojú ìjàǹbá ni ojú tó ń yọ́ obìnrin wò ní ọ̀nà àìtọ́ àti àwọn ìwòkíwò mìíràn. Ìyẹn ni pé, ìjàǹbá ni fún ọkùnrin kan láti máa yọ́ obìnrin olóbìnrin wò. Ohun tí ọkàn sì fi pamọ́ ni èrò-ọkàn ọkùnrin náà nípa obìnrin tó ń yọ́ wò àti ohun mìíràn tó wà nínú ọkàn rẹ̀ ní aburú.
التفاسير العربية:
وَٱللَّهُ يَقۡضِي بِٱلۡحَقِّۖ وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ لَا يَقۡضُونَ بِشَيۡءٍۗ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ
Àti pé Allāhu l’Ó máa fi òdodo dájọ́. Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò lè ṣe ìdájọ́ kan kan. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
التفاسير العربية:
۞ أَوَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُواْ هُمۡ أَشَدَّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗ وَءَاثَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُ بِذُنُوبِهِمۡ وَمَا كَانَ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن وَاقٖ
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀ (fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ Allāhu mú wọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kò sì sí olùṣọ́ kan fún wọn (níbi ìyà) Allāhu.
التفاسير العربية:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانَت تَّأۡتِيهِمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَكَفَرُواْ فَأَخَذَهُمُ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ قَوِيّٞ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
Ìyẹn nítorí pé, àwọn Òjíṣẹ́ wọn ń wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́. Nítorí náà, Allāhu mú wọn. Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ẹni líle níbi ìyà.
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ
Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí tó yanjú rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́
التفاسير العربية:
إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَ وَقَٰرُونَ فَقَالُواْ سَٰحِرٞ كَذَّابٞ
sí Fir‘aon àti Hāmọ̄n àti Ƙọ̄rūn. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: “Òpìdán, òpùrọ́ ni (Ànábì Mūsā).”
التفاسير العربية:
فَلَمَّا جَآءَهُم بِٱلۡحَقِّ مِنۡ عِندِنَا قَالُواْ ٱقۡتُلُوٓاْ أَبۡنَآءَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ وَٱسۡتَحۡيُواْ نِسَآءَهُمۡۚ وَمَا كَيۡدُ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلٖ
Nígbà tí ó mú òdodo náà dé ọ̀dọ̀ wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Ẹ pa àwọn ọmọkùnrin àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin wọn sílẹ̀.” Ète àwọn aláìgbàgbọ́ kò sí nínú kiní kan bí kò ṣe nínú ìṣìnà.
التفاسير العربية:
وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ ذَرُونِيٓ أَقۡتُلۡ مُوسَىٰ وَلۡيَدۡعُ رَبَّهُۥٓۖ إِنِّيٓ أَخَافُ أَن يُبَدِّلَ دِينَكُمۡ أَوۡ أَن يُظۡهِرَ فِي ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡفَسَادَ
Fir‘aon wí pé: “Ẹ fi mí sílẹ̀ kí n̄g pa Mūsā, kí ó sì pe Olúwa rẹ̀ (wò bóyá Ó máa gbà á sílẹ̀). Dájúdájú èmi ń bẹ̀rù pé ó máa yí ẹ̀sìn yín padà tàbí pé ó máa ṣàfi hàn ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀.”
التفاسير العربية:
وَقَالَ مُوسَىٰٓ إِنِّي عُذۡتُ بِرَبِّي وَرَبِّكُم مِّن كُلِّ مُتَكَبِّرٖ لَّا يُؤۡمِنُ بِيَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ
(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú èmi sá di Olúwa mi àti Olúwa yín kúrò lọ́wọ́ gbogbo onígbèéraga, tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́.
التفاسير العربية:
وَقَالَ رَجُلٞ مُّؤۡمِنٞ مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَكۡتُمُ إِيمَٰنَهُۥٓ أَتَقۡتُلُونَ رَجُلًا أَن يَقُولَ رَبِّيَ ٱللَّهُ وَقَدۡ جَآءَكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ مِن رَّبِّكُمۡۖ وَإِن يَكُ كَٰذِبٗا فَعَلَيۡهِ كَذِبُهُۥۖ وَإِن يَكُ صَادِقٗا يُصِبۡكُم بَعۡضُ ٱلَّذِي يَعِدُكُمۡۖ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ مُسۡرِفٞ كَذَّابٞ
Ọkùnrin onígbàgbọ́ òdodo kan tó ń fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ pamọ́ nínú àwọn ènìyàn Fir‘aon sọ pé: “Ṣé ẹ máa pa ọkùnrin kan nítorí pé ó ń sọ pé, “Allāhu ni Olúwa mi.” Ó sì kúkú ti mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Tí ó bá jẹ́ òpùrọ́, (ìyà) irọ́ rẹ̀ wà lórí rẹ̀. Tí ó bá sì jẹ́ olódodo, apá kan èyí tí ó ṣe ní ìlérí fún yín yó sì kò le yín lórí. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, òpùrọ́.
التفاسير العربية:
يَٰقَوۡمِ لَكُمُ ٱلۡمُلۡكُ ٱلۡيَوۡمَ ظَٰهِرِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَن يَنصُرُنَا مِنۢ بَأۡسِ ٱللَّهِ إِن جَآءَنَاۚ قَالَ فِرۡعَوۡنُ مَآ أُرِيكُمۡ إِلَّا مَآ أَرَىٰ وَمَآ أَهۡدِيكُمۡ إِلَّا سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ̀yin l’ẹ ni ìjọba lónìí, tí ẹ ga jùlọ lórí ilẹ̀ náà (ìyẹn ilẹ̀ Misrọ). Ṣùgbọ́n ta ni ó máa ràn wá lọ́wọ́ tí ìyà Allāhu bá dé bá wa?” Fir‘aon wí pé: “Èmi kò fi n̄ǹkan kan hàn yín bí kò ṣe ohun tí mo rí (nínú òye mi). Èmi kò sì tọ yín sí ọ̀nà kan bí kò ṣe ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.”
التفاسير العربية:
وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُم مِّثۡلَ يَوۡمِ ٱلۡأَحۡزَابِ
Ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú irú ọjọ́ (ẹ̀san ìyà tó ṣẹlẹ̀ sí) àwọn ọmọ-ogun oníjọ ni èmi ń páyà lórí yín;
التفاسير العربية:
مِثۡلَ دَأۡبِ قَوۡمِ نُوحٖ وَعَادٖ وَثَمُودَ وَٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡۚ وَمَا ٱللَّهُ يُرِيدُ ظُلۡمٗا لِّلۡعِبَادِ
Irú ìṣe (ìparun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn) ènìyàn Nūh, ‘Ād, Thamūd àti àwọn tó tẹ̀lé wọn. Allāhu kò sì gbèrò àbòsí sí àwọn ẹrúsìn náà.
التفاسير العربية:
وَيَٰقَوۡمِ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ يَوۡمَ ٱلتَّنَادِ
Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi ń páyà Ọjọ́ ìpè fún yín.¹
1. Nínú àwọn orúkọ fún Ọjọ́ àjíǹde ni Ọjọ́ ìpè. Ìyẹn ni pé, ọjọ́ tí àwọn mọlāika máa pe àwọn ènìyàn àti àlùjànnú láti sọ fún wọn pé, tí ẹ bá lè sá lọ báyìí, ẹ sá lọ wò. Éyí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah ar-Rahmọ̄n; 55:33. Bákan náà, ìpè máa wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra sí ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Iná. Èyí wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:44. Ìpè tún máa wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Iná sí ọ̀dọ̀ àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Èyí tún wà nínú sūrah al-’A‘rọ̄f; 7:50.
التفاسير العربية:
يَوۡمَ تُوَلُّونَ مُدۡبِرِينَ مَا لَكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنۡ عَاصِمٖۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِنۡ هَادٖ
Ọjọ́ tí ẹ máa pẹ̀yìndà láti sá lọ; kò sì níí sí aláàbò kan fún yín lọ́dọ̀ Allāhu. Àti pé ẹni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un.
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ جَآءَكُمۡ يُوسُفُ مِن قَبۡلُ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَمَا زِلۡتُمۡ فِي شَكّٖ مِّمَّا جَآءَكُم بِهِۦۖ حَتَّىٰٓ إِذَا هَلَكَ قُلۡتُمۡ لَن يَبۡعَثَ ٱللَّهُ مِنۢ بَعۡدِهِۦ رَسُولٗاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَنۡ هُوَ مُسۡرِفٞ مُّرۡتَابٌ
Àti pé dájúdájú (Ànábì) Yūsuf ti tọ̀ yín wá ṣíwájú pẹ̀lú àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ tó yanjú, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yé wà nínú iyèméjì nípa ohun tí ó mú wá ba yín títí di ìgbà tí ó fi kú, tí ẹ fi wí pé: “Allāhu kò níí gbé Òjíṣẹ́ kan dìde mọ́ lẹ́yìn rẹ̀. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ ẹni tí ó jẹ́ aláṣejù, oníyèméjì nù.”
التفاسير العربية:
ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡۖ كَبُرَ مَقۡتًا عِندَ ٱللَّهِ وَعِندَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ يَطۡبَعُ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ قَلۡبِ مُتَكَبِّرٖ جَبَّارٖ
Àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìsí ẹ̀rí kan tí ó dé bá wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni ní ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní ọ̀dọ̀ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Báyẹn ni Allāhu ṣe ń fi èdídí bo gbogbo ọkàn onígbèéraga, ajẹninípá.”
التفاسير العربية:
وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ يَٰهَٰمَٰنُ ٱبۡنِ لِي صَرۡحٗا لَّعَلِّيٓ أَبۡلُغُ ٱلۡأَسۡبَٰبَ
Fir‘aon wí pé: “Hāmọ̄n, mọ ilé gíga fíofío kan fún mi nítorí kí èmi lè dé àwọn ojú ọ̀nà náà.
التفاسير العربية:
أَسۡبَٰبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ فَأَطَّلِعَ إِلَىٰٓ إِلَٰهِ مُوسَىٰ وَإِنِّي لَأَظُنُّهُۥ كَٰذِبٗاۚ وَكَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِفِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ عَمَلِهِۦ وَصُدَّ عَنِ ٱلسَّبِيلِۚ وَمَا كَيۡدُ فِرۡعَوۡنَ إِلَّا فِي تَبَابٖ
Àwọn ojú ọ̀nà (inú) sánmọ̀ ni, nítorí kí èmi lè yọjú wo Ọlọ́hun Mūsā nítorí pé, dájúdájú èmi ń rò ó sí òpùrọ́.” Báyẹn ni wọ́n ṣe iṣẹ́ aburú (ọwọ́) Fir‘aon ní ọ̀ṣọ́ fún un. Wọ́n sì ṣẹ́rí rẹ̀ kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Ète Fir‘aon kò sì wà nínú kiní kan bí kò ṣe nínú òfò.
التفاسير العربية:
وَقَالَ ٱلَّذِيٓ ءَامَنَ يَٰقَوۡمِ ٱتَّبِعُونِ أَهۡدِكُمۡ سَبِيلَ ٱلرَّشَادِ
Ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo tún sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ tẹ̀lé mi, mo máa júwe yín sí ojú ọ̀nà ìmọ̀nà.
التفاسير العربية:
يَٰقَوۡمِ إِنَّمَا هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا مَتَٰعٞ وَإِنَّ ٱلۡأٓخِرَةَ هِيَ دَارُ ٱلۡقَرَارِ
Ẹ̀yin ènìyàn mi, ìgbádùn lásán ni ìṣẹ̀mí ilé ayé yìí. Dájúdájú ọ̀run sì ni ilé gbére.
التفاسير العربية:
مَنۡ عَمِلَ سَيِّئَةٗ فَلَا يُجۡزَىٰٓ إِلَّا مِثۡلَهَاۖ وَمَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا مِّن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ يُرۡزَقُونَ فِيهَا بِغَيۡرِ حِسَابٖ
Ẹni tí ó bá ṣe aburú kan, Wọn kò níí san án ní ẹ̀san kan àyàfi irú rẹ̀. Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ rere ní ọkùnrin tàbí ní obìnrin, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo,¹ àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọn yóò máa pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún wọn nínú rẹ̀ láì níí ní ìṣírò.²
1. Kíyè sí gbólóhùn yìí dáradára “tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo”. Ó ń túmọ̀ sí pé, èyíkéyìí iṣẹ́ rere tí Ànábì kan bá mú wá fún ìjọ rẹ̀, bí ẹni tí kò bá ní ìgbàgbọ́ òdodo ’Islām bá ṣe iṣẹ́ rere náà fún gbogbo ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, Allāhu kò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí náà, májẹ̀mu kan lọ́tọ̀ ni ìgbàgbọ́ òdodo ’Islām jẹ́ lórí ṣíṣe iṣẹ́ rere.
2. Ìyẹn ni pé, ẹ̀san rere tó máa jẹ́ àwọn ìjẹ-ìmu àti àwọn ìgbádùn oníran-ànran ní ọ̀run fún àwọn olùṣe-rere máa pọ̀ gan-an jaburata. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:212.
التفاسير العربية:
۞ وَيَٰقَوۡمِ مَا لِيٓ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلنَّجَوٰةِ وَتَدۡعُونَنِيٓ إِلَى ٱلنَّارِ
Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ló mú yín tí mò ń pè yín síbi ìgbàlà, tí ẹ̀yin sì ń pè mí síbi Iná?
التفاسير العربية:
تَدۡعُونَنِي لِأَكۡفُرَ بِٱللَّهِ وَأُشۡرِكَ بِهِۦ مَا لَيۡسَ لِي بِهِۦ عِلۡمٞ وَأَنَا۠ أَدۡعُوكُمۡ إِلَى ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡغَفَّٰرِ
Ẹ̀yin ń pè mí pé kí n̄g ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu, kí n̄g sì sọ n̄ǹkan tí èmi kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Un.¹ Èmi sì ń pè yín sí ọ̀dọ̀ Alágbára, Aláforíjìn.
1. Sísọ n̄ǹkan tí ẹ̀dá kò nímọ̀ nípa rẹ̀ di akẹgbẹ́ fún Allāhu - Ọba tí kò ní akẹgbẹ́ - túmọ̀ sí pé sísọ n̄ǹkan tí Allāhu kò fi mọ ẹ̀dá gẹ́gẹ́ bí akẹgbẹ́ Rẹ̀ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu.
التفاسير العربية:
لَا جَرَمَ أَنَّمَا تَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِ لَيۡسَ لَهُۥ دَعۡوَةٞ فِي ٱلدُّنۡيَا وَلَا فِي ٱلۡأٓخِرَةِ وَأَنَّ مَرَدَّنَآ إِلَى ٱللَّهِ وَأَنَّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè mí sí, kò ní ẹ̀tọ́ sí ìpè kan ní ayé àti ní ọ̀run. Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu ni àbọ̀ wa. Dájúdájú àwọn olùtayọ-ẹnu-ààlà, àwọn ni èrò inú Iná.
التفاسير العربية:
فَسَتَذۡكُرُونَ مَآ أَقُولُ لَكُمۡۚ وَأُفَوِّضُ أَمۡرِيٓ إِلَى ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بَصِيرُۢ بِٱلۡعِبَادِ
Nítorí náà, ẹ máa rántí ohun tí mò ń sọ fún yín. Mo sì ń fi ọ̀rọ̀ mi tì sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn.”
التفاسير العربية:
فَوَقَىٰهُ ٱللَّهُ سَيِّـَٔاتِ مَا مَكَرُواْۖ وَحَاقَ بِـَٔالِ فِرۡعَوۡنَ سُوٓءُ ٱلۡعَذَابِ
Allāhu sì ṣọ́ ọ níbi àwọn aburú tí wọ́n dète rẹ̀. Ìyà burúkú sì yí àwọn ènìyàn Fir‘aon po.
التفاسير العربية:
ٱلنَّارُ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا غُدُوّٗا وَعَشِيّٗاۚ وَيَوۡمَ تَقُومُ ٱلسَّاعَةُ أَدۡخِلُوٓاْ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ أَشَدَّ ٱلۡعَذَابِ
Iná ni Wọ́n yóò máà ṣẹ́rí wọn sí ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́. Àti pé ní ọjọ́ tí Àkókò náà bá dé (A máa sọ pé): “Ẹ mú àwọn ènìyàn Fir‘aon wọ inú ìyà Iná tó le jùlọ.”
التفاسير العربية:
وَإِذۡ يَتَحَآجُّونَ فِي ٱلنَّارِ فَيَقُولُ ٱلضُّعَفَٰٓؤُاْ لِلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُنَّا لَكُمۡ تَبَعٗا فَهَلۡ أَنتُم مُّغۡنُونَ عَنَّا نَصِيبٗا مِّنَ ٱلنَّارِ
(Rántí) nígbà tí wọ́n bá ń bá ara wọn ṣe àríyànjiyàn nínú Iná. Àwọn ọ̀lẹ yóò wí fún àwọn tí wọ́n ṣègbéraga pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ ọmọlẹ́yìn fún yín, ǹjẹ́ ẹ̀yin lè gbé ìpín kan kúrò fún wa nínú ìyà Iná?”
التفاسير العربية:
قَالَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَكۡبَرُوٓاْ إِنَّا كُلّٞ فِيهَآ إِنَّ ٱللَّهَ قَدۡ حَكَمَ بَيۡنَ ٱلۡعِبَادِ
Àwọn tó ṣègbéraga máa wí pé: “Dájúdájú gbogbo wa l’a wà nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu kúkú ti dájọ́ láààrin àwọn ẹrú náà.”
التفاسير العربية:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ فِي ٱلنَّارِ لِخَزَنَةِ جَهَنَّمَ ٱدۡعُواْ رَبَّكُمۡ يُخَفِّفۡ عَنَّا يَوۡمٗا مِّنَ ٱلۡعَذَابِ
Àwọn tó wà nínú Iná tún máa wí fún àwọn ẹ̀ṣọ́-Iná pé: “Ẹ bá wa pe Olúwa yín, kí Ó ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wa fún ọjọ́ kan.”
التفاسير العربية:
قَالُوٓاْ أَوَلَمۡ تَكُ تَأۡتِيكُمۡ رُسُلُكُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِۖ قَالُواْ بَلَىٰۚ قَالُواْ فَٱدۡعُواْۗ وَمَا دُعَٰٓؤُاْ ٱلۡكَٰفِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَٰلٍ
Wọ́n yóò sọ pé: “Ǹjẹ́ àwọn Òjísẹ́ yín kì í mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín bí?” Wọ́n á wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, (wọ́n mú un wá).” Wọ́n máa sọ pé: “Ẹ ṣàdúà wò.” Àdúà (àti ìpè) àwọn aláìgbàgbọ́ kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe sínú ìṣìnà.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Ra‘d;13:14.
التفاسير العربية:
إِنَّا لَنَنصُرُ رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَيَوۡمَ يَقُومُ ٱلۡأَشۡهَٰدُ
Dájúdájú Àwa kúkú máa ṣàrànṣe fún àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìgbésí ayé yìí àti ní ọjọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí yó dìde (ní Ọjọ́ Àjíǹde).
التفاسير العربية:
يَوۡمَ لَا يَنفَعُ ٱلظَّٰلِمِينَ مَعۡذِرَتُهُمۡۖ وَلَهُمُ ٱللَّعۡنَةُ وَلَهُمۡ سُوٓءُ ٱلدَّارِ
Ní ọjọ́ tí àwáwí àwọn alábòsí kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní; ègún ń bẹ fún wọn, ilé (ìyà) burúkú sì wà fún wọn.
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡهُدَىٰ وَأَوۡرَثۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱلۡكِتَٰبَ
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní ìmọ̀nà. A sì jogún Tírà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.
التفاسير العربية:
هُدٗى وَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
(Ó jẹ́) ìmọ̀nà àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè.
التفاسير العربية:
فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لِذَنۢبِكَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ بِٱلۡعَشِيِّ وَٱلۡإِبۡكَٰرِ
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.¹ Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ² ní ìrọ̀lẹ́ àti ní òwúrọ̀ kùtùkùtù.
1. Irú gbólóhùn yìí tún wà nínú sūrah Muhammad; 47:19. Ẹ̀̀ṣẹ̀ wo ni Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dá? Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kì i ṣé ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn tàbí olùyapa àṣẹ Allāhu - Ọba Aláforíjìn -. Àmọ́ nítorí pé, Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kì í ṣe mọlāika, kì í sì ṣe ọlọ́hun, ó ṣeé ṣe kí ó ṣe ìṣe kan tí Allāhu máa sọ di ní ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Irúfẹ́ àwọn ìṣe náà kò tàbùkù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sì yọ ọ́ kúrò nípò àwòkọ́ṣe rere fún gbogbo ẹ̀dá.
Allāhu kì í kúkú ṣe Ọba alábòsí, Ó ṣàfi hàn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dá.
Àṣìṣe kìíní tó di ẹ̀ṣẹ̀: Títú tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tú àwọn ẹrú ogun Badr sílẹ̀ dípò pípa wọ́n, ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn nítorí pé, àwọn tí Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tú sílẹ̀ wọ̀nyí, àwọn ni olórí àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah. Wọ́n sì ti pa àwọn mùsùlùmí kan nípakúpa ṣíwájú kí ọwọ́ tó tẹ àwọn náà lójú ogun Badr. Àmọ́ ohun tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - rò tó fi tú wọn sílẹ̀ ni pé, àwùjọ mùsùlùmí bùkátà sí owó àti ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrú kan nínú àwọn ẹrú ogun náà, nígbà tí àwọn ẹrú mìíràn rí ìtúsílẹ̀ gbà nípasẹ̀ kíkọ́ àwọn Sọhābah kan ní ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ní òdodo ni pé, ìgbésẹ̀ yìí dára. Àmọ́ Allāhu kà á kún àṣìṣe. Ó sì jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún un pé, pípa wọ́n lásìkò náà l’ó lóore ju títú wọn sílẹ̀ wọn lọ nítorí pé, àìpa wọ́n l’ó padà bí àwọn ogun mìíràn.
Ńṣe ni àwọn ọ̀ṣẹbọ náà lọ túnra mú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn ogun mìíràn dìde. Wọn ìbá ti pa wọ́n nígbà àkọ́kọ́, ogun ìbá ti dáwọ́ dúró. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Anfāl; 8:67 - 71. Allāhu sì padà yọ̀ǹda ìtúsílẹ̀ ẹrú ogún pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ tàbí ní ọ̀fẹ́ fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú sūrah Muhammad; 47:4.
Àṣìṣe kejì tó di ẹ̀ṣẹ̀: Àìtètè gbà kí Zaed ọmọ Hārithah - kí Allāhu yọ́nú sí i - kọ Zaenab ọmọ Jahṣ - kí Allāhu yọ́nú sí i - sílẹ̀ lẹ́yìn tí Allāhu ti sọ ọ́ di mímọ̀ fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé Zaed ti lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí kò bùkátà sí i mọ́. Ohun tí ó sì mú kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kóra ró ni pé, ó ń páyà pé àwọn aláìsàn-ọkàn yóò máa sọ pé, “Ó gba ìyàwó lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, ó sì fi ṣaya!”. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Zaed ọmọ Hārithah - kí Allāhu yọ́nú sí i - kì í ṣe ọmọbíbí inú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Àti pé kò sí èèwọ̀ nínú kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fẹ́ Zaenab ọmọ Jahṣ lẹ́yìn tí Allāhu ti pa á láṣẹ fún un láti fi ṣaya. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah al-’Ahzāb; 33:37-38. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ṣẹ́rí padà síbi ohun tí Allāhu yàn fún un.
Àṣìṣe kẹta tó di ẹ̀ṣẹ̀: Sísọ tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ fún ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ pé òun kò níí fi ẹrúbìnrin rẹ̀ kan ṣaya. Sísọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àṣìṣe fún un nítorí pé, ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un ni ó fẹ́ ṣe ní èèwọ̀ fún ẹ̀mí ara rẹ̀ láti fi wá ìyọ́nú ìyàwó rẹ̀ kan. Èyí ni Allāhu sọ nípa rẹ̀ nínú sūrah at-Tahrīm; 66:1.
Àṣìṣe kẹ́rin tó di ẹ̀ṣẹ̀: Fífajúro tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fajú ro sí afọ́jú kan tí Allāhu ti ṣípayá ọkàn rẹ̀ fún gbígba ’Islām. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nip é, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wà pẹ̀lú ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ, tí ó ń ṣe wáàsí fún lọ́wọ́ nígbà tí afọ́jú yìí ń sáré bọ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ti kó ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ léyà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí kò fi fẹ́ kí afọ́jú tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé di òun lọ́wọ́. Ṣíṣẹ bẹ́ẹ̀ l’ó di ẹ̀ṣẹ̀ sí i lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi ìdí èyí náà múlẹ̀ nínú sūrah ‘Abas; 80:1-11.
Ìwọ̀nyẹn ni àwọn àṣìṣe tó di ẹ̀ṣẹ̀ sí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́rùn. Kì í ṣe pé Ànábì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ńla kan tàbí ọ̀daràn. Tòhun tí bí ó ṣe mọ yìí, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò yé tọrọ àforíjìn lórí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Kódà Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò lè má tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu lórí ìwọ̀nyẹn nígbà ọgọ́rùn-ún lójúmọ́.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó yẹ kí èyí kọ́ èmi àti ẹ̀yin ni pé, a kò gbọ́dọ̀ fojú bín-íntín wo èyíkéyìí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀. A gbọ́dọ̀ kún fún títọrọ àforíjìn ni lọ́dọ̀ Allāhu, Aláforíjìn. Kò sí ohun tó dára tó rírí àforíjìn gbà lọ́dọ̀ Allāhu lórí gbogbo àṣìṣe wa ṣíwájú ọjọ́ ikú wa, irú àforíjìn yìí ni Allāhu ṣe fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí Allāhu sì sọ ọ́ di mímọ̀ fún gbogbo ayé nínú sūrah al-Fath; 48:1 - 2.
Ìyẹn ni abala èyí tó jẹmọ́ àṣìṣe Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́yìn tí ó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣẹrh; 94:3 fún abala kejì, èyí tó jẹmọ́ àṣìṣe rẹ̀ ṣíwájú kí ó tó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
2. Ìyẹn ni pé, ṣe àfọ̀mọ́ Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù, kí o sì yìn Ín lógo pé, Ó pé tán pátápátá.
التفاسير العربية:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ بِغَيۡرِ سُلۡطَٰنٍ أَتَىٰهُمۡ إِن فِي صُدُورِهِمۡ إِلَّا كِبۡرٞ مَّا هُم بِبَٰلِغِيهِۚ فَٱسۡتَعِذۡ بِٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ
Dájúdájú àwọn tó ń jiyàn nípa àwọn āyah Allāhu láìní ẹrí kan (lọ́wọ́) tí ó wá bá wọn (láti ọ̀dọ̀ Allāhu), kò sí kiní kan nínú igbá-àyà wọn àyàfi ọkàn-gíga. Wọn kò sì lè dé ibi gíga (pẹ̀lú ọkàn gíga). Nítorí náà, sá di Allāhu. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Olùríran.
التفاسير العربية:
لَخَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ أَكۡبَرُ مِنۡ خَلۡقِ ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Dájúdájú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ tóbi ju ìṣẹ̀dá àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò mọ̀.
التفاسير العربية:
وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَلَا ٱلۡمُسِيٓءُۚ قَلِيلٗا مَّا تَتَذَكَّرُونَ
Afọ́jú àti olùríran kò dọ́gba. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere àti oníṣẹ́-aburú (kò dọ́gba). Díẹ̀ l’ẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
التفاسير العربية:
إِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَأٓتِيَةٞ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́.
التفاسير العربية:
وَقَالَ رَبُّكُمُ ٱدۡعُونِيٓ أَسۡتَجِبۡ لَكُمۡۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِي سَيَدۡخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ
Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn tó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi,¹ wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ.”
1. Ẹ wo sūrah Yūnus; 10:22 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀.
التفاسير العربية:
ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fún yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un).
التفاسير العربية:
ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ
Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?
التفاسير العربية:
كَذَٰلِكَ يُؤۡفَكُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ
Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn tó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn).
التفاسير العربية:
ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ قَرَارٗا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءٗ وَصَوَّرَكُمۡ فَأَحۡسَنَ صُوَرَكُمۡ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡۖ فَتَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ibùgbé. Ó sì ṣe sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱلۡحَيُّ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱدۡعُوهُ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَۗ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.¹ Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:29.
التفاسير العربية:
۞ قُلۡ إِنِّي نُهِيتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَمَّا جَآءَنِيَ ٱلۡبَيِّنَٰتُ مِن رَّبِّي وَأُمِرۡتُ أَنۡ أُسۡلِمَ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ مِنۡ عَلَقَةٖ ثُمَّ يُخۡرِجُكُمۡ طِفۡلٗا ثُمَّ لِتَبۡلُغُوٓاْ أَشُدَّكُمۡ ثُمَّ لِتَكُونُواْ شُيُوخٗاۚ وَمِنكُم مَّن يُتَوَفَّىٰ مِن قَبۡلُۖ وَلِتَبۡلُغُوٓاْ أَجَلٗا مُّسَمّٗى وَلَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà láti inú àtọ̀, lẹ́yìn náà láti inú ẹ̀jẹ̀ dídì, lẹ́yìn náà Ó mu yín jáde ní òpóǹló. Lẹ́yìn náà, (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè sánn̄gun dópin agbára yín. Lẹ́yìn náà (Ó tún da yín sí) nítorí kí ẹ lè di àgbàlágbà. Ó wà nínú yín ẹni tí A óò ti gba ẹ̀mí rẹ̀ ṣíwájú (ipò àgbà). Àti pé (Ó da yín sí) nítorí kí ẹ lè dàgbà dé gbèdéke àkókò kan àti nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ فَإِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Òun ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.
التفاسير العربية:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ أَنَّىٰ يُصۡرَفُونَ
Ṣé o kò wòye sí àwọn tí ń ṣàríyànjiyàn nípa àwọn āyah Allāhu bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo!
التفاسير العربية:
ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِٱلۡكِتَٰبِ وَبِمَآ أَرۡسَلۡنَا بِهِۦ رُسُلَنَاۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ
Àwọn tó pe Tírà náà àti ohun tí A fi rán àwọn Òjíṣẹ́ Wa níṣẹ́ ní irọ́, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
التفاسير العربية:
إِذِ ٱلۡأَغۡلَٰلُ فِيٓ أَعۡنَٰقِهِمۡ وَٱلسَّلَٰسِلُ يُسۡحَبُونَ
Nígbà tí àwọn sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n bá wà ní ọrùn wọn, tí wọn yóò fi máa wọ́ wọn
التفاسير العربية:
فِي ٱلۡحَمِيمِ ثُمَّ فِي ٱلنَّارِ يُسۡجَرُونَ
sínú omi tó gbóná parí. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi wọ́n ko Iná.
التفاسير العربية:
ثُمَّ قِيلَ لَهُمۡ أَيۡنَ مَا كُنتُمۡ تُشۡرِكُونَ
Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ fún wọn pé: “Ibo ni ohun tí ẹ sọ di òrìṣà wà?”
التفاسير العربية:
مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالُواْ ضَلُّواْ عَنَّا بَل لَّمۡ نَكُن نَّدۡعُواْ مِن قَبۡلُ شَيۡـٔٗاۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ ٱلۡكَٰفِرِينَ
“(Ohun tí ẹ jọ́sìn fún) lẹ́yìn Allāhu (dà)?” Wọ́n á wí pé: “Wọ́n ti di òfò mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ kọ́, àwa kì í pe n̄ǹkan kan tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́nà.
التفاسير العربية:
ذَٰلِكُم بِمَا كُنتُمۡ تَفۡرَحُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَبِمَا كُنتُمۡ تَمۡرَحُونَ
Ìyẹn nítorí pé ẹ̀ ń yọ lórí ilẹ̀ ní ọ̀nà àìtọ́ àti nítorí pé, ẹ̀ ń ṣe fáàrí (lórí àìgbàgbọ́).
التفاسير العربية:
ٱدۡخُلُوٓاْ أَبۡوَٰبَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَاۖ فَبِئۡسَ مَثۡوَى ٱلۡمُتَكَبِّرِينَ
Ẹ wọ àwọn ẹnu ọ̀na iná Jahanamọ; olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó sì burú ní ibùgbé fún àwọn onígbèéraga.
التفاسير العربية:
فَٱصۡبِرۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۚ فَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعۡضَ ٱلَّذِي نَعِدُهُمۡ أَوۡ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيۡنَا يُرۡجَعُونَ
Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà). Ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni wọ́n máa dá wọn padà sí.
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا رُسُلٗا مِّن قَبۡلِكَ مِنۡهُم مَّن قَصَصۡنَا عَلَيۡكَ وَمِنۡهُم مَّن لَّمۡ نَقۡصُصۡ عَلَيۡكَۗ وَمَا كَانَ لِرَسُولٍ أَن يَأۡتِيَ بِـَٔايَةٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ فَإِذَا جَآءَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قُضِيَ بِٱلۡحَقِّ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ
Àti pé A kúkú ti rán àwọn Òjísẹ́ níṣẹ́ ṣíwájú rẹ. Àwọn tí A sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àwọn tí A kò sọ ìtàn wọn fún ọ wà nínú wọn. Àti pé kò tọ́ fún Òjísẹ́ kan láti mú àmì kan wá àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Nígbà tí àṣẹ Allāhu bá sì dé, A máa fi òdodo dájọ́. Àwọn òpùrọ́ sì máa ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah ar-Ra‘d; 13:38 lórí ìtúmọ̀ “àmì”.
التفاسير العربية:
ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَنۡعَٰمَ لِتَرۡكَبُواْ مِنۡهَا وَمِنۡهَا تَأۡكُلُونَ
Allāhu ni Ẹni tí Ó dá àwọn ẹran-ọ̀sìn fún yín nítorí kí ẹ lè máa gùn nínú wọn. Ẹ ó sì máa jẹ nínú wọn.
التفاسير العربية:
وَلَكُمۡ فِيهَا مَنَٰفِعُ وَلِتَبۡلُغُواْ عَلَيۡهَا حَاجَةٗ فِي صُدُورِكُمۡ وَعَلَيۡهَا وَعَلَى ٱلۡفُلۡكِ تُحۡمَلُونَ
Àwọn àǹfààní (mìíràn) wà fún yín lára ẹran-ọ̀sìn. Àti nítorí kí ẹ lè dé ọ̀nà jíjìn tó wà lọ́kàn yín lórí (gígùn) wọ́n (kiri). Ẹ sì ń fi àwọn (ẹran-ọ̀sìn) àti ọkọ̀ ojú-omi gbé àwọn ẹrù.
التفاسير العربية:
وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ فَأَيَّ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ تُنكِرُونَ
(Allāhu) ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín. Nítorí náà, èwo nínú àwọn àmì Allāhu l’ẹ máa takò?¹
1. Kíyè sí i! Àwọn asòòkùn sẹ́sìn àti àwọn onibidiah yóò máa pe iṣẹ́ aburú ọwọ́ wọn nípasẹ̀ idán pípa àti bidiah ṣíṣe ní “àmì Allāhu” láti lè ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Kíyè sí i, ohunkóhun tí ó bá máa jẹ́ “àmì Allāhu / àmì Ọlọ́hun” kò níí fi ọ̀nà kan kan lòdì sí “āyah” kan kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé nítorí pé, àwọn āyah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé ni òṣùwọ̀n ìdáláre àti ìdálẹ́bi fún ohun tí ẹnikẹ́ni bá pè ní “àmì Ọlọ́hun”. Kódà, ohunkóhun tí ó bá máa jẹ́ “àmì Allāhu” kò níí fi ọ̀nà kan kan lòdì sí hadīth kan nínú àwọn hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.
Síwájú sí i, ọ̀tọ̀ ni pàápàá bíbẹ Allāhu - tó ga jùlọ -, ọ̀tọ̀ ni “àmì Ọlọ́hun”. Ẹlẹ́dàá ni Allāhu. Àmì Ọlọ́hun sì ń túmọ̀ sí ẹ̀dá Ọlọ́hun tàbí ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun gẹ́gẹ́ bí āyah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Nítorí náà, àmì Ọlọ́hun ni a lè fojú rí nílé ayé yìí, kì í ṣe pàápàá bíbẹ Allāhu. Ẹni tí ó rí àmì Ọlọ́hun, kò rí Ọlọ́hun. Wallāhu ’a‘lam.
التفاسير العربية:
أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِنۡهُمۡ وَأَشَدَّ قُوَّةٗ وَءَاثَارٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Wọ́n pọ̀ (ní òǹkà) jù wọ́n lọ. Wọ́n ní agbára jù wọ́n lọ. Wọ́n sì lo ilẹ̀(fún oko dídá jù wọ́n lọ). Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
التفاسير العربية:
فَلَمَّا جَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَرِحُواْ بِمَا عِندَهُم مِّنَ ٱلۡعِلۡمِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn, wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ nítorí ohun tó wà lọ́dọ̀ wọn nínú ìmọ̀ (ayé). Ohun tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
التفاسير العربية:
فَلَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥ وَكَفَرۡنَا بِمَا كُنَّا بِهِۦ مُشۡرِكِينَ
Nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa, wọ́n wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. A sì lòdì sí n̄ǹkan tí a sọ di akẹgbẹ́ fún Un.”
التفاسير العربية:
فَلَمۡ يَكُ يَنفَعُهُمۡ إِيمَٰنُهُمۡ لَمَّا رَأَوۡاْ بَأۡسَنَاۖ سُنَّتَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي قَدۡ خَلَتۡ فِي عِبَادِهِۦۖ وَخَسِرَ هُنَالِكَ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Ìgbàgbọ́ wọn kò sì ṣe wọ́n ní àǹfààní nígbà tí wọ́n rí ìyà Wa. Ìṣe Allāhu, èyí tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú sí àwọn ẹrú Rẹ̀ (ni èyí). Àwọn aláìgbàgbọ́ sì ṣòfò dànù níbẹ̀ yẹn.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: غافر
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق