ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: الحشر   آية:

سورة الحشر - Suuratul-Hash'r

سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن دِيَٰرِهِمۡ لِأَوَّلِ ٱلۡحَشۡرِۚ مَا ظَنَنتُمۡ أَن يَخۡرُجُواْۖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُم مَّانِعَتُهُمۡ حُصُونُهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَأَتَىٰهُمُ ٱللَّهُ مِنۡ حَيۡثُ لَمۡ يَحۡتَسِبُواْۖ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَۚ يُخۡرِبُونَ بُيُوتَهُم بِأَيۡدِيهِمۡ وَأَيۡدِي ٱلۡمُؤۡمِنِينَ فَٱعۡتَبِرُواْ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ
Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítír๠jáde kúrò nínú ilé wọn fún àkọ́kọ́ àkójọ (wọ́n sínú ìlú Ṣām). Ẹ̀yin kò lérò pé wọn yóò jáde. Àwọn náà sì lérò pé dájúdájú àwọn odi ilé wọn yóò dáàbò bo àwọn lọ́dọ̀ Allāhu. Ṣùgbọ́n Allāhu wá bá wọn ní ibi tí wọn kò ti lérò; Allāhu sì ju ìbẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Wọ́n ń fi ọwọ́ ara wọn àti ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo wó àwọn ilé wọn. Nítorí náà, ẹ wòye, ẹ̀yin tí ẹ ní ojú ìríran.
1. Ìyẹn àwọn Yẹhudi ọmọ Nadīr.
التفاسير العربية:
وَلَوۡلَآ أَن كَتَبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡجَلَآءَ لَعَذَّبَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابُ ٱلنَّارِ
Àti pé tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ti kọ ìjáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah lé àwọn onítírà lórí ni, dájúdájú (Allāhu) ìbá jẹ wọ́n níyà nílé ayé. Ìyà Iná sì tún wà fún wọn ní ọ̀run.¹
1. Ìyẹn ni pé, tí àwọn onítírà kò bá fi ìlú Mọdīnah sílẹ̀ fún àwọn mùsùlùmí ni, ẹ̀mí wọn ìbá lọ sí i nítorí pé, wọ́n ti da àwọn mùsùlùmí.
التفاسير العربية:
ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ شَآقُّواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥۖ وَمَن يُشَآقِّ ٱللَّهَ فَإِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yapa (ọ̀rọ̀) Allāhu, dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.
التفاسير العربية:
مَا قَطَعۡتُم مِّن لِّينَةٍ أَوۡ تَرَكۡتُمُوهَا قَآئِمَةً عَلَىٰٓ أُصُولِهَا فَبِإِذۡنِ ٱللَّهِ وَلِيُخۡزِيَ ٱلۡفَٰسِقِينَ
Ẹ̀yin kò níí ge igi dàbínù kan tàbí kí ẹ fi sílẹ̀ kí ó dúró sórí gbòǹgbò rẹ̀, (àfi) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Ó lè dójú ti àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ni.¹
1. Ìyẹn ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun ẹ̀sìn kò sí fún bíba àwọn dúkìá ọ̀tá ẹ̀sìn jẹ́, èyí tí ó bá padà bàjẹ́ nínú àwọn dúkìá náà kò níí di ọ̀ràn sí ìjọ mùsùlùmí lọ́rùn ní ọ̀run nítorí pé, kò sí bí ogun ẹ̀sìn ṣe lè ṣẹlẹ̀ tí àwọn dúkìá kan kò níí bàjẹ́.
التفاسير العربية:
وَمَآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ مِنۡهُمۡ فَمَآ أَوۡجَفۡتُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ خَيۡلٖ وَلَا رِكَابٖ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يُسَلِّطُ رُسُلَهُۥ عَلَىٰ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ wọn fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, tí ẹ kò gbé ẹṣin àti ràkúnmí sáré fún (ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ni). Ṣùgbọ́n Allāhu yóò máa fún àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní agbára lórí ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
التفاسير العربية:
مَّآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡقُرَىٰ فَلِلَّهِ وَلِلرَّسُولِ وَلِذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِ كَيۡ لَا يَكُونَ دُولَةَۢ بَيۡنَ ٱلۡأَغۡنِيَآءِ مِنكُمۡۚ وَمَآ ءَاتَىٰكُمُ ٱلرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَىٰكُمۡ عَنۡهُ فَٱنتَهُواْۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
Ohunkóhun tí Allāhu bá dá padà láti ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (ó jẹ́) ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ àti ti àwọn ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn tálíkà àti onírìn-àjò (tí agara dá) nítorí kí ó má baá jẹ́ àdápín láààrin àwọn ọlọ́rọ̀ nínú yín. Ohunkóhun tí Òjíṣẹ́ bá fún yín, ẹ gbà á. Ohunkóhun tí ó bá sì kọ̀ fún yín, ẹ jáwọ́ nínú rẹ. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le níbi ìyà.
التفاسير العربية:
لِلۡفُقَرَآءِ ٱلۡمُهَٰجِرِينَ ٱلَّذِينَ أُخۡرِجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَأَمۡوَٰلِهِمۡ يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٗا وَيَنصُرُونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلصَّٰدِقُونَ
(Ìkógun náà tún wà fún) àwọn aláìní, (ìyẹn,) al-Muhājirūn, àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ilé wọn àti níbi dúkìá wọn, tí wọ́n sì ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí wọ́n sì ń ṣàrànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olódodo.
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ تَبَوَّءُو ٱلدَّارَ وَٱلۡإِيمَٰنَ مِن قَبۡلِهِمۡ يُحِبُّونَ مَنۡ هَاجَرَ إِلَيۡهِمۡ وَلَا يَجِدُونَ فِي صُدُورِهِمۡ حَاجَةٗ مِّمَّآ أُوتُواْ وَيُؤۡثِرُونَ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ وَلَوۡ كَانَ بِهِمۡ خَصَاصَةٞۚ وَمَن يُوقَ شُحَّ نَفۡسِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ
Àwọn tó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ òdodo ṣíwájú wọn,¹ wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn (ní ìlú Mọdīnah). Wọn kò sì ní bùkátà kan nínú igbá-àyà wọn sí n̄ǹkan tí wọ́n bá fún wọn. Wọ́n sì ń gbé àjùlọ fún wọn lórí ẹ̀mí ara wọn, kódà kí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ní bùkátà (sí ohun tí wọ́n fún wọn). Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ọmọ ìlú Mọdīnah, tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ òdodo ṣíwájú kí àwọn mùsùlùmi tó ṣe hijrah wá bá wọn.
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ جَآءُو مِنۢ بَعۡدِهِمۡ يَقُولُونَ رَبَّنَا ٱغۡفِرۡ لَنَا وَلِإِخۡوَٰنِنَا ٱلَّذِينَ سَبَقُونَا بِٱلۡإِيمَٰنِ وَلَا تَجۡعَلۡ فِي قُلُوبِنَا غِلّٗا لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ رَبَّنَآ إِنَّكَ رَءُوفٞ رَّحِيمٌ
Àwọn tó dé lẹ́yìn wọn ń sọ pé: “Olúwa wa, foríjin àwa àti àwọn ọmọ ìyá wa tó ṣíwájú wa nínú ìgbàgbọ́ òdodo. Má ṣe jẹ́ kí inúnibíni wà nínú ọkàn wa sí àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ ni Aláàánú, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”¹
1. Àdúà kan nìyí tí a lè máa fi tọrọ àforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn òkú mùsùlùmí.
التفاسير العربية:
۞ أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ نَافَقُواْ يَقُولُونَ لِإِخۡوَٰنِهِمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ لَئِنۡ أُخۡرِجۡتُمۡ لَنَخۡرُجَنَّ مَعَكُمۡ وَلَا نُطِيعُ فِيكُمۡ أَحَدًا أَبَدٗا وَإِن قُوتِلۡتُمۡ لَنَنصُرَنَّكُمۡ وَٱللَّهُ يَشۡهَدُ إِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ
Ṣé o ò rí àwọn tó ṣàgàbà ǹgebè nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń wí fún àwọn ọmọ ìyá wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn onítírà, pé “Dájúdájú tí wọ́n bá le yín jáde (kúrò nínú ìlú), àwa náà gbọ́dọ̀ jáde pẹ̀lú yín ni. Àwa kò sì níí tẹ̀lé àṣẹ ẹnì kan lórí yín láéláé. Tí wọ́n bá sì gbé ogun dìde si yín, àwa gbọ́dọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín ni.” Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n.
التفاسير العربية:
لَئِنۡ أُخۡرِجُواْ لَا يَخۡرُجُونَ مَعَهُمۡ وَلَئِن قُوتِلُواْ لَا يَنصُرُونَهُمۡ وَلَئِن نَّصَرُوهُمۡ لَيُوَلُّنَّ ٱلۡأَدۡبَٰرَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ
Dájúdájú tí wọ́n bá lé wọn jáde, wọn kò níí jáde pẹ̀lú wọn.¹ Dájúdájú tí wọ́n bá sì gbógun tì wọ́n, wọn kò níí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn. Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ wọn, dájúdájú wọn yóò pẹ̀yìndà (láti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ). Lẹ́yìn náà, wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.
1. Ìyẹn ni pé, tí àwọn mùsùlùmí bá lé àwọn yẹhudi jáde kúrò nínú ìlú Mọdīnah, àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kò níí jáde pẹ̀lú àwọn yẹhudi. Wọ́n kàn ń tàn wọ́n lásán ni.
التفاسير العربية:
لَأَنتُمۡ أَشَدُّ رَهۡبَةٗ فِي صُدُورِهِم مِّنَ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٞ لَّا يَفۡقَهُونَ
Dájúdájú ẹ̀yin ni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó lágbára ju Allāhu lọ nínú igbá-àyà wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé.
التفاسير العربية:
لَا يُقَٰتِلُونَكُمۡ جَمِيعًا إِلَّا فِي قُرٗى مُّحَصَّنَةٍ أَوۡ مِن وَرَآءِ جُدُرِۭۚ بَأۡسُهُم بَيۡنَهُمۡ شَدِيدٞۚ تَحۡسَبُهُمۡ جَمِيعٗا وَقُلُوبُهُمۡ شَتَّىٰۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٞ لَّا يَعۡقِلُونَ
Wọn kò lè parapọ̀ dojú ìjà kọ yín àfi (kí wọ́n) wà nínú odi ìlú tàbí (kí wọ́n wà) lẹ́yìn àwọn ògiri. Ogun ààrin ara wọn gan-an le. Ò ń lérò pé wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ ni, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ọkàn wọn wà. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú àwọn ni ìjọ tí kò ní làákàyè.
التفاسير العربية:
كَمَثَلِ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ قَرِيبٗاۖ ذَاقُواْ وَبَالَ أَمۡرِهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Àpẹ̀ẹrẹ wọn dà bí àwọn tó ṣíwájú wọn tí kò tí ì pẹ́ lọ títí. Wọ́n tọ́ aburú ọ̀rọ̀ ara wọn wò. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
التفاسير العربية:
كَمَثَلِ ٱلشَّيۡطَٰنِ إِذۡ قَالَ لِلۡإِنسَٰنِ ٱكۡفُرۡ فَلَمَّا كَفَرَ قَالَ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّنكَ إِنِّيٓ أَخَافُ ٱللَّهَ رَبَّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Àpẹ̀ẹrẹ wọn dà bí Èṣù nígbà tí ó bá wí fún ènìyàn pé: “Ṣàì gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá ṣàì gbàgbọ́ (tán), ó máa wí pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. Dájúdájú èmi ń páyà Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
التفاسير العربية:
فَكَانَ عَٰقِبَتَهُمَآ أَنَّهُمَا فِي ٱلنَّارِ خَٰلِدَيۡنِ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَٰٓؤُاْ ٱلظَّٰلِمِينَ
Nítorí náà, ìkángun àwọn méjèèjì ni pé, dájúdájú àwọn méjèèjì yóò wà nínú Iná. Olùṣegbére ni àwọn méjèèjì nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí.
التفاسير العربية:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلۡتَنظُرۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ لِغَدٖۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ̀mí kan sì wòye sí ohun tí ó tì ṣíwájú fún ọ̀la (àlùkìyáámọ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
التفاسير العربية:
وَلَا تَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ نَسُواْ ٱللَّهَ فَأَنسَىٰهُمۡ أَنفُسَهُمۡۚ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ
Kí ẹ sì má ṣe dà bí àwọn tó gbàgbé Allāhu. (Allāhu) sì mú wọn gbàgbé ẹ̀mí ara wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni arúfin.
التفاسير العربية:
لَا يَسۡتَوِيٓ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِ وَأَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۚ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِ هُمُ ٱلۡفَآئِزُونَ
Àwọn èrò inú Iná àti àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra kò dọ́gba. Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, àwọn ni olùjèrè.
التفاسير العربية:
لَوۡ أَنزَلۡنَا هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ عَلَىٰ جَبَلٖ لَّرَأَيۡتَهُۥ خَٰشِعٗا مُّتَصَدِّعٗا مِّنۡ خَشۡيَةِ ٱللَّهِۚ وَتِلۡكَ ٱلۡأَمۡثَٰلُ نَضۡرِبُهَا لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ
Tí ó bá jẹ́ pé A sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ sórí àpáta ni, dájúdájú o máa rí i tí ó máa wálẹ̀, tí ó máa fọ́ pẹ́tẹpẹ̀tẹ fún ìpáyà Allāhu. Ìwọ̀nyí ni àwọn àkàwé tí À ń fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِۖ هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ٱلرَّحِيمُ
Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Onímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Òun ni Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡقُدُّوسُ ٱلسَّلَٰمُ ٱلۡمُؤۡمِنُ ٱلۡمُهَيۡمِنُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡجَبَّارُ ٱلۡمُتَكَبِّرُۚ سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يُشۡرِكُونَ
Òun ni Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ọba (ẹ̀dá), Ẹni-mímọ́ jùlọ, Aláìlábùkù, Olùjẹ́rìí-Òjíṣẹ́-Rẹ̀, Olùjẹ́rìí-ẹ̀dá, Alágbára, Olùjẹni-nípá, Atóbi. Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n fi ń ṣẹbọ sí I.
التفاسير العربية:
هُوَ ٱللَّهُ ٱلۡخَٰلِقُ ٱلۡبَارِئُ ٱلۡمُصَوِّرُۖ لَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ يُسَبِّحُ لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Òun ni Allāhu, Ẹlẹ́dàá, Olùpilẹ̀-ẹ̀dá, Olùyàwòrán-ẹ̀dá. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Un. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: الحشر
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق