ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: الشرح   آية:

سورة الشرح - Suuratu Shar'h

أَلَمۡ نَشۡرَحۡ لَكَ صَدۡرَكَ
Ṣé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
التفاسير العربية:
وَوَضَعۡنَا عَنكَ وِزۡرَكَ
A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ,
التفاسير العربية:
ٱلَّذِيٓ أَنقَضَ ظَهۡرَكَ
èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.¹
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò ṣẹbọ rí ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Allāhu, ọ̀kan nínú ohun tí ó máa ń kọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lóminú, tí ó sì máa ń bà á nínú jẹ́ ni àìdá ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ àti àìní ìlànà ìjọ́sìn kan lọ́wọ́ ṣíwájú ogójì ọdún tí ó kọ́kọ́ lò.
Ní òdodo ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní orúkọ rere gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ àti olùfọkàntán láààrin àwọn Lárúbáwá ṣíwájú kí Allāhu tó gbé e dìde ní Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àmọ́ ńṣe ni ìṣẹ̀mí ayé ìgbà-àìmọ̀kan àkọ́kọ́ nínú ìlú Mọkkah máa ń bà á nínú jẹ́ gan-an. Ìdí nìyí tí Allāhu ṣe ń fún un ní ìró ìdùnnú pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà-àìmọ̀kan ní ọrùn rẹ̀ mọ́ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Àti pé Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kàn wulẹ̀ ń banújẹ́ lórí ìgbà-àìmọ̀kan, èyí tí ìdàjọ́ rẹ̀ jẹ́ pé tí ó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹnikẹ́ni, àmọ́ tí onítọ̀ún padà gba ’Islām, ìbáà jẹ́ pé ó gbà á ní òwúrọ̀, ó sì jáde kúrò láyé ní ọ̀sán ọjọ́ náà, bí ó tilẹ̀ wù kí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wúwo tó, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ náà ti di ohun tí wọ́n ti ṣàforíjìn rẹ̀ fún un pátápátá. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:17-18.
التفاسير العربية:
وَرَفَعۡنَا لَكَ ذِكۡرَكَ
A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ.
التفاسير العربية:
فَإِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرًا
Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira.
التفاسير العربية:
إِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرٗا
Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
التفاسير العربية:
فَإِذَا فَرَغۡتَ فَٱنصَبۡ
Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ohun tí ó jẹmọ́ táyé), gbìyànjú (dáadáa lórí ìjọ́sìn).
التفاسير العربية:
وَإِلَىٰ رَبِّكَ فَٱرۡغَب
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: الشرح
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق