ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: الإنشقاق   آية:

سورة الإنشقاق - Suuratul-In'shiqaaq

إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنشَقَّتۡ
Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
التفاسير العربية:
وَأَذِنَتۡ لِرَبِّهَا وَحُقَّتۡ
- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀¹ -
1. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah ;2:210, sūrah al-Furƙọ̄n; 25:25 àti sūrah al-’Infitọ̄r; 82:1-2.
التفاسير العربية:
وَإِذَا ٱلۡأَرۡضُ مُدَّتۡ
àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,
التفاسير العربية:
وَأَلۡقَتۡ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتۡ
ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo
التفاسير العربية:
وَأَذِنَتۡ لِرَبِّهَا وَحُقَّتۡ
- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)
التفاسير العربية:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدۡحٗا فَمُلَٰقِيهِ
Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.
التفاسير العربية:
فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ
Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,
التفاسير العربية:
فَسَوۡفَ يُحَاسَبُ حِسَابٗا يَسِيرٗا
láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.
التفاسير العربية:
وَيَنقَلِبُ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِۦ مَسۡرُورٗا
Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.
التفاسير العربية:
وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ وَرَآءَ ظَهۡرِهِۦ
Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hāƙƙọh; 69:25.
التفاسير العربية:
فَسَوۡفَ يَدۡعُواْ ثُبُورٗا
láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.
التفاسير العربية:
وَيَصۡلَىٰ سَعِيرًا
Ó sì máa wọ inú Iná tó ń jó.
التفاسير العربية:
إِنَّهُۥ كَانَ فِيٓ أَهۡلِهِۦ مَسۡرُورًا
Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).
التفاسير العربية:
إِنَّهُۥ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ
Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).
التفاسير العربية:
بَلَىٰٓۚ إِنَّ رَبَّهُۥ كَانَ بِهِۦ بَصِيرٗا
Bẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.
التفاسير العربية:
فَلَآ أُقۡسِمُ بِٱلشَّفَقِ
Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.
التفاسير العربية:
وَٱلَّيۡلِ وَمَا وَسَقَ
Mo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.
التفاسير العربية:
وَٱلۡقَمَرِ إِذَا ٱتَّسَقَ
Mo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.
التفاسير العربية:
لَتَرۡكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٖ
Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.
التفاسير العربية:
فَمَا لَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?
التفاسير العربية:
وَإِذَا قُرِئَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقُرۡءَانُ لَا يَسۡجُدُونَۤ۩
Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.
التفاسير العربية:
بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ يُكَذِّبُونَ
Rárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.
التفاسير العربية:
وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا يُوعُونَ
Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).
التفاسير العربية:
فَبَشِّرۡهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ
Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
التفاسير العربية:
إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ أَجۡرٌ غَيۡرُ مَمۡنُونِۭ
Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pin¹ ń bẹ fún wọn.
1. Ẹ̀san tí kò níí pin; ẹ̀san tí kò níí dópin, ẹ̀san tí kò níí dáwọ́ dúró, ẹ̀san tí yóò máa lọ títí láéláé.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: الإنشقاق
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق