কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ - ইয়োরুবা ভাষায় অনুবাদ * - অনুবাদসমূহের সূচী

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

অর্থসমূহের অনুবাদ সূরা: সূরা আল-কাহাফ   আয়াত:

Suuratul-Kah'f

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَىٰ عَبۡدِهِ ٱلۡكِتَٰبَ وَلَمۡ يَجۡعَل لَّهُۥ عِوَجَاۜ
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَيِّمٗا لِّيُنذِرَ بَأۡسٗا شَدِيدٗا مِّن لَّدُنۡهُ وَيُبَشِّرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرًا حَسَنٗا
(Ó ṣe é ni tírà) tó dúró déédé¹ nítorí kí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí ó lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra);
1. Ìyẹn ni pé, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé jẹ́ tírà tí kì í gbèfún ìbàjẹ́, irọ́, àbòsí àti ìsọkúsọ.
আরবি তাফসীরসমূহ:
مَّٰكِثِينَ فِيهِ أَبَدٗا
Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَيُنذِرَ ٱلَّذِينَ قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗا
Àti nítorí kí ó lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
مَّا لَهُم بِهِۦ مِنۡ عِلۡمٖ وَلَا لِأٓبَآئِهِمۡۚ كَبُرَتۡ كَلِمَةٗ تَخۡرُجُ مِنۡ أَفۡوَٰهِهِمۡۚ إِن يَقُولُونَ إِلَّا كَذِبٗا
Kò sí ìmọ̀ kan kan fún àwọn àti bàbá wọn nípa rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wọn tóbi. Dájúdájú wọn kò wí kiní kan bí kò ṣe irọ́.
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَلَعَلَّكَ بَٰخِعٞ نَّفۡسَكَ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ إِن لَّمۡ يُؤۡمِنُواْ بِهَٰذَا ٱلۡحَدِيثِ أَسَفًا
Nítorí náà, nítorí kí ni o ṣe máa fi ìbànújẹ́ para rẹ lórí ìgbésẹ̀ wọn pé wọn kò gba ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí gbọ́.
আরবি তাফসীরসমূহ:
إِنَّا جَعَلۡنَا مَا عَلَى ٱلۡأَرۡضِ زِينَةٗ لَّهَا لِنَبۡلُوَهُمۡ أَيُّهُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗا
Dájúdájú Àwa ṣe ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ fún ará-ayé nítorí kí Á lè dán wọn wò (pé) èwo nínú wọn ló máa dára jùlọ níbi iṣẹ́ ṣíṣe (nínú ẹ̀sìn).
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَإِنَّا لَجَٰعِلُونَ مَا عَلَيۡهَا صَعِيدٗا جُرُزًا
Àti pé dájúdájú Àwa máa sọ n̄ǹkan tí ń bẹ lórí (ilẹ̀) di erùpẹ̀ gbígbẹ tí kò níí hu irúgbìn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
أَمۡ حَسِبۡتَ أَنَّ أَصۡحَٰبَ ٱلۡكَهۡفِ وَٱلرَّقِيمِ كَانُواْ مِنۡ ءَايَٰتِنَا عَجَبًا
Tàbí o lérò pé dájúdájú àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta àti wàláhà orúkọ wọn jẹ́ èèmọ̀ kan nínú àwọn àmì Wa?
আরবি তাফসীরসমূহ:
إِذۡ أَوَى ٱلۡفِتۡيَةُ إِلَى ٱلۡكَهۡفِ فَقَالُواْ رَبَّنَآ ءَاتِنَا مِن لَّدُنكَ رَحۡمَةٗ وَهَيِّئۡ لَنَا مِنۡ أَمۡرِنَا رَشَدٗا
(Rántí) nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà wá ibùgbé sínú ọ̀gbun àpáta, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Rẹ, kí O ṣe ìmọ̀nà ní ìrọ̀rùn fún wa nínú ọ̀rọ̀ wa.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَضَرَبۡنَا عَلَىٰٓ ءَاذَانِهِمۡ فِي ٱلۡكَهۡفِ سِنِينَ عَدَدٗا
A kùn wọ́n l’óorun àsùnpiyè nínú ọ̀gbun àpáta f’ọ́dún gbọọrọ.
আরবি তাফসীরসমূহ:
ثُمَّ بَعَثۡنَٰهُمۡ لِنَعۡلَمَ أَيُّ ٱلۡحِزۡبَيۡنِ أَحۡصَىٰ لِمَا لَبِثُوٓاْ أَمَدٗا
Lẹ́yìn náà, A gbé wọn dìde nítorí kí Á lè ṣàfi hàn èwo nínú ìjọ méjèèjì ló mọ gbèdéke òǹkà ọdún tó lò (nínú ọ̀gbun àpáta náà).
আরবি তাফসীরসমূহ:
نَّحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ نَبَأَهُم بِٱلۡحَقِّۚ إِنَّهُمۡ فِتۡيَةٌ ءَامَنُواْ بِرَبِّهِمۡ وَزِدۡنَٰهُمۡ هُدٗى
Àwa ń sọ ìròyìn wọn fún ọ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n. Wọ́n gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. A sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún wọn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَرَبَطۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ إِذۡ قَامُواْ فَقَالُواْ رَبُّنَا رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَن نَّدۡعُوَاْ مِن دُونِهِۦٓ إِلَٰهٗاۖ لَّقَدۡ قُلۡنَآ إِذٗا شَطَطًا
A sì kì wọ́n lọ́kàn nígbà tí wọ́n dìde, tí wọ́n sọ pé: “Olúwa wa ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. A ò sì níí pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀. (Tí a bá pe ọlọ́hun kan lẹ́yìn Rẹ̀) dájúdájú nígbà náà a ti sọ̀rọ̀ tó tayọ ẹnu-ààlà.
আরবি তাফসীরসমূহ:
هَٰٓؤُلَآءِ قَوۡمُنَا ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗۖ لَّوۡلَا يَأۡتُونَ عَلَيۡهِم بِسُلۡطَٰنِۭ بَيِّنٖۖ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا
Àwọn ìjọ wa wọ̀nyí sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu. Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n mú ẹ̀rí tó yanjú wá nípa wọn? Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?”
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَإِذِ ٱعۡتَزَلۡتُمُوهُمۡ وَمَا يَعۡبُدُونَ إِلَّا ٱللَّهَ فَأۡوُۥٓاْ إِلَى ٱلۡكَهۡفِ يَنشُرۡ لَكُمۡ رَبُّكُم مِّن رَّحۡمَتِهِۦ وَيُهَيِّئۡ لَكُم مِّنۡ أَمۡرِكُم مِّرۡفَقٗا
(Rántí nígbà tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fúnra wọn pé:) nígbà tí ẹ bá yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, kí ẹ wá ibùgbé sínú ọ̀gbun àpáta, Olúwa yín yóò tẹ́ nínú ìkẹ́ Rẹ̀ sílẹ̀ fún yín. Ó sì máa ṣe ọ̀rọ̀ yín ní ìrọ̀rùn fún yín.
আরবি তাফসীরসমূহ:
۞ وَتَرَى ٱلشَّمۡسَ إِذَا طَلَعَت تَّزَٰوَرُ عَن كَهۡفِهِمۡ ذَاتَ ٱلۡيَمِينِ وَإِذَا غَرَبَت تَّقۡرِضُهُمۡ ذَاتَ ٱلشِّمَالِ وَهُمۡ فِي فَجۡوَةٖ مِّنۡهُۚ ذَٰلِكَ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِۗ مَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ وَلِيّٗا مُّرۡشِدٗا
O máa rí òòrùn nígbà tí ó bá yọ, ó máa yẹ̀bá kúrò níbi ọ̀gbun wọn sí ọwọ́ ọ̀tún. Nígbà tí ó bá tún wọ̀, ó máa fi wọ́n sílẹ̀ sí ọwọ́ òsì. Wọ́n sì wà nínú àyè tí ó fẹjú nínú ọ̀gbun àpáta. Ìyẹn wà nínú àwọn àmì Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá ṣì lọ́nà, o ò sì níí rí olùrànlọ́wọ́ atọ́ni-sọ́nà kan fún un.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَتَحۡسَبُهُمۡ أَيۡقَاظٗا وَهُمۡ رُقُودٞۚ وَنُقَلِّبُهُمۡ ذَاتَ ٱلۡيَمِينِ وَذَاتَ ٱلشِّمَالِۖ وَكَلۡبُهُم بَٰسِطٞ ذِرَاعَيۡهِ بِٱلۡوَصِيدِۚ لَوِ ٱطَّلَعۡتَ عَلَيۡهِمۡ لَوَلَّيۡتَ مِنۡهُمۡ فِرَارٗا وَلَمُلِئۡتَ مِنۡهُمۡ رُعۡبٗا
(Tí o bá rí wọn), ó máa lérò pé wọ́n kò sí lójú oorun, ojú oorun ni wọ́n sì wà. A sì ń yí wọn ní ẹ̀gbẹ́ padà sí ọ̀tún àti sí òsì. Ajá wọn sì na apá rẹ̀ méjèèjì sílẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà. Tí ó bá jẹ́ pé o yọjú wò wọ́n ni, ìwọ ìbá pẹ̀yìndà láti họ fún wọn, ìwọ ìbá sì kún fún ìbẹ̀rù-bojo láti ara wọn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَكَذَٰلِكَ بَعَثۡنَٰهُمۡ لِيَتَسَآءَلُواْ بَيۡنَهُمۡۚ قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ كَمۡ لَبِثۡتُمۡۖ قَالُواْ لَبِثۡنَا يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۚ قَالُواْ رَبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَا لَبِثۡتُمۡ فَٱبۡعَثُوٓاْ أَحَدَكُم بِوَرِقِكُمۡ هَٰذِهِۦٓ إِلَى ٱلۡمَدِينَةِ فَلۡيَنظُرۡ أَيُّهَآ أَزۡكَىٰ طَعَامٗا فَلۡيَأۡتِكُم بِرِزۡقٖ مِّنۡهُ وَلۡيَتَلَطَّفۡ وَلَا يُشۡعِرَنَّ بِكُمۡ أَحَدًا
Báyẹn (ni wọ́n wà) tí A fi gbé wọn dìde padà nítorí kí wọ́n lè bi ara wọn léèrè ìbéèrè. Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ìgbà wo lẹ ti wà níbí?” Wọ́n sọ pé: “A wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí apá kan nínú ọjọ́.” Wọ́n sọ pé: “Olúwa yín lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ìgbà tí ẹ ti wà níbí.” Nítorí náà, ẹ gbé ọ̀kan nínú yín dìde lọ sí inú ìlú pẹ̀lú owó fàdákà yín yìí. Kí ó wo èwó nínú oúnjẹ ìlú ló mọ́ jùlọ, kí ó sì mú àsè wá fún yín nínú rẹ̀. Kí ó ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kò sì gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnì kan kan fura si yín.
আরবি তাফসীরসমূহ:
إِنَّهُمۡ إِن يَظۡهَرُواْ عَلَيۡكُمۡ يَرۡجُمُوكُمۡ أَوۡ يُعِيدُوكُمۡ فِي مِلَّتِهِمۡ وَلَن تُفۡلِحُوٓاْ إِذًا أَبَدٗا
(Nítorí pé) dájúdájú tí wọ́n bá fi lè mọ̀ nípa yín, wọn yóò jù yín lókò tàbí kí wọ́n da yín padà sínú ẹ̀sìn wọn. (Tí ó bá sì fi rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà, ẹ kò níí jèrè mọ́ láéláé.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَكَذَٰلِكَ أَعۡثَرۡنَا عَلَيۡهِمۡ لِيَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ لَا رَيۡبَ فِيهَآ إِذۡ يَتَنَٰزَعُونَ بَيۡنَهُمۡ أَمۡرَهُمۡۖ فَقَالُواْ ٱبۡنُواْ عَلَيۡهِم بُنۡيَٰنٗاۖ رَّبُّهُمۡ أَعۡلَمُ بِهِمۡۚ قَالَ ٱلَّذِينَ غَلَبُواْ عَلَىٰٓ أَمۡرِهِمۡ لَنَتَّخِذَنَّ عَلَيۡهِم مَّسۡجِدٗا
Báyẹn ni A ṣe jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ pé dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Àti pé dájúdájú Àkókò náà kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Rántí (nígbà tí àwọn ènìyàn) ń ṣe àríyànjiyàn láààrin ara wọn nípa ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n sọ pé: “Ẹ mọ ilé kan lé wọn lórí. Olúwa wọn lÓ nímọ̀ jùlọ nípa wọn.” Àwọn tó borí lórí ọ̀rọ̀ wọn sì wí pé: “Dájúdájú a máa sọ orí àpáta wọn di mọ́sálásí.”¹
1. Láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn tí ó kú sórí rẹ̀ pé: “Ibi dandan Allāhu ń bẹ lórí àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ (nítorí pé), wọ́n sọ sàréè àwọn Ànábì di ilé ìjọ́sìn.” ‘Ā’iṣah sọ pé: “Tí kì í bá ṣe nítorí èyí ni, wọn ìbá ṣe àfihàn ojú sàréè rẹ̀ ṣùgbọ́n dájúdájú ẹ̀rù ń bà wọ́n pé kí wọ́n má sọ sàréè rẹ̀ di mọ́sálásí. (Muslim) Kíyè sí i, ní ìpìlẹ̀ wọ́n sin òkú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sí ibi tí ó kú sí nínú yàrá ìyá wa, ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Ní ọjọ́ náà sì nìyí wọ́n kọ́ ilé Ànábì papọ̀ mọ́ mọ́sálásí rẹ̀ ni. Ilé rẹ̀ sì bọ́ sí ọwọ́ iwájú mọ́sálásí. Àmọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín fífẹ̀ tí wọ́n padà fẹ mọ́sálásí rẹ̀ lójú sí ọ̀tún, òsì, ẹ̀yìn àti iwájú, wọn kò sì fẹ́ wú òkú Ànábì àti òkú Abu-Bakr àti òkú ‘Umar jáde kúrò nínú sàréè, èyí ló ṣokùnfà tí ilé náà fi bọ́ sínú mọ́sálásí. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ sí mọ́sálásí, ní ìbámu sí hadīth ìyá wa ‘Ā’iṣah tí a mú wá ṣíwájú. Èyí tí ó sì ṣẹlẹ̀ sí mọ́sálásì Òjísẹ́ yìí náà - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yóò padà ní àtúnṣe lọ́jọ́ iwájú - ’in ṣā Allāhu - nítorí pé, èèwọ̀ ni kí sàréè bọ́ sínú mọ́sálásí láì ní àyàfi nínú!
আরবি তাফসীরসমূহ:
سَيَقُولُونَ ثَلَٰثَةٞ رَّابِعُهُمۡ كَلۡبُهُمۡ وَيَقُولُونَ خَمۡسَةٞ سَادِسُهُمۡ كَلۡبُهُمۡ رَجۡمَۢا بِٱلۡغَيۡبِۖ وَيَقُولُونَ سَبۡعَةٞ وَثَامِنُهُمۡ كَلۡبُهُمۡۚ قُل رَّبِّيٓ أَعۡلَمُ بِعِدَّتِهِم مَّا يَعۡلَمُهُمۡ إِلَّا قَلِيلٞۗ فَلَا تُمَارِ فِيهِمۡ إِلَّا مِرَآءٗ ظَٰهِرٗا وَلَا تَسۡتَفۡتِ فِيهِم مِّنۡهُمۡ أَحَدٗا
Wọ́n ń wí pé: “Mẹ́ta ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹrin wọn.” Wọ́n tún ń wí pé: “Márùn-ún ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹfà wọn.” Ọ̀rọ̀ tó pamọ́ fún wọn ni wọ́n ń sọ, (wọ́n ń dá àbá ni). Wọ́n tún ń wí pé: “Méje ni wọ́n. Ajá wọn ṣe ìkẹjọ wọn.” Sọ pé: “Olúwa mi lÓ nímọ̀ jùlọ nípa òǹkà wọn. Kò sí (ẹni tí) ó mọ (òǹkà) wọn àfi àwọn díẹ̀. Nítorí náà, má ṣe bá wọn ṣe àríyànjiyàn nípa (òǹkà) wọn àfi (kí o fi) àríyànjiyàn (náà tì síbi ẹ̀rí) tó yanjú (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ yìí). Má sì ṣe bi ẹnì kan nínú wọn léèrè nípa (òǹkà) wọn.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَلَا تَقُولَنَّ لِشَاْيۡءٍ إِنِّي فَاعِلٞ ذَٰلِكَ غَدًا
Má ṣe sọ nípa kiní kan pé: “Dájúdájú èmi yóò ṣe ìyẹn ní ọ̀la.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ وَٱذۡكُر رَّبَّكَ إِذَا نَسِيتَ وَقُلۡ عَسَىٰٓ أَن يَهۡدِيَنِ رَبِّي لِأَقۡرَبَ مِنۡ هَٰذَا رَشَدٗا
Àyàfi (kí o fi kún un pé) “tí Allāhu bá fẹ́.” Ṣe ìrántí Olúwa rẹ nígbà tí o bá gbàgbé (láti sọ bẹ́ẹ̀ lásìkò náà). Kí o sì sọ (fún wọn) pé: “Ó rọrùn kí Olúwa mi tọ́ mi sọ́nà lórí rẹ̀ pẹ̀lú èyí tí ó súnmọ́ jù èyí lọ ní ìmọ̀nà (fún yín).”¹
1. Okùnfà āyah yìí ni pé, nígbà tí àwọn yẹhudi wá bi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - léèrè nípa ọ̀rọ̀ àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta pẹ̀lú èròǹgbà wọn pé tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní ti òdodo, ó yẹ kí ó nímọ̀ nípa wọn, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wá gbọ́ ìtàn wọn ní ọjọ́ kejì pẹ̀lú èròǹgbà rẹ̀ pé Allāhu á ti fi ìmísí nípa wọn ránṣẹ́ sí òun. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò sì sọ fún àwọn yẹhudi náà pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Àmọ́ àì sọ bẹ́ẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ọjọ́ àdéhùn tó ṣe fún wọn yẹ̀.
Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọ́ Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ẹ̀kọ́ pé, ó yẹ kí ó fi kún un fún wọn pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Lẹ́yìn náà, ìmísí nípa àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta dé. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì tún jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé, àwọn ìtàn ìmọ̀nà mìíràn wà tó lè mú kí àwọn yẹhudi wọ̀nyẹn mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ní í ṣe. Tí wọ́n bá ṣetán láti tẹ̀lé ìmọ̀nà tí Ànábì mú wá, Allāhu tún lè sọ àwọn ìtàn tó lọ́jọ́ lórí ju ti àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta, tó sì tún lágbára jùlọ láti fún àwọn ọkàn ní ìmọ̀nà. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì kúkú ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ayérayé, àwọn ọ̀rọ̀ ìgbà-àwá-sẹ̀ bíi ìtàn ìṣẹ̀dá ayé àti ọ̀run, ìtàn àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun tó ti ré kọjá lọ tí kò sí déètì rẹ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan kan. Àmọ́ sá, olórí-kunkun ni àwọn yẹhudi; wọ́n gbọ àwọn ìyáláàyá ìtàn òdodo náà, wọ́n sì gbúnrí, wọn kò sì padà sínú ’Islām.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَلَبِثُواْ فِي كَهۡفِهِمۡ ثَلَٰثَ مِاْئَةٖ سِنِينَ وَٱزۡدَادُواْ تِسۡعٗا
Wọ́n wà nínú ọ̀gbun àpáta wọn fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún. Wọ́n tún lo àlékún ọdún mẹ́sàn-án.
আরবি তাফসীরসমূহ:
قُلِ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا لَبِثُواْۖ لَهُۥ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ أَبۡصِرۡ بِهِۦ وَأَسۡمِعۡۚ مَا لَهُم مِّن دُونِهِۦ مِن وَلِيّٖ وَلَا يُشۡرِكُ فِي حُكۡمِهِۦٓ أَحَدٗا
Sọ pé: “Allāhu lÓ nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n lò (nínú ọ̀gbun àpáta). TiRẹ̀ ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kì ni kò rí tán, kì sí ni kò gbọ́ tán! Kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀. Kò sì fi ẹnì kan ṣe akẹgbẹ́ nínú ìdájọ́ Rẹ̀.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَٱتۡلُ مَآ أُوحِيَ إِلَيۡكَ مِن كِتَابِ رَبِّكَۖ لَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَٰتِهِۦ وَلَن تَجِدَ مِن دُونِهِۦ مُلۡتَحَدٗا
Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí ó lè yí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ padà. Ìwọ kò sì lè rí ibùsásí kan lẹ́yìn ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَٱصۡبِرۡ نَفۡسَكَ مَعَ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ وَلَا تَعۡدُ عَيۡنَاكَ عَنۡهُمۡ تُرِيدُ زِينَةَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَا تُطِعۡ مَنۡ أَغۡفَلۡنَا قَلۡبَهُۥ عَن ذِكۡرِنَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ وَكَانَ أَمۡرُهُۥ فُرُطٗا
Ṣe sùúrù fún ẹ̀mí rẹ láti wà pẹ̀lú àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń wá Ojú rere Rẹ̀. Má ṣe fojú pa wọ́n rẹ́ láti wá ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Má sì ṣe tẹ̀lé ẹni tí A mú ọkàn rẹ̀ gbàgbé ìrántí Wa. Ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àṣejù.¹
1. Àwọn onisūfi lérò pé āyah yìí gbè fún àwọn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al- ’An‘ām; 6:52 fún àgbọ́yé āyah yìí.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَقُلِ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَن شَآءَ فَلۡيُؤۡمِن وَمَن شَآءَ فَلۡيَكۡفُرۡۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا لِلظَّٰلِمِينَ نَارًا أَحَاطَ بِهِمۡ سُرَادِقُهَاۚ وَإِن يَسۡتَغِيثُواْ يُغَاثُواْ بِمَآءٖ كَٱلۡمُهۡلِ يَشۡوِي ٱلۡوُجُوهَۚ بِئۡسَ ٱلشَّرَابُ وَسَآءَتۡ مُرۡتَفَقًا
Sọ pé: “Òdodo (nìyí) láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó gbàgbọ́ ní òdodo. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ kí ó ṣàì gbàgbọ́. Dájúdájú Àwa pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn alábòsí, tí ọgbà rẹ̀ yóò yí wọn po. Tí wọ́n bá ń tọrọ omi mímu, A óò fún wọn ní omi mímu kan tó dà bí ògéré epo gbígbóná, tí (ìgbóná rẹ̀) yó sì máa ṣe àwọn ojú. Ohun mímu náà burú. Ó sì burú ní ibùkójọ.
আরবি তাফসীরসমূহ:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجۡرَ مَنۡ أَحۡسَنَ عَمَلًا
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ráre.
আরবি তাফসীরসমূহ:
أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ جَنَّٰتُ عَدۡنٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهِمُ ٱلۡأَنۡهَٰرُ يُحَلَّوۡنَ فِيهَا مِنۡ أَسَاوِرَ مِن ذَهَبٖ وَيَلۡبَسُونَ ثِيَابًا خُضۡرٗا مِّن سُندُسٖ وَإِسۡتَبۡرَقٖ مُّتَّكِـِٔينَ فِيهَا عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِۚ نِعۡمَ ٱلثَّوَابُ وَحَسُنَتۡ مُرۡتَفَقٗا
Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra ‘Adn, tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ wọn. Wọn máa ṣe wọ́n ní ọ̀ṣọ́ nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn n̄ǹkan ọwọ́ látara wúrà. Wọn yóò máa wọ aṣọ àrán aláwọ̀ ewéko (èyí tí ó) fẹ́lẹ́ àti (èyí tí) ó nípọn. Wọn yó sì máa rọ̀gbọ̀kú lórí ibùsùn ọlá nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra). Ẹ̀san náà dára. Ó sì dára ní ibùkójọ.
আরবি তাফসীরসমূহ:
۞ وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلٗا رَّجُلَيۡنِ جَعَلۡنَا لِأَحَدِهِمَا جَنَّتَيۡنِ مِنۡ أَعۡنَٰبٖ وَحَفَفۡنَٰهُمَا بِنَخۡلٖ وَجَعَلۡنَا بَيۡنَهُمَا زَرۡعٗا
Fi àwọn ọkùnrin méjì kan ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún wọn; A fún ọ̀kan nínú wọn ní ọgbà èso àjàrà méjì. A sì fi àwọn igi dàbínù yí wọn ká. A tún fi àwọn igi eléso là wọ́n láààrin.
আরবি তাফসীরসমূহ:
كِلۡتَا ٱلۡجَنَّتَيۡنِ ءَاتَتۡ أُكُلَهَا وَلَمۡ تَظۡلِم مِّنۡهُ شَيۡـٔٗاۚ وَفَجَّرۡنَا خِلَٰلَهُمَا نَهَرٗا
Ìkíní kejì àwọn oko méjèèjì ń so èso wọn. Àwọn èso rẹ̀ kì í pẹ̀ dín. A sì jẹ́ kí odò ṣàn kọjá láààrin oko méjèèjì.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَكَانَ لَهُۥ ثَمَرٞ فَقَالَ لِصَٰحِبِهِۦ وَهُوَ يُحَاوِرُهُۥٓ أَنَا۠ أَكۡثَرُ مِنكَ مَالٗا وَأَعَزُّ نَفَرٗا
Ó ní èso (sẹ́). Ó sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó ń bá a jiyàn (báyìí) pé: “Èmi ní dúkìá lọ́wọ́ jù ọ́ lọ. Mo tún fi àwọn ènìyàn ní agbára jù ọ́ lọ.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَدَخَلَ جَنَّتَهُۥ وَهُوَ ظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ قَالَ مَآ أَظُنُّ أَن تَبِيدَ هَٰذِهِۦٓ أَبَدٗا
Ó wọ inú oko rẹ̀ ní ẹni tí ó ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀, ó wí pé: “Èmi kò lérò pé èyí máa parun láéláé.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةٗ وَلَئِن رُّدِدتُّ إِلَىٰ رَبِّي لَأَجِدَنَّ خَيۡرٗا مِّنۡهَا مُنقَلَبٗا
Èmi kò sì lérò pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé tí wọ́n bá tiẹ̀ dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú mo tún máa rí ibùdésí tó dára ju èyí lọ.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ لَهُۥ صَاحِبُهُۥ وَهُوَ يُحَاوِرُهُۥٓ أَكَفَرۡتَ بِٱلَّذِي خَلَقَكَ مِن تُرَابٖ ثُمَّ مِن نُّطۡفَةٖ ثُمَّ سَوَّىٰكَ رَجُلٗا
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un nígbà tí ó ń jà á níyàn (báyìí) pé: “Ṣé o máa ṣàì gbàgbọ́ nínú Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú erùpẹ̀, lẹ́yìn náà, láti inú àtọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ́ ní ọkùnrin tó pé ní ẹ̀dá.
আরবি তাফসীরসমূহ:
لَّٰكِنَّا۠ هُوَ ٱللَّهُ رَبِّي وَلَآ أُشۡرِكُ بِرَبِّيٓ أَحَدٗا
Ṣùgbọ́n ní tèmi, Olúwa mi, Òun ni Allāhu. Èmi kò sì níí sọ ẹnì kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَلَوۡلَآ إِذۡ دَخَلۡتَ جَنَّتَكَ قُلۡتَ مَا شَآءَ ٱللَّهُ لَا قُوَّةَ إِلَّا بِٱللَّهِۚ إِن تَرَنِ أَنَا۠ أَقَلَّ مِنكَ مَالٗا وَوَلَدٗا
Nígbà tí o wọ inú ọgbà oko rẹ, kí ni kò mú ọ sọ pé: “Ohun tí Allāhu bá fẹ́! Kò sí agbára kan bí kò ṣe pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí o bá sì rí èmi pé mo kéré sí ọ ní dúkìá àti ọmọ,
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَعَسَىٰ رَبِّيٓ أَن يُؤۡتِيَنِ خَيۡرٗا مِّن جَنَّتِكَ وَيُرۡسِلَ عَلَيۡهَا حُسۡبَانٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فَتُصۡبِحَ صَعِيدٗا زَلَقًا
ó súnmọ́ kí Olúwa mi fún èmi náà ní oore kan tí ó máa dára ju ọgbà oko tìrẹ. (Ó sì súnmọ́) kí Ó sọ ìyà kan kalẹ̀ sínú ọgbà oko rẹ láti sánmọ̀; ó sì máa di ilẹ̀ aṣálẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
أَوۡ يُصۡبِحَ مَآؤُهَا غَوۡرٗا فَلَن تَسۡتَطِيعَ لَهُۥ طَلَبٗا
Tàbí kí omi rẹ̀ gbẹ. O ò sì níí lè wá omi kàn.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَأُحِيطَ بِثَمَرِهِۦ فَأَصۡبَحَ يُقَلِّبُ كَفَّيۡهِ عَلَىٰ مَآ أَنفَقَ فِيهَا وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا وَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُشۡرِكۡ بِرَبِّيٓ أَحَدٗا
Wọ́n sì pa èso rẹ̀ run pátápátá. Ó sì di ẹni tó ń fí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lura wọn pẹ́ẹ́pẹ́¹ nípa ohun tí ó ti ná sórí rẹ̀. (Àwọn ilé rẹ̀) dàwó lulẹ̀ tòrùlé-tòrùlé wọn. Ó sì ń wí pé: “Yéè! Èmi ìbá tí sọ ẹnì kan kan di akẹgbẹ́ fún Olúwa mi. (Èmi ìbá má ṣẹbọ)”
1. “ó ń fí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lura wọn pẹ́ẹ́pẹ́” ó ń ká àbámọ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَلَمۡ تَكُن لَّهُۥ فِئَةٞ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مُنتَصِرًا
Kò ní ìjọ kan tí ó máa ràn án lọ́wọ́ mọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.
আরবি তাফসীরসমূহ:
هُنَالِكَ ٱلۡوَلَٰيَةُ لِلَّهِ ٱلۡحَقِّۚ هُوَ خَيۡرٞ ثَوَابٗا وَخَيۡرٌ عُقۡبٗا
Níbẹ̀ yẹn, ti Allāhu, Ọba Òdodo ni ìjọba. Ó lóore jùlọ ní ẹ̀san, Ó sì lóore jùlọ ní ìkángun (rere).
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَٱضۡرِبۡ لَهُم مَّثَلَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَآءٍ أَنزَلۡنَٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخۡتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلۡأَرۡضِ فَأَصۡبَحَ هَشِيمٗا تَذۡرُوهُ ٱلرِّيَٰحُۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ مُّقۡتَدِرًا
Ṣe àkàwé ilé ayé fún wọn; ó dà bí omi tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀. Lẹ́yìn náà, ó ròpọ̀ mọ́ irúgbìn ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, (irúgbìn) di gbígbẹ, tí atẹ́gùn ń fọ́nká. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
আরবি তাফসীরসমূহ:
ٱلۡمَالُ وَٱلۡبَنُونَ زِينَةُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَٱلۡبَٰقِيَٰتُ ٱلصَّٰلِحَٰتُ خَيۡرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابٗا وَخَيۡرٌ أَمَلٗا
Ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé ni dúkìá àti àwọn ọmọ. Àwọn iṣẹ́ rere tó máa wà títí láéláé lóore jùlọ ní ẹ̀san lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, ó sì lóore jùlọ ní ìrètí.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَيَوۡمَ نُسَيِّرُ ٱلۡجِبَالَ وَتَرَى ٱلۡأَرۡضَ بَارِزَةٗ وَحَشَرۡنَٰهُمۡ فَلَمۡ نُغَادِرۡ مِنۡهُمۡ أَحَدٗا
(Rántí) ọjọ́ tí A máa mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn). O sì máa rí ilẹ̀ tí ó máa fojú hàn (tí kò níí sí n̄ǹkan kan mọ́ lórí rẹ̀). A máa kó wọn jọ. A ò sì níí fi ẹnì kan sílẹ̀ nínú wọn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَعُرِضُواْ عَلَىٰ رَبِّكَ صَفّٗا لَّقَدۡ جِئۡتُمُونَا كَمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةِۭۚ بَلۡ زَعَمۡتُمۡ أَلَّن نَّجۡعَلَ لَكُم مَّوۡعِدٗا
Wọn yó sì kó wọn wá síwájú Olúwa rẹ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹ ti wá bá Wa (báyìí) gẹ́gẹ́ bí A ṣe da yín nígbà àkọ́kọ́. Àmọ́ ẹ sọ láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé A ò níí mú ọjọ́ àdéhùn ṣẹ fún yín.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَوُضِعَ ٱلۡكِتَٰبُ فَتَرَى ٱلۡمُجۡرِمِينَ مُشۡفِقِينَ مِمَّا فِيهِ وَيَقُولُونَ يَٰوَيۡلَتَنَا مَالِ هَٰذَا ٱلۡكِتَٰبِ لَا يُغَادِرُ صَغِيرَةٗ وَلَا كَبِيرَةً إِلَّآ أَحۡصَىٰهَاۚ وَوَجَدُواْ مَا عَمِلُواْ حَاضِرٗاۗ وَلَا يَظۡلِمُ رَبُّكَ أَحَدٗا
A máa gbé ìwé iṣẹ́ ẹ̀dá kalẹ̀ (fún wọn). Nígbà náà, o máa rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn yóò máa bẹ̀rù nípa ohun tí ń bẹ nínú ìwé iṣẹ́ wọn. Wọn yóò wí pé: “Ègbé wa! Kí ló mú ìwé yìí ná; kò fi ohun kékeré àti ńlá kan sílẹ̀ láì kọ ọ́ sílẹ̀?” Wọ́n sì bá ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ níbẹ̀. Olúwa rẹ kò sì níí ṣàbòsí sí ẹnì kan.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ كَانَ مِنَ ٱلۡجِنِّ فَفَسَقَ عَنۡ أَمۡرِ رَبِّهِۦٓۗ أَفَتَتَّخِذُونَهُۥ وَذُرِّيَّتَهُۥٓ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِي وَهُمۡ لَكُمۡ عَدُوُّۢۚ بِئۡسَ لِلظَّٰلِمِينَ بَدَلٗا
(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.” Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àlùjànnú. Ó sì yapa sí àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nítorí náà, ṣé ẹ máa mú òun àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ ní aláfẹ̀yìntì lẹ́yìn Mi ni, ọ̀tá yín sì ni wọ́n. Pàṣípààrọ̀ tó burú ni fún àwọn alábòsí.¹
1. Ìyẹn ni pé, aburú ni fún ẹni tí ó mú Èṣù ní aláfẹ̀yìntì rẹ̀ dípò Allāhu.
আরবি তাফসীরসমূহ:
۞ مَّآ أَشۡهَدتُّهُمۡ خَلۡقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَا خَلۡقَ أَنفُسِهِمۡ وَمَا كُنتُ مُتَّخِذَ ٱلۡمُضِلِّينَ عَضُدٗا
Èmi kò fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí sí ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ìṣẹ̀dá àwọn gan-an alára. Èmi kò sì mú àwọn aṣinilọ́nà ní olùrànlọ́wọ́.¹
1. Ó ṣe wá jẹ́ tí ẹ̀ ń sọ wọ́n di akẹgbẹ́ Mi?
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَيَوۡمَ يَقُولُ نَادُواْ شُرَكَآءِيَ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُمۡ فَدَعَوۡهُمۡ فَلَمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَهُمۡ وَجَعَلۡنَا بَيۡنَهُم مَّوۡبِقٗا
(Rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò sọ pé: “Ẹ pe àwọn akẹgbẹ́ Mi tí ẹ sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n).” Wọ́n pè wọ́n. Wọn kò sì dá wọn lóhùn. A sì ti fi àyè ìparun sáààrin wọn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَرَءَا ٱلۡمُجۡرِمُونَ ٱلنَّارَ فَظَنُّوٓاْ أَنَّهُم مُّوَاقِعُوهَا وَلَمۡ يَجِدُواْ عَنۡهَا مَصۡرِفٗا
Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sì rí Iná. Wọ́n sì mọ̀ dájúdájú pé àwọn yóò kó sínú rẹ̀. Wọn kò sì rí ibùsásí kan kúrò nínú rẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لِلنَّاسِ مِن كُلِّ مَثَلٖۚ وَكَانَ ٱلۡإِنسَٰنُ أَكۡثَرَ شَيۡءٖ جَدَلٗا
Dájúdájú A ti ṣe àlàyé oníran-ànran sínú al-Ƙur’ān fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú gbogbo àkàwé. Ènìyàn sì jẹ́ olùjiyàn ju ohunkóhun lọ.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤۡمِنُوٓاْ إِذۡ جَآءَهُمُ ٱلۡهُدَىٰ وَيَسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّهُمۡ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمۡ سُنَّةُ ٱلۡأَوَّلِينَ أَوۡ يَأۡتِيَهُمُ ٱلۡعَذَابُ قُبُلٗا
Kò sí ohun tó dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn, (kò sì sí ohun tó dí wọn lọ́wọ́ láti) tọrọ àforíjìn Olúwa wọn, bí kò ṣe pé (wọ́n fẹ́) kí ìṣe (Allāhu nípa ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ dé bá àwọn náà tàbí kí ìyà dé bá wọn ní ojúkojú.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَمَا نُرۡسِلُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَۚ وَيُجَٰدِلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ لِيُدۡحِضُواْ بِهِ ٱلۡحَقَّۖ وَٱتَّخَذُوٓاْ ءَايَٰتِي وَمَآ أُنذِرُواْ هُزُوٗا
Àti pé A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ (lásán) àfi kí wọ́n jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń fi irọ́ ṣàtakò nítorí kí wọ́n lè fi ba òdodo jẹ́. Wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn di yẹ̀yẹ́.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦ فَأَعۡرَضَ عَنۡهَا وَنَسِيَ مَا قَدَّمَتۡ يَدَاهُۚ إِنَّا جَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٗاۖ وَإِن تَدۡعُهُمۡ إِلَى ٱلۡهُدَىٰ فَلَن يَهۡتَدُوٓاْ إِذًا أَبَدٗا
Ta sì ló ṣàbòsí ju ẹni tí wọ́n fi àwọn āyah Olúwa rẹ̀ ṣèrántí fún, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀, tí ó sì gbàgbé ohun tí ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì tì síwájú? Dájúdájú Àwa fi èbìbò bo ọkàn wọn nítorí kí wọ́n má baà gbọ́ ọ yé. A sì fi èdídí sínú etí wọn. Tí ìwọ bá pè wọ́n síbi ìmọ̀nà, nígbà náà wọn kò sì níí mọ̀nà láéláé.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَرَبُّكَ ٱلۡغَفُورُ ذُو ٱلرَّحۡمَةِۖ لَوۡ يُؤَاخِذُهُم بِمَا كَسَبُواْ لَعَجَّلَ لَهُمُ ٱلۡعَذَابَۚ بَل لَّهُم مَّوۡعِدٞ لَّن يَجِدُواْ مِن دُونِهِۦ مَوۡئِلٗا
Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́. Bí ó bá jẹ́ pé Ó máa fi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ mú wọn ni, ìbá tètè mú ìyà wá fún wọn. Ṣùgbọ́n àkókò àdéhùn (àjíǹde) wà fún wọn. Wọn kò sì níí rí ibùsásí kan lẹ́yìn rẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَتِلۡكَ ٱلۡقُرَىٰٓ أَهۡلَكۡنَٰهُمۡ لَمَّا ظَلَمُواْ وَجَعَلۡنَا لِمَهۡلِكِهِم مَّوۡعِدٗا
Ìwọ́nyí ni àwọn ìlú tí A ti parẹ́ nígbà tí wọ́n ṣàbòsí. A sì fún wọn ní (àkókò) àdéhùn fún ìparun wọn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِفَتَىٰهُ لَآ أَبۡرَحُ حَتَّىٰٓ أَبۡلُغَ مَجۡمَعَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ أَوۡ أَمۡضِيَ حُقُبٗا
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi kò níí yé rìn títí mo máa fi dé ibi tí odò méjì ti papọ̀ tàbí (títí) mo máa fi lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَلَمَّا بَلَغَا مَجۡمَعَ بَيۡنِهِمَا نَسِيَا حُوتَهُمَا فَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِي ٱلۡبَحۡرِ سَرَبٗا
Nígbà tí àwọn méjèèjì sì dé ibi tí odò méjèèjì ti papọ̀, wọ́n gbàgbé ẹja wọn. (Ẹja náà) sì sọ ojú ọ̀nà rẹ̀ di poro ọ̀nà nínú odò.
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَلَمَّا جَاوَزَا قَالَ لِفَتَىٰهُ ءَاتِنَا غَدَآءَنَا لَقَدۡ لَقِينَا مِن سَفَرِنَا هَٰذَا نَصَبٗا
Nígbà tí àwọn méjèèjì ré kọjá (àyè náà), ó sọ fún ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Fún wa ní oúnjẹ ọ̀sán wa. Dájúdájú a ti ko wàhálà nínú ìrìn-àjò wa yìí.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ أَرَءَيۡتَ إِذۡ أَوَيۡنَآ إِلَى ٱلصَّخۡرَةِ فَإِنِّي نَسِيتُ ٱلۡحُوتَ وَمَآ أَنسَىٰنِيهُ إِلَّا ٱلشَّيۡطَٰنُ أَنۡ أَذۡكُرَهُۥۚ وَٱتَّخَذَ سَبِيلَهُۥ فِي ٱلۡبَحۡرِ عَجَبٗا
(Ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀) sọ pé: “Ṣé o rí i! Nígbà tí a wà níbi àpáta (fún ìsinmi), dájúdájú mo ti gbàgbé ẹja náà (síbẹ̀)? Kò sì sí ohun tí ó mú mi gbàgbé rẹ̀ bí kò ṣe Èṣù, tí kò jẹ́ kí n̄g rántí rẹ̀. (Ẹja náà) sì ti mú ọ̀nà rẹ̀ tọ̀ lọ nínú odò ní ọ̀nà ìyanu.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ ذَٰلِكَ مَا كُنَّا نَبۡغِۚ فَٱرۡتَدَّا عَلَىٰٓ ءَاثَارِهِمَا قَصَصٗا
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “(Ibi tí ẹja ti lọ) yẹn ni ohun tí à ń wá.”¹ Àwọn méjèèjì sì padà sẹ́yìn láti tọ orípa ẹsẹ̀ wọn bí wọ́n ti ṣe tọ̀ ọ́ wá.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ti sọ fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - tẹ́lẹ̀ pé, ibi tí wọ́n bá gbàgbé ẹja sí, ibẹ̀ ni wọ́n máa ti pàdé ẹni tí ó ń lọ ṣàbẹ̀wò rẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَوَجَدَا عَبۡدٗا مِّنۡ عِبَادِنَآ ءَاتَيۡنَٰهُ رَحۡمَةٗ مِّنۡ عِندِنَا وَعَلَّمۡنَٰهُ مِن لَّدُنَّا عِلۡمٗا
Àwọn méjèèjì sì bá ẹrúsìn kan nínú àwọn ẹrúsìn Wa (níbẹ̀), tí A fún ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. A sì fún un ní ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Wa.
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ لَهُۥ مُوسَىٰ هَلۡ أَتَّبِعُكَ عَلَىٰٓ أَن تُعَلِّمَنِ مِمَّا عُلِّمۡتَ رُشۡدٗا
(Ànábì) Mūsā sọ fún un pé: “Ṣé kí n̄g tẹ̀lé ọ nítorí kí o lè kọ́ mi nínú ohun tí Wọ́n fi mọ̀ ọ́ ní ìmọ̀nà.”¹
1. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lérò pé lílọ tí Ànábì Mūsā lọ sí ọ̀dọ̀ Kidr túmọ̀ sí pé Kidr lóore ju Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - lọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Tí Kidr bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Allāhu “waliyyu-llāh”, ipò jíjẹ́ Ànábì jẹ́ oore àjùlọ lórí ipò jíjẹ́ waliyyu. Tí àwọn méjèèjì bá sì dìjọ jẹ́ Ànábì, fífún tí Allāhu - subhanahu wa ta‘ālā - fún Ànábì Mūsā ní Tírà tún jẹ́ oore àjùlọ mìíràn lórí Kidr. Àti pé Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - tún ní oore àjùlọ mìíràn nípa bí ó tún ṣe jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn Òjíṣẹ́ tí a mọ̀ sí àwọn Onípinnu nínú àwọn Òjíṣẹ́ " ’ulul-‘azmi minar-Rusul" - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.
Síwájú sí i, gbogbo mùsùlùmí ni waliyyu-llāh, àmọ́ bí mùsùlùmí kọ̀ọ̀kan bá ṣe súnmọ́ Allāhu tó, nínú ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù rẹ̀ nípa lílo òfin ẹ̀sìn ’Islām, ló máa ṣ’òdíwọ̀n ìsúnmọ́ tí ń bẹ láààrin Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - àti ẹrúsìn Rẹ̀ náà.
Ṣíwájú Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, Allāhu fún àwọn mùsùlùmí kan ní àǹfààní láti rí ìṣípayá mímọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Lára àwọn tí Allāhu ṣe èyí fún ni ìyá Mūsā, Mọryam ìya ‘Īsā, Thul-Ƙọrneen àti Kidr. Ìṣípayá mímọ́ tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn yìí kò sọ wọ́n di Ànábì tàbí Òjíṣẹ́. Àmọ́ wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé àṣẹ tí ìṣípayá mímọ́ náà mú wá fún wọn, bí àpẹ̀ẹrẹ, ìya Ànábì Mūsā kò ṣàdédé gbé ọmọ rẹ̀, Ànábì Mūsā jù sínú odò, tí kì í bá ṣe pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - l’Ó pa á láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìṣípayá mímọ́ tí Ó fi ránṣẹ́ sí i.
Bákan náà, àwọn n̄ǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn tí Kidr dánwò lójú Ànábì Mūsā, ìbá tí ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, tí kì í bá ṣe pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - l’Ó pa á láṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Irú àǹfààní wọ̀nyí wà fún àwọn tó ṣíwájú Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ṣùgbọ́n kò sí fún ìjọ Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Èyí ni pé, lásìkò yìí ẹnì kan kan kò gbọdọ̀ lo òfin kan tí ó yapa sí òfin tí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - mú wá, kí ó wí pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - l’Ó fún òun náà ní ìṣípayá mímọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́ọ́rọ́wọ́ ni onítọ̀ún yóò jáde kúrò nínú ipò jíjẹ́ mùsùlùmí. Ọ̀wọ́ ẹnì kan ṣoṣo tí Allāhu ìbá fún ní ìṣípayá mímọ́ nínú ìjọ Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, òun ni ’Amīrul-mu’minīn, ‘Umar bun Kattọ̄b - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Èyí wà ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tí ó sọ pé: “Dájúdájú ṣíwájú yín nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, ni a ti rí àwọn ènìyàn kan tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (ní ti ìṣípayá mímọ́), wọn kì í sì ṣe Ànábì. Tí ó bá jẹ́ pé ọ̀kan nínú wọn máa wà nínú ìjọ mi ni, ‘Umar ni ìbá jẹ́.” [Al-Bukāriy; bāb mọnāƙib ‘Umọr]
Bákan náà, ohun tí Ànábì Mūsā - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kọ́ lọ́dọ̀ Kidr kò túmọ̀ sí pé, ó kọ́ ọ fún lílò láààrin ìjọ rẹ̀. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ti fún Ànábì Mūsā ní òfin àti ìlànà tirẹ̀ nínú ’Islām, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún un láti lo òfin àti ìlànà tí Allāhu fún Kidr, yálà Kidr jẹ́ waliyyu tàbí Ànábì. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah al-Mọ̄’idah; 5:48.
Nítorí náà, ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fẹ́ kọ́ Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - nípa ìrìn-àjò rẹ̀ sọ́dọ̀ Kidr ni pé, ìmọ̀ nípa òfin àti ìlànà ’Islām, èyí tí Allāhu fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra wọn díẹ̀díẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Ànábì kan sí òmíràn. Àti pé kò rọrùn fún ẹnì kan nínú wọn láti jẹ́ alámọ̀tán ohun gbogbo. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nìkan ṣoṣo sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ إِنَّكَ لَن تَسۡتَطِيعَ مَعِيَ صَبۡرٗا
(Kidr) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ kò lè ṣe sùúrù pẹ̀lú mi.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَكَيۡفَ تَصۡبِرُ عَلَىٰ مَا لَمۡ تُحِطۡ بِهِۦ خُبۡرٗا
Àti pé báwo ni o ṣe máa ṣe sùúrù lórí ohun tí o ò fi ìmọ̀ rọkiri ká rẹ̀?”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ صَابِرٗا وَلَآ أَعۡصِي لَكَ أَمۡرٗا
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí Allāhu bá fẹ́, ó máa bá mi ní onísùúrù. Èmi kò sì níí yapa àṣẹ rẹ.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ فَإِنِ ٱتَّبَعۡتَنِي فَلَا تَسۡـَٔلۡنِي عَن شَيۡءٍ حَتَّىٰٓ أُحۡدِثَ لَكَ مِنۡهُ ذِكۡرٗا
(Kidr) sọ pé: “Tí o bá tẹ̀lé mi, má ṣe bi mí ní ìbéèrè nípa n̄ǹkan kan títí mo fi máa kọ́kọ́ mú ìrántí wá fún ọ nípa rẹ̀.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَا رَكِبَا فِي ٱلسَّفِينَةِ خَرَقَهَاۖ قَالَ أَخَرَقۡتَهَا لِتُغۡرِقَ أَهۡلَهَا لَقَدۡ جِئۡتَ شَيۡـًٔا إِمۡرٗا
Nítorí náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi wọ inú ọkọ̀ ojú-omi. (Kidr) sì dá ọkọ̀ náà lu. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe dá a lu, (ṣé) kí àwọn èrò rẹ̀ lè tẹ̀ rì ni? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan aburú kan!”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ أَلَمۡ أَقُلۡ إِنَّكَ لَن تَسۡتَطِيعَ مَعِيَ صَبۡرٗا
(Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé dájúdájú ìwọ kò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ لَا تُؤَاخِذۡنِي بِمَا نَسِيتُ وَلَا تُرۡهِقۡنِي مِنۡ أَمۡرِي عُسۡرٗا
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Má ṣe bá mi wí nípa ohun tí mo gbàgbé. Má sì ṣe kó ìnira bá mi nínú ọ̀rọ̀ (ìrìn-àjò) mi (pẹ̀lú rẹ).”
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَا لَقِيَا غُلَٰمٗا فَقَتَلَهُۥ قَالَ أَقَتَلۡتَ نَفۡسٗا زَكِيَّةَۢ بِغَيۡرِ نَفۡسٖ لَّقَدۡ جِئۡتَ شَيۡـٔٗا نُّكۡرٗا
Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n fi pàdé ọmọdékùnrin kan. (Kidr) sì pa á. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “O ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) mímọ́, láì gba ẹ̀mí? Dájúdájú o ti ṣe n̄ǹkan aburú o.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
۞ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكَ إِنَّكَ لَن تَسۡتَطِيعَ مَعِيَ صَبۡرٗا
(Kidr) sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé dájúdájú ìwọ kò níí lè ṣe sùúrú pẹ̀lú mi.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ إِن سَأَلۡتُكَ عَن شَيۡءِۭ بَعۡدَهَا فَلَا تُصَٰحِبۡنِيۖ قَدۡ بَلَغۡتَ مِن لَّدُنِّي عُذۡرٗا
(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí mo bá tún bi ọ́ nípa kiní kan lẹ́yìn rẹ̀, má ṣe bá mi rìn mọ́. Dájúdájú o ti mú àwáwí dé òpin lọ́dọ̀ mi.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَٱنطَلَقَا حَتَّىٰٓ إِذَآ أَتَيَآ أَهۡلَ قَرۡيَةٍ ٱسۡتَطۡعَمَآ أَهۡلَهَا فَأَبَوۡاْ أَن يُضَيِّفُوهُمَا فَوَجَدَا فِيهَا جِدَارٗا يُرِيدُ أَن يَنقَضَّ فَأَقَامَهُۥۖ قَالَ لَوۡ شِئۡتَ لَتَّخَذۡتَ عَلَيۡهِ أَجۡرٗا
Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì lọ títí di ìgbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú kan. Wọ́n tọrọ oúnjẹ lọ́dọ̀ àwọn ará ìlú náà. Wọ́n sì kọ̀ láti ṣe wọ́n ní àlejò. Àwọn méjèèjì sì bá ògiri kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ wó. (Kidr) sì gbé e dìde. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé o bá fẹ́, kí o sì gba owó-ọ̀yà lórí rẹ̀.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ هَٰذَا فِرَاقُ بَيۡنِي وَبَيۡنِكَۚ سَأُنَبِّئُكَ بِتَأۡوِيلِ مَا لَمۡ تَسۡتَطِع عَّلَيۡهِ صَبۡرًا
(Kidr) sọ pé: “Èyí ni òpínyà láààrin èmi àti ìwọ. Mo sì máa fún ọ ní ìtúmọ̀ ohun tí ìwọ kò lè ṣe sùúrù lórí rẹ̀.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
أَمَّا ٱلسَّفِينَةُ فَكَانَتۡ لِمَسَٰكِينَ يَعۡمَلُونَ فِي ٱلۡبَحۡرِ فَأَرَدتُّ أَنۡ أَعِيبَهَا وَكَانَ وَرَآءَهُم مَّلِكٞ يَأۡخُذُ كُلَّ سَفِينَةٍ غَصۡبٗا
Ní ti ọkọ̀ ojú-omi, ó jẹ́ ti àwọn mẹ̀kúnnù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí omi. Mo sì fẹ́ láti fi àlébù kàn án (nítorí pé), ọba kan wà níwájú wọn tó ń gba gbogbo ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú ipá.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَأَمَّا ٱلۡغُلَٰمُ فَكَانَ أَبَوَاهُ مُؤۡمِنَيۡنِ فَخَشِينَآ أَن يُرۡهِقَهُمَا طُغۡيَٰنٗا وَكُفۡرٗا
Ní ti ọmọdékùnrin náà, àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. A sì ń bẹ̀rù pé kí ó màa kó ìtayọ ẹnu-ààlà àti àìgbàgbọ́ bá àwọn méjèèjì.¹
1. Ìyẹn ni pé, òbí ń ṣẹ Allāhu níbi ìfẹ́ ọmọ nígbà tí òbí bá ń pọ̀n lẹ́yìn ọmọ burúkú. Aburú ńlá sì ni fún àwọn méjèèjì.
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَأَرَدۡنَآ أَن يُبۡدِلَهُمَا رَبُّهُمَا خَيۡرٗا مِّنۡهُ زَكَوٰةٗ وَأَقۡرَبَ رُحۡمٗا
Nítorí náà, A fẹ́ kí Olúwa àwọn méjèèjì pààrọ̀ rẹ̀ fún wọn pẹ̀lú (èyí) tó lóore jù ú lọ tó máa jẹ́ ẹni mímọ́ jù ú lọ àti (èyí) tó máa jẹ́ ọmọ rere olújú-àánú sí (àwọn òbí rẹ̀) jù ú lọ.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَأَمَّا ٱلۡجِدَارُ فَكَانَ لِغُلَٰمَيۡنِ يَتِيمَيۡنِ فِي ٱلۡمَدِينَةِ وَكَانَ تَحۡتَهُۥ كَنزٞ لَّهُمَا وَكَانَ أَبُوهُمَا صَٰلِحٗا فَأَرَادَ رَبُّكَ أَن يَبۡلُغَآ أَشُدَّهُمَا وَيَسۡتَخۡرِجَا كَنزَهُمَا رَحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَۚ وَمَا فَعَلۡتُهُۥ عَنۡ أَمۡرِيۚ ذَٰلِكَ تَأۡوِيلُ مَا لَمۡ تَسۡطِع عَّلَيۡهِ صَبۡرٗا
Nípa ti ògiri, ó jẹ́ ti àwọn ọmọdékùnrin, ọmọ òrukàn méjì kan nínú ìlú náà. Àpótí-ọrọ̀ kan sì ń bẹ fún àwọn méjèèjì lábẹ́ ògiri náà. Bàbá àwọn méjèèjì sì jẹ́ ẹni rere. Nítorí náà, Olúwa rẹ fẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà dáadáa (bá dúkìá náà), kí wọ́n sì hú dúkìá wọn jáde (kí ó lè jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Èmi kò dá a ṣe láti ọ̀dọ̀ ara mi; (Allāhu l’Ó pa mí láṣẹ rẹ̀). Ìyẹn ni ìtúmọ̀ ohun tí ìwọ kò lè ṣe sùúrù fún.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَن ذِي ٱلۡقَرۡنَيۡنِۖ قُلۡ سَأَتۡلُواْ عَلَيۡكُم مِّنۡهُ ذِكۡرًا
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Thul-Ƙọrneen. Sọ pé: “Mo máa mú ọ̀rọ̀ ìrántí wá fún yín nípa rẹ̀.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
إِنَّا مَكَّنَّا لَهُۥ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَءَاتَيۡنَٰهُ مِن كُلِّ شَيۡءٖ سَبَبٗا
Dájúdájú Àwa fún un ní ipò lórí ilẹ̀. A sì fún un ní ọ̀nà tó lè gbà ṣe gbogbo n̄ǹkan (tí ó bá fẹ́ ṣe).
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَأَتۡبَعَ سَبَبًا
Nítorí náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
আরবি তাফসীরসমূহ:
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ مَغۡرِبَ ٱلشَّمۡسِ وَجَدَهَا تَغۡرُبُ فِي عَيۡنٍ حَمِئَةٖ وَوَجَدَ عِندَهَا قَوۡمٗاۖ قُلۡنَا يَٰذَا ٱلۡقَرۡنَيۡنِ إِمَّآ أَن تُعَذِّبَ وَإِمَّآ أَن تَتَّخِذَ فِيهِمۡ حُسۡنٗا
títí ó fi dé ibùwọ̀ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń wọ̀ sínú ìṣẹ́lẹ̀rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ dúdú kan. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níbẹ̀. A sọ pé: “Thul-Ƙọrneen, yálà kí o jẹ wọ́n níyà tàbí kí o mú ohun rere jáde lára wọn.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ أَمَّا مَن ظَلَمَ فَسَوۡفَ نُعَذِّبُهُۥ ثُمَّ يُرَدُّ إِلَىٰ رَبِّهِۦ فَيُعَذِّبُهُۥ عَذَابٗا نُّكۡرٗا
(Allāhu) sọ pé: “Ní ti ẹni tí ó bá ṣàbòsí, láìpẹ́ A máa jẹ ẹ́ níyà. Lẹ́yìn náà, wọn máa dá a padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì máa jẹ ẹ́ níyà tó burú.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَأَمَّا مَنۡ ءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَهُۥ جَزَآءً ٱلۡحُسۡنَىٰۖ وَسَنَقُولُ لَهُۥ مِنۡ أَمۡرِنَا يُسۡرٗا
Ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, tirẹ̀ ni ẹ̀san rere. A ó sì sọ̀rọ̀ ìrọ̀rùn fún un nínú àṣẹ Wa.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
ثُمَّ أَتۡبَعَ سَبَبًا
Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
আরবি তাফসীরসমূহ:
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ مَطۡلِعَ ٱلشَّمۡسِ وَجَدَهَا تَطۡلُعُ عَلَىٰ قَوۡمٖ لَّمۡ نَجۡعَل لَّهُم مِّن دُونِهَا سِتۡرٗا
títí ó fi dé ibùyọ òòrùn ayé. Ó rí i tí ń yọ lórí àwọn ènìyàn kan, tí A kò fún ní gàgá (ààbò) kan níbi òòrùn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
كَذَٰلِكَۖ وَقَدۡ أَحَطۡنَا بِمَا لَدَيۡهِ خُبۡرٗا
Báyẹn ni (Thul-Ƙọrneen ṣe ń tẹ̀ síwájú). Dájúdájú A rọkiriká ohun tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
ثُمَّ أَتۡبَعَ سَبَبًا
Lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀nà kan tọ̀
আরবি তাফসীরসমূহ:
حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ بَيۡنَ ٱلسَّدَّيۡنِ وَجَدَ مِن دُونِهِمَا قَوۡمٗا لَّا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ قَوۡلٗا
títí ó fi dé ààrin àpáta méjì. Ó sì bá àwọn ènìyàn kan níwájú rẹ̀. Wọn kò sì fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan (nínú èdè mìíràn).
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالُواْ يَٰذَا ٱلۡقَرۡنَيۡنِ إِنَّ يَأۡجُوجَ وَمَأۡجُوجَ مُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَهَلۡ نَجۡعَلُ لَكَ خَرۡجًا عَلَىٰٓ أَن تَجۡعَلَ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَهُمۡ سَدّٗا
Wọ́n sọ pé: “Thul-Ƙọrneen, dájúdájú (ìran) Ya’jūj àti Ma’jūj ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Ṣé kí á fún ọ ní owó-òde nítorí kí o lè bá wa mọ odi kan sáààrin àwa àti àwọn?”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ مَا مَكَّنِّي فِيهِ رَبِّي خَيۡرٞ فَأَعِينُونِي بِقُوَّةٍ أَجۡعَلۡ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُمۡ رَدۡمًا
Ó sọ pé: “Ohun tí Olúwa mi fún mi nínú ipò lóore jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi agbára ràn mí lọ́wọ́ ni nítorí kí n̄g lè mọ odi sáààrin ẹ̀yin àti àwọn.
আরবি তাফসীরসমূহ:
ءَاتُونِي زُبَرَ ٱلۡحَدِيدِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا سَاوَىٰ بَيۡنَ ٱلصَّدَفَيۡنِ قَالَ ٱنفُخُواْۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَعَلَهُۥ نَارٗا قَالَ ءَاتُونِيٓ أُفۡرِغۡ عَلَيۡهِ قِطۡرٗا
Ẹ máa fún mi ni ègígé irin títí di ìgbà tí ó fi máa bá ẹ̀gbẹ́ àpáta méjèèjì dọ́gba.” Ó sọ pé: “Ẹ máa fẹ́ atẹ́gùn ẹwìrì (sí i lára) títí di ìgbà tí ó máa (pọ́n wẹ̀ẹ̀ bí) iná.” Ó sọ pé: “Ẹ mu idẹ wá fún mi kí n̄g yọ́ ọ lé e lórí.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
فَمَا ٱسۡطَٰعُوٓاْ أَن يَظۡهَرُوهُ وَمَا ٱسۡتَطَٰعُواْ لَهُۥ نَقۡبٗا
Nítorí náà, wọn kò lè gùn ún, wọn kò sì lè dá a lu.
আরবি তাফসীরসমূহ:
قَالَ هَٰذَا رَحۡمَةٞ مِّن رَّبِّيۖ فَإِذَا جَآءَ وَعۡدُ رَبِّي جَعَلَهُۥ دَكَّآءَۖ وَكَانَ وَعۡدُ رَبِّي حَقّٗا
Ó sọ pé: “Èyí ni ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi. Nígbà tí àdéhùn Olúwa mi bá dé, (Allāhu) yó sì sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Àdéhùn Olúwa mi sì jẹ́ òdodo.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
۞ وَتَرَكۡنَا بَعۡضَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ يَمُوجُ فِي بَعۡضٖۖ وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَجَمَعۡنَٰهُمۡ جَمۡعٗا
A máa fi àwọn (ènìyàn àti àlùjànnú) sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, tí apá kan wọn yó sì máa rúpọ̀ mọ́ apá kan. Wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A ó sì kó gbogbo wọn jọ papọ̀ pátápátá.
আরবি তাফসীরসমূহ:
وَعَرَضۡنَا جَهَنَّمَ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡكَٰفِرِينَ عَرۡضًا
Ní ọjọ́ yẹn, A ó sì fi iná Jahanamọ han àwọn aláìgbàgbọ́ kedere.
আরবি তাফসীরসমূহ:
ٱلَّذِينَ كَانَتۡ أَعۡيُنُهُمۡ فِي غِطَآءٍ عَن ذِكۡرِي وَكَانُواْ لَا يَسۡتَطِيعُونَ سَمۡعًا
(Àwọn ni) àwọn tí ojú wọn wà nínú èbìbò nípa ìrántí Mi. Wọn kò sì lè gbọ́rọ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
أَفَحَسِبَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَن يَتَّخِذُواْ عِبَادِي مِن دُونِيٓ أَوۡلِيَآءَۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا جَهَنَّمَ لِلۡكَٰفِرِينَ نُزُلٗا
Ṣé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé àwọn yóò mú àwọn ẹrúsìn Mi ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Mi ni? Dájúdájú Àwa pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ ní ibùdésí fún àwọn aláìgbàgbọ́.
আরবি তাফসীরসমূহ:
قُلۡ هَلۡ نُنَبِّئُكُم بِٱلۡأَخۡسَرِينَ أَعۡمَٰلًا
Sọ pé: “Ṣé kí Á fún yín ní ìró àwọn ẹni òfò jùlọ nípa iṣẹ́ (ọwọ́ wọn)?
আরবি তাফসীরসমূহ:
ٱلَّذِينَ ضَلَّ سَعۡيُهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَهُمۡ يَحۡسَبُونَ أَنَّهُمۡ يُحۡسِنُونَ صُنۡعًا
(Àwọn ni) àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ nínú ìṣẹ̀mí ayé, (àmọ́ tí) wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ń ṣe iṣẹ́ rere.
আরবি তাফসীরসমূহ:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ وَلِقَآئِهِۦ فَحَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فَلَا نُقِيمُ لَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَزۡنٗا
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa wọn àti ìpàdé Rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ wọn sì bàjẹ́. Nítorí náà, A ò níí jẹ́ kí wọ́n jámọ́ n̄ǹkan kan lórí ìwọ̀n ní Ọjọ́ Àjíǹde.
আরবি তাফসীরসমূহ:
ذَٰلِكَ جَزَآؤُهُمۡ جَهَنَّمُ بِمَا كَفَرُواْ وَٱتَّخَذُوٓاْ ءَايَٰتِي وَرُسُلِي هُزُوًا
Jahanamọ, ìyẹn ni ẹ̀san wọn nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́, wọ́n sì sọ àwọn āyah Mi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi di oníyẹ̀yẹ́.
আরবি তাফসীরসমূহ:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ كَانَتۡ لَهُمۡ جَنَّٰتُ ٱلۡفِرۡدَوۡسِ نُزُلًا
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn ọgbà Firdaos ti wà fún wọn ní ibùdésí.
আরবি তাফসীরসমূহ:
خَٰلِدِينَ فِيهَا لَا يَبۡغُونَ عَنۡهَا حِوَلٗا
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Wọn kò sì níí fẹ́ kúrò nínú rẹ̀.
আরবি তাফসীরসমূহ:
قُل لَّوۡ كَانَ ٱلۡبَحۡرُ مِدَادٗا لِّكَلِمَٰتِ رَبِّي لَنَفِدَ ٱلۡبَحۡرُ قَبۡلَ أَن تَنفَدَ كَلِمَٰتُ رَبِّي وَلَوۡ جِئۡنَا بِمِثۡلِهِۦ مَدَدٗا
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ibúdò jẹ́ tàdáà fún àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi, ibúdò kúkú máa tán ṣíwájú kí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Mi tó tán, kódà kí Á tún mú (ibúdò) irú rẹ̀ wá ní àlékún.”
আরবি তাফসীরসমূহ:
قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ بَشَرٞ مِّثۡلُكُمۡ يُوحَىٰٓ إِلَيَّ أَنَّمَآ إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ فَمَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ رَبِّهِۦ فَلۡيَعۡمَلۡ عَمَلٗا صَٰلِحٗا وَلَا يُشۡرِكۡ بِعِبَادَةِ رَبِّهِۦٓ أَحَدَۢا
Sọ pé: “Abara ni èmi bí irú yín. Wọ́n ń fí ìmísí ránṣẹ́ sí mi pé Ọlọ́hun yín, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Olúwa rẹ̀, kí ó ṣe iṣẹ́ rere. Kò sì gbọdọ̀ fi ẹnì kan kan ṣe akẹgbẹ́ níbi jíjọ́sìn fún Olúwa rẹ̀ (kò gbọ́dọ̀ ṣẹbọ sí Olúwa rẹ̀).”
আরবি তাফসীরসমূহ:
 
অর্থসমূহের অনুবাদ সূরা: সূরা আল-কাহাফ
সূরাসমূহের সূচী পৃষ্ঠার নাম্বার
 
কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ - ইয়োরুবা ভাষায় অনুবাদ - অনুবাদসমূহের সূচী

ইয়োরুবা ভাষায় কুরআনুল কারীমের অর্থসমূহের অনুবাদ। অনুবাদ করেছেন শায়খ আবূ রাহীমাহ মিকাঈল আইকুয়েনী। প্রকাশকাল ১৪৩২হি.।

বন্ধ