Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik * - Sadržaj prijevodā

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Prijevod značenja Sura: Sura el-Furkan   Ajet:

Suuratul-Fur'qaan

تَبَارَكَ ٱلَّذِي نَزَّلَ ٱلۡفُرۡقَانَ عَلَىٰ عَبۡدِهِۦ لِيَكُونَ لِلۡعَٰلَمِينَ نَذِيرًا
Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣe ìpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá.
Tefsiri na arapskom jeziku:
ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَخَلَقَ كُلَّ شَيۡءٖ فَقَدَّرَهُۥ تَقۡدِيرٗا
(Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗ لَّا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ وَلَا يَمۡلِكُونَ لِأَنفُسِهِمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا وَلَا يَمۡلِكُونَ مَوۡتٗا وَلَا حَيَوٰةٗ وَلَا نُشُورٗا
(Àwọn aláìgbàgbọ́) sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu, àwọn tí kò lè dá n̄ǹkan kan, A sì dá wọn ni. Wọn kò sì ní ìkápá ìnira tàbí àǹfààní kan fún ẹ̀mí ara wọn. Àti pé wọn kò ní ìkápá lórí ikú, ìṣẹ̀mí àti àjíǹde.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ إِفۡكٌ ٱفۡتَرَىٰهُ وَأَعَانَهُۥ عَلَيۡهِ قَوۡمٌ ءَاخَرُونَۖ فَقَدۡ جَآءُو ظُلۡمٗا وَزُورٗا
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àdápa irọ́ kan tí ó dá àdápa rẹ̀ (mọ́ Allāhu), tí àwọn ènìyàn mìíràn sì ràn án lọ́wọ́ lórí rẹ̀.” Dájúdájú (àwọn aláìgbàgbọ́) ti gbé àbòsí àti irọ́ dé.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ٱكۡتَتَبَهَا فَهِيَ تُمۡلَىٰ عَلَيۡهِ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلٗا
Wọ́n tún wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́, tí ó ṣàdàkọ rẹ̀ ni. Òhun ni wọ́n ń pè fún un ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
قُلۡ أَنزَلَهُ ٱلَّذِي يَعۡلَمُ ٱلسِّرَّ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ إِنَّهُۥ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
Sọ pé: “Ẹni tí Ó mọ ìkọ̀kọ̀ tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀. Dájúdájú Òun ni Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَالُواْ مَالِ هَٰذَا ٱلرَّسُولِ يَأۡكُلُ ٱلطَّعَامَ وَيَمۡشِي فِي ٱلۡأَسۡوَاقِ لَوۡلَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِ مَلَكٞ فَيَكُونَ مَعَهُۥ نَذِيرًا
Wọ́n tún wí pé: “Kí ló mú Òjíṣẹ́ yìí, tó ń jẹun, tó ń rìn nínú àwọn ọjà? Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ pẹ̀lú rẹ̀?
Tefsiri na arapskom jeziku:
أَوۡ يُلۡقَىٰٓ إِلَيۡهِ كَنزٌ أَوۡ تَكُونُ لَهُۥ جَنَّةٞ يَأۡكُلُ مِنۡهَاۚ وَقَالَ ٱلظَّٰلِمُونَ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا رَجُلٗا مَّسۡحُورًا
Tàbí (nítorí kí ni) wọn kò ṣe ju àpótí-ọrọ̀ kan sọ́dọ̀ rẹ̀, tàbí kí ó ní ọgbà oko kan tí ó ma máa jẹ nínú rẹ̀?” Àwọn alábòsí sì tún wí pé: “Ta ni ẹ̀ ń tẹ̀lé bí kò ṣe ọkùnrin eléèdì kan.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
ٱنظُرۡ كَيۡفَ ضَرَبُواْ لَكَ ٱلۡأَمۡثَٰلَ فَضَلُّواْ فَلَا يَسۡتَطِيعُونَ سَبِيلٗا
Wo bí wọ́n ṣe fún ọ ní àwọn àfiwé (burúkú)! Nítorí náà, wọ́n ti ṣìnà; wọn kò sì lè mọ̀nà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
تَبَارَكَ ٱلَّذِيٓ إِن شَآءَ جَعَلَ لَكَ خَيۡرٗا مِّن ذَٰلِكَ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ وَيَجۡعَل لَّكَ قُصُورَۢا
Ìbùkún ni fún Ẹni tí (ó jẹ́ pé) bí Ó bá fẹ́, Ó máa ṣoore tó dára ju ìyẹn fún ọ. (Ó sì máa jẹ́) àwọn ọgbà tí àwọn odò yóò máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ó sì máa fún ọ ni àwọn ààfin kan.
Tefsiri na arapskom jeziku:
بَلۡ كَذَّبُواْ بِٱلسَّاعَةِۖ وَأَعۡتَدۡنَا لِمَن كَذَّبَ بِٱلسَّاعَةِ سَعِيرًا
Ńṣe ni wọ́n pe Àkókò náà nírọ́. A sì ti pèsè Iná tó ń jo sílẹ̀ de ẹnikẹ́ni tí ó bá pe Àkókò náà nírọ́.
Tefsiri na arapskom jeziku:
إِذَا رَأَتۡهُم مِّن مَّكَانِۭ بَعِيدٖ سَمِعُواْ لَهَا تَغَيُّظٗا وَزَفِيرٗا
Nígbà tí (Iná náà) bá rí wọn láti àyè kan tí ó jìnnà, wọn yó sì máa gbọ́ ohùn ìbínú àti kíkùn (rẹ̀).
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَإِذَآ أُلۡقُواْ مِنۡهَا مَكَانٗا ضَيِّقٗا مُّقَرَّنِينَ دَعَوۡاْ هُنَالِكَ ثُبُورٗا
Nígbà tí wọ́n bá sì jù wọ́n sí àyè tó há gádígádí nínú (Iná), tí wọ́n de ọwọ́ wọn mọ́ wọn lọ́rùn, wọn yó sì máa kígbe ìparun níbẹ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
لَّا تَدۡعُواْ ٱلۡيَوۡمَ ثُبُورٗا وَٰحِدٗا وَٱدۡعُواْ ثُبُورٗا كَثِيرٗا
(A ó sọ pé): “Ẹ má ṣe kígbe ìparun ẹyọ kan, ẹ kígbe ìparun lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
قُلۡ أَذَٰلِكَ خَيۡرٌ أَمۡ جَنَّةُ ٱلۡخُلۡدِ ٱلَّتِي وُعِدَ ٱلۡمُتَّقُونَۚ كَانَتۡ لَهُمۡ جَزَآءٗ وَمَصِيرٗا
Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìyẹn ló lóore jùlọ ni tàbí Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére, èyí tí A ṣe ní àdéhùn fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu. Ó sì jẹ́ ẹ̀san àti ìkángun rere fún wọn.
Tefsiri na arapskom jeziku:
لَّهُمۡ فِيهَا مَا يَشَآءُونَ خَٰلِدِينَۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ وَعۡدٗا مَّسۡـُٔولٗا
Ohunkóhun tí wọ́n bá ń fẹ́ wà fún wọn nínú rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n (nínú rẹ̀). (Èyí) jẹ́ àdéhùn tí wọ́n ti tọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ وَمَا يَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ فَيَقُولُ ءَأَنتُمۡ أَضۡلَلۡتُمۡ عِبَادِي هَٰٓؤُلَآءِ أَمۡ هُمۡ ضَلُّواْ ٱلسَّبِيلَ
Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó àwọn abọ̀rìṣà àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu jọ, (Allāhu) yó sì sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣi àwọn ẹrúsìn Mi wọ̀nyí lọ́nà ni tàbí àwọn ni wọ́n ṣìnà (fúnra wọn)?”¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74.
Tefsiri na arapskom jeziku:
قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ مَا كَانَ يَنۢبَغِي لَنَآ أَن نَّتَّخِذَ مِن دُونِكَ مِنۡ أَوۡلِيَآءَ وَلَٰكِن مَّتَّعۡتَهُمۡ وَءَابَآءَهُمۡ حَتَّىٰ نَسُواْ ٱلذِّكۡرَ وَكَانُواْ قَوۡمَۢا بُورٗا
Wọ́n wí pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Kò tọ́ fún wa láti mú àwọn kan ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Rẹ. Ṣùgbọ́n Ìwọ l’O fún àwọn àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn, títí wọ́n fi gbàgbé Ìrántí. Wọ́n sì jẹ́ ẹni ìparun.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
فَقَدۡ كَذَّبُوكُم بِمَا تَقُولُونَ فَمَا تَسۡتَطِيعُونَ صَرۡفٗا وَلَا نَصۡرٗاۚ وَمَن يَظۡلِم مِّنكُمۡ نُذِقۡهُ عَذَابٗا كَبِيرٗا
(Allāhu sọ pé): “Dájúdájú àwọn òrìṣà ti pe ẹ̀yin abọ̀rìṣà ní òpùrọ́ nípa ohun tí ẹ̀ ń sọ (pé olùṣìpẹ̀ ni wọ́n). Ní báyìí wọn kò lè gbé ìyà Iná kúrò fún yín, wọn kò sì lè ràn yín lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣe àbòsí (ẹbọ ṣíṣe) nínú yín, A sì máa fún un ní ìyà tó tóbi tọ́ wò.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا قَبۡلَكَ مِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّآ إِنَّهُمۡ لَيَأۡكُلُونَ ٱلطَّعَامَ وَيَمۡشُونَ فِي ٱلۡأَسۡوَاقِۗ وَجَعَلۡنَا بَعۡضَكُمۡ لِبَعۡضٖ فِتۡنَةً أَتَصۡبِرُونَۗ وَكَانَ رَبُّكَ بَصِيرٗا
A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ níṣẹ́ rí ṣíwájú rẹ àfi kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì rìn nínú ọjà. A ti fi apá kan yín ṣe àdánwò fún apá kan, ǹjẹ́ ẹ máa ṣe sùúrù bí? Olúwa Rẹ sì ń jẹ́ Olùríran.
Tefsiri na arapskom jeziku:
۞ وَقَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ أَوۡ نَرَىٰ رَبَّنَاۗ لَقَدِ ٱسۡتَكۡبَرُواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ وَعَتَوۡ عُتُوّٗا كَبِيرٗا
Àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) wí pé: “Wọn kò ṣe sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wa tàbí kí á rí Olúwa wa (ní ojúkojú)? Dájúdájú wọ́n ti ṣègbéraga nínú ẹ̀mí wọn. Wọ́n sì ti tayọ ẹnu-ààlà ní ìtayọ ẹnu-ààlà tó tóbi.
Tefsiri na arapskom jeziku:
يَوۡمَ يَرَوۡنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ لَا بُشۡرَىٰ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُجۡرِمِينَ وَيَقُولُونَ حِجۡرٗا مَّحۡجُورٗا
(Rántí) ọjọ́ tí wọ́n yóò rí àwọn mọlāika, kò níí sí ìró ìdùnnú fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. (Àwọn mọlāika) yó sì sọ pé: “Èèwọ̀, èèwọ̀ (ni ìró ìdùnnú fún ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀).”
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَدِمۡنَآ إِلَىٰ مَا عَمِلُواْ مِنۡ عَمَلٖ فَجَعَلۡنَٰهُ هَبَآءٗ مَّنثُورًا
Àti pé A máa wá ṣíbi ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa sọ ọ́ di eruku tí wọ́n fẹ́ dànù.
Tefsiri na arapskom jeziku:
أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِ يَوۡمَئِذٍ خَيۡرٞ مُّسۡتَقَرّٗا وَأَحۡسَنُ مَقِيلٗا
Àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ní ọjọ́ yẹn, (ọgbà wọn) máa lóore jùlọ ní ibùgbé. Ó sì máa dára jùlọ ní ibùsinmi.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَيَوۡمَ تَشَقَّقُ ٱلسَّمَآءُ بِٱلۡغَمَٰمِ وَنُزِّلَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ تَنزِيلًا
Àti pé (rántí) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣújò funfun (tí yóò máa tú jáde nínú wọn).¹ A sì máa sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ tààrà.
1. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah ; 2:210, sūrah al-’Infitọ̄r; 82:1-2 àti sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:1-2.
Tefsiri na arapskom jeziku:
ٱلۡمُلۡكُ يَوۡمَئِذٍ ٱلۡحَقُّ لِلرَّحۡمَٰنِۚ وَكَانَ يَوۡمًا عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ عَسِيرٗا
Ìjọba òdodo ti ọjọ́ yẹn ń jẹ́ ti Àjọkẹ́-ayé. Ó sì jẹ́ ọjọ́ kan tí ó máa nira fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَيَوۡمَ يَعَضُّ ٱلظَّالِمُ عَلَىٰ يَدَيۡهِ يَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي ٱتَّخَذۡتُ مَعَ ٱلرَّسُولِ سَبِيلٗا
(Rántí) ọjọ́ tí alábòsí yóò jẹ ìka ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì, ó sì máa wí pé: “Yéè! Èmi ìbá ti tọ ọ̀nà kan (náà) pẹ̀lú Òjíṣẹ́ náà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
يَٰوَيۡلَتَىٰ لَيۡتَنِي لَمۡ أَتَّخِذۡ فُلَانًا خَلِيلٗا
Ègbé mi o, yéè! Èmi ìbá tí mú lágbájá ní ọ̀rẹ́ àyò.
Tefsiri na arapskom jeziku:
لَّقَدۡ أَضَلَّنِي عَنِ ٱلذِّكۡرِ بَعۡدَ إِذۡ جَآءَنِيۗ وَكَانَ ٱلشَّيۡطَٰنُ لِلۡإِنسَٰنِ خَذُولٗا
Dájúdájú ó ti ṣì mí lọ́nà kúrò níbi Ìrántí lẹ́yìn tí ó dé bá mi. Dájúdájú Èṣù ń jẹ́ adáni-dáṣòro fún ọmọnìyàn.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَالَ ٱلرَّسُولُ يَٰرَبِّ إِنَّ قَوۡمِي ٱتَّخَذُواْ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ مَهۡجُورٗا
Òjíṣẹ́ náà sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pa al-Ƙur’ān yìí tì.”
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَكَذَٰلِكَ جَعَلۡنَا لِكُلِّ نَبِيٍّ عَدُوّٗا مِّنَ ٱلۡمُجۡرِمِينَۗ وَكَفَىٰ بِرَبِّكَ هَادِيٗا وَنَصِيرٗا
Báyẹn ni A ṣe àwọn kan nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan. Olúwa rẹ sì tó ní Afinimọ̀nà àti Alárànṣe.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ عَلَيۡهِ ٱلۡقُرۡءَانُ جُمۡلَةٗ وَٰحِدَةٗۚ كَذَٰلِكَ لِنُثَبِّتَ بِهِۦ فُؤَادَكَۖ وَرَتَّلۡنَٰهُ تَرۡتِيلٗا
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí pé: “Wọn kò ṣe sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún un ní àpapọ̀ ní ẹ̀ẹ̀ kan náà?” (A sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀) báyẹn nítorí kí A lè fi rinlẹ̀ sínú ọkàn rẹ. A sì ké e fún ọ díẹ̀díẹ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَلَا يَأۡتُونَكَ بِمَثَلٍ إِلَّا جِئۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ وَأَحۡسَنَ تَفۡسِيرًا
Wọn kò níí mú àpẹ̀ẹrẹ kan wá fún ọ (gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè láti fi takò ọ́) àfi kí Á mú òdodo (ìyẹn, al-ƙur’ān) àti àlàyé tó dára jùlọ wá fún ọ (lórí rẹ̀).
Tefsiri na arapskom jeziku:
ٱلَّذِينَ يُحۡشَرُونَ عَلَىٰ وُجُوهِهِمۡ إِلَىٰ جَهَنَّمَ أُوْلَٰٓئِكَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضَلُّ سَبِيلٗا
Àwọn tí A máa kó jọ lọ sínú iná Jahanamọ ní ìdojúbolẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn ni àyè wọn burú jùlọ. Wọ́n sì ṣìnà jùlọ.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَجَعَلۡنَا مَعَهُۥٓ أَخَاهُ هَٰرُونَ وَزِيرٗا
Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A tún ṣe arákùnrin rẹ̀, Hārūn, ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ fún un.
Tefsiri na arapskom jeziku:
فَقُلۡنَا ٱذۡهَبَآ إِلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا فَدَمَّرۡنَٰهُمۡ تَدۡمِيرٗا
A sì sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ sọ́dọ̀ ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. A sì pa ìjọ náà run pátápátá.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَقَوۡمَ نُوحٖ لَّمَّا كَذَّبُواْ ٱلرُّسُلَ أَغۡرَقۡنَٰهُمۡ وَجَعَلۡنَٰهُمۡ لِلنَّاسِ ءَايَةٗۖ وَأَعۡتَدۡنَا لِلظَّٰلِمِينَ عَذَابًا أَلِيمٗا
(Rántí) ìjọ (Ànábì) Nūh. Nígbà tí wọ́n pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́, A tẹ̀ wọ́n rì sínú omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì kan fún àwọn ènìyàn. A sì ti pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn alábòsí.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَعَادٗا وَثَمُودَاْ وَأَصۡحَٰبَ ٱلرَّسِّ وَقُرُونَۢا بَيۡنَ ذَٰلِكَ كَثِيرٗا
(Rántí) àwọn ìjọ ‘Ād, ìjọ Thamūd, ìjọ Rass àti àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran mìíràn (tó ń bẹ) láààrin wọn.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَكُلّٗا ضَرَبۡنَا لَهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَۖ وَكُلّٗا تَبَّرۡنَا تَتۡبِيرٗا
Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fún ní àwọn àpẹ̀ẹrẹ (gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí àti àlàyé ọ̀rọ̀). Ìkọ̀ọ̀kan wọn sì ni A parun pátápátá (torí àìgbàgbọ́ wọn).
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَلَقَدۡ أَتَوۡاْ عَلَى ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلَّتِيٓ أُمۡطِرَتۡ مَطَرَ ٱلسَّوۡءِۚ أَفَلَمۡ يَكُونُواْ يَرَوۡنَهَاۚ بَلۡ كَانُواْ لَا يَرۡجُونَ نُشُورٗا
Àti pé dájúdájú àwọn náà kọjá ní ìlú tí A rọ òjò burúkú lé lórí. Ṣé wọn kì í rí i ni? Rárá, ńṣe ni wọn kò retí Àjíǹde.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَإِذَا رَأَوۡكَ إِن يَتَّخِذُونَكَ إِلَّا هُزُوًا أَهَٰذَا ٱلَّذِي بَعَثَ ٱللَّهُ رَسُولًا
Nígbà tí wọ́n bá sì rí ọ, kò sí ohun tí wọn yóò fi ọ́ ṣe bí kò ṣe yẹ̀yẹ́. (Wọ́n á wí pé): “Ṣé èyí ni ẹni tí Allāhu gbé dìde ní Òjíṣẹ́!?
Tefsiri na arapskom jeziku:
إِن كَادَ لَيُضِلُّنَا عَنۡ ءَالِهَتِنَا لَوۡلَآ أَن صَبَرۡنَا عَلَيۡهَاۚ وَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ حِينَ يَرَوۡنَ ٱلۡعَذَابَ مَنۡ أَضَلُّ سَبِيلًا
Ó mà fẹ́ẹ̀ ṣẹ́rí wa kúrò níbi àwọn ọlọ́hun wa, tí kì í bá ṣe pé a takú sorí rẹ̀.” Láìpẹ́ wọn máa mọ ẹni tí ó ṣìnà jùlọ nígbà tí wọ́n bá rí ìyà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
أَرَءَيۡتَ مَنِ ٱتَّخَذَ إِلَٰهَهُۥ هَوَىٰهُ أَفَأَنتَ تَكُونُ عَلَيۡهِ وَكِيلًا
Sọ fún mi nípa ẹni tí ó sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ di ọlọ́hun rẹ̀! Nítorí náà, ṣé ìwọ máa jẹ́ aláàbò fún un ni (níbi ìyà)?
Tefsiri na arapskom jeziku:
أَمۡ تَحۡسَبُ أَنَّ أَكۡثَرَهُمۡ يَسۡمَعُونَ أَوۡ يَعۡقِلُونَۚ إِنۡ هُمۡ إِلَّا كَٱلۡأَنۡعَٰمِ بَلۡ هُمۡ أَضَلُّ سَبِيلًا
Tàbí ìwọ ń rò pé dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ń gbọ́ràn tàbí pé wọ́n ń ṣe làákàyè? Kí ni wọ́n ná, bí kò ṣe bí àgùtàn. Rárá, wọ́n ṣìnà jùlọ.
Tefsiri na arapskom jeziku:
أَلَمۡ تَرَ إِلَىٰ رَبِّكَ كَيۡفَ مَدَّ ٱلظِّلَّ وَلَوۡ شَآءَ لَجَعَلَهُۥ سَاكِنٗا ثُمَّ جَعَلۡنَا ٱلشَّمۡسَ عَلَيۡهِ دَلِيلٗا
Ṣé o ò rí (iṣẹ́) Olúwa rẹ ni, bí Ó ṣe fẹ òkùnkùn òwúrọ̀ lójú (sójú sánmọ̀)? Tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá dá a dúró síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, A fi òòrùn ṣe atọ́ka sí bíbẹ òkùnkùn.
Tefsiri na arapskom jeziku:
ثُمَّ قَبَضۡنَٰهُ إِلَيۡنَا قَبۡضٗا يَسِيرٗا
Lẹ́yìn náà, A (fi ìmọ́lẹ̀ òòrùn) mú òkùnkùn (kúrò níta) wá sí ọ̀dọ̀ Wa ní mímú díẹ̀díẹ̀ (kí ojúmọ́ lè mọ́).
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِبَاسٗا وَٱلنَّوۡمَ سُبَاتٗا وَجَعَلَ ٱلنَّهَارَ نُشُورٗا
Àti pé Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru ní ìbora fún yín. (Ó ṣe) oorun ní ìsinmi (fún yín). Ó tún ṣe ọ̀sán ní àsìkò ìtúsíta (fún wíwá ìjẹ-ìmu).
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ ٱلرِّيَٰحَ بُشۡرَۢا بَيۡنَ يَدَيۡ رَحۡمَتِهِۦۚ وَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ طَهُورٗا
Òun sì ni Ẹni t’Ó ń rán atẹ́gùn ní ìró-ìdùnnú ṣíwájú ìkẹ́ Rẹ̀. A sì sọ omi mímọ́ kalẹ̀ láti sánmọ̀
Tefsiri na arapskom jeziku:
لِّنُحۡـِۧيَ بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗا وَنُسۡقِيَهُۥ مِمَّا خَلَقۡنَآ أَنۡعَٰمٗا وَأَنَاسِيَّ كَثِيرٗا
nítorí kí A lè fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀ àti nítorí kí A lè fún ẹran-ọ̀sìn àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn nínú àwọn tí A dá ní omi mu.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَٰهُ بَيۡنَهُمۡ لِيَذَّكَّرُواْ فَأَبَىٰٓ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ إِلَّا كُفُورٗا
Dájúdájú À ń darí omi yìí káàkiri láààrin wọn¹ nítorí kí wọ́n lè rántí (ìkẹ́ Olúwa wọn). Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ (láti rántí) àfi àìmoore.
1. A lè rọ̀jọ̀ sí ìlú kan, kí Á mú ọ̀dá òjò wá sí ibò mìíràn.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَلَوۡ شِئۡنَا لَبَعَثۡنَا فِي كُلِّ قَرۡيَةٖ نَّذِيرٗا
Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, A ìbá gbé olùkìlọ̀ kan dìde nínú ìlú kọ̀ọ̀kan.¹
1. Nínú oore àjùlọ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ṣe fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, kò sí ànábì mìíràn ní ibikíbi ní àsìkò ìṣẹ̀mí rẹ̀ lójú ayé rẹ̀. Èyí ni àgbọ́yé āyah yìí. Àmọ́ ṣíwájú àsìkò tirẹ̀, Allāhu nìkan ló mọ iye ìgbà tí Ó fi iṣẹ́ Rẹ̀ rán Ànábì méjì tàbí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní àsìkò kan-ùn nínú ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àpẹ̀ẹrẹ, àsìkò kan-ùn ni àsìkò Ànábì ’Ibrọ̄hīm àti Ànábì Lūt, àsìkò kan-ùn ni àsìkò Ànábì Ṣu‘aeb, Ànábì Mūsā àti Ànábì Hārūn - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.
Síwájú sí i, oore àjùlọ yìí ló fi jẹ́ pé, gbogbo ayé pátápátá ni Allāhu rán Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - níṣẹ́ sí, =
= elédè Lárúbáwá àti elédè mìíràn, ènìyàn àti àlùjọ̀nnú. (sūrah āl-‘Imrọ̄n; 3:110, sūrah al-’An‘ām; 6:19, surah al-Jinn; 72:1 àti sūrah al-’Anbiyā’; 21:107.) Àmọ́ ṣíwájú àsìkò Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ìjọ Ànábì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ jẹ́ elédè Ànábì rẹ̀ nìkan. Èyí ni ó jẹyọ nínú sūrah ’Ibrọ̄hīm; 14:4.
Bákan náà, nínú oore àjùlọ tí Allāhu ṣe fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, kò níí sí ànábì mìíràn mọ́ ní ibikíbi lẹ́yìn ikú Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - títí di òpin ayé. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ahzāb; 33:40.
Tefsiri na arapskom jeziku:
فَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَجَٰهِدۡهُم بِهِۦ جِهَادٗا كَبِيرٗا
Nítorí náà, má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́. Kí o sì fi (al-Ƙur’ān) jà wọ́n ní ogun tó tóbi.
Tefsiri na arapskom jeziku:
۞ وَهُوَ ٱلَّذِي مَرَجَ ٱلۡبَحۡرَيۡنِ هَٰذَا عَذۡبٞ فُرَاتٞ وَهَٰذَا مِلۡحٌ أُجَاجٞ وَجَعَلَ بَيۡنَهُمَا بَرۡزَخٗا وَحِجۡرٗا مَّحۡجُورٗا
Òun ni Ẹni tí Ó mú àwọn odò méjì ṣàn kiri. Èyí (ni omi) tó dùn gan-an. Èyí sì (ni omi) iyọ̀ tó móró. Ó sì fi gàgá sí ààrin àwọn méjèèjì. (Ó sì) ṣe é ní èèwọ̀ pọ́nńbélé (fún wọn láti kó ìnira bá ẹ̀dá).
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ مِنَ ٱلۡمَآءِ بَشَرٗا فَجَعَلَهُۥ نَسَبٗا وَصِهۡرٗاۗ وَكَانَ رَبُّكَ قَدِيرٗا
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára.¹
1. Ìṣẹ̀dá ènìyàn wáyé nípasẹ̀ oríṣi ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkíní; nípasẹ̀ erùpẹ̀. Èyí sì ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá bàbá wa àkọ́kọ́, Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń ki ìṣẹ̀dá wa kan erùpẹ̀ nítorí ti Ànábì Ādam ni - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
Ìkejì; nípasẹ̀ ẹfọ́nhà. Èyí sì ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá ìyá wa àkọ́kọ́, Hawā’ - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí =
= Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń kí ìṣẹ̀dá àwọn obìnrin kan àwa ọkùnrin, nítorí ti Hawā’ ni - kí Allāhu yọ́nú sí i -.
Ìkẹta; nípasẹ̀ omi àtọ̀. Èyí si ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá èmi àti ẹ̀yin. Nítorí náà, ìgbàkígbà tí Allāhu Ẹlẹ́dàá bá ń ki ìṣẹ̀dá wa kan omi nítorí ti èmi àti ẹ̀yin ni.
Ìkẹrin; nípasẹ̀ atẹ́gùn ẹ̀mí àti gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀. Èyí sì ni Allāhu Ẹlẹ́dàá fi ṣe ẹ̀dá ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
Kíyè sí i! Àti ìkíní àti ìkejì àti ìkẹta, kò sí ènìyàn kan tí kò ní atẹ́gùn ẹ̀mí lára ṣíwájú kí ó tó di abẹ̀mí. Ṣebí atẹ́gùn ẹ̀mí tí Allāhu ṣẹ̀ṣẹ̀ fi rán mọlāika Jibril - kí ọlà Allāhu máa bá a - sí Mọryam, ìyá Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni Allāhu fúnra Rẹ̀ fẹ́ sínú ọbọrọgidi Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Èyí kò sì sọ Ànábì Ādam di olúwa àti olùgbàlà. Báwo ni Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - yó ṣe wá jẹ́ olúwa àti olùgbàlà! Kò sì sí ènìyàn tàbí ẹ̀dá kan tí Allāhu Ẹlẹ́dàá kò ni sọ gbólóhùn “kunfayakūn” fún, ṣíwájú kí ó tó máa bẹ.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُهُمۡ وَلَا يَضُرُّهُمۡۗ وَكَانَ ٱلۡكَافِرُ عَلَىٰ رَبِّهِۦ ظَهِيرٗا
Wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ohun tí kò lè ṣe wọ́n ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wọn. Aláìgbàgbọ́ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ (fún Èṣù) láti tako Olúwa rẹ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا مُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا
A kò sì rán ọ níṣẹ́ tayọ kí o jẹ́ oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
قُلۡ مَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍ إِلَّا مَن شَآءَ أَن يَتَّخِذَ إِلَىٰ رَبِّهِۦ سَبِيلٗا
Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ àfi ẹni tí ó bá fẹ́ mú ọ̀nà (dáadáa) tọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀.”¹
1. Ìyẹn ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì kan tí ó ń gba owó-ọ̀yà lọ́wọ́ ìjọ rẹ̀ lórí iṣẹ́ tí Allāhu fi rán an níṣẹ́ sí wọn, iṣẹ́ olóore ni fún ẹnikẹ́ni láti máa fún Òjíṣẹ́ tí Allāhu rán sí wọn lọ́rẹ. Ọrẹ sì yàtọ̀ sí owó-ọ̀yà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱلۡحَيِّ ٱلَّذِي لَا يَمُوتُ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِهِۦۚ وَكَفَىٰ بِهِۦ بِذُنُوبِ عِبَادِهِۦ خَبِيرًا
Gbáralé Alààyè tí kò níí kú. Ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Un.¹ Allāhu sì tó ní Alámọ̀tán nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
1. Ìyẹn ni pé, ṣe àfọ̀mọ́ Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù, kí o sì yìn Ín lógo pé, Ó pé tán pátápátá.
Tefsiri na arapskom jeziku:
ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ ٱلرَّحۡمَٰنُ فَسۡـَٔلۡ بِهِۦ خَبِيرٗا
(Òun ni) Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti àwọn n̄ǹkan tó ń bẹ láààrin méjèèjì láààrin ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá. Àjọkẹ́-ayé ni, nítorí náà, bèèrè nípa Rẹ̀ (lọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí pé, Ó jẹ́) Alámọ̀tán.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱسۡجُدُواْۤ لِلرَّحۡمَٰنِ قَالُواْ وَمَا ٱلرَّحۡمَٰنُ أَنَسۡجُدُ لِمَا تَأۡمُرُنَا وَزَادَهُمۡ نُفُورٗا۩
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ fún Àjọkẹ́-ayé.” Wọ́n á wí pé: “Kí ni Àjọkẹ-ayé? Ṣé kí á forí kanlẹ̀ fún ohun tí ò ń pa wá láṣẹ rẹ̀ ni?” (Ìpèpè náà) sì mú wọn lékún ní sísá-sẹ́yìn.
Tefsiri na arapskom jeziku:
تَبَارَكَ ٱلَّذِي جَعَلَ فِي ٱلسَّمَآءِ بُرُوجٗا وَجَعَلَ فِيهَا سِرَٰجٗا وَقَمَرٗا مُّنِيرٗا
Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ṣe àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀. Ó tún ṣe òòrùn àti òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀ sínú rẹ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ خِلۡفَةٗ لِّمَنۡ أَرَادَ أَن يَذَّكَّرَ أَوۡ أَرَادَ شُكُورٗا
Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òru àti ọ̀sán ní ìtẹ̀léǹtẹ̀lé (tí ìkíní yàtọ̀ sí ìkejì) nítorí ẹni tí ó bá gbèrò láti ṣe ìrántí (Allāhu) tàbí tí ó bá gbèrò ìdúpẹ́ (fún Un).
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَعِبَادُ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلَّذِينَ يَمۡشُونَ عَلَى ٱلۡأَرۡضِ هَوۡنٗا وَإِذَا خَاطَبَهُمُ ٱلۡجَٰهِلُونَ قَالُواْ سَلَٰمٗا
Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn tó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn òpè bá sì dojú ọ̀rọ̀ kọ wọ́n, wọn yóò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱلَّذِينَ يَبِيتُونَ لِرَبِّهِمۡ سُجَّدٗا وَقِيَٰمٗا
(Àwọn ni) àwọn tó ń lo òru wọn ní ìforíkanlẹ̀ àti ní ìdúró-kírun fún Olúwa wọn.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا ٱصۡرِفۡ عَنَّا عَذَابَ جَهَنَّمَۖ إِنَّ عَذَابَهَا كَانَ غَرَامًا
(Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, gbé ìyà iná Jahanamọ kúrò fún wa. Dájúdájú ìyà rẹ̀ jẹ́ ìyà àìnípẹ̀kun.
Tefsiri na arapskom jeziku:
إِنَّهَا سَآءَتۡ مُسۡتَقَرّٗا وَمُقَامٗا
Dájúdájú ó burú ní ibùgbé àti ibùdúró.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَنفَقُواْ لَمۡ يُسۡرِفُواْ وَلَمۡ يَقۡتُرُواْ وَكَانَ بَيۡنَ ذَٰلِكَ قَوَامٗا
Àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá náwó, wọn kò ná ìná-àpà, wọn kò sì ṣahun; (ìnáwó wọn) wà láààrin ìyẹn ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱلَّذِينَ لَا يَدۡعُونَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ وَلَا يَقۡتُلُونَ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَلَا يَزۡنُونَۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ يَلۡقَ أَثَامٗا
(Àwọn ni) àwọn tí kò pe ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Wọn kò pa ẹ̀mí tí Allāhu ṣe (pípa rẹ̀) ní èèwọ̀ àfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àti pé wọn kò ṣe zinā. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe (aburú) yẹn, ó máa pàdé (ìyà) ẹ̀ṣẹ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
يُضَٰعَفۡ لَهُ ٱلۡعَذَابُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَيَخۡلُدۡ فِيهِۦ مُهَانًا
A óò ṣe ìyà ní ìlọ́po fún un ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ní ẹni yẹpẹrẹ.
Tefsiri na arapskom jeziku:
إِلَّا مَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ عَمَلٗا صَٰلِحٗا فَأُوْلَٰٓئِكَ يُبَدِّلُ ٱللَّهُ سَيِّـَٔاتِهِمۡ حَسَنَٰتٖۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا
Àfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu yóò fi iṣẹ́ rere rọ́pò iṣẹ́ aburú wọn (ìyẹn, nípa ìronúpìwàdà wọn). Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَمَن تَابَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَإِنَّهُۥ يَتُوبُ إِلَى ٱللَّهِ مَتَابٗا
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, (kí ó mọ̀) pé dájúdájú ó ń ronú pìwàdà pátápátá sọ́dọ̀ Allāhu ni.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱلَّذِينَ لَا يَشۡهَدُونَ ٱلزُّورَ وَإِذَا مَرُّواْ بِٱللَّغۡوِ مَرُّواْ كِرَامٗا
(Àwọn ni) àwọn tí kò jẹ́rìí èké. Tí wọ́n bá sì kọjá níbi ìbàjẹ́, wọ́n á kọjá pẹ̀lú àpọ́nlé.¹
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ẹrúsìn Allāhu ń pọ́nra wọn lé nípa àìjókòó pọ̀ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ. Wọ́n sì ń pọ́nra wọn lé nípa yíyẹra fún ìjókòó tí àwọn aláìmọ̀kan bá ti ń ṣe ìbàjẹ̀ nínú rẹ̀.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ لَمۡ يَخِرُّواْ عَلَيۡهَا صُمّٗا وَعُمۡيَانٗا
(Àwọn ni) àwọn tí ó jẹ́ pé tí wọ́n bá fi àwọn āyah Olúwa wọn ṣèrántí fún wọn, wọn kò dà lulẹ̀ bí adití àti afọ́jú.
Tefsiri na arapskom jeziku:
وَٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَا هَبۡ لَنَا مِنۡ أَزۡوَٰجِنَا وَذُرِّيَّٰتِنَا قُرَّةَ أَعۡيُنٖ وَٱجۡعَلۡنَا لِلۡمُتَّقِينَ إِمَامًا
(Àwọn ni) àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, ta wá ní ọrẹ ìtutù-ojú (ìdùnnú àti ayọ̀) láti ara àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa. Kí O sì ṣe wá ní aṣíwájú (àwòkọ́ṣe rere) fún àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ).”
Tefsiri na arapskom jeziku:
أُوْلَٰٓئِكَ يُجۡزَوۡنَ ٱلۡغُرۡفَةَ بِمَا صَبَرُواْ وَيُلَقَّوۡنَ فِيهَا تَحِيَّةٗ وَسَلَٰمًا
Àwọn wọ̀nyẹn, ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gíga (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ni A máa fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé, wọ́n ṣe sùúrù. Ìkíni àti sísálámọ̀ ni A óò fi máa pàdé wọn nínú rẹ̀
Tefsiri na arapskom jeziku:
خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ حَسُنَتۡ مُسۡتَقَرّٗا وَمُقَامٗا
Olúṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ó dára ní ibùgbé àti ibùdúró.
Tefsiri na arapskom jeziku:
قُلۡ مَا يَعۡبَؤُاْ بِكُمۡ رَبِّي لَوۡلَا دُعَآؤُكُمۡۖ فَقَدۡ كَذَّبۡتُمۡ فَسَوۡفَ يَكُونُ لِزَامَۢا
Sọ pé: “Olúwa mi kò kà yín kún tí kì í bá ṣe àdúà yín (àti ìjọ́sìn yín). Ẹ kúkú ti pe (àwọn āyah Rẹ̀) nírọ́. Láìpẹ́ ó sì máa di ìyà àìnípẹ̀kun (fún yín).”
Tefsiri na arapskom jeziku:
 
Prijevod značenja Sura: Sura el-Furkan
Indeks sura Broj stranice
 
Prijevod značenja časnog Kur'ana - Prijevod na joruba jezik - Sadržaj prijevodā

Prijevod značenja Plemenitog Kur'ana na joruba jezik - Šejh Ebu Rahima MIhail Akvinski, 1432. godine po Hidžri.

Zatvaranje