Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Yūsuf   Ayah:

Suuratu Yuusuf

الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ
’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹ Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tó yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ
Dájúdájú Àwa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ ní n̄ǹkan kíké ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
Arabic explanations of the Qur’an:
نَحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ أَحۡسَنَ ٱلۡقَصَصِ بِمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ وَإِن كُنتَ مِن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلۡغَٰفِلِينَ
Àwa ń sọ ìtàn tó dára jùlọ fún ọ pẹ̀lú ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ (nínú ìmísí) al-Ƙur’ān yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíwájú ìmísí náà ìwọ wà lára àwọn tí kò nímọ̀ (nípa rẹ̀).
Arabic explanations of the Qur’an:
إِذۡ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَٰٓأَبَتِ إِنِّي رَأَيۡتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوۡكَبٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ رَأَيۡتُهُمۡ لِي سَٰجِدِينَ
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ يَٰبُنَيَّ لَا تَقۡصُصۡ رُءۡيَاكَ عَلَىٰٓ إِخۡوَتِكَ فَيَكِيدُواْ لَكَ كَيۡدًاۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لِلۡإِنسَٰنِ عَدُوّٞ مُّبِينٞ
Ó sọ pé: “Ọmọ mi, má ṣe rọ́ àlá rẹ fún àwọn ọbàkan rẹ kí wọ́n má baà déte sí ọ. Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَكَذَٰلِكَ يَجۡتَبِيكَ رَبُّكَ وَيُعَلِّمُكَ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِ وَيُتِمُّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَعَلَىٰٓ ءَالِ يَعۡقُوبَ كَمَآ أَتَمَّهَا عَلَىٰٓ أَبَوَيۡكَ مِن قَبۡلُ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَۚ إِنَّ رَبَّكَ عَلِيمٌ حَكِيمٞ
Báyẹn ni Olúwa rẹ yóò ṣe ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Ó máa fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́. Ó sì máa pé ìdẹ̀ra Rẹ̀ fún ìwọ àti àwọn ẹbí Ya‘ƙūb, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe pé e ṣíwájú fún àwọn bàbá rẹ méjèèjì, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ishāƙ. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ لَّقَدۡ كَانَ فِي يُوسُفَ وَإِخۡوَتِهِۦٓ ءَايَٰتٞ لِّلسَّآئِلِينَ
Dájúdájú àwọn àmì (àríwòye) ń bẹ fún àwọn oníbèéèrè nípa (ìtàn Ànábì) Yūsuf àti àwọn ọbàkan rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِذۡ قَالُواْ لَيُوسُفُ وَأَخُوهُ أَحَبُّ إِلَىٰٓ أَبِينَا مِنَّا وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّ أَبَانَا لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
(Rántí) nígbà tí wọ́n sọ pé: “Dájúdájú Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀ ni bàbá wa nífẹ̀ẹ́ sí ju àwa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni àwa. Dájúdájú bàbá wa mà ti wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱقۡتُلُواْ يُوسُفَ أَوِ ٱطۡرَحُوهُ أَرۡضٗا يَخۡلُ لَكُمۡ وَجۡهُ أَبِيكُمۡ وَتَكُونُواْ مِنۢ بَعۡدِهِۦ قَوۡمٗا صَٰلِحِينَ
Ẹ pa Yūsuf tàbí kí ẹ lọ gbé e jùnù sí ilẹ̀ kan nítorí kí bàbá yín lè rójú gbọ́ tiyín. Ẹ sì máa di ènìyàn rere lẹ́yìn rẹ̀.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ لَا تَقۡتُلُواْ يُوسُفَ وَأَلۡقُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّ يَلۡتَقِطۡهُ بَعۡضُ ٱلسَّيَّارَةِ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ
Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn sọ pé: “Ẹ má ṣe pa Yūsuf. Tí ó bá jẹ́ pé ẹ ṣá fẹ́ wá n̄ǹkan ṣe (sí ọ̀rọ̀ rẹ̀), ẹ gbé e jù sínú ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga nítorí kí apá kan nínú àwọn onírìn-àjò lè he é lọ.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا مَا لَكَ لَا تَأۡمَ۬نَّا عَلَىٰ يُوسُفَ وَإِنَّا لَهُۥ لَنَٰصِحُونَ
Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni kò mú ọ fi ọkàn tán wa lórí Yūsuf. Dájúdájú àwa yóò máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَرۡسِلۡهُ مَعَنَا غَدٗا يَرۡتَعۡ وَيَلۡعَبۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ
Jẹ́ kí ó bá wa lọ ní ọ̀la kí ó lè dára yá, kí ó sì lè ṣeré. Àti pé dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ إِنِّي لَيَحۡزُنُنِيٓ أَن تَذۡهَبُواْ بِهِۦ وَأَخَافُ أَن يَأۡكُلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَأَنتُمۡ عَنۡهُ غَٰفِلُونَ
Ó sọ pé: “Dájúdájú ó máa bà mí nínú jẹ́ pé kí ẹ mú u lọ. Mo sì ń páyà kí ìkokò má lọ pa á jẹ nígbà tí ẹ̀yin bá gbàgbé rẹ̀ (síbì kan).”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ لَئِنۡ أَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُ وَنَحۡنُ عُصۡبَةٌ إِنَّآ إِذٗا لَّخَٰسِرُونَ
Wọ́n sọ pé: “Tí ìkokò bá fi pa á jẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ni wá, dájúdájú àwa nígbà náà ni ẹni òfò.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا ذَهَبُواْ بِهِۦ وَأَجۡمَعُوٓاْ أَن يَجۡعَلُوهُ فِي غَيَٰبَتِ ٱلۡجُبِّۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡهِ لَتُنَبِّئَنَّهُم بِأَمۡرِهِمۡ هَٰذَا وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Nígbà tí wọ́n mú un lọ tán, wọ́n panupọ̀ pé kí àwọn jù ú sí ìsàlẹ̀ẹ̀sàlẹ̀ kànǹga. À si fí ìmísí ránṣẹ́ sí Yūsuf (níbẹ̀) pé: “Dájúdájú ìwọ yóò fún wọn ní ìró nípa ọ̀rọ̀ wọn yìí nígbà tí wọn kò níí fura.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَآءُوٓ أَبَاهُمۡ عِشَآءٗ يَبۡكُونَ
Wọ́n dé bá bàbá wọn ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń sunkún.
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ يَٰٓأَبَانَآ إِنَّا ذَهَبۡنَا نَسۡتَبِقُ وَتَرَكۡنَا يُوسُفَ عِندَ مَتَٰعِنَا فَأَكَلَهُ ٱلذِّئۡبُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُؤۡمِنٖ لَّنَا وَلَوۡ كُنَّا صَٰدِقِينَ
Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, àwa lọ díje eré sísá. A sì fi Yūsuf sílẹ̀ síbi àwọn ẹrù wa. Nígbà náà ni ìkokò pa á jẹ. Ìwọ kò sì níí gbà wá gbọ́, àwa ìbáà jẹ́ olódodo.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَآءُو عَلَىٰ قَمِيصِهِۦ بِدَمٖ كَذِبٖۚ قَالَ بَلۡ سَوَّلَتۡ لَكُمۡ أَنفُسُكُمۡ أَمۡرٗاۖ فَصَبۡرٞ جَمِيلٞۖ وَٱللَّهُ ٱلۡمُسۡتَعَانُ عَلَىٰ مَا تَصِفُونَ
Wọ́n dé pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ irọ́ lára ẹ̀wù rẹ̀. (Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù abiyì (lọ̀rọ̀ mi kàn). Allāhu sì ni Ẹni tí à ń wá àánú Rẹ̀ lórí ohun tí ẹ̀ ń ròyìn (yìí).”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَآءَتۡ سَيَّارَةٞ فَأَرۡسَلُواْ وَارِدَهُمۡ فَأَدۡلَىٰ دَلۡوَهُۥۖ قَالَ يَٰبُشۡرَىٰ هَٰذَا غُلَٰمٞۚ وَأَسَرُّوهُ بِضَٰعَةٗۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ
Àwọn onírìn-àjò kan sì dé. Wọ́n rán apọnmi wọn (ní omi). Ó sì ju doro rẹ̀ sínú kànǹga. (Yūsuf sì dìrọ̀ mọ́ okùn doro bọ́ síta. Apọnmi sì) sọ pé: “Ire ìdùnnú rè é! Èyí ni ọmọdékùnrin.” Wọ́n sì fi pamọ́ fún títà (bí ọjà). Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَشَرَوۡهُ بِثَمَنِۭ بَخۡسٖ دَرَٰهِمَ مَعۡدُودَةٖ وَكَانُواْ فِيهِ مِنَ ٱلزَّٰهِدِينَ
Wọ́n tà á ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú owó diriham tó níye. Wọ́n kò sì wowọ́ mọ́ ọn.¹
1. Ìyẹn ni pé, wọn kò tà á ní ọ̀wọ́n gógó.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ ٱلَّذِي ٱشۡتَرَىٰهُ مِن مِّصۡرَ لِٱمۡرَأَتِهِۦٓ أَكۡرِمِي مَثۡوَىٰهُ عَسَىٰٓ أَن يَنفَعَنَآ أَوۡ نَتَّخِذَهُۥ وَلَدٗاۚ وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلِنُعَلِّمَهُۥ مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِۚ وَٱللَّهُ غَالِبٌ عَلَىٰٓ أَمۡرِهِۦ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Ẹni tí ó rà á ní (ìlú) Misrọ sọ fún aya rẹ̀ pé: “Ṣàpọ́nlé ibùgbé rẹ̀. Ó súnmọ́ kí ó wúlò fún wa tàbí kí á fi ṣọmọ.” Báyẹn ni A ṣe fi àyè gba Yūsuf lórí ilẹ̀. Àti pé kí Á tún lè fi ìtúmọ̀ àlá mọ̀ ọ́n. Allāhu ni Olùborí lórí àṣẹ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَمَّا بَلَغَ أَشُدَّهُۥٓ ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Nígbà tí ó sì dàgbà dáadáa, A fún un ní ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san rere.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَرَٰوَدَتۡهُ ٱلَّتِي هُوَ فِي بَيۡتِهَا عَن نَّفۡسِهِۦ وَغَلَّقَتِ ٱلۡأَبۡوَٰبَ وَقَالَتۡ هَيۡتَ لَكَۚ قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ رَبِّيٓ أَحۡسَنَ مَثۡوَايَۖ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّٰلِمُونَ
Obìnrin tí Yūsuf wà nínú ilé rẹ̀ sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì ti àwọn ìlẹ̀kùn pa. Ó sọ pé: “Súnmọ́ mi.” (Yūsuf) sọ pé: “Mo sádi Allāhu. Dájúdájú ọkọ rẹ ni ọ̀gá mi. Ó sì ṣe ibùgbé mi dáadáa. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَقَدۡ هَمَّتۡ بِهِۦۖ وَهَمَّ بِهَا لَوۡلَآ أَن رَّءَا بُرۡهَٰنَ رَبِّهِۦۚ كَذَٰلِكَ لِنَصۡرِفَ عَنۡهُ ٱلسُّوٓءَ وَٱلۡفَحۡشَآءَۚ إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُخۡلَصِينَ
(Obìnrin náà) kúkú gbèrò eré ìfẹ́ sí i. Òun náà gbèrò rẹ̀.¹ Tí kò bá jẹ́ pé ó rí ẹ̀rí Olúwa rẹ̀ (pé harāmu ni sìná, ìbá súnmọ́ ọn). Báyẹn ni (ọ̀rọ̀ náà rí) nítorí kí Á lè ṣẹ́rí aburú àti sìná ṣíṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ipò ànábì).”
1. Ànábì Yūsuf - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò di ẹlẹ́ṣẹ̀ látara bí èròǹgbà ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ ṣe tì í sínú èròkérò ní ìbámu sí hadīth ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, láti ọ̀dọ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú ohun tí ó gbà lẹ́gbàwá làti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ - tó ga jùlọ -. Ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn iṣẹ́ ibi sínú kádàrá. Lẹ́yìn náà, Ó ṣàlàyé èyí (fún ẹ̀dá). Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ rere kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré. Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere mẹ́wàá, títí dé ọgọ́rùn-ún méje àdìpèlé, títí dé àdìpèlé lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò iṣẹ́ ibi kan, kò sì ṣe é, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ rere tó pé pérépéré (fún gbígbé iṣẹ́ ibi jù sílẹ̀). Tí ó bá sì gbèrò rẹ̀, tí ó sì rí i ṣe, Allāhu yóò kọ ọ́ sílẹ̀ fún un lọ́dọ̀ Rẹ̀ ní iṣẹ́ ibi ẹyọ kan.” Bukāriy àti Muslim
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱسۡتَبَقَا ٱلۡبَابَ وَقَدَّتۡ قَمِيصَهُۥ مِن دُبُرٖ وَأَلۡفَيَا سَيِّدَهَا لَدَا ٱلۡبَابِۚ قَالَتۡ مَا جَزَآءُ مَنۡ أَرَادَ بِأَهۡلِكَ سُوٓءًا إِلَّآ أَن يُسۡجَنَ أَوۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Àwọn méjèèjì sáré lọ síbi ìlẹ̀kùn. (Obìnrin yìí) sì fa ẹ̀wù (Yūsuf) ya lẹ́yìn. Àwọn méjèèjì sì bá ọ̀gá rẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà. (Obìnrin yìí) sì sọ pé: “Kí ni ẹ̀san fún ẹni tí ó gbèrò aburú sí ará ilé rẹ bí kò ṣe pé kí wọ́n sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ هِيَ رَٰوَدَتۡنِي عَن نَّفۡسِيۚ وَشَهِدَ شَاهِدٞ مِّنۡ أَهۡلِهَآ إِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن قُبُلٖ فَصَدَقَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلۡكَٰذِبِينَ
(Yūsuf) sọ pé: “Òun ló jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ mi.” Ẹlẹ́rìí kan nínú ará ile (obìnrin náà) sì jẹ́rìí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya níwájú, (obìnrin yìí) ló sọ òdodo, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn òpùrọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِن كَانَ قَمِيصُهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ فَكَذَبَتۡ وَهُوَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀wù rẹ̀ ya lẹ́yìn, (obìnrin yìí) ló parọ́, (Yūsuf) sì wà nínú àwọn olódodo.”¹
1. Ẹlẹ́rìí yìí ni ọmọ òpóǹló tí Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ - fún lọ́rọ̀ sọ lórí ìtẹ́. Nítorí náà, kì í ṣe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - nìkan ni ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní òpóǹló lórí ìtẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا رَءَا قَمِيصَهُۥ قُدَّ مِن دُبُرٖ قَالَ إِنَّهُۥ مِن كَيۡدِكُنَّۖ إِنَّ كَيۡدَكُنَّ عَظِيمٞ
Nígbà tí (ọkọ) rí ẹ̀wù rẹ̀ tí wọ́n ti fà á ya lẹ́yìn, ó sọ pé: “Dájúdájú nínú ète ẹ̀yin obìnrin ni (èyí). Dájúdájú ète yín tóbi.
Arabic explanations of the Qur’an:
يُوسُفُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَاۚ وَٱسۡتَغۡفِرِي لِذَنۢبِكِۖ إِنَّكِ كُنتِ مِنَ ٱلۡخَاطِـِٔينَ
Yūsuf, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Kí ìwọ (obìnrin yìí) sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Dájúdájú ìwọ wà lára àwọn aláṣìṣe.”
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ وَقَالَ نِسۡوَةٞ فِي ٱلۡمَدِينَةِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ تُرَٰوِدُ فَتَىٰهَا عَن نَّفۡسِهِۦۖ قَدۡ شَغَفَهَا حُبًّاۖ إِنَّا لَنَرَىٰهَا فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Àwọn obìnrin kan nínú ìlú sọ pé: “Ayaba ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀; ìfẹ́ kúkú ti kó sí i lọ́kàn. Dájúdájú àwa ń rí òun pé ó wà nínú àṣìṣe pọ́nńbélé.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا سَمِعَتۡ بِمَكۡرِهِنَّ أَرۡسَلَتۡ إِلَيۡهِنَّ وَأَعۡتَدَتۡ لَهُنَّ مُتَّكَـٔٗا وَءَاتَتۡ كُلَّ وَٰحِدَةٖ مِّنۡهُنَّ سِكِّينٗا وَقَالَتِ ٱخۡرُجۡ عَلَيۡهِنَّۖ فَلَمَّا رَأَيۡنَهُۥٓ أَكۡبَرۡنَهُۥ وَقَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّ وَقُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا هَٰذَا بَشَرًا إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا مَلَكٞ كَرِيمٞ
Nígbà tí (ayaba) gbọ́ ète (ọ̀rọ̀) wọn (tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀), ó ránṣẹ́ sí wọn. Ó sì pèsè ohun jíjẹ tí wọ́n máa rọ̀gbọ̀kú jẹ lórí tìmùtìmù àti ìrọ̀rí sílẹ̀ fún wọn. Ó fún ìkọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀bẹ (tí ó máa fi jẹun). Ó sì sọ pé: “Jáde sí wọn, (Yūsuf).” Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n gbé e tóbi (fún ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì rẹ́ra wọn lọ́wọ́ (fún ìyanu ẹwà ara rẹ̀). Wọ́n sì wí pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu! Èyí kì í ṣe abara. Kí ni èyí bí kò ṣe mọlāika alápọ̀n-ọ́nlé.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَتۡ فَذَٰلِكُنَّ ٱلَّذِي لُمۡتُنَّنِي فِيهِۖ وَلَقَدۡ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ فَٱسۡتَعۡصَمَۖ وَلَئِن لَّمۡ يَفۡعَلۡ مَآ ءَامُرُهُۥ لَيُسۡجَنَنَّ وَلَيَكُونٗا مِّنَ ٱلصَّٰغِرِينَ
(Ayaba) sọ pé: “Ìyẹn ni ẹni tí ẹ bú mi fún. Dájúdájú mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wá ìṣọ́ra. Dájúdájú tí kò bá ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún un, wọ́n kúkú máa fi sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni. Dájúdájú ó sì máa wà nínú àwọn ẹni yẹpẹrẹ.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ رَبِّ ٱلسِّجۡنُ أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا يَدۡعُونَنِيٓ إِلَيۡهِۖ وَإِلَّا تَصۡرِفۡ عَنِّي كَيۡدَهُنَّ أَصۡبُ إِلَيۡهِنَّ وَأَكُن مِّنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ
(Yūsuf) sọ pé: “Olúwa (Ẹlẹ́dàá) mi, ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo nífẹ̀ẹ́ sí ju ohun tí wọ́n ń pè mí sí. Tí O ò bá sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ mi, èmi yóò kó sínú ète wọn, èmi yó sì wà lára àwọn aláìmọ̀kan.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَٱسۡتَجَابَ لَهُۥ رَبُّهُۥ فَصَرَفَ عَنۡهُ كَيۡدَهُنَّۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Nítorí náà, Olúwa rẹ̀ jẹ́pè rẹ̀. Ó sì ṣẹ́rí ète wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
ثُمَّ بَدَا لَهُم مِّنۢ بَعۡدِ مَا رَأَوُاْ ٱلۡأٓيَٰتِ لَيَسۡجُنُنَّهُۥ حَتَّىٰ حِينٖ
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti rí àwọn àmì (pé Yūsuf kò jẹ̀bi ẹ̀sùn), lẹ́yìn náà, ó hàn sí wọn pé àwọn gbọ́dọ̀ sọ ọ́ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di àsìkò kan ná.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَدَخَلَ مَعَهُ ٱلسِّجۡنَ فَتَيَانِۖ قَالَ أَحَدُهُمَآ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَعۡصِرُ خَمۡرٗاۖ وَقَالَ ٱلۡأٓخَرُ إِنِّيٓ أَرَىٰنِيٓ أَحۡمِلُ فَوۡقَ رَأۡسِي خُبۡزٗا تَأۡكُلُ ٱلطَّيۡرُ مِنۡهُۖ نَبِّئۡنَا بِتَأۡوِيلِهِۦٓۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì kan wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì sọ pé: “Èmi lálàá rí ara mi pé mò ń fún ọtí.” Ẹnì kejì sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí ara mi pé mo gbé búrẹ́dì rù sórí mi, ẹyẹ sì ń jẹ nínú rẹ̀.” Sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún wa. Dájúdájú àwa ń rí ọ pé o wà nínú àwọn ẹni rere.
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ لَا يَأۡتِيكُمَا طَعَامٞ تُرۡزَقَانِهِۦٓ إِلَّا نَبَّأۡتُكُمَا بِتَأۡوِيلِهِۦ قَبۡلَ أَن يَأۡتِيَكُمَاۚ ذَٰلِكُمَا مِمَّا عَلَّمَنِي رَبِّيٓۚ إِنِّي تَرَكۡتُ مِلَّةَ قَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ
Ó sọ pé: “Oúnjẹ tí wọ́n ń pèsè fún ẹ̀yin méjèèjì kò ní tí ì dé ba yín, àfi kí èmi ti sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ẹ̀yin méjèèjì ṣíwájú kí ó tó dé ba yín. Ìyẹn wà nínú n̄ǹkan tí Olúwa mi fi mọ̀ mí. Dájúdájú èmi fi ẹ̀sìn àwọn ènìyàn tí kò gbàgbọ́ nínú Allāhu sílẹ̀. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱتَّبَعۡتُ مِلَّةَ ءَابَآءِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۚ مَا كَانَ لَنَآ أَن نُّشۡرِكَ بِٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۚ ذَٰلِكَ مِن فَضۡلِ ٱللَّهِ عَلَيۡنَا وَعَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ
Mo sì tẹ̀lé ẹ̀sìn àwọn bàbá mi, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb. Kò tọ́ sí wa pé kí á sọ n̄ǹkan kan di akẹgbẹ́ fún Allāhu. Ìyẹn wà nínú oore àjùlọ Allāhu lórí àwa àti lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Allāhu).
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰصَٰحِبَيِ ٱلسِّجۡنِ ءَأَرۡبَابٞ مُّتَفَرِّقُونَ خَيۡرٌ أَمِ ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ
Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ṣé àwọn olúwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló lóore jùlọ (láti jọ́sìn fún) tàbí Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí?
Arabic explanations of the Qur’an:
مَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ أَسۡمَآءٗ سَمَّيۡتُمُوهَآ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بِهَا مِن سُلۡطَٰنٍۚ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِ أَمَرَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Kò sí ohun kan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Rẹ̀ bí kò ṣe àwọn orúkọ kan tí ẹ sọ wọ́n - ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín - Allāhu kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún un. Ìdájọ́ (ta ni a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo) kò sí fún ẹnì kan àyàfi Allāhu. Ó sì ti pàṣẹ pé ẹ má ṣe jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Òun nìkan. Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰصَٰحِبَيِ ٱلسِّجۡنِ أَمَّآ أَحَدُكُمَا فَيَسۡقِي رَبَّهُۥ خَمۡرٗاۖ وَأَمَّا ٱلۡأٓخَرُ فَيُصۡلَبُ فَتَأۡكُلُ ٱلطَّيۡرُ مِن رَّأۡسِهِۦۚ قُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ ٱلَّذِي فِيهِ تَسۡتَفۡتِيَانِ
Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi méjéèjì nínú ẹ̀wọ̀n, ní ti ẹnì kan nínú yín, ó máa fún ọ̀gá rẹ̀ ní ọtí mu. Ní ti ẹnì kejì, wọn yóò kàn án mọ́ igi àgbélébùú, ẹyẹ yó sì máa jẹ nínú orí rẹ̀. Wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe ìbéèrè nípa rẹ̀.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ لِلَّذِي ظَنَّ أَنَّهُۥ نَاجٖ مِّنۡهُمَا ٱذۡكُرۡنِي عِندَ رَبِّكَ فَأَنسَىٰهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ ذِكۡرَ رَبِّهِۦ فَلَبِثَ فِي ٱلسِّجۡنِ بِضۡعَ سِنِينَ
Ó sì sọ fún ẹni tí ó rò pé ó máa là nínú àwọn méjèèjì pé: “Rántí mi lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ.” Èṣù sì mú (Yūsuf) gbàgbé ìrántí Olúwa rẹ̀ (nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀). Nítorí náà, ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n fún àwọn ọdún díẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ إِنِّيٓ أَرَىٰ سَبۡعَ بَقَرَٰتٖ سِمَانٖ يَأۡكُلُهُنَّ سَبۡعٌ عِجَافٞ وَسَبۡعَ سُنۢبُلَٰتٍ خُضۡرٖ وَأُخَرَ يَابِسَٰتٖۖ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡمَلَأُ أَفۡتُونِي فِي رُءۡيَٰيَ إِن كُنتُمۡ لِلرُّءۡيَا تَعۡبُرُونَ
Ọbá sọ pé: “Dájúdájú èmi lálàá rí màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. (Mo tún lálàá rí) ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. Ẹ̀yin ìjòyè, ẹ fún mi ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá mi tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó máa ń túmọ̀ àlá.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُوٓاْ أَضۡغَٰثُ أَحۡلَٰمٖۖ وَمَا نَحۡنُ بِتَأۡوِيلِ ٱلۡأَحۡلَٰمِ بِعَٰلِمِينَ
Wọ́n sọ pé: “Àwọn àlá tí ó lọ́pọ̀ mọ́ra wọn tí kò ní ìtúmọ̀ (nìyí). Àti pé àwa kì í ṣe onímọ̀ nípa ìtúmọ̀ àwọn àlá.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ ٱلَّذِي نَجَا مِنۡهُمَا وَٱدَّكَرَ بَعۡدَ أُمَّةٍ أَنَا۠ أُنَبِّئُكُم بِتَأۡوِيلِهِۦ فَأَرۡسِلُونِ
Ẹni tí ó là nínú àwọn (ẹlẹ́wọ̀n) méjèèjì sọ pé, - ó rántí (Yūsuf) lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ -: “Èmi yóò fún yín ní ìró nípa ìtúmọ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fi iṣẹ́ rán mi ná (kí n̄g lọ ṣe ìwádìí rẹ̀).”
Arabic explanations of the Qur’an:
يُوسُفُ أَيُّهَا ٱلصِّدِّيقُ أَفۡتِنَا فِي سَبۡعِ بَقَرَٰتٖ سِمَانٖ يَأۡكُلُهُنَّ سَبۡعٌ عِجَافٞ وَسَبۡعِ سُنۢبُلَٰتٍ خُضۡرٖ وَأُخَرَ يَابِسَٰتٖ لَّعَلِّيٓ أَرۡجِعُ إِلَى ٱلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَعۡلَمُونَ
Yūsuf, ìwọ olódodo, fún wa ní àlàyé ìtúmọ̀ àlá (yìí): màálù méje tó sanra. Àwọn màálù méje tó rù sì ń jẹ wọ́n. Àti ṣiri méje tutù àti òmíràn gbígbẹ. (Kí ni ìtúmọ̀ rẹ̀) nítorí kí n̄g lè fi àbọ̀ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn àti nítorí kí wọ́n lè mọ (ìtúmọ̀ rẹ̀).
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ تَزۡرَعُونَ سَبۡعَ سِنِينَ دَأَبٗا فَمَا حَصَدتُّمۡ فَذَرُوهُ فِي سُنۢبُلِهِۦٓ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تَأۡكُلُونَ
Ó sọ pé: “Ẹ̀yin yóò gbin n̄ǹkan ọ̀gbìn fún ọdún méje gbáko (gẹ́gẹ́ bí) ìṣe (yín). Ohunkòhun tí ẹ bá kó lérè oko, kí ẹ fi sílẹ̀ sínú ṣiri rẹ̀ àfi díẹ̀ tí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ سَبۡعٞ شِدَادٞ يَأۡكُلۡنَ مَا قَدَّمۡتُمۡ لَهُنَّ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّا تُحۡصِنُونَ
Lẹ́yìn náà, ọdún méje tó le (fún ọ̀dá òjò) yóò dé lẹ́yìn ìyẹn, (àwọn ará ìlú) yó sì lè jẹ ohun tí ẹ ti (kó lérè oko) ṣíwájú àfi díẹ̀ tí ẹ máa fi pamọ́ (fún gbígbìn).
Arabic explanations of the Qur’an:
ثُمَّ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ عَامٞ فِيهِ يُغَاثُ ٱلنَّاسُ وَفِيهِ يَعۡصِرُونَ
Lẹ́yìn náà, ọdún kan tí Wọn yóò rọ̀jò fún àwọn ènìyàn yóò dé lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn ènìyàn yó sì máa fún èso àti wàrà mu nínú ọdún náà.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦۖ فَلَمَّا جَآءَهُ ٱلرَّسُولُ قَالَ ٱرۡجِعۡ إِلَىٰ رَبِّكَ فَسۡـَٔلۡهُ مَا بَالُ ٱلنِّسۡوَةِ ٱلَّٰتِي قَطَّعۡنَ أَيۡدِيَهُنَّۚ إِنَّ رَبِّي بِكَيۡدِهِنَّ عَلِيمٞ
Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi.” Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ. (Yūsuf) sọ pé: “Padà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, kí o bi í léèrè pé, kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin tí wọ́n rẹ́ ọwọ́ ara wọn. Dájúdájú Olúwa mi ni Onímọ̀ nípa ète wọn.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ مَا خَطۡبُكُنَّ إِذۡ رَٰوَدتُّنَّ يُوسُفَ عَن نَّفۡسِهِۦۚ قُلۡنَ حَٰشَ لِلَّهِ مَا عَلِمۡنَا عَلَيۡهِ مِن سُوٓءٖۚ قَالَتِ ٱمۡرَأَتُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡـَٰٔنَ حَصۡحَصَ ٱلۡحَقُّ أَنَا۠ رَٰوَدتُّهُۥ عَن نَّفۡسِهِۦ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
(Ọba) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tiyín ti jẹ́ tí ẹ fi jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ Yūsuf?” Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Allāhu. àwa kò mọ aburú kan mọ Yūsuf.” Ayaba sọ pé: “Nísinsìn yìí ni òdodo fojú hàn. Èmi ni mo jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún eré ìfẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Dájúdájú ó wà nínú àwọn olódodo.”
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَ لِيَعۡلَمَ أَنِّي لَمۡ أَخُنۡهُ بِٱلۡغَيۡبِ وَأَنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي كَيۡدَ ٱلۡخَآئِنِينَ
(Yūsuf sọ pé): “Ìyẹn nítorí kí ọba lè mọ̀ pé dájúdájú èmi kò jàǹbá rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu kò níí fi ìmọ̀nà síbi ète àwọn oníjàǹbá.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ وَمَآ أُبَرِّئُ نَفۡسِيٓۚ إِنَّ ٱلنَّفۡسَ لَأَمَّارَةُۢ بِٱلسُّوٓءِ إِلَّا مَا رَحِمَ رَبِّيٓۚ إِنَّ رَبِّي غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Èmi kò sì fọra mi mọ́ (níbi èròkérò); dájúdájú ẹ̀mí kúkú ń pàṣẹ èròkérò (fún ẹ̀dá) ni àfi ẹni tí Olúwa mi bá kẹ́. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ ٱلۡمَلِكُ ٱئۡتُونِي بِهِۦٓ أَسۡتَخۡلِصۡهُ لِنَفۡسِيۖ فَلَمَّا كَلَّمَهُۥ قَالَ إِنَّكَ ٱلۡيَوۡمَ لَدَيۡنَا مَكِينٌ أَمِينٞ
Ọba sọ pé: “Ẹ mú (Yūsuf) wá fún mi. Èmi yóò ṣe é ní ẹni ẹ̀ṣà lọ́dọ̀ mi.” Nígbà tí ọba bá a sọ̀rọ̀ tán, ó sọ pé: “Lọ́dọ̀ wa ní òní dájúdájú ìwọ ni ẹni pàtàkì, olùfọkàntán.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ ٱجۡعَلۡنِي عَلَىٰ خَزَآئِنِ ٱلۡأَرۡضِۖ إِنِّي حَفِيظٌ عَلِيمٞ
(Yūsuf) sọ pé: “Fi mí ṣe aláṣẹ lórí àwọn ọrọ̀ ìlú, dájúdájú alámòjúútó onímọ̀ ni mí.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَكَذَٰلِكَ مَكَّنَّا لِيُوسُفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَتَبَوَّأُ مِنۡهَا حَيۡثُ يَشَآءُۚ نُصِيبُ بِرَحۡمَتِنَا مَن نَّشَآءُۖ وَلَا نُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Báyẹn ni A ṣe fún Yūsuf ní ipò àti ibùgbé lórí ilẹ̀. Ó sì ń gbé ní ibi tí ó bá fẹ́. Àwa ń mú ìkẹ́ Wa bá ẹnikẹ́ni tí A bá fẹ́. A ò sì níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَأَجۡرُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ
Dájúdájú ẹ̀san ti ọ̀run lóore jùlọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń bẹ̀rù (Allāhu).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَجَآءَ إِخۡوَةُ يُوسُفَ فَدَخَلُواْ عَلَيۡهِ فَعَرَفَهُمۡ وَهُمۡ لَهُۥ مُنكِرُونَ
Àwọn ọbàkan (Ànábì) Yūsuf dé, wọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́. Ó dá wọn mọ̀. Àwọn kò sì mọ̀ ọ́n mọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمۡ قَالَ ٱئۡتُونِي بِأَخٖ لَّكُم مِّنۡ أَبِيكُمۡۚ أَلَا تَرَوۡنَ أَنِّيٓ أُوفِي ٱلۡكَيۡلَ وَأَنَا۠ خَيۡرُ ٱلۡمُنزِلِينَ
Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù oúnjẹ wọn tán, ó sọ pé: “Ẹ lọ mú ọbàkan yín wá láti ọ̀dọ̀ bàbá yín. Ṣé ẹ kò rí i pé dájúdájú mò ń wọn kóńgò ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ni? Èmi sì dára jùlọ nínú àwọn olùgbàlejò.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَإِن لَّمۡ تَأۡتُونِي بِهِۦ فَلَا كَيۡلَ لَكُمۡ عِندِي وَلَا تَقۡرَبُونِ
Tí ẹ ò bá sì mú un wá, kò sí (ẹrù oúnjẹ) wíwọ̀n fún yín lọ́dọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ mi.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ سَنُرَٰوِدُ عَنۡهُ أَبَاهُ وَإِنَّا لَفَٰعِلُونَ
Wọ́n sọ pé: “A máa jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún un lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Dájúdájú àwa máa ṣe bẹ́ẹ̀.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ لِفِتۡيَٰنِهِ ٱجۡعَلُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ فِي رِحَالِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَعۡرِفُونَهَآ إِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ fi owó-ọjà wọn sínú ẹrù (oúnjẹ) wọn nítorí kí wọ́n lè mọ̀ nígbà tí wọ́n bá padà dé ọ̀dọ̀ ará ilé wọ́n (pé a ti dá a padà fún wọn), wọn yó sì lè padà wá.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا رَجَعُوٓاْ إِلَىٰٓ أَبِيهِمۡ قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا مُنِعَ مِنَّا ٱلۡكَيۡلُ فَأَرۡسِلۡ مَعَنَآ أَخَانَا نَكۡتَلۡ وَإِنَّا لَهُۥ لَحَٰفِظُونَ
Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ bàbá wọn, wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, wọ́n kọ̀ láti wọn oúnjẹ fún wa. Nítorí náà, jẹ́ kí ọbàkan wa bá wa lọ nítorí kí á lè rí oúnjẹ wọ̀n (wálé). Dájúdájú àwa yóò máa ṣọ́ ọ.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ هَلۡ ءَامَنُكُمۡ عَلَيۡهِ إِلَّا كَمَآ أَمِنتُكُمۡ عَلَىٰٓ أَخِيهِ مِن قَبۡلُ فَٱللَّهُ خَيۡرٌ حَٰفِظٗاۖ وَهُوَ أَرۡحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ
Ó sọ pé: “Ṣé kí n̄g gbà yín gbọ́ lórí rẹ̀ bí kò ṣe bí mó ṣe gbà yín gbọ́ ní ìṣaájú lórí ọmọ-ìyá rẹ̀? Nítorí náà, Allāhu lóore jùlọ ní Olùṣọ́. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَمَّا فَتَحُواْ مَتَٰعَهُمۡ وَجَدُواْ بِضَٰعَتَهُمۡ رُدَّتۡ إِلَيۡهِمۡۖ قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا مَا نَبۡغِيۖ هَٰذِهِۦ بِضَٰعَتُنَا رُدَّتۡ إِلَيۡنَاۖ وَنَمِيرُ أَهۡلَنَا وَنَحۡفَظُ أَخَانَا وَنَزۡدَادُ كَيۡلَ بَعِيرٖۖ ذَٰلِكَ كَيۡلٞ يَسِيرٞ
Nígbà tí wọ́n tú ẹrù oúnjẹ wọn, wọ́n rí owó-ọjà wọn tí wọ́n dá padà fún wọn (nínú rẹ̀). Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, kí ni a tún ń fẹ́? Owó-ọjà wa nìyí tí wọ́n ti dá padà fún wa. A ó si tún fi wá oúnjẹ rà fún àwọn ẹbí wa. A ó sì dáàbò bo ọbàkan wa. A sì máa rí àlékún ẹrù oúnjẹ (tí) ràkúnmí kan lè rù sí i. Ìwọ̀n oúnjẹ kékeré sì nìyẹn (lọ́dọ̀ ọba).”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ لَنۡ أُرۡسِلَهُۥ مَعَكُمۡ حَتَّىٰ تُؤۡتُونِ مَوۡثِقٗا مِّنَ ٱللَّهِ لَتَأۡتُنَّنِي بِهِۦٓ إِلَّآ أَن يُحَاطَ بِكُمۡۖ فَلَمَّآ ءَاتَوۡهُ مَوۡثِقَهُمۡ قَالَ ٱللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٞ
Ó sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́ kí ó ba yín lọ títí ẹ máa fi ṣe àdéhùn fún mi ní (orúkọ) Allāhu pé dájúdájú ẹ máa mú un padà wá bá mi àfi tí (àwọn ọ̀tá) bá ka yín mọ́.” Nígbà tí wọ́n fún un ní àdéhùn wọn tán, ó sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí lórí ohun tí à ń sọ (yìí).”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ يَٰبَنِيَّ لَا تَدۡخُلُواْ مِنۢ بَابٖ وَٰحِدٖ وَٱدۡخُلُواْ مِنۡ أَبۡوَٰبٖ مُّتَفَرِّقَةٖۖ وَمَآ أُغۡنِي عَنكُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٍۖ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِۖ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُۖ وَعَلَيۡهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُتَوَكِّلُونَ
Ó tún sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe gba ẹnu ọ̀nà ẹyọ kan wọlé. Ẹ gba ẹnu ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọlé. Èmi kò lè fí n̄ǹkan kan rọ̀ yín lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Allāhu. Kò sí ìdájọ́ (kan) àfi ti Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Òun sì ni kí àwọn olùgbáralé gbáralé.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَمَّا دَخَلُواْ مِنۡ حَيۡثُ أَمَرَهُمۡ أَبُوهُم مَّا كَانَ يُغۡنِي عَنۡهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٍ إِلَّا حَاجَةٗ فِي نَفۡسِ يَعۡقُوبَ قَضَىٰهَاۚ وَإِنَّهُۥ لَذُو عِلۡمٖ لِّمَا عَلَّمۡنَٰهُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ
Nígbà tí wọ́n wọ (inú ìlú) ní àwọn àyè tí bàbá wọn pa láṣẹ fún wọn, kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan lọ́dọ̀ Allāhu bí kò ṣe bùkátà kan nínú ẹ̀mí (Ànábì) Ya‘ƙūb tí ó múṣẹ. Dájúdájú onímọ̀ ni nípa ohun tí A fi mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيۡهِ أَخَاهُۖ قَالَ إِنِّيٓ أَنَا۠ أَخُوكَ فَلَا تَبۡتَئِسۡ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Nígbà tí wọ́n wọlé ti (Ànábì) Yūsuf, ó mú ọmọ-ìyá rẹ̀ mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ni ọmọ-ìyá rẹ. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا جَهَّزَهُم بِجَهَازِهِمۡ جَعَلَ ٱلسِّقَايَةَ فِي رَحۡلِ أَخِيهِ ثُمَّ أَذَّنَ مُؤَذِّنٌ أَيَّتُهَا ٱلۡعِيرُ إِنَّكُمۡ لَسَٰرِقُونَ
Nígbà tí ó sì fún wọn ní ẹrù wọn tán, ó fi ife-ìmumi sínú ẹrù ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan kéde pé: “Ẹ̀yin èrò-ràkúnmí, dájúdájú olè mà ni yín.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ وَأَقۡبَلُواْ عَلَيۡهِم مَّاذَا تَفۡقِدُونَ
Wọ́n dojú kọ wọ́n, wọ́n sọ pé: “Kí l’ẹ ṣàfẹ́kù?”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ نَفۡقِدُ صُوَاعَ ٱلۡمَلِكِ وَلِمَن جَآءَ بِهِۦ حِمۡلُ بَعِيرٖ وَأَنَا۠ بِهِۦ زَعِيمٞ
Wọ́n sọ pé: “A ṣàfẹ́kù ife ọba ni. Ẹni tí ó bá sì mú un wá yóò rí ẹrù oúnjẹ ràkúnmí kan gbà. Èmi sì ni onídùróó fún ẹ̀bùn náà.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ تَٱللَّهِ لَقَدۡ عَلِمۡتُم مَّا جِئۡنَا لِنُفۡسِدَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا كُنَّا سَٰرِقِينَ
Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, dájúdájú ẹ mọ̀ pé a kò wá láti ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀. Àti pé àwa kì í ṣe olè.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ فَمَا جَزَٰٓؤُهُۥٓ إِن كُنتُمۡ كَٰذِبِينَ
Wọ́n sọ pé: “Kí ni ẹ̀san (fún ẹni tí) ó jí i, tí (ó bá hàn pé) ẹ̀yin jẹ́ òpùrọ́?”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ جَزَٰٓؤُهُۥ مَن وُجِدَ فِي رَحۡلِهِۦ فَهُوَ جَزَٰٓؤُهُۥۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلظَّٰلِمِينَ
Wọ́n sọ pé: “Ẹ̀san rẹ̀; ẹni tí wọ́n bá bá a nínú ẹrù rẹ̀, òun náà ni ẹ̀san rẹ̀. Báyẹn ni àwa ṣe ń san àwọn alábòsí ní ẹ̀san (ní ọ̀dọ̀ tiwa).”¹
1. Nínú òfin tí Allāhu gbékalẹ̀ lórí olè ní àsìkò Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni pé, tí ọwọ́ bá tẹ olè, wọ́n máa fà á lé olóhun lọ́wọ́, ó sì máa sọ ọ́ di ẹrú rẹ̀. Àmọ́ ní àsìkò Ànábì tiwa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ọrùn ọwọ́ olè ni wọ́n máa gé pẹ̀lú àwọn májẹ̀mu rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَبَدَأَ بِأَوۡعِيَتِهِمۡ قَبۡلَ وِعَآءِ أَخِيهِ ثُمَّ ٱسۡتَخۡرَجَهَا مِن وِعَآءِ أَخِيهِۚ كَذَٰلِكَ كِدۡنَا لِيُوسُفَۖ مَا كَانَ لِيَأۡخُذَ أَخَاهُ فِي دِينِ ٱلۡمَلِكِ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ نَرۡفَعُ دَرَجَٰتٖ مَّن نَّشَآءُۗ وَفَوۡقَ كُلِّ ذِي عِلۡمٍ عَلِيمٞ
Ó sì bẹ̀rẹ̀ (àyẹ̀wò) pẹ̀lú àpò wọn ṣíwájú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú un jáde láti inú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Báyẹn ní A ṣe fún (Ànábì) Yūsuf ní ète dá. Kò lè fi òfin ọba mú ọmọ-ìyá rẹ̀ àfi tí Allāhu bá fẹ́.¹ À ń ṣàgbéga àwọn ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Onímọ̀ wà lókè gbogbo onímọ̀.²
1. Kò sí òfin sísọ olè dí ẹrú olóhun nínú ìlú Misrọ. Àmọ́ Allāhu fẹ́ kí Ànábì Yūsūf - kí ọlà Allāhu máa bá a - mú ọmọ ìyá rẹ̀ mọ́lẹ̀. Allāhu sì fi ìdàjọ́ tí wọ́n máa lò fún "olè" sí ẹnu àwọn ọmọ Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ohun tí Allāhu fẹ́ sì wá sí ìmúṣẹ.
2. Ìyẹn ni pé, ẹ̀dá fi ipò àti ìmọ̀ ga jura wọn títí ipò àti ìmọ̀ fi pin sí ọ̀dọ̀ Allāhu Ọba tí Ó ga jùlọ nínú ipò àti ìmọ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ قَالُوٓاْ إِن يَسۡرِقۡ فَقَدۡ سَرَقَ أَخٞ لَّهُۥ مِن قَبۡلُۚ فَأَسَرَّهَا يُوسُفُ فِي نَفۡسِهِۦ وَلَمۡ يُبۡدِهَا لَهُمۡۚ قَالَ أَنتُمۡ شَرّٞ مَّكَانٗاۖ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا تَصِفُونَ
Wọ́n sọ pé: “Tí ó bá jalè, dájúdájú ọmọ-ìyá rẹ̀ kan ti jalè ṣíwájú.” (Ànábì) Yūsuf sì fi ọ̀rọ̀ náà pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ̀, kò sì fi hàn sí wọn pé (kò rí bẹ́ẹ̀). Ó (sì) sọ pé: “Ẹ̀yin lẹ burú jùlọ ní ipò. Allāhu l’Ó sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ̀ ń ròyìn rẹ̀.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡعَزِيزُ إِنَّ لَهُۥٓ أَبٗا شَيۡخٗا كَبِيرٗا فَخُذۡ أَحَدَنَا مَكَانَهُۥٓۖ إِنَّا نَرَىٰكَ مِنَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, dájúdájú ó ní bàbá arúgbó àgbàlágbà kan. Nítorí náà, mú ẹnì kan nínú wa dípò rẹ̀. Dájúdájú àwa ń rí ìwọ pé o wà nínú àwọn ẹni-rere.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ مَعَاذَ ٱللَّهِ أَن نَّأۡخُذَ إِلَّا مَن وَجَدۡنَا مَتَٰعَنَا عِندَهُۥٓ إِنَّآ إِذٗا لَّظَٰلِمُونَ
Ó sọ pé: “Mo sádi Allāhu pé kí á mú ẹnì kan àfi ẹni tí a bá ẹrù wa lọ́dọ̀ rẹ. (Tí a bá mú ẹlòmíìràn) dájúdájú nígbà náà alábòsí ni wá.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا ٱسۡتَيۡـَٔسُواْ مِنۡهُ خَلَصُواْ نَجِيّٗاۖ قَالَ كَبِيرُهُمۡ أَلَمۡ تَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ أَبَاكُمۡ قَدۡ أَخَذَ عَلَيۡكُم مَّوۡثِقٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَمِن قَبۡلُ مَا فَرَّطتُمۡ فِي يُوسُفَۖ فَلَنۡ أَبۡرَحَ ٱلۡأَرۡضَ حَتَّىٰ يَأۡذَنَ لِيٓ أَبِيٓ أَوۡ يَحۡكُمَ ٱللَّهُ لِيۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡحَٰكِمِينَ
Nígbà tí wọ́n sọ̀rètí nù lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n tẹ̀ sọ̀rọ̀. Àgbà (nínú) wọn sọ pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé dájúdájú bàbá yín ti gba àdéhùn yín tí (ẹ ṣe ní orúkọ) Allāhu. Àti pé ṣíwájú (èyí, ohun tí ẹ ṣe ní) àṣeètó lórí ọ̀rọ̀ (Ànábì) Yūsuf. Nítorí náà, èmi kò níí fi ilẹ̀ (Misrọ) sílẹ̀ títí bàbá mi yóò fi yọ̀ǹda fún mi tàbí (títí) Allāhu yóò fi ṣe ìdájọ́ fún mi. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱرۡجِعُوٓاْ إِلَىٰٓ أَبِيكُمۡ فَقُولُواْ يَٰٓأَبَانَآ إِنَّ ٱبۡنَكَ سَرَقَ وَمَا شَهِدۡنَآ إِلَّا بِمَا عَلِمۡنَا وَمَا كُنَّا لِلۡغَيۡبِ حَٰفِظِينَ
Ẹ padà sọ́dọ̀ bàbá yín, kí ẹ sì sọ pé: “Bàbá wa, dájúdájú ọmọ rẹ jalè. A kò sì lè jẹ́rìí (sí kiní kan) àfi ohun tí a bá nímọ̀ (nípa) rẹ̀. Àwa sì kọ́ ni à ń ṣọ ìkọ̀kọ̀ (ẹ̀dá).
Arabic explanations of the Qur’an:
وَسۡـَٔلِ ٱلۡقَرۡيَةَ ٱلَّتِي كُنَّا فِيهَا وَٱلۡعِيرَ ٱلَّتِيٓ أَقۡبَلۡنَا فِيهَاۖ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ
Kí o sì bi àwọn ará ìlú tí a wà nínú rẹ̀ àti èrò-ràkúnmí tí a jọ darí dé léèrè wò. Dájúdájú olódodo ni wá.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ بَلۡ سَوَّلَتۡ لَكُمۡ أَنفُسُكُمۡ أَمۡرٗاۖ فَصَبۡرٞ جَمِيلٌۖ عَسَى ٱللَّهُ أَن يَأۡتِيَنِي بِهِمۡ جَمِيعًاۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ
(Ànábì Ya‘ƙūb) sọ pé: “Rárá o, ẹ̀mí yín ló ṣe ọ̀ràn kan lọ́ṣọ̀ọ́ fún yín. Nítorí náà, sùúrù tó rẹwà (lọ̀rọ̀ mi kàn báyìí). Ó ṣeé ṣe kí Allāhu bá mi mú gbogbo wọn wá. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَتَوَلَّىٰ عَنۡهُمۡ وَقَالَ يَٰٓأَسَفَىٰ عَلَىٰ يُوسُفَ وَٱبۡيَضَّتۡ عَيۡنَاهُ مِنَ ٱلۡحُزۡنِ فَهُوَ كَظِيمٞ
Ó pa wọ́n tì, ó sì sọ pé: “Ìbànújẹ́ ń bẹ fún mi lórí Yūsuf!” Ojú rẹ̀ méjèèjì sì funfun wá (kò ríran mọ́) látara ìbànújẹ́ náà; ó sì pa á mọ́ra.
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ تَٱللَّهِ تَفۡتَؤُاْ تَذۡكُرُ يُوسُفَ حَتَّىٰ تَكُونَ حَرَضًا أَوۡ تَكُونَ مِنَ ٱلۡهَٰلِكِينَ
Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra, ìwọ kò yé rántí Yūsuf títí o máa fi di yánnayànna tàbí (títí) o máa fi di ara àwọn òkú.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ إِنَّمَآ أَشۡكُواْ بَثِّي وَحُزۡنِيٓ إِلَى ٱللَّهِ وَأَعۡلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ
Ó sọ pé: “Allāhu mà ni èmi ń ro ẹ̀dùn ọkàn mi àti ìbànújẹ́ mi fún. Mo sì mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰبَنِيَّ ٱذۡهَبُواْ فَتَحَسَّسُواْ مِن يُوسُفَ وَأَخِيهِ وَلَا تَاْيۡـَٔسُواْ مِن رَّوۡحِ ٱللَّهِۖ إِنَّهُۥ لَا يَاْيۡـَٔسُ مِن رَّوۡحِ ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ lọ wádìí nípa Yūsuf àti ọmọ-ìyá rẹ̀. Ẹ sì má ṣe sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu. Dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Allāhu àfi ìjọ aláìgbàgbọ́.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَيۡهِ قَالُواْ يَٰٓأَيُّهَا ٱلۡعَزِيزُ مَسَّنَا وَأَهۡلَنَا ٱلضُّرُّ وَجِئۡنَا بِبِضَٰعَةٖ مُّزۡجَىٰةٖ فَأَوۡفِ لَنَا ٱلۡكَيۡلَ وَتَصَدَّقۡ عَلَيۡنَآۖ إِنَّ ٱللَّهَ يَجۡزِي ٱلۡمُتَصَدِّقِينَ
Nìgbà tí wọ́n wọlé tọ Yūsuf, wọ́n sọ pé: “Ìwọ ọba, ìnira (ebi) ti mú àwa àti ará ilé wa. A sì mú owó kan tí ẹ máa ta dànù lọ́wọ́.¹ Nítorí náà, wọn kóńgò (oúnjẹ) náà kún fún wa, kí ó sì ta wá lọ́rẹ. Dájúdájú Allāhu yóò san àwọn olùtọrẹ ní ẹ̀san rere.”
1. Ìyẹn ni pé, owó tí wọ́n mú dání kì í ṣe owó tí wọ́n lè gbà lọ́wọ́ wọn torí pé ó kéré púpọ̀, tàbí owó náà ti fẹ́ di kọ̀ǹdẹ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ هَلۡ عَلِمۡتُم مَّا فَعَلۡتُم بِيُوسُفَ وَأَخِيهِ إِذۡ أَنتُمۡ جَٰهِلُونَ
Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ẹ ṣe fún Yūsuf àti ọmọ ìyá rẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ aláìmọ̀kan?”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُوٓاْ أَءِنَّكَ لَأَنتَ يُوسُفُۖ قَالَ أَنَا۠ يُوسُفُ وَهَٰذَآ أَخِيۖ قَدۡ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡنَآۖ إِنَّهُۥ مَن يَتَّقِ وَيَصۡبِرۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Wọ́n sọ pé: “Ṣé dájúdájú ìwọ ni Yūsuf?” Ó sọ pé: “Èmi ni Yūsuf. Ọmọ ìyá mi sì nìyí. Dájúdájú Allāhu ti ṣe ìdẹ̀ra fún wa. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu), tí ó sì ṣe sùúrù, dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ تَٱللَّهِ لَقَدۡ ءَاثَرَكَ ٱللَّهُ عَلَيۡنَا وَإِن كُنَّا لَخَٰطِـِٔينَ
Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú Allāhu ti gbọ́lá fún ọ jù wá lọ. Àti pé dájúdájú àwa ni aláṣìṣe.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ لَا تَثۡرِيبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡيَوۡمَۖ يَغۡفِرُ ٱللَّهُ لَكُمۡۖ وَهُوَ أَرۡحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ
Ó sọ pé: “Kò sí ìbáwí fún yín ní òní. Allāhu yóò foríjìn yín. Òun sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.
Arabic explanations of the Qur’an:
ٱذۡهَبُواْ بِقَمِيصِي هَٰذَا فَأَلۡقُوهُ عَلَىٰ وَجۡهِ أَبِي يَأۡتِ بَصِيرٗا وَأۡتُونِي بِأَهۡلِكُمۡ أَجۡمَعِينَ
Ẹ mú ẹ̀wù mi yìí lọ, kí ẹ fi lé iwájú bàbá mi, ó máa padà di olùríran. Kí ẹ sì kó gbogbo ẹbí yín wá bá mi.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَمَّا فَصَلَتِ ٱلۡعِيرُ قَالَ أَبُوهُمۡ إِنِّي لَأَجِدُ رِيحَ يُوسُفَۖ لَوۡلَآ أَن تُفَنِّدُونِ
Nígbà tí èrò-ràkúnmí náà sí pínyà (kúrò lọ́dọ̀ Ànábì Yūsuf), bàbá wọn sọ pé: “Dájúdájú èmi ń gbọ́ òórùn Yūsuf tí ẹ kò bá níí sọ pé mò ń jarán.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ تَٱللَّهِ إِنَّكَ لَفِي ضَلَٰلِكَ ٱلۡقَدِيمِ
Wọ́n sọ pé: “A fi Allāhu búra! Dájúdájú ìwọ sì wà nínú àṣìṣe rẹ ti àtijọ́ (nípa ìfẹ́ Yūsuf).”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّآ أَن جَآءَ ٱلۡبَشِيرُ أَلۡقَىٰهُ عَلَىٰ وَجۡهِهِۦ فَٱرۡتَدَّ بَصِيرٗاۖ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مِنَ ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ
Nígbà tí oníròó-ìdùnnú dé, ó ju (ẹ̀wù náà) lé e níwájú, ó sì ríran padà. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú mo mọ ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Allāhu.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ يَٰٓأَبَانَا ٱسۡتَغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَآ إِنَّا كُنَّا خَٰطِـِٔينَ
Wọ́n sọ pé: “Bàbá wa, tọrọ àforíjìn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa, dájúdájú àwa jẹ́ aláṣìṣe.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ سَوۡفَ أَسۡتَغۡفِرُ لَكُمۡ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Ó sọ pé: “Láìpẹ́ mo máa tọrọ àforíjìn fún yín lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا دَخَلُواْ عَلَىٰ يُوسُفَ ءَاوَىٰٓ إِلَيۡهِ أَبَوَيۡهِ وَقَالَ ٱدۡخُلُواْ مِصۡرَ إِن شَآءَ ٱللَّهُ ءَامِنِينَ
Nígbà tí wọ́n wọlé tọ (Ànábì) Yūsuf, ó kó àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì mọ́ra sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ wọ ìlú Misrọ ní olùfàyàbalẹ̀ - tí Allāhu bá fẹ́ -.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَرَفَعَ أَبَوَيۡهِ عَلَى ٱلۡعَرۡشِ وَخَرُّواْ لَهُۥ سُجَّدٗاۖ وَقَالَ يَٰٓأَبَتِ هَٰذَا تَأۡوِيلُ رُءۡيَٰيَ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَعَلَهَا رَبِّي حَقّٗاۖ وَقَدۡ أَحۡسَنَ بِيٓ إِذۡ أَخۡرَجَنِي مِنَ ٱلسِّجۡنِ وَجَآءَ بِكُم مِّنَ ٱلۡبَدۡوِ مِنۢ بَعۡدِ أَن نَّزَغَ ٱلشَّيۡطَٰنُ بَيۡنِي وَبَيۡنَ إِخۡوَتِيٓۚ إِنَّ رَبِّي لَطِيفٞ لِّمَا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ
Ó gbé àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì sórí ìtẹ́. Wọ́n sì wó lulẹ̀ fún un, tí wọ́n forí kanlẹ̀ kí i.¹ Ó sọ pé: “Bàbá mi, èyí ni ìtúmọ̀ àlá mi (tí mo lá) ṣíwájú. Dájúdájú Olúwa mi ti sọ ọ́ di òdodo. Ó sì ṣe dáadáa fún mi nígbà tí Ó mú mi jáde kúrò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó tún mu yín wá (bá mi) láti inú oko lẹ́yìn tí Èṣù ti saburú sáààrin èmi àti àwọn ọbà-kan mi. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú fún ohun tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ní àsìkò náà, kò lòdì sí òfin tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - fún Ànábì Ya'ƙūb àti àwọn ọmọ rẹ̀ - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Àmọ́ nínú òfin tí Allāhu fún Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó ti di èèwọ̀ láti fi ìdọ̀bálẹ̀ àti ìkúnlẹ̀ kí ẹnikẹ́ni. Ẹ wọ ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:34.
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ رَبِّ قَدۡ ءَاتَيۡتَنِي مِنَ ٱلۡمُلۡكِ وَعَلَّمۡتَنِي مِن تَأۡوِيلِ ٱلۡأَحَادِيثِۚ فَاطِرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ أَنتَ وَلِيِّۦ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ تَوَفَّنِي مُسۡلِمٗا وَأَلۡحِقۡنِي بِٱلصَّٰلِحِينَ
Olúwa mi, dájúdájú O ti fún mi nínú ìjọba. O tún fún mi nínú ìmọ̀ ìtúmọ̀ àlá. Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Ìwọ ni Alátìlẹ́yìn mi ní ayé àti ní ọ̀run, pa mí sípò mùsùlùmí. Kí O sì fi mí pẹ̀lú àwọn ẹni rere.”
Arabic explanations of the Qur’an:
ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهِ إِلَيۡكَۖ وَمَا كُنتَ لَدَيۡهِمۡ إِذۡ أَجۡمَعُوٓاْ أَمۡرَهُمۡ وَهُمۡ يَمۡكُرُونَ
Ìyẹn wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí A fi ìmísí (rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Àti pé ìwọ kò sí lọ́dọ̀ wọn nígbà tí wọ́n fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ wọn, tí wọ́n ń déte.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَآ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ وَلَوۡ حَرَصۡتَ بِمُؤۡمِنِينَ
Ìwọ ìbáà ṣojú kòkòrò (ìgbàlà wọn), ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò níí gbàgbọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَا تَسۡـَٔلُهُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ
Ìwọ kò sì bi wọ́n léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَكَأَيِّن مِّنۡ ءَايَةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ يَمُرُّونَ عَلَيۡهَا وَهُمۡ عَنۡهَا مُعۡرِضُونَ
Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn àmì tí ń bẹ ní sánmọ̀ àti ní orí ilẹ̀ tí wọ́n ń ré kọjá lórí rẹ̀, tí wọ́n sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَا يُؤۡمِنُ أَكۡثَرُهُم بِٱللَّهِ إِلَّا وَهُم مُّشۡرِكُونَ
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni kò níí gbàgbọ́ nínú Allāhu àfi kí wọ́n tún máa ṣẹbọ.¹
1. Ìyẹn ni pé, àwọn ènìyàn kan ń bẹ láààrin àwa mùsùlùmí tí ó jẹ́ pé, tòhun ti bí wọ́n ṣe ń ṣe ’Islām, wọ́n tún ń ṣẹbọ yálà ní kọ̀rọ̀ tàbí ní gban̄gba. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, “mùsùlùmí” tó ń lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ààfáà ẹlẹ́bọ, páítọ̀ àti babaláwo, “mùsùlùmí” tí ó ń pe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu, “mùsùlùmí” tí ó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, “mùsùlùmí” tí ó ń bọ àwọn òrìṣà bí òrìṣà egúngún, òrìṣà ìbejì, òrìṣà Ajé àti “mùsùlùmí” tí ó ń lo ìfúnpá àti àsorọ̀ òògùn àti àsorọ̀ tíà àti “mùsùlùmí” tí ó ń gbé ẹbọ àti ètùtù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì í ṣe mùsùlùmí ní ọ̀dọ̀ Allāhu - Ọba mímọ́ jùlọ.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَفَأَمِنُوٓاْ أَن تَأۡتِيَهُمۡ غَٰشِيَةٞ مِّنۡ عَذَابِ ٱللَّهِ أَوۡ تَأۡتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Ṣé wọ́n fàyà balẹ̀ pé ohun tí ń bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ nínú ìyà Allāhu kò lè dé bá àwọn ni tàbí pé Àkókò náà kò lè kò lé àwọn lórí ní òjijì, tí wọn kò sì níí fura?
Arabic explanations of the Qur’an:
قُلۡ هَٰذِهِۦ سَبِيلِيٓ أَدۡعُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِۚ عَلَىٰ بَصِيرَةٍ أَنَا۠ وَمَنِ ٱتَّبَعَنِيۖ وَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
Sọ pé: “Èyí ni ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) mi, èmi àti àwọn tó tẹ̀lé mi sì ń pèpè sí (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí. Mímọ́ ni fún Allāhu. Èmi kò sì sí lára àwọn ọ̀ṣẹbọ.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡقُرَىٰٓۗ أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۗ وَلَدَارُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ
A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí nínú àwọn ará ìlú.¹ Ṣé wọn kò rìn kiri lórí ilẹ̀ kí wọ́n wo bí ìkángun àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe rí? Dájúdájú Ilé ìkẹ́yìn lóore jùlọ fún àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?
1. Lóde òní yìí, à ń rí àwọn obìnrin kan tí wọ́n ń sọra wọn di aṣíwájú ẹlẹ́sìn nínú ìjọ ’Islām àti nínú ìjọ nasọ̄rọ̄. Wọ́n sì ń sọ pé Ọlọ́hun l’Ó fi iṣẹ́ ẹ̀sìn rán àwọn níṣẹ́. Wọ́n ń sọra wọn di ànábì Ọlọ́hun àti òjíṣẹ́ Rẹ̀. Āyah yìí ti já wọn nírọ́. Allāhu - Ọba mímọ́ - ti fi rinlẹ̀ pé, Òun kò fi iṣẹ́ ìmísí rán obìnrin kan kan níṣẹ́ rí sí ẹnikẹ́ni. Ẹ jìnnà sí irú àwọn obìnrin abẹ̀sìnjẹ́ náà. Kíyè sí i! Bí Allāhu ṣe ṣa Mọryam, ìyá Ànábì ‘Īsā lẹ́ṣà tó, kò fi iṣẹ́ ìmísí rán an níṣẹ́ sí ẹnikẹ́ni.
Arabic explanations of the Qur’an:
حَتَّىٰٓ إِذَا ٱسۡتَيۡـَٔسَ ٱلرُّسُلُ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ قَدۡ كُذِبُواْ جَآءَهُمۡ نَصۡرُنَا فَنُجِّيَ مَن نَّشَآءُۖ وَلَا يُرَدُّ بَأۡسُنَا عَنِ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ
(A kì í jẹ àwọn ènìyàn níyà) títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ bá tó sọ̀rètí nù (nípa ìgbàgbọ́ wọn), tí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n ti pe àwọn ní òpùrọ́. Àrànṣe Wa yó sì dé bá wọn. A sì máa gba ẹni tí A bá fẹ́ là. Wọn kò lè dá ìyà Wa padà lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
لَقَدۡ كَانَ فِي قَصَصِهِمۡ عِبۡرَةٞ لِّأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِۗ مَا كَانَ حَدِيثٗا يُفۡتَرَىٰ وَلَٰكِن تَصۡدِيقَ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَتَفۡصِيلَ كُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú àríwòye wà nínú ìtàn wọn fún àwọn onílàákàyè. (Al-Ƙur’ān) kì í ṣe ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ń hun, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣàlàyé gbogbo n̄ǹkan;¹ ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìkẹ́ fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:114.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Yūsuf
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close