Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Ahqāf   Ayah:

Suuratul-Ah'koof

حمٓ
Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
Arabic explanations of the Qur’an:
تَنزِيلُ ٱلۡكِتَٰبِ مِنَ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ
Tírà náà sọ̀kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Arabic explanations of the Qur’an:
مَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّ وَأَجَلٖ مُّسَمّٗىۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَمَّآ أُنذِرُواْ مُعۡرِضُونَ
A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo àti fún gbèdéke àkókò kan. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa gbúnrí kúrò níbi ohun tí A fi ṣèkìlọ̀ fún wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
قُلۡ أَرَءَيۡتُم مَّا تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُواْ مِنَ ٱلۡأَرۡضِ أَمۡ لَهُمۡ شِرۡكٞ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِۖ ٱئۡتُونِي بِكِتَٰبٖ مِّن قَبۡلِ هَٰذَآ أَوۡ أَثَٰرَةٖ مِّنۡ عِلۡمٍ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu; ẹ fi wọ́n hàn mí ná, kí ni wọ́n ṣẹ̀dá nínú (ohun tó wà lórí) ilẹ̀. Tàbí wọ́n ní ìpín kan (pẹ̀lú Allāhu) nínú (ìṣẹ̀dá) àwọn sánmọ̀? Ẹ mú Tírà kan wá fún mi tó ṣíwájú (al-Ƙur’ān) yìí tàbí orípa kan nínú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَنۡ أَضَلُّ مِمَّن يَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَن لَّا يَسۡتَجِيبُ لَهُۥٓ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَهُمۡ عَن دُعَآئِهِمۡ غَٰفِلُونَ
Ta l’ó sì ṣìnà ju ẹni tí ó ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹni tí kò lè jẹ́ ìpè rẹ̀ títí di Ọjọ́ Àjíǹde! Àti pé wọn kò ní òye sí pípè tí wọ́n ń pè wọ́n.¹
1. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn olùṣìnà jùlọ yìí ni àwọn nasọ̄rọ̄ tí wọ́n ń pe Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - pẹ̀lú àwáwí pé ó wà láàyè nínú sánmọ̀, àmọ́ tí wọn kò mọ̀ pé ó kàn wà nínú sánmọ̀ ni, kò lè gbọ́ ìpè wọn áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa jẹ́pè wọn. Allāhu nìkan ṣoṣo l’Ó lè jẹ́pè àwọn ẹrúsìn rẹ̀, onígbàgbọ́ òdodo.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا حُشِرَ ٱلنَّاسُ كَانُواْ لَهُمۡ أَعۡدَآءٗ وَكَانُواْ بِعِبَادَتِهِمۡ كَٰفِرِينَ
Nígbà tí A bá sì kó àwọn ènìyàn jọ (fún Àjíǹde), àwọn òrìṣà yóò di ọ̀tá fún àwọn abọ̀rìṣà. Wọ́n sì máa tako ìjọ́sìn tí wọ́n ṣe fún wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ هَٰذَا سِحۡرٞ مُّبِينٌ
Nígbà tí wọ́n bá ń ké áwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yó sì máa sọ ìsọkúsọ sí òdodo nígbà tí ó dé bá wọn pé: “Èyí ni idán pọ́nńbélé.”
Arabic explanations of the Qur’an:
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ إِنِ ٱفۡتَرَيۡتُهُۥ فَلَا تَمۡلِكُونَ لِي مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔاۖ هُوَ أَعۡلَمُ بِمَا تُفِيضُونَ فِيهِۚ كَفَىٰ بِهِۦ شَهِيدَۢا بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۖ وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá (al-Ƙur’ān) hun fúnra rẹ̀ ni.” Sọ pé: “Tí mo bá hun ún fúnra mi, ẹ kò ní ìkápá kiní kan fún mi ní ọ̀dọ̀ Allāhu (níbi ìyà Rẹ̀). Òun ni Onímọ̀-jùlọ nípa ìsọkúsọ tí ẹ̀ ń sọ nípa rẹ̀. Ó (sì) tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قُلۡ مَا كُنتُ بِدۡعٗا مِّنَ ٱلرُّسُلِ وَمَآ أَدۡرِي مَا يُفۡعَلُ بِي وَلَا بِكُمۡۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّ وَمَآ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٞ مُّبِينٞ
Sọ pé: “Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin.¹ Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé gbólóhùn tí Allāhu pa Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láṣẹ láti sọ yìí “Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin.” túmọ̀ sí pé “Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa já sí ní ọ̀run!” Ìtúmọ̀ tó lòdì sí òdidi al-Ƙur’ān ni ìtúmọ̀ tí àwọn nasọ̄rọ̄ ń lò fún āyah náà.
Ní àkọ́kọ́ ná, àwọn āyah méjì tó ṣíwájú āyah yìí ń sọ nípa ìhà àìgbàgbọ́ tí àwọn aláìgbàgbọ́ kọ sí al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Lórí inúfu-àyàfu ni ọ̀wọ́ àwọn tó gba al-Ƙur’ān gbọ́ wà lásìkò náà nítorí pé, wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí níí yọwọ́ kọ́wọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Lásìkò náà, ipò ọ̀lẹ ni àwọn mùsùlùmí wà nínú ìlú náà. Kò sí ohun tó wá lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ sínú ’Islām tayọ kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, ní ti òdodo, Allāhu l’Ó fi iṣẹ́ mímọ́ rán òun níṣẹ́ sí gbogbo ayé. Òun kò sì tayọ àṣẹ iṣẹ́ jíjẹ́ náà. Àmọ́ irú ọwọ́ ìyà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa gbé ko òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn òun lójú lásìkò náà, òun kò mọ̀ nítorí pé, oríṣiríṣi ọwọ́ ni irúfẹ́ wọn ti yọ sí àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun.
Bí àpẹ̀ẹrẹ, ṣebí àwọn ọ̀tá ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - l’ó pète pèrò láti kàn án pa mọ́ orí igi àgbélébùú. Àmọ́ tí Allāhu kò gbà fún wọn. Bákan náà, àwọn ọ̀ṣẹbọ l’ó ju Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - sínú iná. Àmọ́ tí Allāhu Alágbára kó ọ yọ. Àwọn ọ̀tá òdodo kúkú pa Ànábì Zakariyā àti Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá àwọn méjèèjì -, bàbá àti ọmọ! A rí nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kù lókò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí ni ìtúmọ̀ tó wà fún “Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” Ìyẹn ni pé, Allāhu kò fi ìmọ̀ mọ̀ mí nípa irú iyá tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa gbé dìde sí èmi àti ẹ̀yin.
Àwọn ọ̀ṣẹbọ sì kúkú nawọ́ oníran-ànran ìyà sí wọn títí àwọn mùsùlùmí fi gbé ẹ̀sìn wọn sá kúrò nínú ìlú nígbà náà. Èyí tí a mọ̀ sí hijrah. Lẹ́yìn náà, ogun ẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò yé fi ìnira, ìjìyà àti pípa han àwọn mùsùlùmí ní èèmọ̀ ìfojú-egbò-rìn. Mọ̀ dájú pé, kò sí Ànábì kan nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - tí kò mọ̀ pé, inú ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀wọ́ àwọn tó bá tẹ̀lé e lẹ́yìn ní ọ̀nà tó dára máa já sí ní ọ̀run.
Ṣíwájú sí i, Allāhu ló fi iṣẹ́ rán Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí ó bá jẹ́ pé ìtúmọ̀ tí àwọn nasọ̄rọ̄ fún āyah náà l’ó bá jẹ́ òdodo, “èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí Allāhu máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” ni ìbá jẹ́ àgbékalẹ̀ rẹ̀.
Bákan náà, a ìbá tí rí Lárúbáwá ẹyọ kan tó máa gbà fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí pé, pẹ̀lú èdè wọn ni Allāhu fi sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀.
Ní àkótán, āyah náà ń fi rinlẹ̀ fún wa pé, iṣẹ́ tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ fún ayé kò yàtọ̀ sí ti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.
Bákan náà, āyah náà ń pè wá síbi ìdúró ṣinṣin àti àtẹ̀mọra lásìkò ìnira àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn tí kò tẹ̀lé ohun kan tayọ ìfẹ́-inú wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كَانَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ وَكَفَرۡتُم بِهِۦ وَشَهِدَ شَاهِدٞ مِّنۢ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ عَلَىٰ مِثۡلِهِۦ فَـَٔامَنَ وَٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni (al-Ƙur’ān) ti wá, tí ẹ sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ẹlẹ́rìí kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl sì jẹ́rìí lórí irú rẹ̀, tí ó sì gbà á gbọ́, (àmọ́) tí ẹ̀yin ṣègbéraga sí i, (ṣé ẹ ò ti ṣàbòsí báyẹn bí?). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَوۡ كَانَ خَيۡرٗا مَّا سَبَقُونَآ إِلَيۡهِۚ وَإِذۡ لَمۡ يَهۡتَدُواْ بِهِۦ فَسَيَقُولُونَ هَٰذَآ إِفۡكٞ قَدِيمٞ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn tó gbàgbọ́ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān jẹ́ oore ni, wọn kò níí ṣíwájú wa débẹ̀.” Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò ti tẹ̀lé ìmọ̀nà rẹ̀, ni wọ́n ń wí pé: “Irọ́ ijọ́un ni èyí.”
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمِن قَبۡلِهِۦ كِتَٰبُ مُوسَىٰٓ إِمَامٗا وَرَحۡمَةٗۚ وَهَٰذَا كِتَٰبٞ مُّصَدِّقٞ لِّسَانًا عَرَبِيّٗا لِّيُنذِرَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُحۡسِنِينَ
Tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn. Al-Ƙur’ān) yìí tún ni Tírà kan tó ń jẹ́rìí sí òdodo ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ó lè ṣèkìlọ̀ fún àwọn tó ṣàbòsí, (ó sì jẹ́) ìró ìdùnnú fún àwọn olùṣe-rere.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِنَّ ٱلَّذِينَ قَالُواْ رَبُّنَا ٱللَّهُ ثُمَّ ٱسۡتَقَٰمُواْ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
Dájúdájú àwọn tó sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa”, lẹ́yìn náà, tí wọ́n dúró ṣinṣin nínú ẹ̀sìn, kò níí sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِ خَٰلِدِينَ فِيهَا جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَوَصَّيۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ بِوَٰلِدَيۡهِ إِحۡسَٰنًاۖ حَمَلَتۡهُ أُمُّهُۥ كُرۡهٗا وَوَضَعَتۡهُ كُرۡهٗاۖ وَحَمۡلُهُۥ وَفِصَٰلُهُۥ ثَلَٰثُونَ شَهۡرًاۚ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُۥ وَبَلَغَ أَرۡبَعِينَ سَنَةٗ قَالَ رَبِّ أَوۡزِعۡنِيٓ أَنۡ أَشۡكُرَ نِعۡمَتَكَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَٰلِدَيَّ وَأَنۡ أَعۡمَلَ صَٰلِحٗا تَرۡضَىٰهُ وَأَصۡلِحۡ لِي فِي ذُرِّيَّتِيٓۖ إِنِّي تُبۡتُ إِلَيۡكَ وَإِنِّي مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ
A pa á ní àsẹ fún ènìyàn pé kí ó máa ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Ìyá rẹ̀ ní oyún rẹ̀ pẹ̀lú wàhálà. Ó sì bí i pẹ̀lú wàhálà. Oyún rẹ̀ àti gbígba ọmú lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n oṣù. (Ó sì ń tọ́ ọ) títí ó fi dàgbà dáadáa, tí ó fi di ọmọ ogójì ọdún, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, fi mọ̀ mí kí n̄g máa dúpẹ́ ìdẹ̀ra Rẹ, èyí tí Ó fi ṣe ìdẹ̀ra fún mi àti fún àwọn òbí mi méjèèjì, kí n̄g sì máa ṣe iṣẹ́ rere, èyí tí O yọ́nú sí. Kí O sì ṣe rere fún mi lórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi. Dájúdájú èmi ti ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Dájúdájú èmi sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”
Arabic explanations of the Qur’an:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنۡهُمۡ أَحۡسَنَ مَا عَمِلُواْ وَنَتَجَاوَزُ عَن سَيِّـَٔاتِهِمۡ فِيٓ أَصۡحَٰبِ ٱلۡجَنَّةِۖ وَعۡدَ ٱلصِّدۡقِ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A máa gba iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe níṣẹ́, A sì máa ṣe àmójúkúrò níbi àwọn aburú iṣẹ́ wọn; wọ́n máa wà nínú àwọn èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱلَّذِي قَالَ لِوَٰلِدَيۡهِ أُفّٖ لَّكُمَآ أَتَعِدَانِنِيٓ أَنۡ أُخۡرَجَ وَقَدۡ خَلَتِ ٱلۡقُرُونُ مِن قَبۡلِي وَهُمَا يَسۡتَغِيثَانِ ٱللَّهَ وَيۡلَكَ ءَامِنۡ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ فَيَقُولُ مَا هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Ẹni tí ó sọ fún àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì pé: “Ṣíọ̀ ẹ̀yin méjèèjì! Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣèlérí fún mi pé Wọn yóò mú mi jáde (láàyè láti inú sàréè), ṣebí àwọn ìran kan ti ré kọjá lọ ṣíwájú mi (tí Wọn kò tí ì mú wọn jáde láti inú sàréè wọn).” Àwọn (òbí rẹ̀) méjèèjì sì ń tọrọ ìgbàlà ní ọ̀dọ̀ Allāhu (fún ọmọ yìí. Wọ́n sì sọ pé): “Ègbé ni fún ọ! (O jẹ́) gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo.” (Ọ̀mọ̀ náà sì) wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”
Arabic explanations of the Qur’an:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ حَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقَوۡلُ فِيٓ أُمَمٖ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ إِنَّهُمۡ كَانُواْ خَٰسِرِينَ
Àwọn (aláìgbàgbọ́) wọ̀nyẹn ni àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí nínú àwọn ìjọ kan tí ó ti ré kọjá ṣíwájú wọn nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ẹni òfò.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلِكُلّٖ دَرَجَٰتٞ مِّمَّا عَمِلُواْۖ وَلِيُوَفِّيَهُمۡ أَعۡمَٰلَهُمۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ
Àwọn ipò yóò wà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Àti pé (èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí (Allāhu) lè san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Àwa kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيَوۡمَ يُعۡرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَلَى ٱلنَّارِ أَذۡهَبۡتُمۡ طَيِّبَٰتِكُمۡ فِي حَيَاتِكُمُ ٱلدُّنۡيَا وَٱسۡتَمۡتَعۡتُم بِهَا فَٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ عَذَابَ ٱلۡهُونِ بِمَا كُنتُمۡ تَسۡتَكۡبِرُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَبِمَا كُنتُمۡ تَفۡسُقُونَ
Ní ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kọ Iná, (wọ́n máa sọ fún wọn pé:) “Ẹ ti lo ìgbádùn yín tán nínú ìṣẹ̀mí ayé? Ẹ sì ti jẹ ìgbádùn ayé? Nítorí náà, ní òní, wọ́n máa san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí pé ẹ̀ ń ṣègbéraga ní orí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ àti nítorí pé ẹ̀ ń ṣèbàjẹ́.”
Arabic explanations of the Qur’an:
۞ وَٱذۡكُرۡ أَخَا عَادٍ إِذۡ أَنذَرَ قَوۡمَهُۥ بِٱلۡأَحۡقَافِ وَقَدۡ خَلَتِ ٱلنُّذُرُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَمِنۡ خَلۡفِهِۦٓ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ
Ṣèrántí arákùnrin (ìjọ) ‘Ād. Nígbà tí ó ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tó ń gbé nínú yanrìn tí atẹ́gùn kójọ bí òkè. Àwọn olùkìlọ̀ sì ti ré kọjá ṣíwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀. (Ó sì sọ pé:) “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún kiní kan àyàfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ńlá kan fún yín.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا لِتَأۡفِكَنَا عَنۡ ءَالِهَتِنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
Wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ wá bá wa láti ṣẹ́ wa lórí kúrò níbi àwọn òrìṣà wa ni? Mú ohun tí ò ń ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa wá tí ìwọ bá wà nínú àwọn olódodo.”
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالَ إِنَّمَا ٱلۡعِلۡمُ عِندَ ٱللَّهِ وَأُبَلِّغُكُم مَّآ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦ وَلَٰكِنِّيٓ أَرَىٰكُمۡ قَوۡمٗا تَجۡهَلُونَ
Ó sọ pé: “Ìmọ̀ (nípa rẹ̀) wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ṣoṣo. Èmi yó sì jẹ́ ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ dé òpin fún yín, ṣùgbọ́n èmi ń ri ẹ̀yin ní ìjọ aláìmọ̀kan.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَمَّا رَأَوۡهُ عَارِضٗا مُّسۡتَقۡبِلَ أَوۡدِيَتِهِمۡ قَالُواْ هَٰذَا عَارِضٞ مُّمۡطِرُنَاۚ بَلۡ هُوَ مَا ٱسۡتَعۡجَلۡتُم بِهِۦۖ رِيحٞ فِيهَا عَذَابٌ أَلِيمٞ
Nígbà tí wọ́n rí ìyà náà ní ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, tó ń wọ́ bọ̀ wá sínú àwọn kòtò ìlú wọn, wọ́n wí pé: “Èyí ni ẹ̀ṣújò rẹgẹdẹ, tí ó máa rọ̀jò fún wa.” Kò sì rí bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ni. Atẹ́gùn tí ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà nínú rẹ̀ ni.
Arabic explanations of the Qur’an:
تُدَمِّرُ كُلَّ شَيۡءِۭ بِأَمۡرِ رَبِّهَا فَأَصۡبَحُواْ لَا يُرَىٰٓ إِلَّا مَسَٰكِنُهُمۡۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ
Ó ń pa gbogbo n̄ǹkan rẹ́ (ìyẹn nínú ìlú wọn) pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n di ẹni tí wọn kò rí mọ́ àfi àwọn ibùgbé wọn. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَقَدۡ مَكَّنَّٰهُمۡ فِيمَآ إِن مَّكَّنَّٰكُمۡ فِيهِ وَجَعَلۡنَا لَهُمۡ سَمۡعٗا وَأَبۡصَٰرٗا وَأَفۡـِٔدَةٗ فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُمۡ سَمۡعُهُمۡ وَلَآ أَبۡصَٰرُهُمۡ وَلَآ أَفۡـِٔدَتُهُم مِّن شَيۡءٍ إِذۡ كَانُواْ يَجۡحَدُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
A kúkú ṣe àyè ìrọ̀rùn (nílé ayé) fún wọn nínú èyí tí A kò ṣe àyè ìrọ̀rùn (irú rẹ̀) fún ẹ̀yin nínú rẹ̀. A sì fún wọn ní ìgbọ́rọ̀, àwọn ìríran àti àwọn ọkàn. Àmọ́ ìgbọ́rọ̀ wọn àti àwọn ìríran wọn pẹ̀lú àwọn ọkàn wọn kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ kan kan níbi ìyà nítorí pé, wọ́n ń ṣe àtakò sí àwọn āyah Allāhu. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí wọn po.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلَقَدۡ أَهۡلَكۡنَا مَا حَوۡلَكُم مِّنَ ٱلۡقُرَىٰ وَصَرَّفۡنَا ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Àwa kúkú ti pa rẹ́ nínú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká yín. Àwa sì ti ṣàlàyé àwọn āyah náà ní oríṣiríṣi ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَوۡلَا نَصَرَهُمُ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ قُرۡبَانًا ءَالِهَةَۢۖ بَلۡ ضَلُّواْ عَنۡهُمۡۚ وَذَٰلِكَ إِفۡكُهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Àwọn ọlọ́hun tí wọ́n sọ di ohun tí ó máa mú wọn súnmọ́ (ìgbàlà) lẹ́yìn Allāhu kò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́? Rárá (kò lè sí àrànṣe fún wọn)! Wọ́n ti di ofò mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìyẹn sì ni (ọlọ́hun) irọ́ wọn àti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذۡ صَرَفۡنَآ إِلَيۡكَ نَفَرٗا مِّنَ ٱلۡجِنِّ يَسۡتَمِعُونَ ٱلۡقُرۡءَانَ فَلَمَّا حَضَرُوهُ قَالُوٓاْ أَنصِتُواْۖ فَلَمَّا قُضِيَ وَلَّوۡاْ إِلَىٰ قَوۡمِهِم مُّنذِرِينَ
(Rántí) nígbà tí A darí ìjọ kan nínú àwọn àlùjànnú sí ọ, tí wọ́n ń tẹ́tí gbọ́ al-Ƙur’ān. Nígbà tí wọ́n dé síbẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ẹ dákẹ́ (fún al-Ƙur’ān).” Nígbà tí wọ́n sì parí (kíké rẹ̀ tán), wọ́n padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ wọn, tí wọ́n ń ṣèkìlọ̀ (fún wọn).
Arabic explanations of the Qur’an:
قَالُواْ يَٰقَوۡمَنَآ إِنَّا سَمِعۡنَا كِتَٰبًا أُنزِلَ مِنۢ بَعۡدِ مُوسَىٰ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّ وَإِلَىٰ طَرِيقٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Wọ́n sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ wa, dájúdájú àwa gbọ́ (nípa) Tírà kan tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn (Ànábì) Mūsā, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó sì ń tọ́ni sí ọ̀nà òdodo àti ọ̀nà tààrà.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَٰقَوۡمَنَآ أَجِيبُواْ دَاعِيَ ٱللَّهِ وَءَامِنُواْ بِهِۦ يَغۡفِرۡ لَكُم مِّن ذُنُوبِكُمۡ وَيُجِرۡكُم مِّنۡ عَذَابٍ أَلِيمٖ
Ẹ̀yin ìjọ wa, ẹ jẹ́ ìpè olùpèpè Allāhu. Kí ẹ sì gbà á gbọ́ ní òdodo. (Allāhu) yó sì forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa gbà yín là kúrò nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَن لَّا يُجِبۡ دَاعِيَ ٱللَّهِ فَلَيۡسَ بِمُعۡجِزٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَيۡسَ لَهُۥ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءُۚ أُوْلَٰٓئِكَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٍ
Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì jẹ́pè olùpèpè Allāhu, kò lè mórí bọ́ mọ́ (Allāhu) lọ́wọ́ lórí ilẹ̀. Kò sì sí aláàbò kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn sì wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
Arabic explanations of the Qur’an:
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَلَمۡ يَعۡيَ بِخَلۡقِهِنَّ بِقَٰدِرٍ عَلَىٰٓ أَن يُحۡـِۧيَ ٱلۡمَوۡتَىٰۚ بَلَىٰٓۚ إِنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ṣé wọn kò wòye pé dájúdájú Allāhu, Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí kò sì káàárẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá wọn, (ṣé kò) ní agbára láti sọ àwọn òkú di alààyè ni? Bẹ́ẹ̀ ni, (Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú Ó ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَيَوۡمَ يُعۡرَضُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ عَلَى ٱلنَّارِ أَلَيۡسَ هَٰذَا بِٱلۡحَقِّۖ قَالُواْ بَلَىٰ وَرَبِّنَاۚ قَالَ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ
(Rántí) ọjọ́ tí wọ́n máa darí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kọ Iná, (wọ́n sì máa sọ fún wọn pé:) “Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?” Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, (òdodo ni) Olúwa wa.” (Allāhu máa) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé, ẹ̀yin jẹ́ aláìgbàgbọ́.”
Arabic explanations of the Qur’an:
فَٱصۡبِرۡ كَمَا صَبَرَ أُوْلُواْ ٱلۡعَزۡمِ مِنَ ٱلرُّسُلِ وَلَا تَسۡتَعۡجِل لَّهُمۡۚ كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَ مَا يُوعَدُونَ لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا سَاعَةٗ مِّن نَّهَارِۭۚ بَلَٰغٞۚ فَهَلۡ يُهۡلَكُ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ
Nítorí náà, ṣe sùúrù gẹ́gẹ́ bí àwọn onípinnu ọkàn nínú àwọn Òjíṣẹ́ ti ṣe sùúrù. Má ṣe bá wọn wá ìyà pẹ̀lú ìkánjú. Ní ọjọ́ tí wọ́n bá rí ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, wọn yóò dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé (yìí) tayọ àkókò kan nínú ọ̀sán. Ìkéde (ẹ̀sìn nìyí fún wọn). Ta ni ó sì máa parun bí kò ṣe ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Ahqāf
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close