Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: Al-Balad   Ayah:

Suuratul-Balad

لَآ أُقۡسِمُ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ
Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìí¹ búra.
1. Ìbúra Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - àti ìbúra ẹ̀dá: Nígbà tí ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe kan bá jẹ́ kìkìdá òdodo àti àmọ̀dájú, ìbura lórí rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì tí a lè gba ṣe àfihàn ìdánilójú rẹ̀ fún ẹlòmíìràn nítorí kí ó lè bi iyèméjì àti rújúrújú wó lulẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ àti ìṣe Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì ti dájú pé iṣẹ́ Ọwọ́ Rẹ̀ ni níti òdodo àti àmọ̀dàjù, ẹ̀tọ́ ni fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - láti fi èyíkéyìí nínú wọn búra. Ṣebí iṣẹ́ ọwọ́ Allāhu ni gbogbo bíbẹ.
Àmọ́, ẹ̀dá kan kò gbọdọ̀ fi ẹ̀dá mìíràn búra nítorí pé, ẹ̀dá kan kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá mìíràn. Allāhu nìkan ni òdodo àti àmọ̀dájú fún ẹ̀dá pé, Òun nìkan ni Ẹlẹ́dàá wa tí a lè fi búra nítorí pé, fífi Allāhu nìkan ṣoṣo búra ni ẹ̀sìn gbà wá láyè mọ láti fi búra. Bíbá Allāhu wá akẹgbẹ́ (ẹbọ ṣíṣe) sì ni fífi n̄ǹkan mìíràn búra lẹ́yìn Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ
Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).¹
1. Ẹ̀tọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fún Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni kíkógun ja ìlú Mọkkah lásìkò ogun Ìṣí Mọkkah “Fat-hu Mọkkah”. Ṣíwájú àsìkò yìí àti lẹ́yìn rẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún ẹnikẹ́ni mọ́ láti jagun nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَوَالِدٖ وَمَا وَلَدَ
Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.
Arabic explanations of the Qur’an:
لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِي كَبَدٍ
Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَيَحۡسَبُ أَن لَّن يَقۡدِرَ عَلَيۡهِ أَحَدٞ
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
Arabic explanations of the Qur’an:
يَقُولُ أَهۡلَكۡتُ مَالٗا لُّبَدًا
Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”
Arabic explanations of the Qur’an:
أَيَحۡسَبُ أَن لَّمۡ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ
Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
Arabic explanations of the Qur’an:
أَلَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ عَيۡنَيۡنِ
Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?
Arabic explanations of the Qur’an:
وَلِسَانٗا وَشَفَتَيۡنِ
Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
Arabic explanations of the Qur’an:
وَهَدَيۡنَٰهُ ٱلنَّجۡدَيۡنِ
A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
Arabic explanations of the Qur’an:
فَلَا ٱقۡتَحَمَ ٱلۡعَقَبَةَ
Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!
Arabic explanations of the Qur’an:
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡعَقَبَةُ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?
Arabic explanations of the Qur’an:
فَكُّ رَقَبَةٍ
(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَوۡ إِطۡعَٰمٞ فِي يَوۡمٖ ذِي مَسۡغَبَةٖ
Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
Arabic explanations of the Qur’an:
يَتِيمٗا ذَا مَقۡرَبَةٍ
(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
Arabic explanations of the Qur’an:
أَوۡ مِسۡكِينٗا ذَا مَتۡرَبَةٖ
tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).
Arabic explanations of the Qur’an:
ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡمَرۡحَمَةِ
Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
Arabic explanations of the Qur’an:
أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ
Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ
Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:7.
Arabic explanations of the Qur’an:
عَلَيۡهِمۡ نَارٞ مُّؤۡصَدَةُۢ
Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: Al-Balad
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Translations’ Index

Translation of the Quran meanings into Yoruba by Abu Rahima Mikhail Aikweiny, printed in 1432 H.

close