قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى * - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

مەنالار تەرجىمىسى سۈرە: سۈرە پاتىھە   ئايەت:

Suuratul-Fatiha

بِسۡمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.¹
1. Sūratun Mọkkiyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú Hijrah. Bákan náà, sūratun Mọdaniyyah túmọ̀ sí sūrah tí ó sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn Hijrah. Ìyẹn ni pé, Hijrah tí àwọn mùsùlùmí ṣe láti ìlú Mọkkah Alápọ̀n-ọ́nlé sí ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀ ni wọ́n fi pín gbogbo sūrah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé sábẹ́ sūratun Mọkkiyyah àti sūratun Mọdaniyyah. Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ sūrah yìí: (1) Fātihatul-kitāb “Sūrah Ìbẹ̀rẹ̀ Tírà (ìyẹn ní ti àkọsílẹ̀, kì í ṣe ní ti ìsọ̀kalẹ̀.” (2) ’Ummul-Ƙur’ān “Ìpìlẹ̀ al-Ƙur’ān”, (3) ’Ummul-kitāb “Ìpìlẹ̀ Tírà”, (4) as-Sab‘u al-mọthāniy “sūrah alāyah méje tí ó kún fún ẹyìn Allāhu” (Wọ́n ṣí “bismillāh ar-rahmọ̄n ar-rọhīm” mọ́ ọn.)“, (5) al-Ƙur’ān al-‘aṭḥīm “N̄ǹkan Kíkà ńlá”, (6) al-hamd “ẹyìn”, (7) as-sọlāt “ìrun”, (8) aṣ-ṣifā’ “ìwòsàn” àti (9) ar-ruƙyah “àdúà pàjáwìrì”.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Gbogbo ẹyìn¹ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa² gbogbo ẹ̀dá,
1. Nínú èdè Lárúbáwá, “hamd” yàtọ̀ sí “ṣukr” àmọ́ ìtúmọ̀ ìkíní kejì fẹ́ súnmọ́ ara wọn.
Ìtúmọ̀ “hamd” ni “ẹyìn” èyí tí a sọ jáde ní ẹnu pẹ̀lú ìfẹ́ àti gbígbé-títóbi fún ẹni tí ẹyìn tọ́ sí nítorí pé ẹni náà jẹ́ ẹni tí ó pé tán pátápátá tí kò kù sí ibì kan kan níbi pàápàá rẹ̀, àwọn ìròyìn rẹ̀ àti àwọn ìṣe rẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó pé tán pátápátá bí kò ṣe Allāhu - Ọba tó ga jùlọ -. Nítorí náà, Allāhu nìkan ṣoṣo ni a gbọ́dọ̀ máa yìn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé, Òun nìkan náà ni a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Nígbà tí a bá yin ẹ̀dá ẹgbẹ́ wa, “mọdh” ni wọ́n ń pe ìyẹn nínú èdè Lárúbáwá. Kò sì pọn dandan kí ẹyìn náà dénú, ó lè má kọjá orí ahọ́n, gẹ́gẹ́ bí ẹyìn àwọn eléwì.
Ní ti “ṣukr”, ìtúmọ̀ rẹ̀ ni mímọ rírì oore àti sísọ ọ́ jáde. Ẹni tí ó bá mọ rírì oore kan, tí ó sì sọ ọ́ jáde ló dúpẹ́ oore náà fún ẹni tí ó ṣe oore náà fún un. Bí Allāhu bá ṣe oore kan fún mi, mo lè sọ pé, “’aṣkuru-llāh / ṣukrān lillāh” (mo dúpẹ́ fún Allāhu). Bí ìwọ bá ṣoore kan fún mi, mo lè sọ pé, “ ’aṣkuruk / ṣukrān lak (mo dúpẹ́ fún ọ). Paban̄barì rẹ̀ ni pé kí n̄g sọ fún ọ pé, “jazākumullāhu kọerā” (Allāhu á san yín ní ẹ̀san rere.). Kí ìwọ náà yára fọ èsì pé, “ wa ’antum fajazākumullāhu kọerā” (Àti ẹ̀yin náà, Allāhu á san yín ní ẹ̀san rere.) Èsì kọ́ ni “wa’iyyākum”
Àmọ́ a kò gbọ́dọ̀ lo “hamd” fún ẹ̀dá kan lẹ́yìn Allāhu - Ọba Ẹlẹ́yìn. Ẹni tí ó bá wá sọ pé, “alhamdu lillāh” Ó ti kó ẹyìn àti ọpẹ́ sínú. Nítorí náà, kí ẹ̀dá máa ṣe “alhamdu lillāh” ní àsìkò tí a bá rí oore kan gbà láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ní àsìkò tí a kò ì rí oore náà gbá nítorí pé, oore Allāhu lọ́dọ̀ wa pọ̀ láì ní òǹkà.
Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé, nígbà tí ìdùnnú kan bá ṣẹlẹ̀ sí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó máa sọ pé “ alhamdu lillāh allathī bi ni‘mọtihi tatimmu-ssọ̄lihāt” (gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ẹni tí àwọn ohun rere ń pé (ń kẹ́sẹjá) pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ̀. Tí ìdà kejì bá sì ṣẹlẹ̀, ó máa sọ pé, “alhamdu lillāhi ‘alā kulli hāl” (gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu lórí gbogbo ipò (tí ẹ̀dá bá wà).
2. Ọ̀rọ̀ yìí “rọbb” (Olúwa), ó kó ọ̀rọ̀ mẹ́ta sínú. Dídá ẹ̀dá, ṣíṣe ìjọba lórí ẹ̀dá tàbí níni ẹ̀dá àti dídarí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. Nígbà tí a bá pe Allāhu ní “rọbb” (Olúwa), gbogbo ìwọ̀nyẹn ló kó sínú nítorí pé, Allāhu ni Ẹlẹ́dàá wa, tiRẹ̀ ni ìjọba lórí gbogbo ẹ̀dá, Òun sì ni Ó ń darí kádàrá ẹ̀dá. Nítorí náà, Allāhu ni Olúwa wa.
Àmọ́ nígbà tí a bá pe ẹ̀dá kan ní “rọbb”, kò lè kó gbogbo ìròyìn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyẹn sínú. Bí àpẹ̀ẹrẹ, à ń pe onílé ní “rọbbul-baet” nítorí pé, ìtúmọ̀ kan nínú àwọn ìtúmọ̀ “rọbb” ni níni n̄ǹkan”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱلرَّحۡمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run,
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
مَٰلِكِ يَوۡمِ ٱلدِّينِ
Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِيَّاكَ نَعۡبُدُ وَإِيَّاكَ نَسۡتَعِينُ
Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí.¹
1. Èyí ni àdéhùn ojoojúmọ́ tí à ń ṣe fún Allāhu, Ọlọ́hun tí a gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Nítorí náà, èèwọ̀ ẹ̀sìn ni fún mùsùlùmí láti yapa àdéhùn náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa àdéhùn náà, ó ti di ẹlẹ́bọ pọ́nńbélé títí ó fi máa ronú pìwàdà.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱهۡدِنَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ
Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà (’Islām),¹
1. Sirọ̄tun mustaƙīm “ọ̀nà tààrà” jẹyọ ní àyè 33 nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Ó sì dúró fún ìwọ̀nyí:
(1) Jíjìnnà sí ẹbọ ṣíṣe, jíjìnnà sí ìwà ìbàjẹ́, ṣíṣe rere àti lílo òfin Allāhu; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:151-153.
(2) Jíjọ́sìn fún Allāhu níkan ṣoṣo àti dídúró ṣinṣin nínú ìjọ́sìn Rẹ̀; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:51&101.
(3) Ẹ̀sìn kan ṣoṣo tí gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ṣe; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:83-90.
(4) Ẹ̀sìn ’Islām; ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah al-’Ani-‘Ām; 6:125-126. Nítorí náà, kò sí àyè kan nínú al-Ƙur’ān tí ọ̀nà tààrà ti dúró fún ẹ̀sìn nasọ̄rọ̄ tàbí ẹ̀sìn yẹhudi.
Nígbà tí mùsùlùmí bá sì ń ṣàdúà ní gbogbo ìgbà pé “ihdina-ssirọ̄tọl-mustaƙīm” ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé, “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ l’ójú ọ̀nà tààrà.” Ìyẹn ni pé, “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ sínú ’Islām ọ̀nà tààrà.” Nítorí náà, àdúà ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ sínú ẹ̀sìn ’Islām títí d’ọjọ́ ikú ni àdúà náà dúró fún. Àti pé, āyah 7 ti yanjú ọ̀rọ̀ náà pé, kì í ṣe ọ̀nà yẹhudi nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìbínú lọ́dọ̀ Allāhu. Kì í sì ṣe ọ̀nà nasọ̄rọ̄ nítorí pé, wọ́n ti di olùṣìnà. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:23. =
Kíyè sí i! Ìdí tí àdúà yìí sì fi pàtàkì púpọ̀ ni pé, tí ènìyàn bá ṣe ẹ̀sìn ’Islām, kò lè jèrè rẹ̀ àyàfi kí ó kú sínú rẹ̀ nítorí sūrah Āli-‘Imrọ̄n; 3:102. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:56.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
صِرَٰطَ ٱلَّذِينَ أَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِمۡ غَيۡرِ ٱلۡمَغۡضُوبِ عَلَيۡهِمۡ وَلَا ٱلضَّآلِّينَ
ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún,¹ yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasọ̄rọ̄).
1. Àwọn wo gan-an ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún, tí àwa mùsùlùmí ń tọ ojú-ọ̀nà wọn? Ẹ ka sūrah Mọryam;19:58.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
 
مەنالار تەرجىمىسى سۈرە: سۈرە پاتىھە
سۈرە مۇندەرىجىسى بەت نومۇرى
 
قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

قۇرئان كەرىمنىڭ يورۇباچە تەرجىمىسىنى شەيىخ ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل ئەيكۇينى تەرجىمە قىلغان، ھىجىريە 1432-يىلى بېسىلغان.

تاقاش