قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى * - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

مەنالار تەرجىمىسى سۈرە: سۈرە ھۇد   ئايەت:

Suuratu Huud

الٓرۚ كِتَٰبٌ أُحۡكِمَتۡ ءَايَٰتُهُۥ ثُمَّ فُصِّلَتۡ مِن لَّدُنۡ حَكِيمٍ خَبِيرٍ
’Alif lām rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹ (Èyí ni) Tírà tí wọ́n ti to àwọn āyah inú rẹ̀ ní àtògún régé, lẹ́yìn náà wọ́n ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۚ إِنَّنِي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٞ وَبَشِيرٞ
(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé ẹ má jọ́sìn fún kiní kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún yín láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَأَنِ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِ يُمَتِّعۡكُم مَّتَٰعًا حَسَنًا إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى وَيُؤۡتِ كُلَّ ذِي فَضۡلٖ فَضۡلَهُۥۖ وَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٖ كَبِيرٍ
(A ti ṣàlàyé rẹ̀) pé kí ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó máa fún yín ní ìgbádùn dáadáa títí di gbèdéke àkókò kan. Ó máa fún oníṣẹ́-àṣegbọrẹ ní ẹ̀san iṣẹ́ àṣegbọrẹ rẹ̀. Tí ẹ bá sì pẹ̀yìndà, dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá fún yín.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِلَى ٱللَّهِ مَرۡجِعُكُمۡۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ
Ọ̀dọ̀ Allāhu ni ibùpadàsí yín. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَلَآ إِنَّهُمۡ يَثۡنُونَ صُدُورَهُمۡ لِيَسۡتَخۡفُواْ مِنۡهُۚ أَلَا حِينَ يَسۡتَغۡشُونَ ثِيَابَهُمۡ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Gbọ́, dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń ká (iyèméjì àti ọ̀tá) sínú igbá-àyà wọn láti lè fara pamọ́ fún Allāhu. Kíyè sí i, nígbà tí wọ́n ń yíṣọ wọn bora, Allāhu mọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi pamọ́ àti n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa n̄ǹkan tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ وَمَا مِن دَآبَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِ رِزۡقُهَا وَيَعۡلَمُ مُسۡتَقَرَّهَا وَمُسۡتَوۡدَعَهَاۚ كُلّٞ فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٖ
Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan tó wà lórí ilẹ̀ àfi kí arísìkí rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì mọ ibùgbé rẹ̀ (nílé ayé) àti ilẹ̀ tí ó máa kú sí. Gbogbo rẹ̀ ti wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ وَكَانَ عَرۡشُهُۥ عَلَى ٱلۡمَآءِ لِيَبۡلُوَكُمۡ أَيُّكُمۡ أَحۡسَنُ عَمَلٗاۗ وَلَئِن قُلۡتَ إِنَّكُم مَّبۡعُوثُونَ مِنۢ بَعۡدِ ٱلۡمَوۡتِ لَيَقُولَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ
Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà - Ìtẹ́ ọlá Rẹ̀ sì wà lórí omi (ṣíwájú èyí) - nítorí kí Ó lè dan yín wò pé, èwo nínú yín ló dára jùlọ (níbi) iṣẹ́ rere. Tí o bá kúkú sọ pé dájúdájú wọn yóò gbe yín dìde lẹ́yìn ikú, dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَئِنۡ أَخَّرۡنَا عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابَ إِلَىٰٓ أُمَّةٖ مَّعۡدُودَةٖ لَّيَقُولُنَّ مَا يَحۡبِسُهُۥٓۗ أَلَا يَوۡمَ يَأۡتِيهِمۡ لَيۡسَ مَصۡرُوفًا عَنۡهُمۡ وَحَاقَ بِهِم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Dájúdájú tí A bá sún ìyà ṣíwájú fún wọn di ìgbà tó ní òǹkà, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Kí ló ń dá a dúró ná?” Gbọ́, ní ọjọ́ tí ìyà yóò dé bá wọn, kò níí ṣe é gbé kúrò fún wọn. Àti pé ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì máa dìyà tó máa yí wọn po.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَئِنۡ أَذَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِنَّا رَحۡمَةٗ ثُمَّ نَزَعۡنَٰهَا مِنۡهُ إِنَّهُۥ لَيَـُٔوسٞ كَفُورٞ
Àti pé dájúdájú tí A bá fi ìkẹ́ kan tọ́ ènìyàn lẹ́nu wò láti ọ̀dọ̀ Wa, lẹ́yìn náà, tí A bá gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, dájúdájú ó máa di olùsọ̀rètínù, aláìmoore.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَئِنۡ أَذَقۡنَٰهُ نَعۡمَآءَ بَعۡدَ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُ لَيَقُولَنَّ ذَهَبَ ٱلسَّيِّـَٔاتُ عَنِّيٓۚ إِنَّهُۥ لَفَرِحٞ فَخُورٌ
Dájúdájú tí A bá sì fún un ní ìdẹ̀ra tọ́wò lẹ́yìn ìnira tó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Àwọn aburú ti kúrò lọ́dọ̀ mi.” Dájúdájú ó máa di aláyọ̀pọ̀rọ́, onífáàrí.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِلَّا ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٞ كَبِيرٞ
Àyàfi àwọn tó bá ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn, ti wọn ni àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَعَلَّكَ تَارِكُۢ بَعۡضَ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ وَضَآئِقُۢ بِهِۦ صَدۡرُكَ أَن يَقُولُواْ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ كَنزٌ أَوۡ جَآءَ مَعَهُۥ مَلَكٌۚ إِنَّمَآ أَنتَ نَذِيرٞۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٌ
Bóyá o fẹ́ gbé apá kan ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ sílẹ̀, kí ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá ọkàn rẹ nípa rẹ̀ (ní ti ìpáyà pé) wọ́n ń wí pé: “Kí ó sì jẹ́ pé àpótí-ọrọ̀ kan sọ̀kalẹ̀ fún un, tàbí kí mọlāika kan bá a wá?” Olùkìlọ̀ ni ìwọ. Allāhu sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ فَأۡتُواْ بِعَشۡرِ سُوَرٖ مِّثۡلِهِۦ مُفۡتَرَيَٰتٖ وَٱدۡعُواْ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni.” Sọ pé: “Ẹ mú sūrah mẹ́wàá àdáhun bí irú rẹ̀ wá, kí ẹ sì ké sí ẹni tí ẹ bá lè ké sí lẹ́yìn Allāhu tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَإِلَّمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَكُمۡ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَآ أُنزِلَ بِعِلۡمِ ٱللَّهِ وَأَن لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَهَلۡ أَنتُم مُّسۡلِمُونَ
Nígbà náà tí wọn kò bá da yín lóhùn, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú wọ́n sọ (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ Allāhu. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, ṣé ẹ̀yin yóò di mùsùlùmí?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
مَن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتَهَا نُوَفِّ إِلَيۡهِمۡ أَعۡمَٰلَهُمۡ فِيهَا وَهُمۡ فِيهَا لَا يُبۡخَسُونَ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn nílé ayé. A ò sì níí dín kiní kan kù fún wọn nílé ayé.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَيۡسَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ إِلَّا ٱلنَّارُۖ وَحَبِطَ مَا صَنَعُواْ فِيهَا وَبَٰطِلٞ مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí kò níí sí kiní kan fún wọn mọ́ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn àfi Iná. N̄ǹkan tí wọ́n gbélé ayé ṣe sì máa bàjẹ́. Òfò sì ni ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّهِۦ وَيَتۡلُوهُ شَاهِدٞ مِّنۡهُ وَمِن قَبۡلِهِۦ كِتَٰبُ مُوسَىٰٓ إِمَامٗا وَرَحۡمَةًۚ أُوْلَٰٓئِكَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۚ وَمَن يَكۡفُرۡ بِهِۦ مِنَ ٱلۡأَحۡزَابِ فَٱلنَّارُ مَوۡعِدُهُۥۚ فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّنۡهُۚ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ
Ǹjẹ́ ẹni tó ń bẹ́ lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ (ìyẹn, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -), tí olùjẹ́rìí kan (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) sì ń ké al-Ƙur’ān (fún un) láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí tírà (Ànábì) Mūsā sì ti wá ṣíwájú rẹ̀, tí ó jẹ́ tírà tí wọ́n ń tẹ̀lé, tí ó sì jẹ́ ìkẹ́ (fún wọn), (ǹjẹ́ Ànábì yìí - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jọ olùṣìnà bí?) Àwọn (mùsùlùmí) wọ̀nyí ni wọ́n sì gbà á gbọ́ ní òdodo. Ẹnikẹ́ni tó bá ṣàì gbà á gbọ́ nínú àwọn ìjọ (nasọ̄rọ̄, yẹhudi àti ọ̀ṣẹbọ), nígbà náà Iná ni àdéhùn rẹ̀. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa al-Ƙur’ān. Dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ يُعۡرَضُونَ عَلَىٰ رَبِّهِمۡ وَيَقُولُ ٱلۡأَشۡهَٰدُ هَٰٓؤُلَآءِ ٱلَّذِينَ كَذَبُواْ عَلَىٰ رَبِّهِمۡۚ أَلَا لَعۡنَةُ ٱللَّهِ عَلَى ٱلظَّٰلِمِينَ
Àti pé ta ni ó ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu? Àwọn wọ̀nyẹn ni wọ́n yóò kó wá síwájú Olúwa wọn. Àwọn ẹlẹ́rìí (ìyẹn, àwọn mọlāika) yó sì máa sọ pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó parọ́ mọ́ Olúwa wọn.” Gbọ́, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn alábòsí,
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ٱلَّذِينَ يَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَيَبۡغُونَهَا عِوَجٗا وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ
àwọn tó ń ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, tí wọ́n sì ń fẹ́ kó wọ́. Àwọn sì ni aláìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أُوْلَٰٓئِكَ لَمۡ يَكُونُواْ مُعۡجِزِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا كَانَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِنۡ أَوۡلِيَآءَۘ يُضَٰعَفُ لَهُمُ ٱلۡعَذَابُۚ مَا كَانُواْ يَسۡتَطِيعُونَ ٱلسَّمۡعَ وَمَا كَانُواْ يُبۡصِرُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn kò lè mórí bọ́ nínú ìyà Allāhu lórí ilẹ̀ àti pé kò sí aláàbò kan fún wọn lẹ́yìn Allāhu. A sì máa ṣe àdìpèlé ìyà fún wọn. Wọn kò lè gbọ́. Àti pé wọn kì í ríran (rí òdodo).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn lófò. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:24.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
لَا جَرَمَ أَنَّهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ هُمُ ٱلۡأَخۡسَرُونَ
Ní ti òdodo, dájúdájú àwọn gan-an ni ẹni òfò jùlọ ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَأَخۡبَتُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n sì dúnní mọ́ ìronúpìwàdà sọ́dọ̀ Olúwa wọn, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ مَثَلُ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ كَٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡأَصَمِّ وَٱلۡبَصِيرِ وَٱلسَّمِيعِۚ هَلۡ يَسۡتَوِيَانِ مَثَلًاۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Àpèjúwe ìjọ méjèèjì dà bí afọ́jú àti adití pẹ̀lú olùríran àti olùgbọ́rọ̀. Ǹjẹ́ àwọn méjèèjì dọ́gba ní àpèjúwe bí? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوۡمِهِۦٓ إِنِّي لَكُمۡ نَذِيرٞ مُّبِينٌ
A sì kúkú ti rán (Ànábì) Nūh sí ìjọ rẹ̀ (láti sọ pé) dájúdájú olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni mo jẹ́ fún yín.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَن لَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۖ إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ أَلِيمٖ
(Mò ń kìlọ̀) pé kí ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àfi Allāhu. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà ọjọ́ ẹlẹ́ta-eléro fún yín.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَقَالَ ٱلۡمَلَأُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِن قَوۡمِهِۦ مَا نَرَىٰكَ إِلَّا بَشَرٗا مِّثۡلَنَا وَمَا نَرَىٰكَ ٱتَّبَعَكَ إِلَّا ٱلَّذِينَ هُمۡ أَرَاذِلُنَا بَادِيَ ٱلرَّأۡيِ وَمَا نَرَىٰ لَكُمۡ عَلَيۡنَا مِن فَضۡلِۭ بَلۡ نَظُنُّكُمۡ كَٰذِبِينَ
Àwọn aṣíwájú tó ṣàì gbàgbọ́ nínú ìjọ rẹ̀ sì wí pé: “Àwa kò mọ̀ ọ́ sí ẹnì kan bí kò ṣe abara bí irú wa. Àwa kò sì mọ àwọn tó tẹ̀lé ọ sí ẹnì kan kan bí kò ṣe àwọn ẹni yẹpẹrẹ nínú wa, ọlọ́pọlọ bín-íntín. Àti pé àwa kò ri yín sí ẹni tó fi ọ̀nà kan kan ní àjùlọ lórí wa, ṣùgbọ́n a kà yín kún òpùrọ́.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَءَاتَىٰنِي رَحۡمَةٗ مِّنۡ عِندِهِۦ فَعُمِّيَتۡ عَلَيۡكُمۡ أَنُلۡزِمُكُمُوهَا وَأَنتُمۡ لَهَا كَٰرِهُونَ
(Ànábì Nūh) sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí mo bá wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí Ó sì fún mi ní ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí wọ́n sì dì yín lójú pa sí i (tí ẹ kò ríran rí òdodo náà), ǹjẹ́ a óò fi dandan mu yín bí, nígbà tí ẹ kórira rẹ̀?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَٰقَوۡمِ لَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مَالًاۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِۚ وَمَآ أَنَا۠ بِطَارِدِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْۚ إِنَّهُم مُّلَٰقُواْ رَبِّهِمۡ وَلَٰكِنِّيٓ أَرَىٰكُمۡ قَوۡمٗا تَجۡهَلُونَ
Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè dúkìá kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Èmi kò sì níí le àwọn tó gbàgbọ́ lódodo dànù. Dájúdájú wọn yóò pàdé Olúwa wọn, ṣùgbọ́n dájúdájú èmi ń ri yín sí ìjọ aláìmọ̀kan.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَٰقَوۡمِ مَن يَنصُرُنِي مِنَ ٱللَّهِ إِن طَرَدتُّهُمۡۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Ẹ̀yin ìjọ mi, ta ni ó máa ràn mí lọ́wọ́ níbi (ìyà) Allāhu tí mo bá lé wọn dànù? Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ إِنِّي مَلَكٞ وَلَآ أَقُولُ لِلَّذِينَ تَزۡدَرِيٓ أَعۡيُنُكُمۡ لَن يُؤۡتِيَهُمُ ٱللَّهُ خَيۡرًاۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِمَا فِيٓ أَنفُسِهِمۡ إِنِّيٓ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Èmi kò sì sọ fún yín pé àwọn ilé-ọrọ̀ Allāhu ń bẹ lọ́dọ̀ mi. Èmi kò sì mọ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ pé mọlāika ni mí. Èmi kò sì lè sọ fún àwọn tí ẹ̀ ń fojú bín-íntín wò pé, Allāhu kò níí ṣoore fún wọn. Allāhu l'Ó nímọ̀ jùlọ nípa n̄ǹkan tó ń bẹ nínú ẹ̀mí wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, dájúdájú mo ti wà nínú àwọn alábòsí.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ يَٰنُوحُ قَدۡ جَٰدَلۡتَنَا فَأَكۡثَرۡتَ جِدَٰلَنَا فَأۡتِنَا بِمَا تَعِدُنَآ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
Wọ́n wí pé: “Nūh, o mà kúkú ti jà wá níyàn. O sì ṣe àríyànjiyàn púpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítorí náà, mú ohun tí o ṣe ní ìlérí fún wa wá tí o bá wà lára àwọn olódodo.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ إِنَّمَا يَأۡتِيكُم بِهِ ٱللَّهُ إِن شَآءَ وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ
(Ànábì Nūh) sọ pé: “Allāhu l’Ó máa mú un wá ba yín tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَا يَنفَعُكُمۡ نُصۡحِيٓ إِنۡ أَرَدتُّ أَنۡ أَنصَحَ لَكُمۡ إِن كَانَ ٱللَّهُ يُرِيدُ أَن يُغۡوِيَكُمۡۚ هُوَ رَبُّكُمۡ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Ìmọ̀ràn mi kò sì lè ṣe yín ní àǹfààní tí mo bá fẹ́ gbà yín nìmọ̀ràn, tí Allāhu bá fẹ́ pa yín run. Òun ni Olúwa yín. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ إِنِ ٱفۡتَرَيۡتُهُۥ فَعَلَيَّ إِجۡرَامِي وَأَنَا۠ بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُجۡرِمُونَ
Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni.” Sọ pé: “Tí mó bá hun ún, èmi ni mo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń dá lẹ́ṣẹ̀.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَأُوحِيَ إِلَىٰ نُوحٍ أَنَّهُۥ لَن يُؤۡمِنَ مِن قَوۡمِكَ إِلَّا مَن قَدۡ ءَامَنَ فَلَا تَبۡتَئِسۡ بِمَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ
A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Nūh pé, dájúdájú kò sí ẹnì kan tí ó máa gbàgbọ́ mọ́ nínú ìjọ rẹ àfi ẹni tó ti gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱصۡنَعِ ٱلۡفُلۡكَ بِأَعۡيُنِنَا وَوَحۡيِنَا وَلَا تُخَٰطِبۡنِي فِي ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ إِنَّهُم مُّغۡرَقُونَ
Kí o sì kan ọkọ̀ ojú-omi náà lójú Wa (báyìí) pẹ̀lú ìmísí Wa. Má sì ṣe bá Mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣàbòsí. Dájúdájú wọ́n máa tẹ̀ wọ́n rì ni.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَصۡنَعُ ٱلۡفُلۡكَ وَكُلَّمَا مَرَّ عَلَيۡهِ مَلَأٞ مِّن قَوۡمِهِۦ سَخِرُواْ مِنۡهُۚ قَالَ إِن تَسۡخَرُواْ مِنَّا فَإِنَّا نَسۡخَرُ مِنكُمۡ كَمَا تَسۡخَرُونَ
Ó sì ń kan ọkọ̀ ojú-omi náà lọ. Ìgbàkígbà tí àwọn ọ̀tọ̀kùlú nínú ìjọ rẹ̀ bá kọjá lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n yó sì máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. (Ànábì Nūh) sì sọ pé: “Tí ẹ bá fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, dájúdájú àwa náà yóò fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọmọr; 54:9.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ مَن يَأۡتِيهِ عَذَابٞ يُخۡزِيهِ وَيَحِلُّ عَلَيۡهِ عَذَابٞ مُّقِيمٌ
Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, tí ìyà gbere sì máa kò lé lórí.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَ أَمۡرُنَا وَفَارَ ٱلتَّنُّورُ قُلۡنَا ٱحۡمِلۡ فِيهَا مِن كُلّٖ زَوۡجَيۡنِ ٱثۡنَيۡنِ وَأَهۡلَكَ إِلَّا مَن سَبَقَ عَلَيۡهِ ٱلۡقَوۡلُ وَمَنۡ ءَامَنَۚ وَمَآ ءَامَنَ مَعَهُۥٓ إِلَّا قَلِيلٞ
(Báyìí ni ọ̀rọ̀ wà) títí di ìgbà tí àṣẹ Wa dé, omi sì ṣẹ́yọ gbùú láti ojú-àrò (tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì). A sọ pé: “Kó gbogbo n̄ǹkan ní takọ-tabo méjìméjì àti ará ilé rẹ sínú ọkọ̀ ojú-omi - àyàfi ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ti kò lé lórí (fún ìparun) - àti ẹnikẹ́ni tó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì sí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ òdodo pẹ̀lú rẹ̀ àfi àwọn díẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ وَقَالَ ٱرۡكَبُواْ فِيهَا بِسۡمِ ٱللَّهِ مَجۡر۪ىٰهَا وَمُرۡسَىٰهَآۚ إِنَّ رَبِّي لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ
(Ànábì Nūh) sọ pé: “Ẹ wọ inú ọkọ̀ ojú-omi náà. Ní orúkọ Allāhu ni ìrìn rẹ̀ àti ìgúnlẹ̀ rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَهِيَ تَجۡرِي بِهِمۡ فِي مَوۡجٖ كَٱلۡجِبَالِ وَنَادَىٰ نُوحٌ ٱبۡنَهُۥ وَكَانَ فِي مَعۡزِلٖ يَٰبُنَيَّ ٱرۡكَب مَّعَنَا وَلَا تَكُن مَّعَ ٱلۡكَٰفِرِينَ
Ó sì ń gbé wọn lọ nínú ìgbì omi tó dà bí àpáta. (Ànábì Nūh) sì ké sí ọmọkùnrin rẹ̀, tí ó ti yara rẹ̀ sọ́tọ̀: “Ọmọkùnrin mi, gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú wa. Má sì ṣe wà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ سَـَٔاوِيٓ إِلَىٰ جَبَلٖ يَعۡصِمُنِي مِنَ ٱلۡمَآءِۚ قَالَ لَا عَاصِمَ ٱلۡيَوۡمَ مِنۡ أَمۡرِ ٱللَّهِ إِلَّا مَن رَّحِمَۚ وَحَالَ بَيۡنَهُمَا ٱلۡمَوۡجُ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُغۡرَقِينَ
Ó wí pé: “Èmi yóò fara pamọ́ síbi àpáta kan tí ó máa gbà mí là níbi omi.” (Ànábì Nūh) sọ pé: “Kò sí olùgbàlà kan (kò sí ẹni tí wọ́n máa gbàlà) ní òní níbi àṣẹ Allāhu (ẹ̀kún omi) àfi ẹni tí Allāhu bá ṣàánú.” Ìgbì omi sì la àwọn méjèèjì láààrin. Ó sì di ara àwọn olùtẹ̀rì sínú omi.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَقِيلَ يَٰٓأَرۡضُ ٱبۡلَعِي مَآءَكِ وَيَٰسَمَآءُ أَقۡلِعِي وَغِيضَ ٱلۡمَآءُ وَقُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ وَٱسۡتَوَتۡ عَلَى ٱلۡجُودِيِّۖ وَقِيلَ بُعۡدٗا لِّلۡقَوۡمِ ٱلظَّٰلِمِينَ
A sọ pé: “Ilẹ̀, fa omi rẹ mu. Sánmọ̀, dáwọ́ (òjò) dúró.” Wọ́n sì dín omi kù. Àṣẹ (ìparun wọn) sì wá sí ìmúṣẹ. (Ọkọ̀ ojú-omi) sì gúnlẹ̀ sórí àpáta Jūdī. Wọ́n sì sọ pé: “Kí ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu máa jẹ́ ti ìjọ alábòsí.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَنَادَىٰ نُوحٞ رَّبَّهُۥ فَقَالَ رَبِّ إِنَّ ٱبۡنِي مِنۡ أَهۡلِي وَإِنَّ وَعۡدَكَ ٱلۡحَقُّ وَأَنتَ أَحۡكَمُ ٱلۡحَٰكِمِينَ
(Ànábì) Nūh pe Olúwa rẹ̀, ó sì sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú ọmọ mi wà nínú ará ilé mi. Àti pé dájúdájú àdéhùn Rẹ, òdodo ni. Ìwọ l’O sì mọ ẹjọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ يَٰنُوحُ إِنَّهُۥ لَيۡسَ مِنۡ أَهۡلِكَۖ إِنَّهُۥ عَمَلٌ غَيۡرُ صَٰلِحٖۖ فَلَا تَسۡـَٔلۡنِ مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٌۖ إِنِّيٓ أَعِظُكَ أَن تَكُونَ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ
Allāhu sọ pé: “Nūh, dájúdájú kò sí nínú ará ilé rẹ (ní ti ẹ̀sìn). Dájúdájú iṣẹ́ tí kò dára ni.¹ Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ bi Mí léèrè n̄ǹkan tí o ò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀. Dájúdájú Èmi ń kìlọ̀ fún ọ nítorí kí o má baà di ara àwọn aláìmọ̀kan.”
1. Nínú èdè Lárúbáwá, wọ́n lè pe ọmọ ẹni ní iṣẹ́ ọwọ́ ẹni. Nínú èdè Lárúbáwá èyí lè jẹ́ ‘amal tàbí kasb. Láti ọ̀dọ̀ ‘Ā’iṣah - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Dájúdájú n̄ǹkan tó dára jùlọ ni n̄ǹkan tí ẹ bá jẹ nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín. Dájúdájú nínú iṣẹ́ ọwọ́ yín ni àwọn ọmọ yín wà. (Sunan at-Tirmithiy; 1358. Abu ‘Īsā at-Tirmithiy sọ pé: “Èyí ni hadīth tó dára, tó fẹsẹ̀ rìnlẹ̀.)
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ رَبِّ إِنِّيٓ أَعُوذُ بِكَ أَنۡ أَسۡـَٔلَكَ مَا لَيۡسَ لِي بِهِۦ عِلۡمٞۖ وَإِلَّا تَغۡفِرۡ لِي وَتَرۡحَمۡنِيٓ أَكُن مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ
Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi ń sá di Ọ́ níbi kí n̄g bi Ọ́ léèrè n̄ǹkan tí èmi kò ní ìmọ̀ rẹ̀. Tí O ò bá foríjìn mí, kí O sì ṣàánú mi, èmi yóò wà lára àwọn ẹni òfò.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قِيلَ يَٰنُوحُ ٱهۡبِطۡ بِسَلَٰمٖ مِّنَّا وَبَرَكَٰتٍ عَلَيۡكَ وَعَلَىٰٓ أُمَمٖ مِّمَّن مَّعَكَۚ وَأُمَمٞ سَنُمَتِّعُهُمۡ ثُمَّ يَمَسُّهُم مِّنَّا عَذَابٌ أَلِيمٞ
A sọ pé: “Nūh, sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Wa. Àti pé kí ìbùkún wà pẹ̀lú rẹ àti àwọn ìjọ nínú àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ. Àwọn ìjọ kan (tún ń bọ̀), tí A óò fún wọn ní ìgbádùn (oore ayé). Lẹ́yìn náà, ìyà ẹlẹ́ta-eléro yó sì fọwọ́ bà wọ́n láti ọ̀dọ̀ Wa.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
تِلۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡغَيۡبِ نُوحِيهَآ إِلَيۡكَۖ مَا كُنتَ تَعۡلَمُهَآ أَنتَ وَلَا قَوۡمُكَ مِن قَبۡلِ هَٰذَاۖ فَٱصۡبِرۡۖ إِنَّ ٱلۡعَٰقِبَةَ لِلۡمُتَّقِينَ
Ìwọ̀nyí wà nínú ìró ìkọ̀kọ̀ tí À ń fi (ìmísí rẹ̀) ránṣẹ́ sí ọ. Ìwọ àti ìjọ rẹ kò nímọ̀ rẹ̀ ṣíwájú èyí (tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ). Nítorí náà, ṣe sùúrù. Dájúdájú ìkángun rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَإِلَىٰ عَادٍ أَخَاهُمۡ هُودٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥٓۖ إِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا مُفۡتَرُونَ
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran ‘Ād ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Hūd. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀yin kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe aládàápa irọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
يَٰقَوۡمِ لَآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًاۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱلَّذِي فَطَرَنِيٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ
Ẹ̀yin ìjọ mi, èmi kò bi yín léèrè owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kò sí ẹ̀san mi níbì kan bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá mi. Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَٰقَوۡمِ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِ يُرۡسِلِ ٱلسَّمَآءَ عَلَيۡكُم مِّدۡرَارٗا وَيَزِدۡكُمۡ قُوَّةً إِلَىٰ قُوَّتِكُمۡ وَلَا تَتَوَلَّوۡاْ مُجۡرِمِينَ
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olùwa Ẹlẹ́dàá yín, lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè rọ̀jò fún yín ní púpọ̀ láti sánmọ̀ àti nítorí kí Ó lè ṣe àlékún agbára kún agbára yín. Ẹ má ṣe pẹ̀yìn dà láti di ẹlẹ́ṣẹ̀ (sínú àìgbàgbọ́).”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ يَٰهُودُ مَا جِئۡتَنَا بِبَيِّنَةٖ وَمَا نَحۡنُ بِتَارِكِيٓ ءَالِهَتِنَا عَن قَوۡلِكَ وَمَا نَحۡنُ لَكَ بِمُؤۡمِنِينَ
Wọ́n wí pé: “Hūd, o ò mú ẹ̀rí kan tó yanjú wá fún wa. Àwa kò sì níí gbé àwọn òrìṣà wa jù sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ. Àti pé àwa kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِن نَّقُولُ إِلَّا ٱعۡتَرَىٰكَ بَعۡضُ ءَالِهَتِنَا بِسُوٓءٖۗ قَالَ إِنِّيٓ أُشۡهِدُ ٱللَّهَ وَٱشۡهَدُوٓاْ أَنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ
A kò níí sọ n̄ǹkan kan (sí ọ) bí kò ṣe pé, àwọn kan nínú àwọn òrìṣà wa ti fi ìnira kàn ọ́ (ló fi ń sọ ìsọkúsọ nípa wọn).” Ó sọ pé: “Dájúdájú èmi ń fi Allāhu ṣe Ẹlẹ́rìí àti pé kí ẹ̀yin náà jẹ́rìí pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
مِن دُونِهِۦۖ فَكِيدُونِي جَمِيعٗا ثُمَّ لَا تُنظِرُونِ
dípò jíjọ́sìn fún Allāhu. Nítorí náà, ẹ parapọ̀ déte sí mi. Lẹ́yìn náà, kí ẹ má ṣe lọ́ mi lára.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنِّي تَوَكَّلۡتُ عَلَى ٱللَّهِ رَبِّي وَرَبِّكُمۚ مَّا مِن دَآبَّةٍ إِلَّا هُوَ ءَاخِذُۢ بِنَاصِيَتِهَآۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Dájúdájú èmi gbáralé Allāhu, Olúwa mi àti Olúwa yín. Kò sí ẹ̀dá abẹ̀mí kan àfi kí (ó jẹ́ pé) Òun l’Ó máa fi àásó orí rẹ̀ mú un. Dájúdájú Olúwa mi wà lórí ọ̀nà tààrà.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَقَدۡ أَبۡلَغۡتُكُم مَّآ أُرۡسِلۡتُ بِهِۦٓ إِلَيۡكُمۡۚ وَيَسۡتَخۡلِفُ رَبِّي قَوۡمًا غَيۡرَكُمۡ وَلَا تَضُرُّونَهُۥ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ رَبِّي عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَفِيظٞ
Nítorí náà, tí ẹ bá pẹ̀yìn dà (níbi òdodo), mo kúkú ti fi ohun tí Wọ́n fi rán mi níṣẹ́ jíṣẹ́ fún yín, Olúwa mi yó sì fi ìjọ kan tó máa yàtọ̀ sí ẹ̀yin rọ́pò yín. Ẹ kò sì lè kó ìnira kan kan bá A. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا هُودٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَنَجَّيۡنَٰهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Hūd àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa; A gbà wọ́n là nínú ìyà tó nípọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَتِلۡكَ عَادٞۖ جَحَدُواْ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِمۡ وَعَصَوۡاْ رُسُلَهُۥ وَٱتَّبَعُوٓاْ أَمۡرَ كُلِّ جَبَّارٍ عَنِيدٖ
Ìran ‘Ād nìyẹn; wọ́n tako àwọn āyah Olúwa wọn. Wọ́n sì yapa àwọn Òjíṣẹ́ wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé àṣẹ gbogbo àwọn aláfojúdi alátakò-òdodo.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَأُتۡبِعُواْ فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا لَعۡنَةٗ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَآ إِنَّ عَادٗا كَفَرُواْ رَبَّهُمۡۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّعَادٖ قَوۡمِ هُودٖ
A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Gbọ́, dájúdájú ìran ‘Ād ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ máa jẹ́ ti ìran ‘Ād, ìjọ (Ànábì) Hūd.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ وَإِلَىٰ ثَمُودَ أَخَاهُمۡ صَٰلِحٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ هُوَ أَنشَأَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ وَٱسۡتَعۡمَرَكُمۡ فِيهَا فَٱسۡتَغۡفِرُوهُ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِۚ إِنَّ رَبِّي قَرِيبٞ مُّجِيبٞ
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Thamūd ni arákùnrin wọn, (Ànábì) Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Òun l’Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá yín láti ara (erùpẹ̀) ilẹ̀. Ó sì fún yín ní ìṣẹ̀mí lò lórí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Olùsúnmọ́, Olùjẹ́pè (ẹ̀dá).”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ يَٰصَٰلِحُ قَدۡ كُنتَ فِينَا مَرۡجُوّٗا قَبۡلَ هَٰذَآۖ أَتَنۡهَىٰنَآ أَن نَّعۡبُدَ مَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَا وَإِنَّنَا لَفِي شَكّٖ مِّمَّا تَدۡعُونَآ إِلَيۡهِ مُرِيبٖ
Wọ́n wí pé: “Sọ̄lih, o ti wà láààrin wa ní ẹni tí a ní ìrètí sí (pé o máa sanjọ́) ṣíwájú (ọ̀rọ̀ tí o sọ) yìí. Ṣé o máa kọ̀ fún wa láti jọ́sìn fún ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún ni? Dájúdájú àwa mà wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wá sí.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَءَاتَىٰنِي مِنۡهُ رَحۡمَةٗ فَمَن يَنصُرُنِي مِنَ ٱللَّهِ إِنۡ عَصَيۡتُهُۥۖ فَمَا تَزِيدُونَنِي غَيۡرَ تَخۡسِيرٖ
Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé èmi wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí ìkẹ́ kan sì dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ta ni ẹni tí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú (ìyà) Allāhu tí mo bá yapa Rẹ̀? Kò sí kiní kan tí ẹ lè fi ṣe àlékún rẹ̀ fún mi yàtọ̀ sí ìparun.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَٰقَوۡمِ هَٰذِهِۦ نَاقَةُ ٱللَّهِ لَكُمۡ ءَايَةٗۖ فَذَرُوهَا تَأۡكُلۡ فِيٓ أَرۡضِ ٱللَّهِۖ وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٖ فَيَأۡخُذَكُمۡ عَذَابٞ قَرِيبٞ
Ẹ̀yin ìjọ mi, èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. Ó jẹ́ àmì fún yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ́ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ìnira kàn án nítorí kí ìyà tó súnmọ́ má báa jẹ yín.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَعَقَرُوهَا فَقَالَ تَمَتَّعُواْ فِي دَارِكُمۡ ثَلَٰثَةَ أَيَّامٖۖ ذَٰلِكَ وَعۡدٌ غَيۡرُ مَكۡذُوبٖ
Wọ́n sì gún un pa. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ̀gbádùn nínú ilé yín fún ọjọ́ mẹ́ta (kí ìyà yín tó dé). Ìyẹn ni àdéhùn tí kì í ṣe irọ́.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا صَٰلِحٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَمِنۡ خِزۡيِ يَوۡمِئِذٍۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ ٱلۡقَوِيُّ ٱلۡعَزِيزُ
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Sọ̄lih àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. (A tún gbà wọ́n là) nínú àbùkù ọjọ́ yẹn. Dájúdájú Olúwa Rẹ, Òun ni Alágbára, Olùborí (ẹ̀dá).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَأَخَذَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلصَّيۡحَةُ فَأَصۡبَحُواْ فِي دِيَٰرِهِمۡ جَٰثِمِينَ
Ohùn igbe líle gbá àwọn tó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
كَأَن لَّمۡ يَغۡنَوۡاْ فِيهَآۗ أَلَآ إِنَّ ثَمُودَاْ كَفَرُواْ رَبَّهُمۡۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّثَمُودَ
Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí.¹ Gbọ́, dájúdájú ìran Thamūd ṣàì gbàgbọ́ nínú Olúwa wọn. Kíyè sí i, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ máa jẹ́ ti ìjọ Thamūd.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ṣẹ̀mí fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún, àmọ́ wọ́n parẹ́ láààrin ìṣẹ́jú kan.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَقَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُنَآ إِبۡرَٰهِيمَ بِٱلۡبُشۡرَىٰ قَالُواْ سَلَٰمٗاۖ قَالَ سَلَٰمٞۖ فَمَا لَبِثَ أَن جَآءَ بِعِجۡلٍ حَنِيذٖ
Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ti mú ìró ìdùnnú wá bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Wọ́n sọ pé: “Àlàáfíà (fún ọ).” Ó sọ pé: “Àlàáfíà (fún yín).” Kò sì pẹ́ rárá tó fi gbé ọmọ màálù àyangbẹ wá.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَمَّا رَءَآ أَيۡدِيَهُمۡ لَا تَصِلُ إِلَيۡهِ نَكِرَهُمۡ وَأَوۡجَسَ مِنۡهُمۡ خِيفَةٗۚ قَالُواْ لَا تَخَفۡ إِنَّآ أُرۡسِلۡنَآ إِلَىٰ قَوۡمِ لُوطٖ
Nígbà tí ó rí ọwọ́ wọn pé kò kan oúnjẹ náà, ó pajú dà sí wọn (ó f’ojú òdì wo àìjẹun wọn). Ìbẹ̀rù wọn sì mú un.¹ Wọ́n sọ pé: “Má ṣe bẹ̀rù. Dájúdájú àwọn ènìyàn (Ànábì) Lūt ni Wọ́n rán àwa sí.”
1. Tàbí “ó pa ìbẹ̀rù wọn mọ́ra”.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱمۡرَأَتُهُۥ قَآئِمَةٞ فَضَحِكَتۡ فَبَشَّرۡنَٰهَا بِإِسۡحَٰقَ وَمِن وَرَآءِ إِسۡحَٰقَ يَعۡقُوبَ
Ìyàwó rẹ̀ wà ní ìdúró, ó rẹ́rìn-ín. A sì fún un ní ìró ìdùnnú (pé ó máa bí) ’Ishāƙ. Àti pé lẹ́yìn ’Ishāƙ ni Ya‘ƙūb (ìyẹn, ọmọọmọ).¹
1. Àsìkò tí àwọn mọlāika fẹ́ pa ìjọ Ànábì Lūt - kí ọlà Allāhu máa bá a - rẹ́ ni àsìkò tí ìró ìdùnnú àsọtẹ́lẹ̀ bíbí Ànábì ’Ishāƙ - kí ọlà Allāhu máa bá a - bọ́ sí. Èyí túmọ̀ sí pé, lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti fẹ́ fi àkọ́bí rẹ̀ Ànábì ’Ismọ̄‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - jọ́sìn fún Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - ni àsọtẹ́lẹ̀ bíbí Ànábì ’Ishāƙ - kí ọlà Allāhu máa bá a - ṣẹlẹ̀. Ìdí ni pé, ọlá àdúà tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - ṣe láti tọrọ ọmọ ló jẹ́ sábàbí fún bíbí Ànábì ’Ismọ̄‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Àmọ́ ọlá ìtẹ̀lé àṣẹ tí Allāhu pa pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - fi “ọmọ àdúà náà” Ànábì ’Ismọ̄‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - jọ́sìn fún Òun ló jẹ́ sábàbí fún bíbí Ànábì ’Ishāƙ - kí ọlà Allāhu máa bá a -.
Kíyè sí i, àdúà “ìrawọ́rasẹ̀” sí Allāhu tí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - ṣe láti fi tọrọ Ànábì ’Ismọ̄‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - kò la ìjẹ́jẹ̀ẹ́ kan kan lọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe lérò. Ẹ ka sūrah ‘Ibrọ̄hīm; 14:39 àti sūrah as-Sọ̄ffāt; 37: 100 - 113.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَتۡ يَٰوَيۡلَتَىٰٓ ءَأَلِدُ وَأَنَا۠ عَجُوزٞ وَهَٰذَا بَعۡلِي شَيۡخًاۖ إِنَّ هَٰذَا لَشَيۡءٌ عَجِيبٞ
Ó sọ pé: “Hẹ̀n-ẹ́n! Ṣé pé mo máa bímọ, arúgbóbìnrin ni mí, baálé mi yìí sì ti dàgbàlágbà! Dájúdájú èyí ni n̄ǹkan ìyanu.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُوٓاْ أَتَعۡجَبِينَ مِنۡ أَمۡرِ ٱللَّهِۖ رَحۡمَتُ ٱللَّهِ وَبَرَكَٰتُهُۥ عَلَيۡكُمۡ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِۚ إِنَّهُۥ حَمِيدٞ مَّجِيدٞ
Wọ́n sọ pé: “Ṣé o máa ṣèèmọ̀ nípa àṣẹ Allāhu ni? Ìkẹ́ Allāhu àti ìbùkún Rẹ̀ kí ó máa bẹ fún yín, ẹ̀yin ará ilé (yìí). Dájúdájú Allāhu ni Ẹlẹ́yìn, Ológo.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَمَّا ذَهَبَ عَنۡ إِبۡرَٰهِيمَ ٱلرَّوۡعُ وَجَآءَتۡهُ ٱلۡبُشۡرَىٰ يُجَٰدِلُنَا فِي قَوۡمِ لُوطٍ
Nígbà tí ìbẹ̀rù kúrò lára (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, tí ìró ìdùnnú sì ti dé bá a ló bá ń pàrọwà fún (àwọn Òjíṣẹ́) Wa nípa ìjọ (Ànábì) Lūt.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ لَحَلِيمٌ أَوَّٰهٞ مُّنِيبٞ
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ni aláfaradà, olùrawọ́rasẹ̀, olùronúpìwàdà.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ أَعۡرِضۡ عَنۡ هَٰذَآۖ إِنَّهُۥ قَدۡ جَآءَ أَمۡرُ رَبِّكَۖ وَإِنَّهُمۡ ءَاتِيهِمۡ عَذَابٌ غَيۡرُ مَرۡدُودٖ
(Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ṣẹ́rí kúrò níbi èyí. Dájúdájú àṣẹ Olúwa rẹ ti dé. Àti pé dájúdájú àwọn (wọ̀nyẹn) ni ìyà tí kò ṣe é dá padà yóò dé bá.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَمَّا جَآءَتۡ رُسُلُنَا لُوطٗا سِيٓءَ بِهِمۡ وَضَاقَ بِهِمۡ ذَرۡعٗا وَقَالَ هَٰذَا يَوۡمٌ عَصِيبٞ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé bá (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Ó sì sọ pé: “Ọjọ́ tó le gan-an ní èyí.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَجَآءَهُۥ قَوۡمُهُۥ يُهۡرَعُونَ إِلَيۡهِ وَمِن قَبۡلُ كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ هَٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِي هُنَّ أَطۡهَرُ لَكُمۡۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَلَا تُخۡزُونِ فِي ضَيۡفِيٓۖ أَلَيۡسَ مِنكُمۡ رَجُلٞ رَّشِيدٞ
Àwọn ènìyàn rẹ̀ wá bá a, tí wọ́n ń sáré gbọ̀n wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ti ń ṣe iṣẹ́ aburú (bí ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin). Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, àwọn wọ̀nyí ni ọmọbìnrin mi¹, wọ́n mọ́ jùlọ fún yín (láti fi ṣaya dípò ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin). Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe dójú tì mí lọ́dọ̀ àlejò mi. Ṣé kò sí ọkùnrin kan tí ó lóye lórí nínú yín ni?”
1. Ànábì Lūt - kí ọlà Allāhu máa bá a - pe “àwọn obìnrin” nínú ìjọ rẹ̀ ní “àwọn ọmọbìnrin rẹ̀” nítorí pé, ipò bàbá ni ànábì kọ̀ọ̀kan wà lórí ìjọ rẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ لَقَدۡ عَلِمۡتَ مَا لَنَا فِي بَنَاتِكَ مِنۡ حَقّٖ وَإِنَّكَ لَتَعۡلَمُ مَا نُرِيدُ
Wọ́n wí pé: “Ìwọ kúkú ti mọ̀ pé àwa kò ní bùkátà kan sí àwọn ọmọbìnrin rẹ. O sì ti mọ n̄ǹkan tí à ń fẹ́.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ لَوۡ أَنَّ لِي بِكُمۡ قُوَّةً أَوۡ ءَاوِيٓ إِلَىٰ رُكۡنٖ شَدِيدٖ
Ó sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú agbára kan wà fún mi lórí yín ni, tàbí (pé) mo lè darapọ̀ mọ́ ẹbí kan (tàbí ikọ̀ ọmọ-ogun kan) tó lágbára ni, (èmi ìbá di yín lọ́wọ́ níbi aburú yín).”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ يَٰلُوطُ إِنَّا رُسُلُ رَبِّكَ لَن يَصِلُوٓاْ إِلَيۡكَۖ فَأَسۡرِ بِأَهۡلِكَ بِقِطۡعٖ مِّنَ ٱلَّيۡلِ وَلَا يَلۡتَفِتۡ مِنكُمۡ أَحَدٌ إِلَّا ٱمۡرَأَتَكَۖ إِنَّهُۥ مُصِيبُهَا مَآ أَصَابَهُمۡۚ إِنَّ مَوۡعِدَهُمُ ٱلصُّبۡحُۚ أَلَيۡسَ ٱلصُّبۡحُ بِقَرِيبٖ
(Àwọn mọlāika) sọ pé: “(Ànábì) Lūt, dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa. Wọn kò lè (fọwọ́ aburú) kàn ọ́. Nítorí náà, mú àwọn ará ilé rẹ jáde ní abala kan nínú òru.¹ Kí ẹnì kan nínú yín má sì ṣe ṣíjú wẹ̀yìn wò, àfi ìyàwó rẹ, dájúdájú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn ló máa ṣẹlẹ̀ sí i. Dájúdájú àkókò (àdánwò) wọn ni òwúrọ̀. Ṣé òwúrọ̀ kò súnmọ́ ni?
1. Abala kan nínú òru nínú āyah yìí dúró fún abala ìparí òru, tí í ṣe àsìkò sààrì gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:34.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا جَعَلۡنَا عَٰلِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهَا حِجَارَةٗ مِّن سِجِّيلٖ مَّنضُودٖ
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n sì dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ sísun lé wọn lórí ní tẹ̀léǹtẹ̀lé.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
مُّسَوَّمَةً عِندَ رَبِّكَۖ وَمَا هِيَ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ بِبَعِيدٖ
(Àwọn òkúta náà) ti ní àmì (orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lára) láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Wọn kò sì jìnnà sí àwọn alábòsí.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ وَإِلَىٰ مَدۡيَنَ أَخَاهُمۡ شُعَيۡبٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مَا لَكُم مِّنۡ إِلَٰهٍ غَيۡرُهُۥۖ وَلَا تَنقُصُواْ ٱلۡمِكۡيَالَ وَٱلۡمِيزَانَۖ إِنِّيٓ أَرَىٰكُم بِخَيۡرٖ وَإِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٖ مُّحِيطٖ
(Ẹni tí A rán níṣẹ́) sí ìran Mọdyan ni arákùnrin wọn (Ànábì) Ṣua‘eb. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ má ṣe dín kóńgò àti òṣùwọ̀n kù. Mo rí yín pẹ̀lú dáadáa (tí Allāhu ṣe fún yín). Dájúdájú èmi sì ń páyà ìyà ọjọ́ kan tí ó máa yi yín po.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَٰقَوۡمِ أَوۡفُواْ ٱلۡمِكۡيَالَ وَٱلۡمِيزَانَ بِٱلۡقِسۡطِۖ وَلَا تَبۡخَسُواْ ٱلنَّاسَ أَشۡيَآءَهُمۡ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gban̄n̄dọ́gba. Ẹ má ṣe dín n̄ǹkan àwọn ènìyàn kù. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
بَقِيَّتُ ٱللَّهِ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَۚ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِحَفِيظٖ
Ohun tí Allāhu bá ṣẹ́kù fún yín (nínú halāl) lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo. Èmi kì í sì ṣe olùṣọ́ lórí yín.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ يَٰشُعَيۡبُ أَصَلَوٰتُكَ تَأۡمُرُكَ أَن نَّتۡرُكَ مَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُنَآ أَوۡ أَن نَّفۡعَلَ فِيٓ أَمۡوَٰلِنَا مَا نَشَٰٓؤُاْۖ إِنَّكَ لَأَنتَ ٱلۡحَلِيمُ ٱلرَّشِيدُ
Wọ́n wí pé: “Ṣu‘aeb, ṣé ìrun rẹ ló ń pa ọ́ láṣẹ pé kí á gbé ohun tí àwọn bàbá wa ń jọ́sìn fún jù sílẹ̀, tàbí (ìrun rẹ ló ń kọ̀ fún wa) láti ṣe ohun tí a bá fẹ́ nínú dúkìá wa? Dájúdájú ìwọ mà ni olùfaradà, olóye (lójú ara rẹ nìyẹn).”¹
1. Ẹ wòye sí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyẹn dáadáa. Wọ́n kò jẹ́pè Ànábì Ṣua‘eb - kí ọlà Allāhu máa bá a - fún ìdí méjì. Ìkíní: wọ́n ti mọ̀ pé ẹni tí ó bá gbà láti máa kírun kò gbọ́dọ̀ ṣẹbọ mọ́. Ìkejì: wọ́n ti mọ̀ pé ẹni tí ó bá gbà láti máa kírun gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún àwọn ọ̀nà owó harām àti ọ̀nà ìnáwó harām. Èyí sì ni òdodo nípa ẹ̀sìn 'Islām níwọ̀n ìgbà tí mùsùlùmí bá ti fẹ́ jèrè ẹ̀sìn rẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَرَزَقَنِي مِنۡهُ رِزۡقًا حَسَنٗاۚ وَمَآ أُرِيدُ أَنۡ أُخَالِفَكُمۡ إِلَىٰ مَآ أَنۡهَىٰكُمۡ عَنۡهُۚ إِنۡ أُرِيدُ إِلَّا ٱلۡإِصۡلَٰحَ مَا ٱسۡتَطَعۡتُۚ وَمَا تَوۡفِيقِيٓ إِلَّا بِٱللَّهِۚ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ
Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé mo wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí (Olúwa mi) sì fún mi ní arísìkí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní arísìkí tó dára (ṣé kí n̄g máa jẹ harāmu pẹ̀lú rẹ̀ ni?). Èmi kò sì fẹ́ yapa yín nípa n̄ǹkan tí mò ń kọ̀ fún yín (ìyẹn ni pé, èmi náà ń lo ohun tí mò ń sọ fún yín). Kò sí ohun tí mo fẹ́ bí kò ṣe àtúnṣe pẹ̀lú bí mo ṣe lágbára mọ. Kò sí kòǹgẹ́ ìmọ̀nà kan fún mi bí kò ṣe pẹ̀lú (ìyọ̀ǹda) Allāhu. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí sí (fún ìronúpìwàdà).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَٰقَوۡمِ لَا يَجۡرِمَنَّكُمۡ شِقَاقِيٓ أَن يُصِيبَكُم مِّثۡلُ مَآ أَصَابَ قَوۡمَ نُوحٍ أَوۡ قَوۡمَ هُودٍ أَوۡ قَوۡمَ صَٰلِحٖۚ وَمَا قَوۡمُ لُوطٖ مِّنكُم بِبَعِيدٖ
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí (bí) ẹ ṣe ń yapa mi mu yín lùgbàdì irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọ (Ànábì) Nūh tàbí ìjọ (Ànábì) Hūd tàbí ìjọ (Ànábì) Sọ̄lih. Ìjọ (Ànábì) Lūt kò sì jìnnà si yín.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِۚ إِنَّ رَبِّي رَحِيمٞ وَدُودٞ
Kí ẹ sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ ronú pìwàdà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Olúwa mi ni Aláàánú, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá).”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالُواْ يَٰشُعَيۡبُ مَا نَفۡقَهُ كَثِيرٗا مِّمَّا تَقُولُ وَإِنَّا لَنَرَىٰكَ فِينَا ضَعِيفٗاۖ وَلَوۡلَا رَهۡطُكَ لَرَجَمۡنَٰكَۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡنَا بِعَزِيزٖ
Wọ́n wí pé: “Ṣu‘aeb, a kò gbọ́ àgbọ́yé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ohun tí ò ń sọ. Dájúdájú àwa sì ń rí ọ ní ọ̀lẹ láààrin wa. Tí kò bá jẹ́ pé nítorí ti ẹbí rẹ ni, àwa ìbá ti kù ọ́ lókò pa; ìwọ kò sì lágbára kan lórí wa.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَهۡطِيٓ أَعَزُّ عَلَيۡكُم مِّنَ ٱللَّهِ وَٱتَّخَذۡتُمُوهُ وَرَآءَكُمۡ ظِهۡرِيًّاۖ إِنَّ رَبِّي بِمَا تَعۡمَلُونَ مُحِيطٞ
Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé ẹbí mi ló lágbára lójú yin ju Allāhu? Ẹ sì sọ Allāhu di Ẹni tí ẹ kọ̀yìn sí! Dájúdájú Olúwa mi ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَيَٰقَوۡمِ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنِّي عَٰمِلٞۖ سَوۡفَ تَعۡلَمُونَ مَن يَأۡتِيهِ عَذَابٞ يُخۡزِيهِ وَمَنۡ هُوَ كَٰذِبٞۖ وَٱرۡتَقِبُوٓاْ إِنِّي مَعَكُمۡ رَقِيبٞ
Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín, dájúdájú èmi náà yóò máa bá ẹ̀sìn mi lọ. Láìpẹ́ ẹ̀yin yóò mọ ẹni tí ìyà máa dé bá, tí ó máa yẹpẹrẹ rẹ̀, (ẹ̀yin yó sì mọ) ta ni òpùrọ́. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín tí mò ń retí (ìkángun ọ̀rọ̀ yín).”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَمَّا جَآءَ أَمۡرُنَا نَجَّيۡنَا شُعَيۡبٗا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ بِرَحۡمَةٖ مِّنَّا وَأَخَذَتِ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ ٱلصَّيۡحَةُ فَأَصۡبَحُواْ فِي دِيَٰرِهِمۡ جَٰثِمِينَ
Nígbà tí àṣẹ Wa dé, A gba (Ànábì) Ṣu‘aeb àti àwọn tó gbàgbọ́ pẹ̀lú rẹ̀ là pẹ̀lú ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ohùn igbe líle gbá àwọn tó ṣàbòsí mú. Wọ́n sì dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
كَأَن لَّمۡ يَغۡنَوۡاْ فِيهَآۗ أَلَا بُعۡدٗا لِّمَدۡيَنَ كَمَا بَعِدَتۡ ثَمُودُ
Àfi bí ẹni pé wọn kò gbénú ìlú náà rí.¹. Gbọ́, kí ìjìnnà sí ìkẹ́ máa jẹ́ ti ìran Mọdyan gẹ́gẹ́ bí ìran Thamūd ṣe jìnnà sí ìkẹ́.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ṣẹ̀mí fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún pẹ̀lú ayé gbẹdẹmukẹ, àmọ́ wọ́n parẹ́ láààrin ìṣẹ́jú kan.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَا وَسُلۡطَٰنٖ مُّبِينٍ
Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَٱتَّبَعُوٓاْ أَمۡرَ فِرۡعَوۡنَۖ وَمَآ أَمۡرُ فِرۡعَوۡنَ بِرَشِيدٖ
sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì tẹ̀lé àṣẹ Fir‘aon. Àṣẹ Fir‘aon kò sì jẹ́ ìmọ̀nà.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
يَقۡدُمُ قَوۡمَهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَأَوۡرَدَهُمُ ٱلنَّارَۖ وَبِئۡسَ ٱلۡوِرۡدُ ٱلۡمَوۡرُودُ
Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَأُتۡبِعُواْ فِي هَٰذِهِۦ لَعۡنَةٗ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ بِئۡسَ ٱلرِّفۡدُ ٱلۡمَرۡفُودُ
A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ẹ̀bùn náà tí wọ́n fún wọn ní tẹ̀léǹtẹ̀lé (ègún àti Iná) sì burú.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
ذَٰلِكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلۡقُرَىٰ نَقُصُّهُۥ عَلَيۡكَۖ مِنۡهَا قَآئِمٞ وَحَصِيدٞ
Ìyẹn wà nínú àwọn ìró ìlú tí À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ. Ó wà nínú àwọn ìlú náà èyí tí ó sì ń jẹ́ ìlú àti èyí tí wọ́n ti parẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡۖ فَمَآ أَغۡنَتۡ عَنۡهُمۡ ءَالِهَتُهُمُ ٱلَّتِي يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖ لَّمَّا جَآءَ أَمۡرُ رَبِّكَۖ وَمَا زَادُوهُمۡ غَيۡرَ تَتۡبِيبٖ
A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَكَذَٰلِكَ أَخۡذُ رَبِّكَ إِذَآ أَخَذَ ٱلۡقُرَىٰ وَهِيَ ظَٰلِمَةٌۚ إِنَّ أَخۡذَهُۥٓ أَلِيمٞ شَدِيدٌ
Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó le.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّمَنۡ خَافَ عَذَابَ ٱلۡأٓخِرَةِۚ ذَٰلِكَ يَوۡمٞ مَّجۡمُوعٞ لَّهُ ٱلنَّاسُ وَذَٰلِكَ يَوۡمٞ مَّشۡهُودٞ
Dájúdájú àmì (fèyíkọ́gbọ́n) wà nínú ìyẹn fún ẹnikẹ́ni tó páyà ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn ni ọjọ́ tí A óò kó àwọn ènìyàn jọ fún. Àti pé ìyẹn ni ọjọ́ tí gbogbo ẹ̀dá yóò fojú rí.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَا نُؤَخِّرُهُۥٓ إِلَّا لِأَجَلٖ مَّعۡدُودٖ
A kò sì fi falẹ̀ bí kò ṣe títí di àkókò kan tí A ti ṣírò kalẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
يَوۡمَ يَأۡتِ لَا تَكَلَّمُ نَفۡسٌ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ فَمِنۡهُمۡ شَقِيّٞ وَسَعِيدٞ
Ní ọjọ́ tó bá dé, ẹ̀mí kan kò níí sọ̀rọ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Olórí burúkú àti olórí ire yó sì wà nínú àwọn ẹ̀dá (ní ọjọ́ náà).
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَأَمَّا ٱلَّذِينَ شَقُواْ فَفِي ٱلنَّارِ لَهُمۡ فِيهَا زَفِيرٞ وَشَهِيقٌ
Ní ti àwọn tó bá ṣorí burúkú, wọn yóò wà nínú Iná. Wọn yóò máa gbin tòò, wọn yó sì máa ké tòò.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَۚ إِنَّ رَبَّكَ فَعَّالٞ لِّمَا يُرِيدُ
Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́¹. Dájúdájú Olúwa ni Aṣèyí-ó-wùú.
1. Ẹ wo àlàyé lórí àgbọ́yé “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’An‘ām; 6:128.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
۞ وَأَمَّا ٱلَّذِينَ سُعِدُواْ فَفِي ٱلۡجَنَّةِ خَٰلِدِينَ فِيهَا مَا دَامَتِ ٱلسَّمَٰوَٰتُ وَٱلۡأَرۡضُ إِلَّا مَا شَآءَ رَبُّكَۖ عَطَآءً غَيۡرَ مَجۡذُوذٖ
Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ¹, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́.² (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin.
1. Bíbẹ nínú Iná àti bíbẹ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ kò túmọ̀ sí pé òpin yóò dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra gẹ́gẹ́ bí òpin yóò ṣe dé bá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìbátan níbi àfiwé tí ń bẹ láààrin àwọn méjéèjì ni pé, ó jẹ́ ara ẹwà èdè láti ṣe àfihàn ìgbà pípẹ́ fún n̄ǹkan. Lára irúfẹ èyí náà ni, bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ọkùnrin kan sọ pé, “Èmi yóò máa jẹ́ ọkúnrin ní òdiwọ̀n ìgbà tí ilẹ̀ bá ń ṣú, tí ilẹ̀ bá ń mọ́.”
Ṣíwájú sí i, ìgbàgbọ́ àwa mùsùlùmí ahlu-sunnah wal-janmọ̄n‘ah ni pé, kò sí òpin ìgbà fún Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra ní ọ̀run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn kan lè kọ́kọ́ wọ inú Iná ṣíwájú kí Allāhu - tó ga jùlọ - tó padà mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀ pẹ̀lú àánú Rẹ̀ tàbí pẹ̀lú ìṣìpẹ̀ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Lẹ́yìn náà, ó máa ṣẹ́ ku kìkìdá àwọn ọmọ Iná Gbére, wọn yó sì ṣe gbére nínú Iná.
Ní ìdà kejì ẹ̀wẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó máa ṣe gbére nínú rẹ̀ ni. Kò sì níí sí ẹnì kan tí ó máa ti inú Ọgbà Ìdẹ̀ra bọ́ sínú Iná Gbére.
Ẹ̀rí nínú sunnah Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí á tún lè fi ní àgbọ́yé àwọn āyah wọ̀nyí dáradára ni hadīth Abu-Sa‘īd al-Kudri - kí Allāhu yọ́nú sí i -. Ó sọ pé, Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sọ pé: “Ní Ọjọ́ Àjíǹde, wọn yóò mú Ikú wá ní ìrísí àgbò funfun, tí ó ní dúdú lára. Olùpèpè kan yó sì pèpè báyìí pé, “Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra”. Àwọn ará Ọgbà Ìdẹ̀ra yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?” Wọn yóò sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.” Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Lẹ́yìn náà, olùpèpè máa pèpè báyìí pé, “Ẹ̀yin ará Iná”. Àwọn ará Iná yó sì narùn jáde síta, wọn yóò wo (ìta). Olùpèpè yó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ èyí?” Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, èyí ni Ikú.” Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì máa rí i. Nígbà náà, A óò pa Ikú. Lẹ́yìn náà, olùpèpè kan yóò sọ pé: “Ẹ̀yin ará Ọgbà Ìdẹ̀ra, gbére (ni tiyín báyìí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra), kò sì sí Ikú mọ́. Olùpèpè yóò tún sọ pé: “Ẹ̀yin ará Iná, gbére (ni tiyín báyìí nínú Iná), kò sì sí Ikú mọ́.” Al-Bukāriy; Kitāb at-Tafsīr.
2. Awẹ́ gbólóhùn yìí “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́”, àgbọ́yé rẹ̀ ni pípẹ́ tí àwọn kan yóò pẹ́ kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó kúkú ti hàn kedere pé àwọn kan yóò ṣíwájú àwọn mìíràn wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra látára bí ìrìn-àjò ẹ̀dá bá ṣe rí lórí afárá Iná.
Bákàn náà, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan yóò kọ́kọ́ wọ inú Iná ṣíwájú kí wọ́n tó wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àti pé àwọn kan wulẹ̀ ti wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra ṣíwájú Ọjọ́ Àjíǹde ẹ̀dá. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n kú sí ipò ṣẹhīd, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mú hadīth wá lórí èyí nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:154.
Nítorí náà, nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra, “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” túmọ̀ sí “àfi pípẹ́ tí Olúwa rẹ bá fẹ́ fún àwọn kan láti pẹ́ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Nígbà tí gbogbo wọn bá sì péjú pésẹ̀ tán sínú rẹ̀, wọn yó sì máa wà nínú rẹ̀ títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá pa Ikú. Kí Allāhu jẹ́ kí á tètè wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra.
Ní ìsọníṣókí, ìyàtọ̀ wà nínú àgbọ́yé “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nípa ti èrò Iná àti “àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́” nípa ti èrò Ọgbà Ìdẹ̀ra. Àmọ́ àgbọ́yé àwọn méjèèjì kò jẹmọ́ pé òpin máa dé bá Iná àti Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ọgbà gbére ni méjèèjì. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sajdah; 32:20.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّمَّا يَعۡبُدُ هَٰٓؤُلَآءِۚ مَا يَعۡبُدُونَ إِلَّا كَمَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُهُم مِّن قَبۡلُۚ وَإِنَّا لَمُوَفُّوهُمۡ نَصِيبَهُمۡ غَيۡرَ مَنقُوصٖ
Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí dín in kù.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَٱخۡتُلِفَ فِيهِۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ
A kúkú fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Wọ́n sì yapa-ẹnu nípa rẹ̀. Àti pé tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan ti ṣíwájú láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni, Àwa ìbá ti ṣèdájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa al-Ƙur’ān.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَإِنَّ كُلّٗا لَّمَّا لَيُوَفِّيَنَّهُمۡ رَبُّكَ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ إِنَّهُۥ بِمَا يَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ
Dájúdájú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni Olúwa rẹ yóò san ní ẹ̀san iṣẹ́ wọn. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَ وَمَن تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطۡغَوۡاْۚ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ
Dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí A ṣe pa ìwọ àti ẹnikẹ́ni tí ó bá rónú pìwàdà pẹ̀lú rẹ láṣẹ. Ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà. Dájúdájú Òun ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَا تَرۡكَنُوٓاْ إِلَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ فَتَمَسَّكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِنۡ أَوۡلِيَآءَ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ
Ẹ má ṣe tẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn tó ṣàbòsí nítorí kí Iná má baà fọwọ́ bà yín. Kò sì níí sí àwọn aláàbò fún yín lẹ́yìn Allāhu. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn yín lọ́wọ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ طَرَفَيِ ٱلنَّهَارِ وَزُلَفٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِۚ إِنَّ ٱلۡحَسَنَٰتِ يُذۡهِبۡنَ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ ذَٰلِكَ ذِكۡرَىٰ لِلذَّٰكِرِينَ
Kírun ní etí ọ̀sán méjèèjì¹ àti ní abala kan nínú òru². Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu).
1. Ìyẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán àti ìparí ọ̀sán. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán dúró fún lílà al-fajr fún ìrun Subh. Ìparí ọ̀sán dúró fún ìrun Ṭḥuhr àti ‘Asr.
2. Ìyẹn ni abala ìbẹ̀rẹ̀ òru. Èyí dúró fún ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱصۡبِرۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Ṣe sùúrù. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ẹ̀san àwọn olùṣe-rere ráre.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
فَلَوۡلَا كَانَ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مِن قَبۡلِكُمۡ أُوْلُواْ بَقِيَّةٖ يَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡفَسَادِ فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّنۡ أَنجَيۡنَا مِنۡهُمۡۗ وَٱتَّبَعَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَآ أُتۡرِفُواْ فِيهِ وَكَانُواْ مُجۡرِمِينَ
Kí ó sì jẹ́ pé àwọn onílàákàyè kan wà nínú àwọn ìran tó ṣíwájú yín (nínú àwọn tí A parẹ́) kí wọ́n máa kọ ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀ - àfi ènìyàn díẹ̀ lára àwọn tí A gbàlà nínú wọn. - Àwọn tó ṣàbòsí sì tẹ̀lé n̄ǹkan tí A fi ṣe gbẹdẹmukẹ fún wọn. Wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَمَا كَانَ رَبُّكَ لِيُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ بِظُلۡمٖ وَأَهۡلُهَا مُصۡلِحُونَ
Olúwa rẹ kì í pa àwọn ìlú run lọ́nà àbòsí, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ bá jẹ́ olùṣàtùn-únṣe.¹
1. Àwọn kan sọ pé, a tún lè túmọ̀ āyah yìí kan náà báyìí pé, “Allāhu kì í pa àwọn ìlú run fún wí pé wọ́n ń ṣẹbọ sí I, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará ìlú náà bá ń ṣe déédé láààrin ara wọn.” (Tọbariy)
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ لَجَعَلَ ٱلنَّاسَ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗۖ وَلَا يَزَالُونَ مُخۡتَلِفِينَ
Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, ìbá ṣe àwọn ènìyàn ní ìjọ ẹlẹ́sìn kan ṣoṣo. (Àmọ́) wọn kò níí yé yapa-ẹnu (lórí ’Islām)
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
إِلَّا مَن رَّحِمَ رَبُّكَۚ وَلِذَٰلِكَ خَلَقَهُمۡۗ وَتَمَّتۡ كَلِمَةُ رَبِّكَ لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ
àfi ẹni tí Olúwa rẹ bá kẹ́. Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn. Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ sì ti ṣẹ (báyìí pé): “Dájúdájú Èmi yóò mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kúnnú iná Jahanamọ.” ¹
1. Gbólóhùn yìí “Nítorí ìyẹn l’Ó fi ṣẹ̀dá wọn.”, ìyẹn ni pé, Allāhu - tó ga jùlọ - dá àwọn ènìyàn àti àlùjànnú kan fún dídúró ṣinṣin lórí ẹ̀sìn ’Islām àti wíwọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ó sì dá àwọn mìíràn fún yíyapa ẹ̀sìn ’Islām àti wíwọ inú Iná.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَكُلّٗا نَّقُصُّ عَلَيۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلرُّسُلِ مَا نُثَبِّتُ بِهِۦ فُؤَادَكَۚ وَجَآءَكَ فِي هَٰذِهِ ٱلۡحَقُّ وَمَوۡعِظَةٞ وَذِكۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ
Gbogbo (n̄ǹkan tí) À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ nínú àwọn ìró àwọn Òjísẹ́ ni èyí tí A fi ń fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. Òdodo tún dé bá ọ nínú (sūrah) yìí. Wáàsí àti ìrántí tún ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَقُل لِّلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنَّا عَٰمِلُونَ
Kí o sì sọ fún àwọn tí kò gbàgbọ́ pé: “Ẹ máa ṣe bí ẹ ti fẹ́ nínú ẹ̀sìn yín. Dájúdájú àwa náà yóò máa bá ẹ̀sìn wa lọ.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَٱنتَظِرُوٓاْ إِنَّا مُنتَظِرُونَ
Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí.”
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
وَلِلَّهِ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَإِلَيۡهِ يُرۡجَعُ ٱلۡأَمۡرُ كُلُّهُۥ فَٱعۡبُدۡهُ وَتَوَكَّلۡ عَلَيۡهِۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ
Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí pátápátá. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí o sì gbáralé E. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbéra nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
 
مەنالار تەرجىمىسى سۈرە: سۈرە ھۇد
سۈرە مۇندەرىجىسى بەت نومۇرى
 
قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

قۇرئان كەرىمنىڭ يورۇباچە تەرجىمىسىنى شەيىخ ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل ئەيكۇينى تەرجىمە قىلغان، ھىجىريە 1432-يىلى بېسىلغان.

تاقاش