قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ * - ترجمے کی لسٹ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

معانی کا ترجمہ سورت: سورۂ شوریٰ   آیت:

Suuratu Shuuraa

حمٓ
Hā mīm.
عربی تفاسیر:
عٓسٓقٓ
‘Aēn sīn ƙọ̄f. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
عربی تفاسیر:
كَذَٰلِكَ يُوحِيٓ إِلَيۡكَ وَإِلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكَ ٱللَّهُ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ.¹
"1. È é ti ṣe tí Allāhu lẹ́yìn tí Ó sọ pé “Báyẹn ni Allāhu, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n ṣe ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí ìwọ àti àwọn tó ṣíwájú rẹ.” kò fi kún un pé, “àti àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ”?
Ìdí ni pé, Allāhu ti fi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe òpin àwọn arímìísígbà “kātamu-nnabiyyīn”. Ẹ wo sūrah al-’Ahzāb; 33:40.
عربی تفاسیر:
لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ
TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ó ga, Ó tóbi.
عربی تفاسیر:
تَكَادُ ٱلسَّمَٰوَٰتُ يَتَفَطَّرۡنَ مِن فَوۡقِهِنَّۚ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ يُسَبِّحُونَ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَيَسۡتَغۡفِرُونَ لِمَن فِي ٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ
Sánmọ̀ fẹ́ẹ̀ fàya láti òkè wọn (nípa títóbi Allāhu). Àwọn mọlāika sì ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa wọn. Wọ́n sì ńtọrọ àforíjìn fún àwọn tó wà lórí ilẹ̀. Gbọ́, dájúdájú Allāhu, Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
عربی تفاسیر:
وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ ٱللَّهُ حَفِيظٌ عَلَيۡهِمۡ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٖ
Àwọn tó mú àwọn alátìlẹ́yìn kan lẹ́yìn Rẹ̀, Allāhu sì ni Aláàbò lórí wọn. Ìwọ sì kọ́ ni olùṣọ́ lórí wọn.
عربی تفاسیر:
وَكَذَٰلِكَ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا لِّتُنذِرَ أُمَّ ٱلۡقُرَىٰ وَمَنۡ حَوۡلَهَا وَتُنذِرَ يَوۡمَ ٱلۡجَمۡعِ لَا رَيۡبَ فِيهِۚ فَرِيقٞ فِي ٱلۡجَنَّةِ وَفَرِيقٞ فِي ٱلسَّعِيرِ
Báyẹn ni A ṣe fi al-Ƙur’ān ránṣẹ́ sí ọ ní èdè Lárúbáwá nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù), àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ nípa Ọjọ́ Àkójọ, tí kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìjọ kan yóò wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ìjọ kan yó sì wà nínú Iná tó ń jò.
عربی تفاسیر:
وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَعَلَهُمۡ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ وَلَٰكِن يُدۡخِلُ مَن يَشَآءُ فِي رَحۡمَتِهِۦۚ وَٱلظَّٰلِمُونَ مَا لَهُم مِّن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٍ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá ṣe wọ́n ní ìjọ ẹlẹ́sìn ẹyọ kan. Ṣùgbọ́n Ó ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Àwọn alábòsí, kò sì níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún wọn.
عربی تفاسیر:
أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَۖ فَٱللَّهُ هُوَ ٱلۡوَلِيُّ وَهُوَ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Ṣé wọ́n mú àwọn aláàbò kan lẹ́yìn Rẹ̀ ni? Allāhu, Òun sì ni Aláàbò. Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
عربی تفاسیر:
وَمَا ٱخۡتَلَفۡتُمۡ فِيهِ مِن شَيۡءٖ فَحُكۡمُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبِّي عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُ وَإِلَيۡهِ أُنِيبُ
Ohunkóhun tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa mi. Òun ni mo gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni mo máa ṣẹ́rí padà sí (ní ti ìronúpìwàdà). ¹
1. Àgbọ́yé méjì ni gbogbo tafsīr mú wá lórí gbólóhùn yìí “Ohunkóhun tí ẹ bá yapa-ẹnu lórí rẹ̀, ìdájọ́ rẹ̀ di ọ̀dọ̀ Allāhu.” Ìkíní ni pé, lẹ́yìn tí Allāhu ti mú ìdájọ́ wá pé ’Islām nìkan ṣoṣo ni ẹ̀sìn àṣelà, àmọ́ tí àwọn aláìgbàgbọ́ yapa rẹ̀, kí àwa mùsùlùmí fi wọ́n sílẹ̀ títí di Ọjọ́ àjíǹde tí Allāhu máa fi ìdájọ́ Rẹ̀ mú ìlèrí ìyà Rẹ̀ ṣẹ lórí wọn. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí, āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah tó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú àwọn āyah tó ń pàṣẹ ìgbógun ti àwọn aláìgbàgbọ́ tó ń gbógun ti àwa mùsùlùmí àti āyah tó ń pàṣẹ gbígba owó-orí lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ tí kò gbógun ti àwa mùsùlùmí.
Ní àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn, āyah yìí ń pàrọwà sùúrù àti ìfaradà fún èyíkéyìí àwùjọ mùsùlùmí tó wà nípò ọ̀lẹ ní orílẹ̀ èdè tí àwọn kèfèrí bá ti ń lo òfin kèfèrí lé wa lórí. Sùúrù náà máa wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ tí ọwọ́ àwa mùsùlùmí yóò ba èkù-idà, tí agbára sì máa jẹ́ ti ’Islām.
Àgbọ́yé kejì ni pé, kí á ṣẹ́rí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ìyapa-ẹnu bá wáyé lórí wọn sínú al-Ƙur’ān, ọ̀rọ̀ Allāhu àti ìdájọ́ Rẹ̀. Pẹ̀lú àgbọ́yé yìí, āyah yìí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn āyah tó ń pa wá láṣẹ láti fi al-Ƙur’an àti sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - yanjú àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu, gẹ́gẹ́ bí sūrah an-Nisā’; 4:59.
Àṣìgbọ́ l’ó jẹ́ nígbà náà láti lérò pé āyah náà ń pa wá láṣẹ láti má ṣe mú ìdájọ́ wá lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìyapa-ẹnu tí al-Ƙur’ān ti yanjú. Èyí sì máa mú ìtúmọ̀ wíwo ìbàjẹ́ níran lọ́wọ́. Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ ìbàjẹ́ oníran-ànran àti àdádáálẹ̀ ẹ̀sìn nínú ’Islam sì máa gbòde kanrí láààrin àwọn ẹ̀dá. Àṣẹ wíwo ìbàjẹ́ níran títí dọjọ́ àjíǹde kò sì ti ọ̀dọ̀ Allāhu wá nínú tírà sánmọ̀ kan kan.
عربی تفاسیر:
فَاطِرُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَمِنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ أَزۡوَٰجٗا يَذۡرَؤُكُمۡ فِيهِۚ لَيۡسَ كَمِثۡلِهِۦ شَيۡءٞۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ
(Òun ni) Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ṣẹ̀dá àwọn obìnrin fún yín láti ara yín. Ó tún ṣẹ̀dá àwọn abo ẹran-ọ̀sìn láti ara àwọn akọ ẹran-ọ̀sìn. Ó ń mu yín pọ̀ sí i (nípa ìṣẹ̀dá yín ní akọ-abo). Kò sí kiní kan bí irú Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Olùríran.
عربی تفاسیر:
لَهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
TiRẹ̀ ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ilé ọ̀rọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń tẹ́ arísìkí sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ (fún ẹlòmíìràn). Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
عربی تفاسیر:
۞ شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحٗا وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ وَمَا وَصَّيۡنَا بِهِۦٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓۖ أَنۡ أَقِيمُواْ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُواْ فِيهِۚ كَبُرَ عَلَى ٱلۡمُشۡرِكِينَ مَا تَدۡعُوهُمۡ إِلَيۡهِۚ ٱللَّهُ يَجۡتَبِيٓ إِلَيۡهِ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِيٓ إِلَيۡهِ مَن يُنِيبُ
(Allāhu) ṣe ní òfin fún yín nínú ẹ̀sìn (’Islām) ohun tí Ó pa ní àṣẹ fún (Ànábì) Nūh àti èyí tí Ó fi ránṣẹ́ sí ọ, àti ohun tí A pa láṣẹ fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) ‘Īsā pé, kí ẹ gbé ẹ̀sìn náà dúró. Kí ẹ sì má ṣe pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú rẹ̀. Wàhálà l’ó jẹ́ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ nípa n̄ǹkan tí ò ń pè wọ́n sí (níbi mímú Allāhu ní ọ̀kan ṣoṣo). Allāhu l’Ó ń ṣẹ̀ṣà ẹni tí Ó bá fẹ́ sínú ẹ̀sìn Rẹ̀ (tí ò ń pè wọ́n sí). Ó sì ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó bá ń ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (nípasẹ̀ ìronúpìwàdà).
عربی تفاسیر:
وَمَا تَفَرَّقُوٓاْ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى لَّقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُورِثُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ
(Àwọn ọ̀ṣẹbọ) kò sì pín sí ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àfi lẹ́yìn tí ìmọ̀ (’Islām) dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tí ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (pé Òun yóò lọ́ wọn lára) títí di gbèdéke àkókò kan ni, Wọn ìbá ti dájọ́ láààrin wọn. Dájúdájú àwọn tí A jogún Tírà fún lẹ́yìn wọn sì tún wà nínú iyèméjì tó gbópọn nípa ’Islām.
عربی تفاسیر:
فَلِذَٰلِكَ فَٱدۡعُۖ وَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَۖ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡۖ وَقُلۡ ءَامَنتُ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِن كِتَٰبٖۖ وَأُمِرۡتُ لِأَعۡدِلَ بَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ رَبُّنَا وَرَبُّكُمۡۖ لَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡۖ لَا حُجَّةَ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَاۖ وَإِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ
Nítorí ìyẹn, pèpè (sínú ’Islām), kí o sì dúró ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí Wọ́n ṣe pa ọ́ lásẹ. Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn. Kí o sì sọ pé: “Mo gbàgbọ́ nínú èyíkéyìí Tírà tí Allāhu sọ̀kalẹ̀. Wọ́n sì pa mí láṣẹ pé kí n̄g ṣe déédé láààrin yín. Allāhu ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Kò sí ìjà láààrin àwa àti ẹ̀yin.¹ Allāhu l’Ó sì máa kó wa jọ papọ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.”
1. Ìyẹn ṣíwájú àwọn āyah tó ń páṣẹ ogun ẹ̀sìn jíjà.
عربی تفاسیر:
وَٱلَّذِينَ يُحَآجُّونَ فِي ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا ٱسۡتُجِيبَ لَهُۥ حُجَّتُهُمۡ دَاحِضَةٌ عِندَ رَبِّهِمۡ وَعَلَيۡهِمۡ غَضَبٞ وَلَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٌ
Àwọn tó ń bá (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) jà nípa (ẹ̀sìn) Allāhu lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ènìyàn ti gbà fún un, ẹ̀rí wọn máa wó lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbínú ń bẹ lórí wọn. Ìyà líle sì wà fún wọn.
عربی تفاسیر:
ٱللَّهُ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ وَٱلۡمِيزَانَۗ وَمَا يُدۡرِيكَ لَعَلَّ ٱلسَّاعَةَ قَرِيبٞ
Allāhu ni Ẹni tí Ó sọ Tírà (al-Ƙur’ān) àti (òfin) òṣùwọ̀n (déédé) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo.¹ Àti pé kí l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí Àkókò náà ti súnmọ́!
1. Ẹ wo sūrah ar-Rahmọ̄n; 55: 7 - 9.
عربی تفاسیر:
يَسۡتَعۡجِلُ بِهَا ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِهَاۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مُشۡفِقُونَ مِنۡهَا وَيَعۡلَمُونَ أَنَّهَا ٱلۡحَقُّۗ أَلَآ إِنَّ ٱلَّذِينَ يُمَارُونَ فِي ٱلسَّاعَةِ لَفِي ضَلَٰلِۭ بَعِيدٍ
Àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú rẹ̀ ń wá a pẹ̀lú ìkánjú. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo ń páyà rẹ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni. Kíyè sí i, dájúdájú àwọn tó ń jiyàn nípa Àkókò náà ti wà nínú ìṣìnà tó jìnnà.
عربی تفاسیر:
ٱللَّهُ لَطِيفُۢ بِعِبَادِهِۦ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُۖ وَهُوَ ٱلۡقَوِيُّ ٱلۡعَزِيزُ
Allāhu ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe arísìkí fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Òun sì ni Alágbára, Olùborí.
عربی تفاسیر:
مَن كَانَ يُرِيدُ حَرۡثَ ٱلۡأٓخِرَةِ نَزِدۡ لَهُۥ فِي حَرۡثِهِۦۖ وَمَن كَانَ يُرِيدُ حَرۡثَ ٱلدُّنۡيَا نُؤۡتِهِۦ مِنۡهَا وَمَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِن نَّصِيبٍ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ọ̀run, A máa ṣe àlékún sí èso rẹ̀ fún un. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbèrò láti gba èso (iṣẹ́ rẹ̀ ní) ayé, A máa fún un nínú rẹ̀. Kò sì níí sí ìpín kan kan fún un mọ́ ní ọ̀run.
عربی تفاسیر:
أَمۡ لَهُمۡ شُرَكَٰٓؤُاْ شَرَعُواْ لَهُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا لَمۡ يَأۡذَنۢ بِهِ ٱللَّهُۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةُ ٱلۡفَصۡلِ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۗ وَإِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Tàbí wọ́n ní àwọn òrìṣà kan tó ṣòfin (ìbọ̀rìṣà) fún wọn nínú ẹ̀sìn, èyí tí Allāhu kò yọ̀ǹda rẹ̀? Tí kò bá jẹ́ ti ọ̀rọ̀ àsọyán (pé A kò níí kánjú jẹ wọ́n ní ìyà), Àwa ìbá ti mú ìdájọ́ wá láààrin wọn. Dájúdájú àwọn alábòsí, ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.
عربی تفاسیر:
تَرَى ٱلظَّٰلِمِينَ مُشۡفِقِينَ مِمَّا كَسَبُواْ وَهُوَ وَاقِعُۢ بِهِمۡۗ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ فِي رَوۡضَاتِ ٱلۡجَنَّاتِۖ لَهُم مَّا يَشَآءُونَ عِندَ رَبِّهِمۡۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَضۡلُ ٱلۡكَبِيرُ
O máa rí àwọn alábòsí tí wọn yóò máa páyà nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, tí ó sì máa kò lé wọn lórí. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere máa wà ní àwọn àbàtà Ọgbà Ìdẹ̀ra,¹. Ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn, òhun ni oore àjùlọ tó tóbi.
1. “Raodọh” ni àyè tí ó kún fún omi àti koríko, àyè tó lọ́ràá lára jùlọ nínú ọgbà oko.
عربی تفاسیر:
ذَٰلِكَ ٱلَّذِي يُبَشِّرُ ٱللَّهُ عِبَادَهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِۗ قُل لَّآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًا إِلَّا ٱلۡمَوَدَّةَ فِي ٱلۡقُرۡبَىٰۗ وَمَن يَقۡتَرِفۡ حَسَنَةٗ نَّزِدۡ لَهُۥ فِيهَا حُسۡنًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ شَكُورٌ
Ìyẹn ni èyí tí Allāhu fi ń ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Sọ pé: “Èmi kò bèèrè owó-ọ̀yà lọ́wọ́ yín lórí rẹ̀ bí kò ṣe ìfẹ́ ẹbí.”¹ Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe rere kan, A máa ṣe àlékún rere fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Ọlọ́pẹ́.²
1. Ìyẹn ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń sọ fún àwọn ẹbí rẹ̀ pé, ẹ má ṣe tìtorí pé mò ń pèyín sínú ẹ̀sìn ’Islām kí ẹ wá máa fi ìnira kan èmi àti àwọn ará ilé mi. Èmi kò kúkú bèèrè owó-ọ̀yà kan kan lọ́wọ́ yín. Ẹ sì mọ̀ pé ẹbí ni wá. Ẹbí sì gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ ẹbí rẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe fi fífi ìnira kan ará ilé mi ṣe ẹ̀san fún mi.
2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:158.
عربی تفاسیر:
أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗاۖ فَإِن يَشَإِ ٱللَّهُ يَخۡتِمۡ عَلَىٰ قَلۡبِكَۗ وَيَمۡحُ ٱللَّهُ ٱلۡبَٰطِلَ وَيُحِقُّ ٱلۡحَقَّ بِكَلِمَٰتِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ
Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni?” Nítorí náà, tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa fi èdídí dí ọkàn rẹ pa. Àti pé Allāhu yóò pa irọ́ rẹ́. Ó sì máa fi òdodo rinlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
عربی تفاسیر:
وَهُوَ ٱلَّذِي يَقۡبَلُ ٱلتَّوۡبَةَ عَنۡ عِبَادِهِۦ وَيَعۡفُواْ عَنِ ٱلسَّيِّـَٔاتِ وَيَعۡلَمُ مَا تَفۡعَلُونَ
Òun ni Ẹni tó ń gba ìronúpìwàdà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó ń ṣe àmójúkúrò níbi àwọn àṣìṣe. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
عربی تفاسیر:
وَيَسۡتَجِيبُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَيَزِيدُهُم مِّن فَضۡلِهِۦۚ وَٱلۡكَٰفِرُونَ لَهُمۡ عَذَابٞ شَدِيدٞ
Ó ń gba àdúà àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Ó sì ń ṣe àlékún fún wọn nínú ọlá Rẹ̀. Àwọn aláìgbàgbọ́, ìyà líle sì wà fún wọn.
عربی تفاسیر:
۞ وَلَوۡ بَسَطَ ٱللَّهُ ٱلرِّزۡقَ لِعِبَادِهِۦ لَبَغَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَٰكِن يُنَزِّلُ بِقَدَرٖ مَّا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرُۢ بَصِيرٞ
Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu tẹ́ arísìkí sílẹ̀ rẹgẹdẹ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀ ni, wọn ìbá tayọ ẹnu-ààlà lórí ilẹ̀. Ṣùgbọ́n Ó ń sọ (arísìkí) tí Ó bá fẹ́ kalẹ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Dájúdájú Òun ni Alámọ̀tán, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.
عربی تفاسیر:
وَهُوَ ٱلَّذِي يُنَزِّلُ ٱلۡغَيۡثَ مِنۢ بَعۡدِ مَا قَنَطُواْ وَيَنشُرُ رَحۡمَتَهُۥۚ وَهُوَ ٱلۡوَلِيُّ ٱلۡحَمِيدُ
Òun sì ni Ẹni tó ń sọ omi òjò kalẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti sọ̀rètí nù. Ó sì ń fọ́n ìkẹ́ Rẹ̀ ká. Òun sì ni Aláàbò, Ẹlẹ́yìn.
عربی تفاسیر:
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِۦ خَلۡقُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَثَّ فِيهِمَا مِن دَآبَّةٖۚ وَهُوَ عَلَىٰ جَمۡعِهِمۡ إِذَا يَشَآءُ قَدِيرٞ
Àti pé nínú àmì Rẹ̀ ni ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti n̄ǹkan tí Ó fọ́nká sáààrin méjèèjì nínú àwọn n̄ǹkan abẹ̀mí. Òun sì ni Alágbára lórí ìkójọ wọn nígbà tí Ó bá fẹ́.
عربی تفاسیر:
وَمَآ أَصَٰبَكُم مِّن مُّصِيبَةٖ فَبِمَا كَسَبَتۡ أَيۡدِيكُمۡ وَيَعۡفُواْ عَن كَثِيرٖ
Ohunkóhun tí ó bá kàn yín nínú àdánwò, ohun tí ẹ fi ọwọ́ ara yín fà ni.¹ Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nisā’; 4:79.
عربی تفاسیر:
وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ
Ẹ̀yin kò lè mórí bọ́ (mọ́ Allāhu lọ́wọ́) lórí ilẹ̀. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.
عربی تفاسیر:
وَمِنۡ ءَايَٰتِهِ ٱلۡجَوَارِ فِي ٱلۡبَحۡرِ كَٱلۡأَعۡلَٰمِ
Ó tún wà nínú àwọn àmì Rẹ̀, àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn lójú omi (tó dà) bí àwọn òkè àpáta gíga.
عربی تفاسیر:
إِن يَشَأۡ يُسۡكِنِ ٱلرِّيحَ فَيَظۡلَلۡنَ رَوَاكِدَ عَلَىٰ ظَهۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٍ
Tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa dá atẹ́gùn náà dúró, (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) sì máa dúró pa sójú kan náà lórí omi. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
عربی تفاسیر:
أَوۡ يُوبِقۡهُنَّ بِمَا كَسَبُواْ وَيَعۡفُ عَن كَثِيرٖ
Tàbí kí Ó kó ìparun bá (àwọn ọkọ̀ ojú-omi náà) nítorí ohun tí àwọn èrò ọkọ̀ ojú-omi ṣe (níṣẹ́ aburú). Ó sì ń ṣàmójúkúrò níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.
عربی تفاسیر:
وَيَعۡلَمَ ٱلَّذِينَ يُجَٰدِلُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٖ
Àwọn tó ń (fi irọ́) ja àwọn āyah Wa ní iyàn sì máa mọ̀ pé kò sí ibùsásí kan fún wọn.
عربی تفاسیر:
فَمَآ أُوتِيتُم مِّن شَيۡءٖ فَمَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَمَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
Nítorí náà, ohunkóhun tí A bá fún yín, ìgbádùn ayé nìkan ni. Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu lóore jùlọ, ó sì máa ṣẹ́kù títí láéláé fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ń gbáralé Olúwa wọn.
عربی تفاسیر:
وَٱلَّذِينَ يَجۡتَنِبُونَ كَبَٰٓئِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡفَوَٰحِشَ وَإِذَا مَا غَضِبُواْ هُمۡ يَغۡفِرُونَ
(Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tó ń jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńlá àti àwọn ìwà ìbàjẹ́, àti (àwọn tó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá bínú, wọn yóò ṣàforíjìn.
عربی تفاسیر:
وَٱلَّذِينَ ٱسۡتَجَابُواْ لِرَبِّهِمۡ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَأَمۡرُهُمۡ شُورَىٰ بَيۡنَهُمۡ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ
(Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tó jẹ́pè ti Olúwa wọn, tí wọ́n ń kírun, ọ̀rọ̀ ara wọn sì jẹ́ ìjíròrò láààrin ara wọn, wọ́n tún ń ná nínú arísìkí tí A pèsè fún wọn.
عربی تفاسیر:
وَٱلَّذِينَ إِذَآ أَصَابَهُمُ ٱلۡبَغۡيُ هُمۡ يَنتَصِرُونَ
(Ohun tí ó wà lọ́dọ̀ Allāhu tún wà fún) àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe àbòsí sí wọn, wọn yóò gbẹ̀san wọn padà.
عربی تفاسیر:
وَجَزَٰٓؤُاْ سَيِّئَةٖ سَيِّئَةٞ مِّثۡلُهَاۖ فَمَنۡ عَفَا وَأَصۡلَحَ فَأَجۡرُهُۥ عَلَى ٱللَّهِۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلظَّٰلِمِينَ
Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀.¹ Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàmójúkúrò, tí ó tún ṣàtúnṣe, ẹ̀san rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn alábòsí.
1. Kíyè sí i, gbólóhùn yìí “Ẹ̀san aburú sì ni aburú bí irú rẹ̀.” kò tako sūrah Fussilat; 41:31. Ìdí ni pé, gbígba ẹ̀san lára alábòsí tàbí gbígba ààrọ̀ kò sọ pé mùsùlùmí kò ní ẹ̀mí àforíjìn, àmọ́ ó lè má nìí agbára láti ṣàmójú kúrò fún alábòsí náà. Bí àpẹ̀ẹrẹ, kí ẹnì kan ba dúkìá mùsùlùmí jẹ́, yálà ó ṣèèsì tàbí ó mọ̀ọ́mọ̀, mùsùlùmí lè gbẹ̀san ààrọ̀ níwọ̀n ìgbà tí agbára rẹ̀ kò bá gbé àtúnṣe rẹ̀ tàbí ìràpadà rẹ̀. Kò sì níí gbà ju ohun tí wọ́n bàjẹ́.
عربی تفاسیر:
وَلَمَنِ ٱنتَصَرَ بَعۡدَ ظُلۡمِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ مَا عَلَيۡهِم مِّن سَبِيلٍ
Dájúdájú ẹni tí ó bá sì gbẹ̀san lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àbòsí sí i, àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ṣàbòsí sí), kò sí ìbáwí kan kan fún wọn.
عربی تفاسیر:
إِنَّمَا ٱلسَّبِيلُ عَلَى ٱلَّذِينَ يَظۡلِمُونَ ٱلنَّاسَ وَيَبۡغُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۚ أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Àwọn tí ìbáwí wà fún ni àwọn tó ń ṣàbòsí sí àwọn ènìyàn, tí wọ́n tún ń tayọ ẹnu-ààlà lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro wà fún.
عربی تفاسیر:
وَلَمَن صَبَرَ وَغَفَرَ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمِنۡ عَزۡمِ ٱلۡأُمُورِ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe sùúrù, tí ó tún ṣàforíjìn, dájúdájú ìyẹn wà nínú àwọn ìpinnu ọ̀rọ̀.
عربی تفاسیر:
وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن وَلِيّٖ مِّنۢ بَعۡدِهِۦۗ وَتَرَى ٱلظَّٰلِمِينَ لَمَّا رَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَ يَقُولُونَ هَلۡ إِلَىٰ مَرَدّٖ مِّن سَبِيلٖ
Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò tún sí aláàbò kan fún un mọ́ lẹ́yìn Rẹ̀. O sì máa rí àwọn alábòsí nígbà tí wọ́n bá rí Iná, wọn yóò wí pé: “Ǹjẹ́ ọ̀nà kan kan wà tí a lè fi padà sí ilé ayé?”
عربی تفاسیر:
وَتَرَىٰهُمۡ يُعۡرَضُونَ عَلَيۡهَا خَٰشِعِينَ مِنَ ٱلذُّلِّ يَنظُرُونَ مِن طَرۡفٍ خَفِيّٖۗ وَقَالَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ ٱلۡخَٰسِرِينَ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَأَهۡلِيهِمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ أَلَآ إِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ فِي عَذَابٖ مُّقِيمٖ
O sì máa rí wọn tí A máa kó wọn lọ sínú Iná; wọn yóò palọ́lọ́ láti ara ìyẹpẹrẹ, wọn yó si máa wò fín-ín-fín. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì máa sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni òfò ni àwọn tó ṣe ẹ̀mí ara wọn àti ara ilé wọn ní òfò ní Ọjọ́ Àjíǹde.” Kíyè sí i, dájúdájú àwọn alábòsí yóò wà nínú ìyà gbére.
عربی تفاسیر:
وَمَا كَانَ لَهُم مِّنۡ أَوۡلِيَآءَ يَنصُرُونَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِۗ وَمَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن سَبِيلٍ
Kò sì níí sí aláàbò kan fún wọn tí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn Allāhu. Àti pé ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà, kò níí sí ọ̀nà kan kan fún un.
عربی تفاسیر:
ٱسۡتَجِيبُواْ لِرَبِّكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا مَرَدَّ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِۚ مَا لَكُم مِّن مَّلۡجَإٖ يَوۡمَئِذٖ وَمَا لَكُم مِّن نَّكِيرٖ
Ẹ jẹ́pè Olúwa yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tí kò ṣe é dá padà tó dé láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Kò sí ibùsásí kan fún yín ní ọjọ́ yẹn. Kò sì níí sí ẹni tí ó máa bá yín kọ ìyà náà.
عربی تفاسیر:
فَإِنۡ أَعۡرَضُواْ فَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ حَفِيظًاۖ إِنۡ عَلَيۡكَ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُۗ وَإِنَّآ إِذَآ أَذَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِنَّا رَحۡمَةٗ فَرِحَ بِهَاۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةُۢ بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡ فَإِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ كَفُورٞ
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbúnrí, A kò rán ọ pé kí o jẹ́ olùṣọ́ fún wọn. Kò sí kiní kan tó di dandan fún ọ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn). Àti pé dájúdájú nígbà tí A bá fún ènìyàn ní ìkẹ́ kan tọ́ wò láti ọ̀dọ̀ Wa, ó máa dunnú sí i. Tí aburú kan bá sì kàn án nípasẹ̀ ohun tí ọwọ́ wọn tì ṣíwájú (ní iṣẹ́ aburú), dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore.
عربی تفاسیر:
لِّلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ يَهَبُ لِمَن يَشَآءُ إِنَٰثٗا وَيَهَبُ لِمَن يَشَآءُ ٱلذُّكُورَ
Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣẹ̀dá ohun tí Ó bá fẹ́. Ó ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́rẹ ọmọbìnrin. Ó sì ń ta ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́rẹ ọmọkùnrin.
عربی تفاسیر:
أَوۡ يُزَوِّجُهُمۡ ذُكۡرَانٗا وَإِنَٰثٗاۖ وَيَجۡعَلُ مَن يَشَآءُ عَقِيمًاۚ إِنَّهُۥ عَلِيمٞ قَدِيرٞ
Tàbí kí Ó ṣe wọ́n ní oríṣi méjì; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ó sì ń ṣe ẹni tí Ó bá fẹ́ ní àgàn. Dájúdájú Òun ni Onímọ̀, Alágbára.
عربی تفاسیر:
۞ وَمَا كَانَ لِبَشَرٍ أَن يُكَلِّمَهُ ٱللَّهُ إِلَّا وَحۡيًا أَوۡ مِن وَرَآيِٕ حِجَابٍ أَوۡ يُرۡسِلَ رَسُولٗا فَيُوحِيَ بِإِذۡنِهِۦ مَا يَشَآءُۚ إِنَّهُۥ عَلِيٌّ حَكِيمٞ
Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún abara kan pé kí Allāhu bá a sọ̀rọ̀ àfi kí (ọ̀rọ̀ náà) jẹ́ ìmísí (ìṣípayá mímọ́), tàbí kí ó jẹ́ lẹ́yìn gàgá, tàbí kí Ó rán Òjíṣẹ́ kan (tí ó jẹ́ mọlāika) sí i, ó sì máa fi ìmísí jíṣẹ́ fún (abara náà) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda (Allāhu). Dájúdájú Ó ga. Ọlọ́gbọ́n sì ni.
عربی تفاسیر:
وَكَذَٰلِكَ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ رُوحٗا مِّنۡ أَمۡرِنَاۚ مَا كُنتَ تَدۡرِي مَا ٱلۡكِتَٰبُ وَلَا ٱلۡإِيمَٰنُ وَلَٰكِن جَعَلۡنَٰهُ نُورٗا نَّهۡدِي بِهِۦ مَن نَّشَآءُ مِنۡ عِبَادِنَاۚ وَإِنَّكَ لَتَهۡدِيٓ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Báyẹn sì ni A ṣe fi ìmísí ránṣẹ́ sí ọ nínú àṣẹ Wa. Ìwọ kò mọ kí ni Tírà àti ìgbàgbọ́ òdodo tẹ́lẹ̀ (ṣíwájú ìmísí náà),¹ ṣùgbọ́n A ṣe ìmísí náà ní ìmọ́lẹ̀ kan tí À ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹni tí A bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Wa. Dájúdájú ìwọ ń pèpè sí ọ̀nà tààrà (’Islām).²
1. Āyah yìí ń fi kókó pàtàkì kan rinlẹ̀ nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí ayé Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - pé, ṣíwájú kí ìmísí mímọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀kalẹ̀ fún un kò sí nínú ẹni tó nímọ̀ sí tírà sánmọ̀ kan kan, kò sì dá ìgbàgbọ́ òdodo mọ. Allāhu - tó ga jùlọ - tún fi èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah ad-Duhā; 93:7. Àmọ́ níkété tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bẹ̀rẹ̀ sí gba ìmísí mímọ́, Allāhu fi ìmọ̀ tírà al-Ƙur’ān àti ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ ọ́n. Ó sì di olùpèpè sínú ìmọ̀nà. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun ni ìṣẹ̀mí ayé wọn rí bí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ti ṣe rí àfi ẹni tí bàbá rẹ̀ bá jẹ́ Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun.
Àmọ́ ṣá, kò sí abọ̀rìṣà kan tí Allāhu sọ di Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ Rẹ̀ rí. Ẹni tí Allāhu máa sọ di Ànábì tàbí Òjíṣẹ́ lè má tí ì mọ tírà nígbà tí Ọlọ́hun kò ì tí ì fún un, ó sì lè má tí ì dá ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀, nígbà tí Ọlọ́hun kò tí ì ròyìn Ara Rẹ̀ fún un, àmọ́ kò níí sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ tàbí àwọn òbìlẹ̀jẹ́ ènìyàn. Kódà, láti kékeré wọn ni Allāhu - Ọba mímọ́ - ti máa ń jogún òye fún wọn pé, “irọ́ ni òrìṣà” títí àsìkò ìmísí wọn yóò fi dé bá wọn.
Síwájú sí i, tí ẹnì kan bá sì sọ pé, iṣẹ́ wiridi ni Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - máa ń ṣe nínú ọ̀gbun Hirā ṣíwájú kí ó tó di Ànábì Ọlọ́hun, irọ́ l’ó fi pa. Ìdí ni pé, ẹnì kan kì í ṣe wiridi láì gbọwọ́, ta ni ó fún Ànábì lọ́wọ́ wiridi? Kò sí.
Bákan náà, kò sí ojú ọ̀nà wiridi tí kò lórúkọ, kí ni orúkọ tọrikọ sūfī tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ṣe? Kò sí.
Èyí tó wá kó ọ̀rọ̀ tán nílẹ̀ ni pé, títẹ̀lé Muhammad ọmọ ‘Abdullah - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, kò di ẹ̀sìn àfi láti àsìkò tí ó di Ànábì àti Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun. Kò sì lọ sínú ọ̀gbun Hirā mọ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mọlāika Jibrīl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti fún un ní ìmísí àkọ́kọ́. Nítorí náà, Ànábì kì í ṣe sūfī, kò sì ṣe wiridi sūfī rí.
2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Ƙọsọs; 28:56.
عربی تفاسیر:
صِرَٰطِ ٱللَّهِ ٱلَّذِي لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِلَى ٱللَّهِ تَصِيرُ ٱلۡأُمُورُ
Ọ̀nà Allāhu, Ẹni tí ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń jẹ́ tiRẹ̀. Gbọ́! Ọ̀dọ̀ Allāhu ni àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá yóò padà sí.
عربی تفاسیر:
 
معانی کا ترجمہ سورت: سورۂ شوریٰ
سورتوں کی لسٹ صفحہ نمبر
 
قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ترجمے کی لسٹ

قرآن کریم کے معانی کا یوروبا ترجمہ۔ ترجمہ شیخ ابو رحیمہ میکائیل ایکویینی نے کیا ہے۔ طباعت سنہ 1432ھ۔

بند کریں