قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ * - ترجمے کی لسٹ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

معانی کا ترجمہ سورت: سورۂ مجادلہ   آیت:

Suuratul-Mujaadalah

قَدۡ سَمِعَ ٱللَّهُ قَوۡلَ ٱلَّتِي تُجَٰدِلُكَ فِي زَوۡجِهَا وَتَشۡتَكِيٓ إِلَى ٱللَّهِ وَٱللَّهُ يَسۡمَعُ تَحَاوُرَكُمَآۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٌ
Dájúdájú Allāhu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ (obìnrin) tó ń bá ọ ṣe àríyànjiyàn nípa ọkọ rẹ̀, tí ó sì ń ṣàròyé fún Allāhu. Allāhu sì ń gbọ ìsọ̀rọ̀gbèsì ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.
عربی تفاسیر:
ٱلَّذِينَ يُظَٰهِرُونَ مِنكُم مِّن نِّسَآئِهِم مَّا هُنَّ أُمَّهَٰتِهِمۡۖ إِنۡ أُمَّهَٰتُهُمۡ إِلَّا ٱلَّٰٓـِٔي وَلَدۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَيَقُولُونَ مُنكَرٗا مِّنَ ٱلۡقَوۡلِ وَزُورٗاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٞ
Àwọn tó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn nínú yín, àwọn ìyàwó kì í ṣe ìyá wọn. Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ìyá wọn bí kò ṣe ìyá tí ó bí wọn lọ́mọ.¹ Dájúdájú wọ́n ń sọ aburú nínú ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ irọ́. Dájúdájú Allāhu ni Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.
1. Kíyè sí i, òfin tó ṣe é ní èèwọ̀ fún ọkọ láti fi ẹ̀yìn ìyàwó rẹ̀ wé ẹ̀yìn ìyá rẹ̀, òfin náà l’ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un láti fi wé ẹ̀yìn ìyá tó fún un ní ọyàn mú ní kékeré nígbà tí kò tí ì já l’ẹ́nu ọyàn.
عربی تفاسیر:
وَٱلَّذِينَ يُظَٰهِرُونَ مِن نِّسَآئِهِمۡ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا قَالُواْ فَتَحۡرِيرُ رَقَبَةٖ مِّن قَبۡلِ أَن يَتَمَآسَّاۚ ذَٰلِكُمۡ تُوعَظُونَ بِهِۦۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ
Àwọn tó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò níbi ohun tí wọ́n sọ, wọn máa tú ẹrú kan sílẹ̀ lóko ẹrú ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó lè súnmọ́ ara wọn. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
عربی تفاسیر:
فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ شَهۡرَيۡنِ مُتَتَابِعَيۡنِ مِن قَبۡلِ أَن يَتَمَآسَّاۖ فَمَن لَّمۡ يَسۡتَطِعۡ فَإِطۡعَامُ سِتِّينَ مِسۡكِينٗاۚ ذَٰلِكَ لِتُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۚ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۗ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Ẹni tí kò bá rí (ẹrú), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó lè súnmọ́ ara wọn. Ẹni tí kò bá ní agbára (ààwẹ̀), ó máa bọ́ ọgọ́ta tálíkà. Ìyẹn nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀ fún ẹ̀dá. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
عربی تفاسیر:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُحَآدُّونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ كُبِتُواْ كَمَا كُبِتَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۚ وَقَدۡ أَنزَلۡنَآ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٖۚ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Dájúdájú àwọn tó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, A óò yẹpẹrẹ wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe yẹpẹrẹ àwọn tó ṣíwájú wọn. A kúkú ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
عربی تفاسیر:
يَوۡمَ يَبۡعَثُهُمُ ٱللَّهُ جَمِيعٗا فَيُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُوٓاْۚ أَحۡصَىٰهُ ٱللَّهُ وَنَسُوهُۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ
Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, àwọn sì gbàgbé rẹ̀. Allāhu sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.
عربی تفاسیر:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ مَا يَكُونُ مِن نَّجۡوَىٰ ثَلَٰثَةٍ إِلَّا هُوَ رَابِعُهُمۡ وَلَا خَمۡسَةٍ إِلَّا هُوَ سَادِسُهُمۡ وَلَآ أَدۡنَىٰ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡثَرَ إِلَّا هُوَ مَعَهُمۡ أَيۡنَ مَا كَانُواْۖ ثُمَّ يُنَبِّئُهُم بِمَا عَمِلُواْ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ
Ṣé o kò wòye pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ni? Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn. Wọ́n kéré sí ìyẹn, wọ́n tún pọ̀ (ju ìyẹn) àfi kí Ó wà pẹ̀lú wọn ní ibikíbi tí wọ́n bá wà.¹ Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Āyah yìí tako sūrah Ƙọ̄f; 50:16.” Bákan náà, àwọn sūfī sọ pé, “Pẹ̀lú äyah yìí kò sí ibi tí Pàápàá Bíbẹ Ọlọ́hun kò sí!” Àwọn igun méjèèjì ti gbé e gbági nítorí pé, ọ̀rọ̀ kò rí bí wọ́n ti sọ.
Ní àkọ́kọ́ ná, kò sí ìtakora láààrin āyah yìí àti sūrah Ƙọ̄f; 50:16. Bákan náà, āyah yìí kò túmọ̀ sí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan. Tí Allāhu bá ṣe ìkejì ẹnì kan, tàbí Ó ṣe ìkẹta ẹni méjì, tí a sì mọ̀ pé Ọ̀kan ṣoṣo ni Pàápàá Bíbẹ Allāhu, tí àwa ẹ̀dá rẹ̀ sì pọ̀ ní òǹkà, èyí ti túmọ̀ sí pé gbólóhùn àkànlò ni gbólóhùn “Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn.” Àti gbólóhùn “Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà.” (sūrah al-Hadīd; 57:4)
Wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ kò túmọ̀ sí sísọ Pàápàá Allāhu di púpọ̀ bí ẹ̀dá, kò sì túmọ̀ sí sísọ Allāhu di Ẹni tí kò níí wà lórí Ìtẹ́-Ọlá Rẹ̀ lókè sánmọ̀ keje, bí kò ṣe pé wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ ni pé, “Allāhu ń gbọ́ ohùn ẹ̀dá”, “Ó ń rí ẹ̀dá”, “Ó mọ ẹ̀dá”, “Ó ń ṣọ́ ẹ̀dá”. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Tọ̄hā; 20:46, sūrah at-Tọlāƙ; 65:12 àti sūrah al-Mulk; 67: 16 àti 17.
Ṣíwájú sí i, nínú sūrah Ƙọ̄f; 50:16 ìsúnmọ́ tí Allāhu súnmọ́ ẹ̀dá ju isan ọrùn rẹ̀ lọ dúró fún bí àwọn mọlāika olùgbọ̀rọ̀-sílẹ̀ lẹ́nu ẹ̀dá ṣe súnmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó. Èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 17 àti 18 nínú sūrah náà.
Bákan náà, nínú sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:85 ìsúnmọ́ tí Allāhu súnmọ́ ẹ̀dá ju bí a ṣe súnmọ́ ara wa lọ dúró fún bí àwọn mọlāika olùgbẹ̀mí-ẹ̀dá ṣe máa súnmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ní àkókò tí ẹ̀mí bá fẹ́ jáde lára ẹ̀dá. Èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 83 àti 84 nínú sūrah náà. Nítorí náà, ìsúnmọ́ tí Allāhu ń tọ́ka sí nínú àwọn āyah wọ̀nyẹn àti irú wọn mìíràn kò túmọ̀ sí ìsọ̀kalẹ̀ Allāhu wá sí inú isan ọrùn ẹ̀dá, bí kò ṣe pé àwọn mọlāika ni ọ̀rọ̀ náà kàn. Allāhu sì tún fi ìmọ̀ Rẹ̀, ìríran Rẹ̀, agbára Rẹ̀ àti ààbò Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn mọlāika náà. Wàyí, sūrah al-’Ani‘ām; 6:61 àti 62 ti yanjú gbogbo àlàyé ọ̀rọ̀ yìí.
عربی تفاسیر:
أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ نُهُواْ عَنِ ٱلنَّجۡوَىٰ ثُمَّ يَعُودُونَ لِمَا نُهُواْ عَنۡهُ وَيَتَنَٰجَوۡنَ بِٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِ وَمَعۡصِيَتِ ٱلرَّسُولِۖ وَإِذَا جَآءُوكَ حَيَّوۡكَ بِمَا لَمۡ يُحَيِّكَ بِهِ ٱللَّهُ وَيَقُولُونَ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ لَوۡلَا يُعَذِّبُنَا ٱللَّهُ بِمَا نَقُولُۚ حَسۡبُهُمۡ جَهَنَّمُ يَصۡلَوۡنَهَاۖ فَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ
Ṣé o kò rí àwọn tí A kọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ fún, lẹ́yìn náà tí wọ́n tún padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Wọ́n ń bára wọn sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Nígbà tí wọ́n bá sì dé ọ̀dọ̀ rẹ, wọn yóò kí ọ ní kíkí tí Allāhu kò fi kí ọ. Wọ́n sì ń wí sínú ẹ̀mí wọn pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Allāhu jẹ wá níyà lórí ohun tí à ń wí (ní ìkọ̀kọ̀)!” Iná Jahanamọ máa tó wọn. Wọ́n máa wọ inú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
عربی تفاسیر:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا تَنَٰجَيۡتُمۡ فَلَا تَتَنَٰجَوۡاْ بِٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِ وَمَعۡصِيَتِ ٱلرَّسُولِ وَتَنَٰجَوۡاْ بِٱلۡبِرِّ وَٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Ẹ bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
عربی تفاسیر:
إِنَّمَا ٱلنَّجۡوَىٰ مِنَ ٱلشَّيۡطَٰنِ لِيَحۡزُنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَيۡسَ بِضَآرِّهِمۡ شَيۡـًٔا إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ
Dájúdájú ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (burúkú) ń wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù nítorí kí ó lè kó ìbànújẹ́ bá àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá wọn àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
عربی تفاسیر:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَكُمۡ تَفَسَّحُواْ فِي ٱلۡمَجَٰلِسِ فَٱفۡسَحُواْ يَفۡسَحِ ٱللَّهُ لَكُمۡۖ وَإِذَا قِيلَ ٱنشُزُواْ فَٱنشُزُواْ يَرۡفَعِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنكُمۡ وَٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ دَرَجَٰتٖۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá sọ fún yín pé kí ẹ gbara yín láyè nínú àwọn ibùjókòó, ẹ gbara yín láyè. Allāhu yóò f’àyè gbà yín. Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: “Ẹ dìde (síbi iṣẹ́ rere).” Ẹ dìde (sí i). Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
عربی تفاسیر:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نَٰجَيۡتُمُ ٱلرَّسُولَ فَقَدِّمُواْ بَيۡنَ يَدَيۡ نَجۡوَىٰكُمۡ صَدَقَةٗۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ لَّكُمۡ وَأَطۡهَرُۚ فَإِن لَّمۡ تَجِدُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá bá Òjíṣẹ́ sọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ,¹ ẹ fi ọrẹ títa ṣíwájú ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín. Ó sì fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Tí ẹ ò bá sì rí (ọrẹ), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hujurọ̄t; 49:7.
عربی تفاسیر:
ءَأَشۡفَقۡتُمۡ أَن تُقَدِّمُواْ بَيۡنَ يَدَيۡ نَجۡوَىٰكُمۡ صَدَقَٰتٖۚ فَإِذۡ لَمۡ تَفۡعَلُواْ وَتَابَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥۚ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ
Ṣé ẹ̀ ń páyà (òṣì) níbi kí ẹ máa ti ọrẹ ṣíwájú àwọn ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín ni? Nígbà tí ẹ ò ṣe é, Allāhu sì gba ìronúpìwàdà yín. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
عربی تفاسیر:
۞ أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ تَوَلَّوۡاْ قَوۡمًا غَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مَّا هُم مِّنكُمۡ وَلَا مِنۡهُمۡ وَيَحۡلِفُونَ عَلَى ٱلۡكَذِبِ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ
Ṣé o ò rí àwọn (ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) tí wọ́n mú ìjọ kan tí Allāhu bínú sí ní ọ̀rẹ́ (ìyẹn àwọn yẹhudi)? Wọn kì í ṣe ara yín, (àwọn munāfiki kì í ṣe ara ẹ̀yin mùsùlùmí) wọn kì í sì ṣe ara wọn (àwọn munāfiki kì í sì ṣe ara àwọn yẹhudi). Wọ́n yó sì máa búra lórí irọ́, wọ́n sì mọ̀.
عربی تفاسیر:
أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُمۡ عَذَابٗا شَدِيدًاۖ إِنَّهُمۡ سَآءَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Allāhu ti pèsè ìyà líle dè wọ́n. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
عربی تفاسیر:
ٱتَّخَذُوٓاْ أَيۡمَٰنَهُمۡ جُنَّةٗ فَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ فَلَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ
Wọ́n fi ìbúra wọn ṣe ààbò; wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Nítorí náà, ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún wọn.
عربی تفاسیر:
لَّن تُغۡنِيَ عَنۡهُمۡ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔاۚ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
عربی تفاسیر:
يَوۡمَ يَبۡعَثُهُمُ ٱللَّهُ جَمِيعٗا فَيَحۡلِفُونَ لَهُۥ كَمَا يَحۡلِفُونَ لَكُمۡ وَيَحۡسَبُونَ أَنَّهُمۡ عَلَىٰ شَيۡءٍۚ أَلَآ إِنَّهُمۡ هُمُ ٱلۡكَٰذِبُونَ
Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde pátápátá, wọn yó sì máa búra fún Un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń búra fún yín. Wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ti rí n̄ǹkan ṣe. Gbọ́! Dájúdájú àwọn gan-an ni òpùrọ́.
عربی تفاسیر:
ٱسۡتَحۡوَذَ عَلَيۡهِمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ فَأَنسَىٰهُمۡ ذِكۡرَ ٱللَّهِۚ أُوْلَٰٓئِكَ حِزۡبُ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ أَلَآ إِنَّ حِزۡبَ ٱلشَّيۡطَٰنِ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
Èṣù jẹ gàba lé wọn lórí. Ó sì mú wọn gbàgbé ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Èṣù. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ èṣù, àwọn ni ẹni òfò.
عربی تفاسیر:
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُحَآدُّونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓ أُوْلَٰٓئِكَ فِي ٱلۡأَذَلِّينَ
Dájúdájú àwọn tó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn olùyẹpẹrẹ jùlọ.
عربی تفاسیر:
كَتَبَ ٱللَّهُ لَأَغۡلِبَنَّ أَنَا۠ وَرُسُلِيٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزٞ
Allāhu kọ ọ́ pé: “Dájúdájú Mo máa borí; Èmi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi.” Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí.
عربی تفاسیر:
لَّا تَجِدُ قَوۡمٗا يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ يُوَآدُّونَ مَنۡ حَآدَّ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَلَوۡ كَانُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ أَوۡ أَبۡنَآءَهُمۡ أَوۡ إِخۡوَٰنَهُمۡ أَوۡ عَشِيرَتَهُمۡۚ أُوْلَٰٓئِكَ كَتَبَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَأَيَّدَهُم بِرُوحٖ مِّنۡهُۖ وَيُدۡخِلُهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ رَضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُۚ أُوْلَٰٓئِكَ حِزۡبُ ٱللَّهِۚ أَلَآ إِنَّ حِزۡبَ ٱللَّهِ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ
O ò níí rí ìjọ kan tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kódà kí wọ́n jẹ́ àwọn bàbá wọn, tàbí àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ìbátan wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ti kọ ìgbàgbọ́ òdodo sínú ọkàn wọn. Allāhu sì fi ẹ̀rí òdodo láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́.¹ Ó sì máa mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Allāhu. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùjèrè.²
1. Kíyè sí i! Ìtúmọ̀ “rūh” nínú āyah yìí ni ẹ̀rí òdodo, ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà. Àmọ́ ìtúmọ̀ “rūh” nínú sūrah an-Nisā’; 4:171, ìyẹn túmọ̀ sí ẹ̀mí tí Allāhu Ẹlẹ́dàá fi dá Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Bákan náà, “minhu” tí ó wà pẹ̀lú “rūh” nínú àwọn āyah méjèèjì túmọ̀ sí pé, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni ẹ̀rí òdodo (ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà) àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - ti wá. Iṣẹ́ ọwọ́ Allāhu sì ni àwọn méjèèjì. Irú “minhu” yìí náà ló wà nínú sūrah al-Jāthiyah; 45:13. Ìyẹn ni pé, “min” tí ó túmọ̀ sí “kí n̄ǹkan wá láti ibì kan”, kì í ṣe “min” tí ó túmọ̀ sí “kí n̄ǹkan jẹ́ ara kan-ùn”.
2. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah at-Taobah; 9:23.
عربی تفاسیر:
 
معانی کا ترجمہ سورت: سورۂ مجادلہ
سورتوں کی لسٹ صفحہ نمبر
 
قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ترجمے کی لسٹ

قرآن کریم کے معانی کا یوروبا ترجمہ۔ ترجمہ شیخ ابو رحیمہ میکائیل ایکویینی نے کیا ہے۔ طباعت سنہ 1432ھ۔

بند کریں