Check out the new design

Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Die Übersetzung in Yoruba - Abu Rahimah Mikail * - Übersetzungen

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Übersetzung der Bedeutungen Surah / Kapitel: Sabaʾ   Vers:
لَقَدۡ كَانَ لِسَبَإٖ فِي مَسۡكَنِهِمۡ ءَايَةٞۖ جَنَّتَانِ عَن يَمِينٖ وَشِمَالٖۖ كُلُواْ مِن رِّزۡقِ رَبِّكُمۡ وَٱشۡكُرُواْ لَهُۥۚ بَلۡدَةٞ طَيِّبَةٞ وَرَبٌّ غَفُورٞ
Dájúdájú àmì kan wà fún àwọn Saba’ nínú ibùgbé wọn; (òhun ni) ọgbà oko méjì tó wà ní ọ̀tún àti ní òsì.[1] “Ẹ jẹ nínú arísìkí Olúwa yín. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un.” Ìlú tó dára ni (ilẹ̀ àwọn Saba’. Allāhu sì ni) Olúwa Aláforíjìn.
1. Ìyẹn ni pé, ìlú wọn wà ní ààrin, ọgbà oko sì yí wọn po.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
فَأَعۡرَضُواْ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ سَيۡلَ ٱلۡعَرِمِ وَبَدَّلۡنَٰهُم بِجَنَّتَيۡهِمۡ جَنَّتَيۡنِ ذَوَاتَيۡ أُكُلٍ خَمۡطٖ وَأَثۡلٖ وَشَيۡءٖ مِّن سِدۡرٖ قَلِيلٖ
Wọ́n gbúnrí (níbi ẹ̀sìn). Nítorí náà, A rán adágún odò tí wọ́n mọ odi yíká sí wọn. A sì pààrọ̀ oko wọn méjèèjì fún wọn pẹ̀lú oko èso méjì mìíràn tí ó jẹ́ oko èso tó korò, oko igi àti kiní kan nínú igi sidir díẹ̀.[1]
1. Oríṣi igi sidr méjì ló wà. Igi sidr kan wà tí wọ́n ń jẹ èso rẹ̀, tí wọ́n ń fi ewé rẹ̀ wẹ̀. Èyí ni “nabƙ”. Igi sidr kejì ni èyí tí kò ní èso, tí wọn kì í fi ewé rẹ̀ wẹ̀. Èyí ni “dọ̄ll”. Òhun sì ni wọ́n gbàlérò nínú āyah yìí.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
ذَٰلِكَ جَزَيۡنَٰهُم بِمَا كَفَرُواْۖ وَهَلۡ نُجَٰزِيٓ إِلَّا ٱلۡكَفُورَ
Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí pé, wọ́n ṣàì moore. Ǹjẹ́ A máa san ẹnì kan lẹ́san ìyà bí kò ṣe aláìmoore?
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
وَجَعَلۡنَا بَيۡنَهُمۡ وَبَيۡنَ ٱلۡقُرَى ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَا قُرٗى ظَٰهِرَةٗ وَقَدَّرۡنَا فِيهَا ٱلسَّيۡرَۖ سِيرُواْ فِيهَا لَيَالِيَ وَأَيَّامًا ءَامِنِينَ
A sì fi àwọn ìlú kan tó wà ní gban̄gba sí ààrin ìlú tí A rán adágún odò sí[1] àti àwọn ìlú tí A fi ìbùkún sí. A sì ṣètò ibùsọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n fún ìrìn-àjò ṣíṣe sínú àwọn ìlú náà.² Ẹ rìn lọ sínú wọn ní òru àti ní ojú ọjọ́ pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀.
1. Ìyẹn àwọn Saba’ ní ilẹ̀ Yamọn. 2. Èyí ni pé, tí onírìn-àjò bá gbéra, ó máa kan àwọn ìlú lójú-ọ̀nà. Ó sì máa ríbi sinmi láti ìlú kan sí ìlú mìíràn láààrin àwọn ìlú tí ó wà láààrin ilẹ̀ Saba’ àti ìlú tí Allāhu fi ìbùkún sí, ìyẹn ilẹ̀ Ṣām.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
فَقَالُواْ رَبَّنَا بَٰعِدۡ بَيۡنَ أَسۡفَارِنَا وَظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَحَادِيثَ وَمَزَّقۡنَٰهُمۡ كُلَّ مُمَزَّقٍۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٖ
(Àwọn ará ìlú Saba’) wí pé: “Olúwa wa, mú àwọn ìrìn-àjò wa láti ìlú kan sí ìlú mìíràn jìnnà síra wọn.” Wọ́n ṣe àbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.[1] A sì sọ wọ́n di ìtàn. A tú wọn ká pátápátá (ìlú wọn di ahoro). Dájúdájú àwọn àmì kan wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
1. Ọ̀kan nínú oore tí Allāhu - Ọba Olóore - ṣe fún àwọn ará Saba’ ni pé, Ó fi àwọn ìlú tó já mọ́ra wọn yí wọn ká. Wọ́n sì ń rí oore púpọ̀ láti ara àwọn onírìn-àjò tó ń gba ìlú wọn kọjá. Àmọ́ wọn kò mọ ìwọ̀nyí sí oore.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
وَلَقَدۡ صَدَّقَ عَلَيۡهِمۡ إِبۡلِيسُ ظَنَّهُۥ فَٱتَّبَعُوهُ إِلَّا فَرِيقٗا مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú ’Iblīs ti sọ àbá-modá rẹ̀ di òdodo lórí wọn. Wọ́n sì tẹ̀lé e àfi igun kan nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
وَمَا كَانَ لَهُۥ عَلَيۡهِم مِّن سُلۡطَٰنٍ إِلَّا لِنَعۡلَمَ مَن يُؤۡمِنُ بِٱلۡأٓخِرَةِ مِمَّنۡ هُوَ مِنۡهَا فِي شَكّٖۗ وَرَبُّكَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٍ حَفِيظٞ
(’Iblīs) kò sì ní agbára kan lórí wọn bí kò ṣe pé kí A lè ṣàfi hàn ẹni tó gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ kúrò lára ẹni tó wà nínú iyèméjì nípa rẹ̀. Olùṣọ́ sì ni Olúwa rẹ lórí gbogbo n̄ǹkan.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
قُلِ ٱدۡعُواْ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَمۡلِكُونَ مِثۡقَالَ ذَرَّةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا لَهُمۡ فِيهِمَا مِن شِرۡكٖ وَمَا لَهُۥ مِنۡهُم مِّن ظَهِيرٖ
Sọ pé: “Ẹ pe àwọn tí ẹ sọ pé (wọ́n jẹ́ ọlọ́hun) lẹ́yìn Allāhu.” Wọn kò ní ìkápá òdiwọ̀n ọmọ-iná igún nínú àwọn sánmọ̀ tàbí nínú ilẹ̀. Wọn kò sì ní ìpín kan nínú méjèèjì. Àti pé kò sí olùrànlọ́wọ́ kan fún Allāhu láààrin wọn.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
 
Übersetzung der Bedeutungen Surah / Kapitel: Sabaʾ
Suren/ Kapiteln Liste Nummer der Seite
 
Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Die Übersetzung in Yoruba - Abu Rahimah Mikail - Übersetzungen

Übersetzt von Schaykh Abu Rahimah Mikail Aykyuni.

Schließen