Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Yorubische Übersetzung * - Übersetzungen

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Übersetzung der Bedeutungen Vers: (1) Surah / Kapitel: At-Tawba

Suuratut-Taobah

بَرَآءَةٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦٓ إِلَى ٱلَّذِينَ عَٰهَدتُّم مِّنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ
(Èyí ni) ìyọwọ́-yọsẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ sí àwọn tí ẹ ṣe àdéhùn fún nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.
1. Ẹ́ẹ́rìnlé láàádọ́fà sūrah (114) ni àpapọ̀ sūrah tí ó wà nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Gbólóhùn “Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm.” sì ni ohun tí wọ́n fi ṣe ìpínrọ̀ láààrin sūrah kan àti òmíràn. Ó tún lè dá dúró lọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí āyah àkọ́kọ́ nínú sūrah al-Fātihah. Bákan náà, ó jẹ́ awẹ́ āyah gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ nínú sūrah an-Naml; 27:30. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín-sūrah ní gbólóhùn “Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm.” dúró fún jùlọ nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, wọn kò fi pín sūrah at-Taobah sọ́tọ̀ nítorí pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò pa á láṣẹ fún àwọn Sọhābah láti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣíwájú kí ó tó jáde kúrò láyé. Kò sì lẹ́tọ̀ó fún àwọn Sọhābah - kí Allāhu yọ́nú sí wọn - láti ṣe àfikún ohunkóhun sí àkọsílẹ̀ al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé yálà lójú ayé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - tàbí lẹ́yìn ikú rẹ̀.
Báyìí sì ni ó ṣe di sunnah pé sūrah at-Taobah kò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn ìpín-sūrah, èyí tí a mọ̀ sí gbólóhùn “Bismi-llāhir-Rahmọ̄nir-Rọhīm.”
Kíyè sí i, kò sí orí-ọ̀rọ̀ kan tó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “Ní orúkọ Ọlọ́hun.” nínú àwọn ìwé kan tí àwọn kan tún ń pè ní “Ìwé Ọlọ́hun”. Àwọn ìwé náà ìbá jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀ Ọlọ́hun, àwọn orí-ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ìbá máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́hun tí wọ́n sọ pé Òun l’Ó sọ̀ ọ́ kalẹ̀! Ẹyìn àti ọpẹ́ ni fún Allāhu, Ọba tó fi orúkọ ara Rẹ̀ ṣe ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn sūrah al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
 
Übersetzung der Bedeutungen Vers: (1) Surah / Kapitel: At-Tawba
Suren/ Kapiteln Liste Nummer der Seite
 
Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Yorubische Übersetzung - Übersetzungen

Übersetzung der Quran-Bedeutung in Yoruba Sprache von Abu Rahima Mikhail Aikweiny in 1432 H.

Schließen