Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci * - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Fassarar Ma'anoni Aya: (112) Sura: Suratu Al'bakara
بَلَىٰۚ مَنۡ أَسۡلَمَ وَجۡهَهُۥ لِلَّهِ وَهُوَ مُحۡسِنٞ فَلَهُۥٓ أَجۡرُهُۥ عِندَ رَبِّهِۦ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ
Bẹ́ẹ̀ kọ́ (wọn kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi) ẹni tí ó bá ju ara rẹ̀ sílẹ̀ (sínú ’Islām) fún Allāhu,¹ tí ó sì jẹ́ olùṣe rere. Nítorí náà, ẹ̀san (rere) rẹ̀ ń bẹ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn.² Wọn kò sì níí banújẹ́.³
1. Ìyẹn ni pé, ẹni tí ó bá ṣe ’Islām pẹ̀lú àfọ̀mọ́-ọkàn.
2. Ìyẹn ni pé, kò níí sí ìbẹ̀rù fún àwọn mùsùlùmí nípa ohun tí wọ́n ń lọ bá pàdé ní Ọjọ́ Àjíǹde.
3. Ìyẹn ni pé, kò níí sí ìbànújẹ́ fún àwọn mùsùlùmí nípa ohun tí ọwọ́ wọn kò bà nínú oore ayé nítorí pé, Allāhu máa dí i fún wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde.
Tafsiran larabci:
 
Fassarar Ma'anoni Aya: (112) Sura: Suratu Al'bakara
Teburin Jerin Sunayen Surori Lambar shafi
 
Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

Fassarar Maanar Al-Qurani Mai girma da Yarabanci Wanda Shiekh Abu Rahima Mikail Alkweiny ya Fassara Wanda aka buga a Shekarar 1432 Hijira

Rufewa