Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci * - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Fassarar Ma'anoni Aya: (212) Sura: Suratu Al'bakara
زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَيَسۡخَرُونَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۘ وَٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ وَٱللَّهُ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٖ
Wọ́n ṣe ìṣẹ̀mí ayé ní ọ̀ṣọ́ (ẹ̀tàn) fún àwọn aláìgbàgbọ́. (Tí ayé bá sì yẹ wọ́n tán,) wọn yó máa fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn tó sì bẹ̀rù Allāhu máa wà l’ókè wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Àti pé Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.¹
1. Bí a bá gbé gbólóhùn yìí “Àti pé Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.” ka orí oore tayé, ó máa túmọ̀ sí pé, Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún àwọn ẹ̀dá nílé ayé, kì í ṣe lórí ìṣírò àti òṣùwọ̀n pé iṣẹ́ ọwọ́ wọn dára tàbí kò dára, kì í sì ṣe lórí ìṣírò àti òṣùwọ̀n pé wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo tàbí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, bí kò ṣe lábẹ́ fífẹ́ bẹ́ẹ̀ Allāhu, Ọba Olùpèsè. Ìyẹn ni pé, oore ayé dúró sórí bí Allāhu ṣe fẹ́ kí ó pọ̀ tó fún ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ ẹ fún. Èyí jẹ́ èsì fún àwọn aláìgbàgbọ́ nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ nínú wọn ń fi àwọn aláìní nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ṣe yẹ̀yẹ́. Ṣebí bí a ṣe rí aláìní láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ náà ni a rí àwọn aláìní láààrin àwọn aláìgbàgbọ́. Kódà kò jẹ́ n̄ǹkan kàyéfì bí gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ bá jẹ́ ọlọ́rọ̀ nílé ayé ní ìbámu sí sūrah az-Zukruf; 43:32 - 33.
Bí a bá sì gbé gbólóhùn náa ka orí oore tọ̀run, ó máa túmọ̀ sí pé, ẹ̀san rere àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ọ̀run máa pọ̀ jaburata débi pé, àwọn gan-an kò níí mọ ìsírò rẹ̀, bí wọ́n bá gbìyànjú láti ṣe ìṣírò rẹ̀. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:173.
Tafsiran larabci:
 
Fassarar Ma'anoni Aya: (212) Sura: Suratu Al'bakara
Teburin Jerin Sunayen Surori Lambar shafi
 
Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

Fassarar Maanar Al-Qurani Mai girma da Yarabanci Wanda Shiekh Abu Rahima Mikail Alkweiny ya Fassara Wanda aka buga a Shekarar 1432 Hijira

Rufewa