Check out the new design

Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassarar Yarabanci - Abu Ruhaimah Mika'il * - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Fassarar Ma'anoni Aya: (12) Sura: Al'an'am
قُل لِّمَن مَّا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ قُل لِّلَّهِۚ كَتَبَ عَلَىٰ نَفۡسِهِ ٱلرَّحۡمَةَۚ لَيَجۡمَعَنَّكُمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا رَيۡبَ فِيهِۚ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ
Sọ pé: “Ti ta ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni.” Ó ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí.[1] Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Àwọn tó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò níí gbàgbọ́.
[1] Irú àánú wo? Èsì rẹ̀ wá níwájú nínú āyah 54, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àànú kan tún ni lílọ́ ẹ̀dá lára títí di Ọjọ́ Àjíǹde gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú āyah tí à ń tọsẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, bí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - kò ṣe fi apá kan mọ̀nà, kò túmọ̀ sí pé Allāhu kì í ṣe Aláàánú, kò sì túmọ̀ sí pé àánú Rẹ̀ kò lè kárí gbogbo wa ní ayé àti ní ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé bí Allāhu ṣe fi ọ̀nà tààrà Rẹ̀ ’Islām mọ apá kan kò túmọ̀ sí pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - jẹ́ alábòsí. Àmọ́ ẹ̀kọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fẹ́ kọ́ wa nínú ìwọ̀nyẹn pọ̀ púpọ̀. Nínú rẹ̀ ni pé, gbogbo ìròyìn ara Rẹ̀ l’ó gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ. Lára ìròyìn Rẹ̀ ni ìfinimọ̀nà àti ìṣinilọ́nà, àánú àti ìyà. Kò sí èyí tó máa ṣe àlékún ọlá Rẹ̀ nínú wọn, kò sì sí èyí tí ó máa tàbùkù ipò Rẹ̀ nínú wọn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni kó wòye sí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ pẹ̀lú ọpọlọ tó mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì nítorí pé, kò sí ẹni tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - kò ní àwíjàre lórí rẹ̀.
Tafsiran larabci:
 
Fassarar Ma'anoni Aya: (12) Sura: Al'an'am
Teburin Jerin Sunayen Surori Lambar shafi
 
Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassarar Yarabanci - Abu Ruhaimah Mika'il - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

Fassara Sheikh Abu Ruhaimah Mika'il Aikuyini.

Rufewa