Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci * - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Fassarar Ma'anoni Sura: Suratu Al'saff   Aya:

Suuratus-Soff

سَبَّحَ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۖ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Tafsiran larabci:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لِمَ تَقُولُونَ مَا لَا تَفۡعَلُونَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nítorí kí ni ẹ ṣe ń sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe níṣẹ́?
Tafsiran larabci:
كَبُرَ مَقۡتًا عِندَ ٱللَّهِ أَن تَقُولُواْ مَا لَا تَفۡعَلُونَ
Ó jẹ́ ohun ìbínú tó tóbi ní ọ̀dọ̀ Allāhu pé kí ẹ sọ ohun tí ẹ ò níí ṣe.
Tafsiran larabci:
إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلَّذِينَ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِهِۦ صَفّٗا كَأَنَّهُم بُنۡيَٰنٞ مَّرۡصُوصٞ
Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn tó ń jagun sí ojú-ọ̀nà Rẹ̀ (tí wọ́n tò ní) ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí ẹni pé ilé tí wọ́n lẹ̀pọ̀ mọ́ra wọn ni wọ́n
Tafsiran larabci:
وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ لِمَ تُؤۡذُونَنِي وَقَد تَّعۡلَمُونَ أَنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُمۡۖ فَلَمَّا زَاغُوٓاْ أَزَاغَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُمۡۚ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, nítorí kí ni ẹ óò ṣe fi ìnira kàn mí. Ẹ sì kúkú mọ̀ pé, dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu ni èmi jẹ́ si yín.” Nígbà tí wọ́n sì yẹ̀ (kúrò níbi òdodo), Allāhu yẹ ọkàn wọn. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
Tafsiran larabci:
وَإِذۡ قَالَ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ إِنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُم مُّصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيَّ مِنَ ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَمُبَشِّرَۢا بِرَسُولٖ يَأۡتِي مِنۢ بَعۡدِي ٱسۡمُهُۥٓ أَحۡمَدُۖ فَلَمَّا جَآءَهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ قَالُواْ هَٰذَا سِحۡرٞ مُّبِينٞ
(Rántí) nígbà tí ‘Īsā ọmọ Mọryam sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu si yín. Mò ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó ṣíwájú mi nínú Taorāh. Mo sì ń mú ìró-ìdùnnú wá nípa Òjíṣẹ́ kan tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Orúkọ rẹ̀ ni ’Ahmọd.”¹ Nígbà tí ó bá sì wá bá wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, wọ́n á wí pé: “Idán pọ́nńbélé ni èyí.”
1. Láti ọ̀dọ̀ Jubaer ọmọ Mut‘im - kí Allāhu yọ́nú sí i -, Ànábì – kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu má abá a - sọ pé: “(Orúkọ mi nìwọ̀nyí): èmi ni Muhammad. Èmi ni ’Ahmad. Èmi ni Mọ̄hī, ẹni tí Allāhu fi pa àìgbàgbọ́ rẹ́. Èmi ni Hāṣir, ẹni tí wọn yóò kó àwọn ènìyàn jọ lẹ́yìn rẹ̀ fún Àjíǹde. Èmi sì ni ‘Āƙib, ẹni tí kò níí sí Ànábì kan mọ́ lẹ́yìn rẹ̀.” (Muslim).
Tafsiran larabci:
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ وَهُوَ يُدۡعَىٰٓ إِلَى ٱلۡإِسۡلَٰمِۚ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ
Ta sì ni ó ṣàbòsí tó tayọ ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tí wọ́n sì ń pè é sínú ’Islām! Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.
Tafsiran larabci:
يُرِيدُونَ لِيُطۡفِـُٔواْ نُورَ ٱللَّهِ بِأَفۡوَٰهِهِمۡ وَٱللَّهُ مُتِمُّ نُورِهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡكَٰفِرُونَ
Wọ́n ń gbèrò láti fi (ọ̀rọ̀) ẹnu wọn pa ìmọ́lẹ̀ Allāhu. Allāhu yó sì mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn kárí, àwọn aláìgbàgbọ́ ìbáà kórira rẹ̀.
Tafsiran larabci:
هُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ رَسُولَهُۥ بِٱلۡهُدَىٰ وَدِينِ ٱلۡحَقِّ لِيُظۡهِرَهُۥ عَلَى ٱلدِّينِ كُلِّهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُشۡرِكُونَ
(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.
Tafsiran larabci:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰ تِجَٰرَةٖ تُنجِيكُم مِّنۡ عَذَابٍ أَلِيمٖ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ṣé kí N̄g tọ́ka yín sí òkòwò kan tí ó máa gbà yín là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?
Tafsiran larabci:
تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتُجَٰهِدُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ بِأَمۡوَٰلِكُمۡ وَأَنفُسِكُمۡۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ẹ jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu pẹ̀lú àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.
Tafsiran larabci:
يَغۡفِرۡ لَكُمۡ ذُنُوبَكُمۡ وَيُدۡخِلۡكُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ وَمَسَٰكِنَ طَيِّبَةٗ فِي جَنَّٰتِ عَدۡنٖۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
(Allāhu) máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ibùgbé tó dára nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.
Tafsiran larabci:
وَأُخۡرَىٰ تُحِبُّونَهَاۖ نَصۡرٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَفَتۡحٞ قَرِيبٞۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Àti n̄ǹkan mìíràn tí ẹ tún nífẹ̀ẹ́ sí; (ìyẹn) àrànṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ìṣẹ́gun tó súnmọ́. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.
Tafsiran larabci:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُونُوٓاْ أَنصَارَ ٱللَّهِ كَمَا قَالَ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ لِلۡحَوَارِيِّـۧنَ مَنۡ أَنصَارِيٓ إِلَى ٱللَّهِۖ قَالَ ٱلۡحَوَارِيُّونَ نَحۡنُ أَنصَارُ ٱللَّهِۖ فَـَٔامَنَت طَّآئِفَةٞ مِّنۢ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ وَكَفَرَت طَّآئِفَةٞۖ فَأَيَّدۡنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ عَلَىٰ عَدُوِّهِمۡ فَأَصۡبَحُواْ ظَٰهِرِينَ
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ́ alárànṣe fún (ẹ̀sìn) Allāhu gẹ́gẹ́ bí (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ta ni ó máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi nípa (ẹ̀sìn) Allāhu?” Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: “Àwa ni alárànṣe (fún ẹ̀sìn) Allāhu.” Igun kan nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́ ní òdodo nígbà náà, igun kan sì ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. A sì fún àwọn tó gbàgbọ́ lágbára lórí àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì di olùborí.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah āl ‘Imrọ̄n; 3:55.
Tafsiran larabci:
 
Fassarar Ma'anoni Sura: Suratu Al'saff
Teburin Jerin Sunayen Surori Lambar shafi
 
Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassara da Yarabanci - Teburin Bayani kan wasu Fassarori

Fassarar Maanar Al-Qurani Mai girma da Yarabanci Wanda Shiekh Abu Rahima Mikail Alkweiny ya Fassara Wanda aka buga a Shekarar 1432 Hijira

Rufewa