Check out the new design

ߞߎ߬ߙߣߊ߬ ߞߟߊߒߞߋ ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߦߙߏߓߊߞߊ߲ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫ * - ߘߟߊߡߌߘߊ ߟߎ߫ ߦߌ߬ߘߊ߬ߥߟߊ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌ߬ߘߊ߬ߟߌ ߝߐߘߊ ߘߏ߫: ߟߎߞߌߡߊ߲߫   ߟߝߊߙߌ ߘߏ߫:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يُولِجُ ٱلَّيۡلَ فِي ٱلنَّهَارِ وَيُولِجُ ٱلنَّهَارَ فِي ٱلَّيۡلِ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ كُلّٞ يَجۡرِيٓ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى وَأَنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu l’Ó ń ti òru bọ inú ọ̀sán, Ó ń ti ọ̀sán bọ inú òru, Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá? Ìkọ̀ọ̀kan wọn máa rìn títí di gbèdéke àkókò kan.[1] Àti pé (ṣé o ò rí i pé) dájúdájú Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?
[1] Gbèdéke àkókò náà ni òpin ayé.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِ ٱلۡبَٰطِلُ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡكَبِيرُ
Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Àti pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀ ni irọ́. Dájúdájú Allāhu, Ó ga, Ó tóbi.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱلۡفُلۡكَ تَجۡرِي فِي ٱلۡبَحۡرِ بِنِعۡمَتِ ٱللَّهِ لِيُرِيَكُم مِّنۡ ءَايَٰتِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّكُلِّ صَبَّارٖ شَكُورٖ
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú ọkọ̀ ojú-omi ń rìn ní ojú omi pẹ̀lú ìdẹ̀ra Rẹ̀, (ṣebí) nítorí kí (Allāhu) lè fi hàn yín nínú àwọn àmì Rẹ̀ ni? Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún gbogbo onísùúrù, olùdúpẹ́.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
وَإِذَا غَشِيَهُم مَّوۡجٞ كَٱلظُّلَلِ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ فَلَمَّا نَجَّىٰهُمۡ إِلَى ٱلۡبَرِّ فَمِنۡهُم مُّقۡتَصِدٞۚ وَمَا يَجۡحَدُ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَّا كُلُّ خَتَّارٖ كَفُورٖ
Nígbà tí ìgbì omi bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru bí ẹ̀ṣújò, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1] Nígbà tí Ó bá sì gbà wọ́n là sórí ilẹ̀, onídéédé sì máa wà nínú wọn. Kò sì sí ẹni tó máa tako àwọn āyah Wa àfi gbogbo ọ̀dàlẹ̀, aláìmoore.
[1] Ẹ wo sūrah Yūnus; 10:22 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱتَّقُواْ رَبَّكُمۡ وَٱخۡشَوۡاْ يَوۡمٗا لَّا يَجۡزِي وَالِدٌ عَن وَلَدِهِۦ وَلَا مَوۡلُودٌ هُوَ جَازٍ عَن وَالِدِهِۦ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞۖ فَلَا تَغُرَّنَّكُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَلَا يَغُرَّنَّكُم بِٱللَّهِ ٱلۡغَرُورُ
Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ bẹ̀rù Olúwa yín. Kí ẹ sì páyà ọjọ́ kan tí òbí kan kò níí ṣàǹfààní fún ọmọ rẹ̀; àti pé ọmọ kan, òun náà kò níí ṣàǹfààní kiní kan fún òbí rẹ̀. Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo. Nítorí náà, ìṣẹ̀mí ayé yìí kò gbọdọ̀ tàn yín jẹ. (aṣ-Ṣaetọ̄n) ẹlẹ́tàn kò sì gbọdọ̀ tàn yín jẹ nípa Allāhu.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
إِنَّ ٱللَّهَ عِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِ وَيُنَزِّلُ ٱلۡغَيۡثَ وَيَعۡلَمُ مَا فِي ٱلۡأَرۡحَامِۖ وَمَا تَدۡرِي نَفۡسٞ مَّاذَا تَكۡسِبُ غَدٗاۖ وَمَا تَدۡرِي نَفۡسُۢ بِأَيِّ أَرۡضٖ تَمُوتُۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرُۢ
Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun tó wà nínú àpòlùkẹ́.[1] Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.
[1] “Ohun tó wà nínú àpòlùkẹ́”, ní abala ìrísí rẹ̀, ó lè di mímọ̀ fún ẹ̀dá nígbà tí ó bá ti di ọlẹ̀.
ߊߙߊߓߎߞߊ߲ߡߊ ߞߘߐߦߌߘߊ ߟߎ߬:
 
ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌ߬ߘߊ߬ߟߌ ߝߐߘߊ ߘߏ߫: ߟߎߞߌߡߊ߲߫
ߝߐߘߊ ߟߎ߫ ߦߌ߬ߘߊ߬ߥߟߊ ߞߐߜߍ ߝߙߍߕߍ
 
ߞߎ߬ߙߣߊ߬ ߞߟߊߒߞߋ ߞߘߐ ߟߎ߬ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߦߙߏߓߊߞߊ߲ ߘߟߊߡߌߘߊ - ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫ - ߘߟߊߡߌߘߊ ߟߎ߫ ߦߌ߬ߘߊ߬ߥߟߊ

ߗߍ߬ߡߐ߯ ߊ߬ߓߎ߰-ߙߊ߬ߤ߭ߌ߯ߡߊ߫ ߡߌߞߊߌߟߎ߫ ߊߦߑߞߏߓߌ߯ߣߌ߯ ߟߊ߫

ߘߊߕߎ߲߯ߠߌ߲