Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Ayet: (110) Sure: Sûratu'l-İsrâ
قُلِ ٱدۡعُواْ ٱللَّهَ أَوِ ٱدۡعُواْ ٱلرَّحۡمَٰنَۖ أَيّٗا مَّا تَدۡعُواْ فَلَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَلَا تَجۡهَرۡ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتۡ بِهَا وَٱبۡتَغِ بَيۡنَ ذَٰلِكَ سَبِيلٗا
Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).”¹ Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn.
1. Pípe Allāhu tàbí ar-Rahmọ̄n tàbí èyíkéyìí nínú àwọn orúkọ Allāhu tí ó dára jùlọ, kò túmọ̀ sí fífa orúkọ kan nínú àwọn orúkọ Allāhu pẹ̀lú òǹkà púpọ̀ bíi sísọ pé Allāhu, Allāhu … tàbí ar-Rahmọ̄n, ar-Rahmọ̄n … Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìlànà àwọn onibid‘ah. Èyí tí ó tọ sunnah ni lílo àwọn orúkọ náà nínú gbólóhùn. Kí á wo àwọn ìhun àti àgbékalẹ̀ àdúà Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú àwọn tírà hadīth lórí èyí tàbí tíra Hisnul-muslim “Odi Ìṣọ́ Mùsùlùmí” ti ààfáà wa Ƙọhtọ̄niy.
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Ayet: (110) Sure: Sûratu'l-İsrâ
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat