Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Ayet: (64) Sure: Sûratu'l-İsrâ
وَٱسۡتَفۡزِزۡ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتَ مِنۡهُم بِصَوۡتِكَ وَأَجۡلِبۡ عَلَيۡهِم بِخَيۡلِكَ وَرَجِلِكَ وَشَارِكۡهُمۡ فِي ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَوۡلَٰدِ وَعِدۡهُمۡۚ وَمَا يَعِدُهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ إِلَّا غُرُورًا
Fi ohùn rẹ kó ẹni tí agbára rẹ bá ká nínú wọn láyà jẹ. Fi àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin rẹ àti ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ rẹ pè wọ́n (sínú ìṣìnà). Kópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn dúkìá àti àwọn ọmọ.¹ Kí o sì ṣe àdéhùn fún wọn.” Èṣù kò sì níí ṣe àdéhùn kan fún wọn bí kò ṣe ẹ̀tàn. ²
1. Ìyẹn ni pé, Èṣù yóò bá wọn lọ́wọ́ sí fífi harām wá owó àti dúkìá. Bákan náà, Èṣù yóò bá wọn lọ́wọ́ sí bíbí ọmọ ní ìpasẹ̀ ìbàjẹ́ àti àgbèrè ṣíṣe.
2. Ohùn Èṣù ni orin àlùjó oníran-ànran, eré ṣíṣe àti ayò títa. Àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sin àti àwọn ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀ tí Èṣù ń lò fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí ni gbogbo olùpèpè sínú ìyapa àṣẹ Allāhu àti àṣẹ àwọn Ànábì Rẹ̀ (‘aleehim sọlātun wa salām).
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Ayet: (64) Sure: Sûratu'l-İsrâ
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat