Check out the new design

Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Tercüme - Ebu Rahime Mikail * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Sure: Sûratu'l-Enbiyâ   Ayet:
وَمِنَ ٱلشَّيَٰطِينِ مَن يَغُوصُونَ لَهُۥ وَيَعۡمَلُونَ عَمَلٗا دُونَ ذَٰلِكَۖ وَكُنَّا لَهُمۡ حَٰفِظِينَ
Nínú àwọn aṣ-Ṣaetọ̄n, àwọn tó ń wa kùsà òkun tún wà fún un. Wọ́n tún ń ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwa sì ń jẹ́ Olùṣọ́ fún wọn.
Arapça tefsirler:
۞ وَأَيُّوبَ إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥٓ أَنِّي مَسَّنِيَ ٱلضُّرُّ وَأَنتَ أَرۡحَمُ ٱلرَّٰحِمِينَ
(Ẹ rántí Ànábì) ’Ayyūb, nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú ọwọ́ ìnira ti kàn mí. Ìwọ sì ni Aláàánú jùlọ nínú àwọn aláàánú.”
Arapça tefsirler:
فَٱسۡتَجَبۡنَا لَهُۥ فَكَشَفۡنَا مَا بِهِۦ مِن ضُرّٖۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ أَهۡلَهُۥ وَمِثۡلَهُم مَّعَهُمۡ رَحۡمَةٗ مِّنۡ عِندِنَا وَذِكۡرَىٰ لِلۡعَٰبِدِينَ
A sì jẹ́pè rẹ̀. A mú gbogbo ìnira rẹ̀ kúrò fún un. A tún fún un ní àwọn ẹbí rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn; (ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn olùjọ́sìn (fún Wa).
Arapça tefsirler:
وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِدۡرِيسَ وَذَا ٱلۡكِفۡلِۖ كُلّٞ مِّنَ ٱلصَّٰبِرِينَ
(Ẹ rántí Ànábì) ’Ismọ̄‘īl àti (Ànábì) ’Idrīs àti (Ànábì) Thul-Kifl; ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) wà nínú àwọn onísùúrù.
Arapça tefsirler:
وَأَدۡخَلۡنَٰهُمۡ فِي رَحۡمَتِنَآۖ إِنَّهُم مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
A sì fi wọ́n sínú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni rere.
Arapça tefsirler:
وَذَا ٱلنُّونِ إِذ ذَّهَبَ مُغَٰضِبٗا فَظَنَّ أَن لَّن نَّقۡدِرَ عَلَيۡهِ فَنَادَىٰ فِي ٱلظُّلُمَٰتِ أَن لَّآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنتَ سُبۡحَٰنَكَ إِنِّي كُنتُ مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ
(Ẹ rántí) ẹlẹ́ja, nígbà tí ó bá ìbínú lọ, ó sì lérò pé A ò níí gbá òun mú. Ó sì pe (Olúwa rẹ̀) nínú àwọn òkùnkùn (inú ẹja) pé: "Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ìwọ (Allāhu). Mímọ́ ni fún Ọ. Dájúdájú èmi wà nínú àwọn alábòsí.”[1]
1. Kíyè sí i, ohun tí Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - kà kún àbòsí nínú àdúà rẹ̀ yìí kì í ṣe ìjàǹbá nítorí pé, kò sí Ànábì tó jẹ́ oníjàǹbá. Àmọ́ ohun tí ó ṣe ni pé, ó kánjú kúrò láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n tọrọ ìyà, tí ìyà náà sì fẹ́ sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí. Nítorí kí ìyà má baà kó òun náà sínú ló fi kánjú yẹra fún wọn.
Arapça tefsirler:
فَٱسۡتَجَبۡنَا لَهُۥ وَنَجَّيۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡغَمِّۚ وَكَذَٰلِكَ نُـۨجِي ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
A jẹ́pè rẹ̀. A sì gbà á là nínú ìbànújẹ́. Báyẹn ni A ṣe ń gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.
Arapça tefsirler:
وَزَكَرِيَّآ إِذۡ نَادَىٰ رَبَّهُۥ رَبِّ لَا تَذَرۡنِي فَرۡدٗا وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلۡوَٰرِثِينَ
(Ẹ rántí Ànábì) Zakariyyā nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Olúwa mi, má fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan (tí kò níí bímọ). Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùjogún.”[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sọffāt; 37:125.
Arapça tefsirler:
فَٱسۡتَجَبۡنَا لَهُۥ وَوَهَبۡنَا لَهُۥ يَحۡيَىٰ وَأَصۡلَحۡنَا لَهُۥ زَوۡجَهُۥٓۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ يُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِ وَيَدۡعُونَنَا رَغَبٗا وَرَهَبٗاۖ وَكَانُواْ لَنَا خَٰشِعِينَ
A jẹ́pè rẹ̀. A sì ta á lọ́rẹ ọmọ, (Ànábì) Yahyā. A sì ṣe àtúnṣe ìyàwó rẹ̀ fún un. Dájúdájú wọ́n ń yára gágá níbi àwọn iṣẹ́ rere. Wọ́n ń pè Wá pẹ̀lú ìrètí àti ìpáyà. Wọ́n sì jẹ́ olùtẹríba fún Wa.
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Sure: Sûratu'l-Enbiyâ
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Tercüme - Ebu Rahime Mikail - Mealler fihristi

Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni tarafından tercüme edilmiştir.

Kapat