Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Ayet: (16) Sure: Sûretu Fussilet
فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا صَرۡصَرٗا فِيٓ أَيَّامٖ نَّحِسَاتٖ لِّنُذِيقَهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَخۡزَىٰۖ وَهُمۡ لَا يُنصَرُونَ
Nítorí náà, A rán atẹ́gùn líle sí wọn ní àwọn ọjọ́ burúkú kan nítorí kí Á lè jẹ́ kí wọ́n tọ́ ìyà yẹpẹrẹ wò nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Ìyà ọjọ́ Ìkẹ́yìn sì máa yẹpẹrẹ wọn jùlọ; Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.¹
1. Àwọn “nasọ̄rọ̄ sọ pé, “Nínú sūrah al-Ƙọmọr; 54:19, Allāhu dárúkọ ọjọ́ kan fún ìparun ìjọ ‘Ād. Àmọ́ nínú sūrah al-Hāƙƙọh; 69:7, Allāhu dárúkọ òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ fún ìparun wọn. Nínú sūrah Fussilat; 41:16, Allāhu dárúkọ àwọn ọjọ́? Wọ́n ní, “Nítorí náà, ìtakora ti jẹyọ lórí òǹkà ọjọ́ ti Allāhu fi pa ìjọ ‘Ād run!
Èsì: Kò sí ìtakora láààrin àwọn āyah náà. Àlàyé rẹ̀ nìyí, āyah ti sūrah al-Ƙọmọr tó pè é ní ọjọ́ kan sọ pé “ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.” Nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀, “ọjọ́ kan” di “àwọn ọjọ́ kan” nínú āyah ti sūrah Fussilat. Àmọ́ àpapọ̀ òǹkà ọjọ́ ìparun wọn l’ó jẹyọ nínú āyah ti sūrah al-Hāƙƙọh. Ṣé ẹ ti rí i báyìí pé, àìnímọ̀ nípa èto láààrin àwọn āyah lè ṣokùnfà ìtakora āyah lójú àwọn aláìmọ̀kan.
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Ayet: (16) Sure: Sûretu Fussilet
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat