Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Ayet: (37) Sure: Sûratu'l-Mâide
يُرِيدُونَ أَن يَخۡرُجُواْ مِنَ ٱلنَّارِ وَمَا هُم بِخَٰرِجِينَ مِنۡهَاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٞ مُّقِيمٞ
Wọn yóò fẹ́ jáde kúrò nínú Iná, wọn kò sì níí lè jáde kúrò nínú rẹ̀. Ìyà gbére sì wà fún wọn.¹
1. Nínú Sọhīh bn Hibbān, láti ọ̀dọ̀ Jābir ọmọ ‘Abdullāh - kí Allāhu yọ́nú sí i -, ó sọ pé, mo gbọ́ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, etí mi méjèèjì yìí ni mo fi gbọ́ ọ, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tọ́ka sí etí rẹ̀ méjèèjì – “Allāhu máa mú àwọn ènìyàn kan jáde kúrò nínú Iná, Ó máa mú wọn wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra.” Ọkùnrin kan sì sọ fún un pé, dájúdájú Allāhu sọ pé, “ Wọn yóò fẹ́ jáde kúrò nínú Iná, wọn kò sì níí lè jáde kúrò nínú rẹ̀.” Jābir ọmọ ‘Abdullāh sọ pé, “Dájúdájú ẹ̀ ń sọ ọ̀rọ̀ àdáyanrí di ọ̀rọ̀ gbogbogbò. Āyah yìí wà fún àwọn aláìgbàgbọ́ (ní àdáyanrí). Ẹ ké ohun tí ó ṣíwájú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ké āyah 36 mọ́ āyah 37. “ Ti àwọn aláìgbàgbọ́ ni.
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Ayet: (37) Sure: Sûratu'l-Mâide
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat