Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Ayet: (41) Sure: Sûratu'l-Mâide
۞ يَٰٓأَيُّهَا ٱلرَّسُولُ لَا يَحۡزُنكَ ٱلَّذِينَ يُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡكُفۡرِ مِنَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِأَفۡوَٰهِهِمۡ وَلَمۡ تُؤۡمِن قُلُوبُهُمۡۛ وَمِنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْۛ سَمَّٰعُونَ لِلۡكَذِبِ سَمَّٰعُونَ لِقَوۡمٍ ءَاخَرِينَ لَمۡ يَأۡتُوكَۖ يُحَرِّفُونَ ٱلۡكَلِمَ مِنۢ بَعۡدِ مَوَاضِعِهِۦۖ يَقُولُونَ إِنۡ أُوتِيتُمۡ هَٰذَا فَخُذُوهُ وَإِن لَّمۡ تُؤۡتَوۡهُ فَٱحۡذَرُواْۚ وَمَن يُرِدِ ٱللَّهُ فِتۡنَتَهُۥ فَلَن تَمۡلِكَ لَهُۥ مِنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔاۚ أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَمۡ يُرِدِ ٱللَّهُ أَن يُطَهِّرَ قُلُوبَهُمۡۚ لَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞۖ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Ìwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn tó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn tó fi ẹnu ara wọn wí pé: “A gbàgbọ́.” - tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn tó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “Tí wọ́n bá fún yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fún yín ẹ ṣọ́ra.”¹ Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.
1. Àwọn yẹhudi rán ara wọn lọ bá Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti bi í léèrè nípa ìdájọ́ onísìná tí ó ti ṣe ìgbéyàwó rí. Wọ́n sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ wọn pé tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní kòbókò àti kíkun ojú onísìná ní dúdú láti fi ṣẹ̀sín níta, kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìdájọ́ yẹn. Àmọ́ tí ó bá pe ìdájọ́ rẹ̀ ní lílẹ̀lókòpa, ẹ ṣọ́ra fún un, kí ẹ má ṣe tẹ̀lé e. Ìyẹn ni àlàyé fún “Tí wọ́n bá fún yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fún yín, ẹ ṣọ́ra.”
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Ayet: (41) Sure: Sûratu'l-Mâide
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali - Mealler fihristi

Yorba Dilinde Kur'an-ı Kerim Meali- Tercüme Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni, Basım Yılı hicri 1432.

Kapat