Check out the new design

Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Tercüme - Ebu Rahime Mikail * - Mealler fihristi

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Anlam tercümesi Sure: Sûratu'l-Enfâl   Ayet:
وَإِن يُرِيدُوٓاْ أَن يَخۡدَعُوكَ فَإِنَّ حَسۡبَكَ ٱللَّهُۚ هُوَ ٱلَّذِيٓ أَيَّدَكَ بِنَصۡرِهِۦ وَبِٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Tí wọ́n bá tún fẹ́ tàn ọ́ jẹ, dájúdájú Allāhu á tó ọ. Òun ni Ẹni tí Ó fi àrànṣe Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ràn ọ́ lọ́wọ́.
Arapça tefsirler:
وَأَلَّفَ بَيۡنَ قُلُوبِهِمۡۚ لَوۡ أَنفَقۡتَ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا مَّآ أَلَّفۡتَ بَيۡنَ قُلُوبِهِمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ أَلَّفَ بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّهُۥ عَزِيزٌ حَكِيمٞ
Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Tí ó bá jẹ́ pé o ná gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá, ìwọ kò lè pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn. Ṣùgbọ́n Allāhu pa ọkàn wọn pọ̀ mọ́ra wọn, dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
Arapça tefsirler:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ حَسۡبُكَ ٱللَّهُ وَمَنِ ٱتَّبَعَكَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Ìwọ Ànábì, Allāhu ti tó ìwọ àti àwọn tó tẹ̀lé ọ nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Arapça tefsirler:
يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ حَرِّضِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ عَلَى ٱلۡقِتَالِۚ إِن يَكُن مِّنكُمۡ عِشۡرُونَ صَٰبِرُونَ يَغۡلِبُواْ مِاْئَتَيۡنِۚ وَإِن يَكُن مِّنكُم مِّاْئَةٞ يَغۡلِبُوٓاْ أَلۡفٗا مِّنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٞ لَّا يَفۡقَهُونَ
Ìwọ Ànábì, gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìyànjú lórí ogun ẹ̀sìn. Tí ogún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ọgọ́rùn-ún bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún nínú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nítorí pé dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ tí kò gbọ́ àgbọ́yé.
Arapça tefsirler:
ٱلۡـَٰٔنَ خَفَّفَ ٱللَّهُ عَنكُمۡ وَعَلِمَ أَنَّ فِيكُمۡ ضَعۡفٗاۚ فَإِن يَكُن مِّنكُم مِّاْئَةٞ صَابِرَةٞ يَغۡلِبُواْ مِاْئَتَيۡنِۚ وَإِن يَكُن مِّنكُمۡ أَلۡفٞ يَغۡلِبُوٓاْ أَلۡفَيۡنِ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ مَعَ ٱلصَّٰبِرِينَ
Nísisìn yìí, Allāhu ti ṣe é ní fífúyẹ́ fún yín. Ó sì mọ̀ pé dájúdájú àìlágbára ń bẹ fún yín. Nítorí náà, tí ọgọ́rùn-ún onísùúrù bá wà nínú yín, wọn yóò borí igba. Tí ẹgbẹ̀rún kan bá sì wà nínú yín, wọn yóò borí ẹgbẹ̀rún méjì pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Allāhu sì wà pẹ̀lú àwọn onísùúrù.
Arapça tefsirler:
مَا كَانَ لِنَبِيٍّ أَن يَكُونَ لَهُۥٓ أَسۡرَىٰ حَتَّىٰ يُثۡخِنَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ تُرِيدُونَ عَرَضَ ٱلدُّنۡيَا وَٱللَّهُ يُرِيدُ ٱلۡأٓخِرَةَۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٞ
Kò yẹ fún Ànábì kan láti ní ẹrú ogun títí ọwọ́ rẹ̀ máa fi ba àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí ilẹ̀ dáadáa ní ti pípa.[1] Ẹ̀yin ń fẹ́ ìgbádùn ayé, Allāhu sì ń fẹ́ ọ̀run. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Gọ̄fir; 40:55.
Arapça tefsirler:
لَّوۡلَا كِتَٰبٞ مِّنَ ٱللَّهِ سَبَقَ لَمَسَّكُمۡ فِيمَآ أَخَذۡتُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ
Tí kì í bá ṣe ti àkọsílẹ̀ kan tó ti gbawájú láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni, ọwọ́ ìyà ńlá kò bá tẹ̀ yín nípa n̄ǹkan tí ẹ gbà (ní owó ìtúsílẹ̀).
Arapça tefsirler:
فَكُلُواْ مِمَّا غَنِمۡتُمۡ حَلَٰلٗا طَيِّبٗاۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí ẹ kó ní ọrọ̀ ogun (tí ó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti) n̄ǹkan dáadáa. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
Arapça tefsirler:
 
Anlam tercümesi Sure: Sûratu'l-Enfâl
Surelerin fihristi Sayfa numarası
 
Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Tercüme - Ebu Rahime Mikail - Mealler fihristi

Şeyh Ebu Rahime Mikail İykuviyni tarafından tercüme edilmiştir.

Kapat