قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى * - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (24) سۈرە: سۈرە ساد
قَالَ لَقَدۡ ظَلَمَكَ بِسُؤَالِ نَعۡجَتِكَ إِلَىٰ نِعَاجِهِۦۖ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡخُلَطَآءِ لَيَبۡغِي بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٍ إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ وَقَلِيلٞ مَّا هُمۡۗ وَظَنَّ دَاوُۥدُ أَنَّمَا فَتَنَّٰهُ فَٱسۡتَغۡفَرَ رَبَّهُۥ وَخَرَّۤ رَاكِعٗاۤ وَأَنَابَ۩
(Ànábì Dāwūd) sọ pé: “Ó ti ṣàbòsí sí ọ nípa bíbèèrè abo ewúrẹ́ tìrẹ mọ́ àwọn abo ewúrẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn olùbáda-n̄ǹkanpọ̀, apá kan wọn máa ń tayọ ẹnu-ààlà lórí apá kan àfi àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Díẹ̀ sì ni wọ́n.” (Ànábì) Dāwūd sì mọ̀ dájú pé A kàn fi (ìbéèrè náà) ṣàdánwò fún òun ni. Nítorí náà, ó tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀ (nípa àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn). Ó dojú bolẹ̀ láti forí kanlẹ̀. Ó sì ronú pìwàdà (sọ́dọ̀ Allāhu).¹
1. Kíyè sí i, àwọn ìtàn kan tí àwọn nasọ̄rọ̄ máa ń sọ nípa Ànábì Dāwūd - kí ọlà Allāhu máa bá a - pé gbígbà tí ó gba ìyàwó ẹnì kan nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, tí ó fi kún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún ìyàwó tirẹ̀ l’ó bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹyọ nínú āyah yìí. Kódà, àwọn tírà tafsīr kan mú ìtàn náà wá pẹ̀lú láì ṣọ̀fín-tótó rẹ̀.
Àwọn olùtọpinpin ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kúkú ti tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì sọ pé, “Ìtàn àwọn ọmọ Isrọ̄’īl lásán ni gbogbo rẹ̀. Ìtàn irọ́ ni. Kódà èyí tí wọ́n ṣàfitì rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nínú rẹ̀ kò fẹsẹ̀ rinlẹ̀, kò sì ní àlàáfíà.” Tafsīr ’Adwā’ul-bayān ti Ṣinƙītiy l’ó kúkú kó ilà kúrò lára ẹ̀kọ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí náà sì nìyẹn nítorí pé, kò sí olùgbàyàwó-oníyàwó nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -. Ní òdodo ni pé, òǹkà ìyàwó wọn lè pọ̀ ní òǹkà, kì í ṣe ní ti ìgbádùn adùn-ara lásán tàbí ní ti ọ̀nà àbòsí tàbí ní ti ọ̀nà àgbèrè (zinā) bí kò ṣe pé, wọ́n fẹ́ òǹkà ìyàwó púpọ̀ lábẹ́ òfin ẹ̀tọ́ fún àgbéga ẹ̀sìn ’Islām. Kò sì yẹ kí ọ̀rọ̀ àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ bá wa ní òjijì rárá nítorí pé, kò sí Ànábì kan tàbí Òjíṣẹ́ kan tí wọn kò tàbùkù rẹ̀.
Síwájú sí i, òye tó wà nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ẹlẹ́ran yìí ni pé, Allāhu - Onídàájọ́ òdodo àti déédé - fẹ́ kọ́ Ànábì Dāwūd - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní ẹ̀kọ́ ìgbẹ́jọ́ nítorí pé, Allāhu fẹ́ fi ṣe adájọ́ láààrin àwọn ìjọ rẹ̀. Àìtẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹni-afẹ̀sùnkàn ni àṣíṣe tó ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Dāwūd - kí ọlà Allāhu máa bá a - nínú ìgbẹ́jọ́ náà. Èyí náà sì ni ohun tí ó tọrọ àforíjìn Ọlọ́hun fún, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìyàwó gbígbà, èyí tí kò ṣẹlẹ̀ nínú āyah náà, tí kò sì ṣẹlẹ̀ sí Ànábì Dāwūd - kí ọlà Allāhu máa bá a - rí nínú ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
 
مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (24) سۈرە: سۈرە ساد
سۈرە مۇندەرىجىسى بەت نومۇرى
 
قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

قۇرئان كەرىمنىڭ يورۇباچە تەرجىمىسىنى شەيىخ ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل ئەيكۇينى تەرجىمە قىلغان، ھىجىريە 1432-يىلى بېسىلغان.

تاقاش