قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى * - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (40) سۈرە: سۈرە پۇسسىلەت
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا لَا يَخۡفَوۡنَ عَلَيۡنَآۗ أَفَمَن يُلۡقَىٰ فِي ٱلنَّارِ خَيۡرٌ أَم مَّن يَأۡتِيٓ ءَامِنٗا يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ ٱعۡمَلُواْ مَا شِئۡتُمۡ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ
Dájúdájú àwọn tó ń darí àwọn āyah Wa kọ ọ̀nà òdì,¹ wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
1. Nínú dídarí àwọn āyah al-Ƙur’ān kọ ọ̀nà òdì ni fífún āyah kan ní ìtúmọ̀ òdì, fífi āyah kan tako āyah mìíràn, lílo āyah kan ní àyè tí kò jẹmọ́ ọn, fífi āyah kan ṣe ẹ̀fẹ̀, ṣíṣe àtakò sí āyah kan, pípa ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān tì láti tẹ̀lé ìròrí, ìṣe àti àṣà ìgbà-àìmọ̀kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ṣókí, ẹni tó darí āyah al-Ƙur’ān kọ ọ̀nà òdì ni ẹni tí kò tẹ̀lé àwọn äyah al-Ƙur’ān ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ àti ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àpẹ̀ẹrẹ igun kìíní ni àwọn oníbídíà bíí àwọn sūfī, àwọn Ahmadi àti àwọn oníjálàbí. Àpẹ̀ẹrẹ igun kejì ni àwọn ọ̀ṣẹbọ, àwọn “nasọ̄rọ̄ àti àwọn yẹhudi.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
 
مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (40) سۈرە: سۈرە پۇسسىلەت
سۈرە مۇندەرىجىسى بەت نومۇرى
 
قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

قۇرئان كەرىمنىڭ يورۇباچە تەرجىمىسىنى شەيىخ ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل ئەيكۇينى تەرجىمە قىلغان، ھىجىريە 1432-يىلى بېسىلغان.

تاقاش