قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى * - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (9) سۈرە: سۈرە ئەھقاپ
قُلۡ مَا كُنتُ بِدۡعٗا مِّنَ ٱلرُّسُلِ وَمَآ أَدۡرِي مَا يُفۡعَلُ بِي وَلَا بِكُمۡۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّ وَمَآ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٞ مُّبِينٞ
Sọ pé: “Èmi kì í ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn Òjíṣẹ́. Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin.¹ Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Èmi kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.”
1. Àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé gbólóhùn tí Allāhu pa Ànábì Rẹ̀ - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láṣẹ láti sọ yìí “Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin.” túmọ̀ sí pé “Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa já sí ní ọ̀run!” Ìtúmọ̀ tó lòdì sí òdidi al-Ƙur’ān ni ìtúmọ̀ tí àwọn nasọ̄rọ̄ ń lò fún āyah náà.
Ní àkọ́kọ́ ná, àwọn āyah méjì tó ṣíwájú āyah yìí ń sọ nípa ìhà àìgbàgbọ́ tí àwọn aláìgbàgbọ́ kọ sí al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé. Lórí inúfu-àyàfu ni ọ̀wọ́ àwọn tó gba al-Ƙur’ān gbọ́ wà lásìkò náà nítorí pé, wọ́n wà lábẹ́ ìjọba àwọn ọ̀ṣẹbọ nínú ìlú Mọkkah alápọ̀n-ọ́nlé. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí níí yọwọ́ kọ́wọ́ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.
Lásìkò náà, ipò ọ̀lẹ ni àwọn mùsùlùmí wà nínú ìlú náà. Kò sí ohun tó wá lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ sínú ’Islām tayọ kí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, ní ti òdodo, Allāhu l’Ó fi iṣẹ́ mímọ́ rán òun níṣẹ́ sí gbogbo ayé. Òun kò sì tayọ àṣẹ iṣẹ́ jíjẹ́ náà. Àmọ́ irú ọwọ́ ìyà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa gbé ko òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn òun lójú lásìkò náà, òun kò mọ̀ nítorí pé, oríṣiríṣi ọwọ́ ni irúfẹ́ wọn ti yọ sí àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́hun.
Bí àpẹ̀ẹrẹ, ṣebí àwọn ọ̀tá ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - l’ó pète pèrò láti kàn án pa mọ́ orí igi àgbélébùú. Àmọ́ tí Allāhu kò gbà fún wọn. Bákan náà, àwọn ọ̀ṣẹbọ l’ó ju Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - sínú iná. Àmọ́ tí Allāhu Alágbára kó ọ yọ. Àwọn ọ̀tá òdodo kúkú pa Ànábì Zakariyā àti Ànábì Yahyā - kí ọlà Allāhu máa bá àwọn méjèèjì -, bàbá àti ọmọ! A rí nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kù lókò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí ni ìtúmọ̀ tó wà fún “Èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí wọ́n máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” Ìyẹn ni pé, Allāhu kò fi ìmọ̀ mọ̀ mí nípa irú iyá tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa gbé dìde sí èmi àti ẹ̀yin.
Àwọn ọ̀ṣẹbọ sì kúkú nawọ́ oníran-ànran ìyà sí wọn títí àwọn mùsùlùmí fi gbé ẹ̀sìn wọn sá kúrò nínú ìlú nígbà náà. Èyí tí a mọ̀ sí hijrah. Lẹ́yìn náà, ogun ẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ kò yé fi ìnira, ìjìyà àti pípa han àwọn mùsùlùmí ní èèmọ̀ ìfojú-egbò-rìn. Mọ̀ dájú pé, kò sí Ànábì kan nínú àwọn Ànábì Ọlọ́hun - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - tí kò mọ̀ pé, inú ọgbà Ìdẹ̀ra gbére ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ọ̀wọ́ àwọn tó bá tẹ̀lé e lẹ́yìn ní ọ̀nà tó dára máa já sí ní ọ̀run.
Ṣíwájú sí i, Allāhu ló fi iṣẹ́ rán Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí ó bá jẹ́ pé ìtúmọ̀ tí àwọn nasọ̄rọ̄ fún āyah náà l’ó bá jẹ́ òdodo, “èmi kò sì mọ n̄ǹkan tí Allāhu máa ṣe fún èmi àti ẹ̀yin” ni ìbá jẹ́ àgbékalẹ̀ rẹ̀.
Bákan náà, a ìbá tí rí Lárúbáwá ẹyọ kan tó máa gbà fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí pé, pẹ̀lú èdè wọn ni Allāhu fi sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀.
Ní àkótán, āyah náà ń fi rinlẹ̀ fún wa pé, iṣẹ́ tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - jẹ́ fún ayé kò yàtọ̀ sí ti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -.
Bákan náà, āyah náà ń pè wá síbi ìdúró ṣinṣin àti àtẹ̀mọra lásìkò ìnira àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn tí kò tẹ̀lé ohun kan tayọ ìfẹ́-inú wọn.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
 
مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (9) سۈرە: سۈرە ئەھقاپ
سۈرە مۇندەرىجىسى بەت نومۇرى
 
قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

قۇرئان كەرىمنىڭ يورۇباچە تەرجىمىسىنى شەيىخ ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل ئەيكۇينى تەرجىمە قىلغان، ھىجىريە 1432-يىلى بېسىلغان.

تاقاش