قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى * - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (80) سۈرە: سۈرە تەۋبە
ٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ أَوۡ لَا تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ إِن تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ سَبۡعِينَ مَرَّةٗ فَلَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَفَرُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ
Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn - kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin - Allāhu kò níí foríjìn wọ́n. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.¹
1. Pẹ̀lú gbólóhùn yìí, àwọn kò-gbédè-ó-gbékèé nínú àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò lè tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu fún àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí Allāhu sì foríjìn wá. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àmọ́ ohun tí ń bẹ nínú āyah yìí ni pé, kò sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, gẹ́gẹ́ bí kò ṣe sí àforíjìn Allāhu fún òkú àwọn aláìgbàgbọ́ àti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹni yòówù ó bá wọn tọrọ àforíjìn. Nípa ti òkú àwọn aláìgbàgbọ́, ẹ wo āyah 84 níwájú. Nípa ti òkú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, ẹ wo sūrah al-Munāfiƙūn; 63:6. Bákan náà, nípa ti òkú àwọn ọ̀ṣẹbọ, ẹ wo sūrah an-Nisā’; 4:48 àti 116 àti sūrah at-Taobah; 9:113.
Bákàn náà, bíbá tí Allāhu ni kí àwọn mùsùlùmí lọ bá Ànábí - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - láti lè bá wọn tọrọ àforíjìn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah an-Nisā’; 4:64, ìyẹn náà ti wá sópin nípasẹ̀ ikú Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Ọ̀wọ́ ìgbà tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń bẹ nílé ayé ṣíwájú kí ó tó kú nìkan ni ó lè bá ẹnikẹ́ni nínú àwọn mùsùlùmí tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu - subhānahu wa ta'ālā -. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sì máa foríjìn ín. Àmọ́, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀ nínú sàréè rẹ̀. Ó sì di Ọjọ́ Àjíǹde kí Ànábì wa - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -tó lè bá wa ṣ’ìpẹ̀ àṣegbà níwájú Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -. Nítorí náà, ìṣẹbọ sí Allāhu ni fún ẹnikẹ́ni láti lọ bá Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ní ìdí sàréè rẹ̀ fún títọrọ n̄ǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀.
ئەرەپچە تەپسىرلەر:
 
مەنالار تەرجىمىسى ئايەت: (80) سۈرە: سۈرە تەۋبە
سۈرە مۇندەرىجىسى بەت نومۇرى
 
قۇرئان كەرىم مەنىلىرىنىڭ تەرجىمىسى - يورۇباچە تەرجىمىسى - تەرجىمىلەر مۇندەرىجىسى

قۇرئان كەرىمنىڭ يورۇباچە تەرجىمىسىنى شەيىخ ئەبۇ رەھىمە مىيكائىل ئەيكۇينى تەرجىمە قىلغان، ھىجىريە 1432-يىلى بېسىلغان.

تاقاش