Check out the new design

የቅዱስ ቁርዓን ይዘት ትርጉም - የዮሩባ ትርጉም - አቡ ረሒማ ሚካኢል * - የትርጉሞች ማዉጫ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

የይዘት ትርጉም ምዕራፍ: አል ኢስራዕ   አንቀጽ:
إِلَّا رَحۡمَةٗ مِّن رَّبِّكَۚ إِنَّ فَضۡلَهُۥ كَانَ عَلَيۡكَ كَبِيرٗا
Àyàfi ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ (ni kò fi ṣe bẹ́ẹ̀). Dájúdájú oore àjùlọ Rẹ̀ lórí rẹ tóbi.
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
قُل لَّئِنِ ٱجۡتَمَعَتِ ٱلۡإِنسُ وَٱلۡجِنُّ عَلَىٰٓ أَن يَأۡتُواْ بِمِثۡلِ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ لَا يَأۡتُونَ بِمِثۡلِهِۦ وَلَوۡ كَانَ بَعۡضُهُمۡ لِبَعۡضٖ ظَهِيرٗا
Sọ pé: “Dájúdájú tí àwọn ènìyàn àti àlùjànnú bá parapọ̀ láti mú irú al-Ƙur’ān yìí wá, wọn kò lè mú irú rẹ̀ wá, apá kan wọn ìbáà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún apá kan.”[1]
1. Bí wọ́n bá gbìyànjú rẹ̀, wọ́n máa fìdí rẹmi.
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
وَلَقَدۡ صَرَّفۡنَا لِلنَّاسِ فِي هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانِ مِن كُلِّ مَثَلٖ فَأَبَىٰٓ أَكۡثَرُ ٱلنَّاسِ إِلَّا كُفُورٗا
Dájúdájú A ti fi àkàwé kọ̀ọ̀kan ṣàlàyé (oríṣiríṣi) fún àwọn ènìyàn sínú al-Ƙur’ān yìí. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kọ̀ láti gbà àfi àtakò sá.
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
وَقَالُواْ لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ تَفۡجُرَ لَنَا مِنَ ٱلۡأَرۡضِ يَنۢبُوعًا
Wọ́n sì wí pé: “A kò níí gbàgbọ́ nínú rẹ títí o máa fi mú omi ìṣẹ́lẹ̀rú ṣẹ́yọ fún wa.
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
أَوۡ تَكُونَ لَكَ جَنَّةٞ مِّن نَّخِيلٖ وَعِنَبٖ فَتُفَجِّرَ ٱلۡأَنۡهَٰرَ خِلَٰلَهَا تَفۡجِيرًا
Tàbí kí o ní ọgbà oko dàbínù àti ọgbà oko àjàrà, tí o sì máa jẹ́ kí àwọn odò ṣàn kọ já dáadáa láààrin wọn.
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
أَوۡ تُسۡقِطَ ٱلسَّمَآءَ كَمَا زَعَمۡتَ عَلَيۡنَا كِسَفًا أَوۡ تَأۡتِيَ بِٱللَّهِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ قَبِيلًا
Tàbí kí o jẹ́ kí sánmọ̀ já lù wá ní kélekèle gẹ́gẹ́ bí o ṣe sọ (pé Allāhu lè ṣe bẹ́ẹ̀). Tàbí kí o mú Allāhu àti àwọn mọlāika wá (bá wa) ní ojúkojú.
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
أَوۡ يَكُونَ لَكَ بَيۡتٞ مِّن زُخۡرُفٍ أَوۡ تَرۡقَىٰ فِي ٱلسَّمَآءِ وَلَن نُّؤۡمِنَ لِرُقِيِّكَ حَتَّىٰ تُنَزِّلَ عَلَيۡنَا كِتَٰبٗا نَّقۡرَؤُهُۥۗ قُلۡ سُبۡحَانَ رَبِّي هَلۡ كُنتُ إِلَّا بَشَرٗا رَّسُولٗا
Tàbí kí o ní ilé wúrà kan, tàbí kí o gun òkè sánmọ̀ lọ. A kò sì níí gba gígun-sánmọ̀ rẹ gbọ́ títí o fi máa sọ tírà kan tí a óò máa ké kalẹ̀ fún wa.” Sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa mi, ǹjẹ́ mo jẹ́ kiní kan bí kò ṣe Òjíṣẹ́ abara?”
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
وَمَا مَنَعَ ٱلنَّاسَ أَن يُؤۡمِنُوٓاْ إِذۡ جَآءَهُمُ ٱلۡهُدَىٰٓ إِلَّآ أَن قَالُوٓاْ أَبَعَثَ ٱللَّهُ بَشَرٗا رَّسُولٗا
Kò sí ohun tí ó kọ̀ fún àwọn ènìyàn láti gbàgbọ́ ní òdodo nígbà tí ìmọ̀nà dé bá wọn àfi kí wọ́n wí pé: “Ṣé Allāhu rán Òjíṣẹ́ abara níṣẹ́ ni?”
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
قُل لَّوۡ كَانَ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَلَٰٓئِكَةٞ يَمۡشُونَ مُطۡمَئِنِّينَ لَنَزَّلۡنَا عَلَيۡهِم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ مَلَكٗا رَّسُولٗا
Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé àwọn mọlāika wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń rìn kiri, (tí wọ́n ń gbé lórí ilẹ̀) pẹ̀lú ìfàyàbalẹ̀, A ìbá sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún wọn láti inú sánmọ̀ (láti jẹ́) Òjíṣẹ́.”[1]
1. Ìyẹn ni pé, irọ́ ńlá ni láti ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ láti sọ pé Ọlọ́hun fúnra Rẹ̀ l’ó wá jíṣẹ́ ara Rẹ̀ ní àwòrán ‘Īsā ọmọ Mọryam láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl! Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń sọ nípa Rẹ̀ ní irọ́.
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
قُلۡ كَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدَۢا بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۚ إِنَّهُۥ كَانَ بِعِبَادِهِۦ خَبِيرَۢا بَصِيرٗا
Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀, Olùríran nípa àwọn ẹrúsìn Rẹ̀.”
የአረብኛ ቁርኣን ማብራሪያ:
 
የይዘት ትርጉም ምዕራፍ: አል ኢስራዕ
የምዕራፎች ማውጫ የገፅ ቁጥር
 
የቅዱስ ቁርዓን ይዘት ትርጉም - የዮሩባ ትርጉም - አቡ ረሒማ ሚካኢል - የትርጉሞች ማዉጫ

በሸይኽ አቡ ረሒማ ሚካኢል አይኮዊኒ የተተረጎመ።

መዝጋት