ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (43) سورة: النحل
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِمۡۖ فَسۡـَٔلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلذِّكۡرِ إِن كُنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
A kò rán ẹnì kan ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi àwọn ọkùnrin tí À ń fi ìmísí ránṣẹ́ sí. Nítorí náà, ẹ bèèrè lọ́dọ̀ àwọn oníràn-ántí tí ẹ̀yin kò bá mọ̀.¹
1. Nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, àyè méjì péré ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ti pe àwọn kan ní “ahlu-ththikr” (ìtúmọ̀ “àwọn oníràn-ántí / àwọn tí A sọ ìrántí kalẹ̀ fún). Àyè kìíní nìyí, sūrah an-Nahl; 16:43. Àyè kejì ni sūrah al-‘Anbiyā’; 21:7. Àwọn sūfī sì ń lérò pé àwọn ni “ahlu-ththikr”. Àti pé àwọn gan-an ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń tọ́ka sí nínú àwọn āyah méjèèjì náà.
Èsì: Ohun tí wọ́n ń sọ yìí kì í ṣe òtítọ́ páàpáà. Èyí tí í ṣe òdodo ọ̀rọ̀ ni pé, àwọn onímọ̀ nípa at-Taorāt àti al-’Injīl ni Allāhu ń tọ́ka sí, kì í ṣe àwọn sūfī. Ìdí ni pé, okùnfà āyah méjèèjì yìí ni pé, Allāhu fi fọ èsì sí ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ tí wọ́n ń sọ pé mọlaika ni Allāhu máa ń fi iṣẹ́ Òjíṣẹ́ rán, kì í ṣe ènìyàn. Àwọn ọ̀ṣẹbọ wọ̀nyẹn sì ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń pàṣẹ fún pé kí wọ́n lọ bèèrè wò lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ nípa tíra ìṣáájú bóyá ní òdodo ni Allāhu ti fi iṣẹ́ Òjíṣẹ́ rán mọlāika kan rí sí àwọn ènìyàn, tí yó sì máa gbé láààrin wọn ṣíwájú Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - . Irú āyah yìí wà nínú sūrah Yūnus; 10:2. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Yūsuf 12:109.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (43) سورة: النحل
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق