ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (48) سورة: النحل
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ إِلَىٰ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ يَتَفَيَّؤُاْ ظِلَٰلُهُۥ عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَٱلشَّمَآئِلِ سُجَّدٗا لِّلَّهِ وَهُمۡ دَٰخِرُونَ
Àti pé ṣé wọn kò wòye sí gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu ṣẹ̀dá rẹ̀, tí òòji rẹ̀ ń tẹ̀ sí ọ̀tún àti òsì¹ tí wọ́n ń forí kanlẹ̀ fún Allāhu; tí wọ́n sì ń yẹpẹrẹ ara wọn (fún Un)?
1. Ìyẹn ni pé, ní àárọ̀ láààrin ìgbà tí òòrùn bá yọ ní ìlà òòrùn títí di àsìkò òòrùn kàntàrí, òòji n̄ǹkan máa tẹ̀ sí agbègbè ìwọ̀ òòrùn ní orí ilẹ̀. Bákan náà, níkété tí òòrùn bá yẹ̀tàrí títí di ìgbà tí òòrùn máa wọ̀ ní ìwọ̀ òòrùn, òòji n̄ǹkan máa tẹ̀ sí agbègbè ìlà òòrùn ní orí ilẹ̀. Wàyí o, ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì -, ó sọ pé, “Títẹ̀ tí òòji gbogbo n̄ǹkan ń tẹ̀ sí ọ̀tún àti òsì ló ń dúró fún ìforíkanlẹ̀ wọn fún Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - . (Ƙurtubiy)
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (48) سورة: النحل
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق