ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (80) سورة: النحل
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُم مِّنۢ بُيُوتِكُمۡ سَكَنٗا وَجَعَلَ لَكُم مِّن جُلُودِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ بُيُوتٗا تَسۡتَخِفُّونَهَا يَوۡمَ ظَعۡنِكُمۡ وَيَوۡمَ إِقَامَتِكُمۡ وَمِنۡ أَصۡوَافِهَا وَأَوۡبَارِهَا وَأَشۡعَارِهَآ أَثَٰثٗا وَمَتَٰعًا إِلَىٰ حِينٖ
Allāhu ṣe ibùsinmi fún yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan tó fúyẹ́ fún yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn,¹ irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀.
1. Ìtàn Sūfiyyah Ní Ṣókí: Nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, àyè kan péré ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ti lo kalmọh “’aswāf”.
“’Aswāf” ni ọ̀pọ̀ “sūf”. Ìtúmọ̀ “sūf” ni “irun àgùtàn”. Bákan náà, lílò tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - lo kalmọh “’aswāf” jẹ́ ṣíṣe ìrègún oore Rẹ̀ lórí wa nípa bí “irun àgùtàn” ṣe jẹ́ ọ̀kan nínú ohun èlò tí a fi ń ṣe àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn nínú ìṣẹ̀mí ayé wa.
Àmọ́ ohun tí a fẹ́ pe àkíyèsí wa sí ní àyè yìí ni pé, Allāhu kò sọ̀rọ̀ “sūf” gẹ́gẹ́ bí ìlànà ìjọ́sìn tàbí àdìsọ́kàn ìgbàgbọ́ fún àwa mùsùlùmí. Ohun èlò àti n̄ǹkan ìgbádùn ayé, bíi lílo “sūf” fún híhun aṣọ fún oríṣiríṣi lílò àti fífi ṣòkòwò kátà-kárà nínú ìṣẹ̀mí ayé wa, ni ìwúlò àti àǹfààní tí à ń rí lára “sūf”.
Síwájú sí i, nínú èdè Lárúbáwá, tí a bá fẹ́ fi ìbátan hàn láààrin n̄ǹkan méjì pẹ̀lú ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ìyẹn nígbà tí a bá fẹ́ ṣe àfihàn ohun tí wọ́n lò láti fi ṣe n̄ǹkan kan, tàbí nígbà tí a bá fẹ́ ròyìn ènìyàn pẹ̀lú ohun tí ó máa ń lò, a kàn máa fi lẹ́tà “yā’un muṣaddadah” kún kalmọh náà, tí “yā’un muṣaddadah” náà sì máa jẹ́ àfòmọ́-ìparí fún kalmọh náà. “Yā’un muṣaddadah” yìí ni à ń pè ní “yā’u-nnisbah” (yā’u ìbátan / yā’u afìbátanhàn) nínú ẹ̀kọ́ mọfọ́lọ́jì èdè Lárúbáwá.
Nítorí náà, nínú èdè Lárúbáwá, nígbà tí a bá fẹ́ sọ pé aṣọ kan jẹ́ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùtàn hun tàbí nígbà tí a bá fẹ́ sọ pé ènìyàn kan máa ń wọ aṣọ tí wọ́n fi irun àgùtàn hun, a kàn máa so àfòmọ́ ìparí “yyun” (èyí tí a pè ní “yā’u-nnisbah”) mọ́ ìparí kalmọh “sūf”, ó sì máa di “صُوفِيٌّ” “sūfiyyun / sūfiyy” (akọ, ẹyọ), “صُوفِيُّونَ” “sūfiyyūn” (akọ, ọ̀pọ̀), “صُوفِيَّةٌ” “sūfiyyatun / sūfiyyah” (abo, ẹyọ / ọ̀rọ̀-orúkọ tí a ṣẹ̀dá láti ara sūf) “صُوفِيَّاتٌ” “sūfiyyāt” (abo, ọ̀pọ̀). Ìtúmọ̀ gbogbo rẹ̀: “aṣọ tí wọ́n fi irun àgùtàn hun / olùwọṣọ-irun àgùtàn.
Síwájú sí i, nínú àwọn ìran n̄ǹkan tí ẹ̀dá ń lò fún híhun aṣọ, aṣọ èyí tí wọ́n bá fi irun àgùtàn hún máa ń jẹ́ aṣọ tó rọjú jùlọ ní rírà. Nítorí èyí, aṣọ irun àgùtàn jẹ́ aṣọ àwọn mẹ̀kúnnù. Àwọn olówó kì í sì fẹ́ rà á fún wíwọ̀ sọ́rùn nítorí pé, ó jẹ́ aṣọ pọ́ọ́kú-lowóẹ̀, kì í sì jọ̀lọ̀ lára rárá bí ìran aṣọ mìíràn. Nítorí pé, aṣọ irun àgùtàn jẹ́ aṣọ tálíkà, ló mú aṣọ náà di ọ̀gá aṣọ fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ráyé sá nínú àwọn ẹni-ìṣáájú.
Ìmúra àwọn ẹni-ìṣáájú gbajúmọ̀ pẹ̀lú wíwọ aṣọ irun àgùtàn láti fi mú ayé bín-íntín tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó fi jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ́ pe ẹnikẹ́ni nínú wọn ní olùráyésá, “sūfiyy” ni wọ́n á pe irú ẹni náà nítorí pé, kò = = sí olùráyésá kan nínú wọn àfi kí ó dúnnímọ́ wíwọ aṣọ irun àgùtàn tààrà. Ìdí nìyí tí a bá gbọ́ pé wọ́n pe àáfà àgbà kan nínú àwọn aṣíwájú rere fún wa ní “sūfiyy” bí Imām Ṣāfi‘iyy tàbí ẹlòmíìràn, ìráyésá wọn nípa wíwọ aṣọ irun àgùtàn ló mú wọn jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Lára sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ni ìráyésá wà. Oríkì ìráyésá nìyí nígbà náà: Ìráyésá ni jíjìnnà sí àwọn n̄ǹkan olówó ńlá àti jíjìnnà sí kíkó ọrọ̀ ilé ayé jọ àti lílo àwọn n̄ǹkan tó kéré jùlọ ní òǹkà láti fi gbé ìṣẹ̀mí ayé ẹni ró. Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ni aṣíwájú gbogbo àwọn olùráyésá. Dídi olùwọṣọ-irun àgùtàn “sūfiyy lábẹ́ ìráyésá” nígbà náà kò lòdì sí ẹ̀sìn ’Islām nítorí pé, jíjẹ́ “sūfiyy” ẹnikẹ́ni nínú wọn kò sọ ọ́ di ẹni tí ó ní ìlànà ẹ̀sìn tàbí àdìsọ́kàn mìíràn tó yàtọ̀ sí sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Bí ọ̀rọ̀ àwọn sūfiyy “àwọn olùwọṣọ-irun àgùtàn” ṣe wà nìyẹn títí di ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún àkọ́kọ́ lẹ́yìn Hijrah.
Lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún àkọ́kọ́ lẹ́yìn Hijrah ni àwọn kan nínú ìlú Basrọ nílẹ̀ ‘Irāƙ bá sọ orúkọ yìí “صُوفِيَّةٌ” “sūfiyyah” di n̄ǹkan mìíràn mọ́ra wọn lọ́wọ́. Àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn gbé ìtúmọ̀ rẹ̀ kúrò lábẹ́ “wíwọ aṣọ irun àgùtàn” pátápátá, wọ́n sì fún un ní ìtúmọ̀ àgbélẹ̀rọ àti ayédèrú bíi kí wọ́n sọ pé “sūfiyyah” túmọ̀ sí dídi ẹni mímọ́, olùfọkànsìn, ẹni ẹ̀ṣà, wòlíì Ọlọ́hun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ . Paríparí rẹ̀ ni pé, àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn bá sọ orúkọ náà “sūfiyyah” di ìlànà ẹ̀sìn titun kan, wọ́n sì gbé e jù sábẹ́ ẹ̀sìn ’Islām. Àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí to ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìròrí àwọn ọ̀ṣẹbọ, ìròrí àwọn yẹhudi àti ìròrí àwọn nasọ̄rọ̄ papọ̀ mọ́ra wọn ní ọ̀nà ẹ̀tàn pẹ̀lú yíyí àwọn ìtúmọ̀ āyah al-Ƙur’ān àti hadīth Ànábì lọ́rùn láti fi ṣe àtìlẹ́yìn fún ìlànà titun náà tí wọ́n ronú gbékalẹ̀ lábẹ́ orúkọ “sūfiyyah”. Nígbà tí wọ́n sì fura mọ̀ pé, orúkọ yìí kò kún tó, wọ́n bá tún ṣe ẹ̀dà orúkọ mìíràn láti ara rẹ̀. Orúkọ náà ni “التَّصَوُّفُ” “at-tasọwwuf”. Báyìí ni “sūfiyyah” tàbí “at-tasọwwuf” ṣe di ìjọ́sìn mìíràn ní pẹrẹu láààrin àwọn aláìlẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bọ́há sọ́wọ́ àwọn àáfà onibidia.
Bákan náà, nígbà tí àwọn àáfà onibidia tasọwwuf wọ̀nyí pèrò sọ́kọ̀ bidiah tasọwwuf tán, òǹpèrò kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àáfà onibidiah wọ̀nyẹn bá tún bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ ara rẹ̀ pèrò dípò lílo orúkọ àgbélẹ̀rọ tí wọ́n dìjọ ṣe àdádáálẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni ayé wọn bá di ìlànà / tọrīkọ “at-tasọwuffu al-kọ̄diriyyah”, “at-tasọwuffu al-kọlwatiyyah” “at-tasọwuffu at-tijāniyyah” “at-tasọwuffu aṣ-Ṣāthiliyyah”, “at-tasọwuffu al-Haṣwatiyyah” àti “at-tasọwuffu an-naƙṣanbadiyyah”. Títí di òní olónìí, wọn kò yé fi orúkọ aṣíwájú wọn pèrò sọ́kọ̀ bidiah tasọwuffu wọn. Èyí ló sì ṣokùnfà bí wọ́n tún ṣe ń pe àwọn kan nínú àwọn ìlànà / tọrīkọ wọn ní “at-tasọwuffu an-Niyāsiyyah””, “at-tasọwuffu al-bulāliyyah” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn mutasọwiffūn wọ̀nyí náà ni wọ́n mú tíà sísà (bíi firāku, katali) àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò, oogun ṣíṣe, idán pípa, lílo àlùjànnú, lílọ nínú ẹ̀mí àti iṣẹ́ jálàbí ṣíṣe (ìyẹn, iṣẹ́ babaláwo) wọ inú ẹ̀sìn ’Islām. Àwọn sì ni wọ́n pọ̀ jùlọ nílẹ̀ aláwọ̀dúdú, pàápàá jùlọ ní ilẹ̀ Naijiria.
Wò ó, ìlànà tasọwuffu ti lé ní ìgbà ọ̀nà. Ó sì ti di tọ́rọ́-fọ́kánlé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó fí jẹ́ pé, tí ọkùnrin kan kò bá ti rí iṣẹ́ halāl ṣe ní iṣẹ́ òòjọ́, ó máa di “ṣééù”, tí obìnrin náà kò bá ti rí ọ̀kan-ṣèkan mọ́, òun náà á sọra rẹ̀ di “ṣééhá”. Òṣì, àìríná àti àìrílò ti kó wọn sínú tasọwuffu. Pẹ̀lú ète àwọn àlùjànnú, iná idán àwọ́rò wọn sì ń jò bùlàbùlà. Kíyè sí i, yálà al-Ƙur’ān tàbí hadīth Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, kò sí ọ̀kan kan nínú méjèèjì tó fàyè gba ìlànà mìíràn yàtọ̀ sí sunnah Ànábì nínú ìjọ́sìn mùsùlùmí tàbí ìṣe mùsùlùmí tàbí ìròrí mùsùlùmí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún lérò pé ìlànà àfikún kan tún wà fún mùsùlùmí láti lè súnmọ́ Allāhu tààrà dípò gbígba tító pẹ̀lú sunnah Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, onítọ̀ún ni a ó máa pè ní onibidiah “aládàádáálẹ̀ ìlànà ẹ̀sìn”. Tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá sì ronú pìwàdà pátápátá kúrò lórí dída sunnah Ànábì pọ̀mọ́ ìlànà àdádáálẹ̀ pẹ̀lú èròǹgbà láti pé lẹ́sìn, Iná ni ẹ̀san rẹ̀ lọ́run ní ìbámu sí sūrah an-Nisā’; 4:115. Àkàwé sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ni àpẹ̀ẹrẹ omi tí wọ́n rọ kún inú ìgò fìfo. Àkàwé èyíkéyìí ìlànà àdádáálé tí wọ́n bá fi kún sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì ni omi mìíràn tí wọ́n tún fẹ́ rọ mọ́ ẹ̀kún igo omi náà. Ìgbàkígbà tí ẹnikẹ́ni bá tún rọ omi mìíràn sínú ẹ̀kún igo omi náà, ilẹ̀ ni yóò máa dà sí títí láéláé. Omi náà yó sì máa ṣòfò dànù. Ìdí nìyí ti gbogbo ìran tasọwuffu àti àpapọ̀ tasọwuffu fi máa di òfò pọ́nńbélé lọ́jọ́ ìṣírò-iṣẹ́. Àti pé, ọ̀kan pàtàkì nínú bidiah Aṣaetāni ni gbogbo ìran tasọwuffāt pátápátá nítorí pé, “sūfiyyah” ti kúrò ní abẹ́ ìráyésá pátápátá, ó sì ti bọ́ sí abẹ́ awo ṣíṣe, awo èṣù. Kí Allāhu bá wa gbé sunnah Ànábì ga. Kí Ó bá wa rẹ bidiah Aṣaetāni nílẹ̀. Kí Ó sì bá wa paná adẹ́bọ rẹ́.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (80) سورة: النحل
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق