ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (219) سورة: البقرة
۞ يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡخَمۡرِ وَٱلۡمَيۡسِرِۖ قُلۡ فِيهِمَآ إِثۡمٞ كَبِيرٞ وَمَنَٰفِعُ لِلنَّاسِ وَإِثۡمُهُمَآ أَكۡبَرُ مِن نَّفۡعِهِمَاۗ وَيَسۡـَٔلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَۖ قُلِ ٱلۡعَفۡوَۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَتَفَكَّرُونَ
Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọtí àti tẹ́tẹ́. Sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi àti àwọn àǹfààní kan wà nínú méjèèjì fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì sì tóbi ju àǹfààní wọn.”¹ Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè pé kí ni àwọn yó máa ná ní sàráà. Sọ pé: “Ohun tí ó bá ṣẹ́kù lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbọ́ bùkátà inú ilé tán (ni kí ẹ ṣe sàráà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀
1. Āyah yìí l’ó kọ́kọ́ sọ̀kalẹ̀ nípa ìdájọ́ ọtí àti tẹ́tẹ́. Lẹ́yìn náà, āyah mìíràn sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’; 4:43. Lẹ́yìn náà, āyah ìkẹ́yìn nípa ìdájọ́ ọtí àti tẹ́tẹ́ sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah al-Mọ̄’idah; 5:90. Àwọn āyah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí kò kúkú takora wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni pé, ọ̀mùtí àsìkò yìí kò lè rí āyah àkọ́kọ́ àti ìkejì tìràn mọ́ láti sọ ọtí àti tẹ́tẹ́ di ẹ̀tọ́. Ní àkọ́kọ́ ná, bí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ṣe fẹ́ l’Ó ṣe mú ìdájọ́ ọtí àti tẹ́tẹ́ wá ní ìmúwá ìpele mẹ́ta. Nínú ìṣe Allāhu sì ni kí Ó fi ìdájọ́ ìkejì pa ìdájọ́ àkọ́kọ́ rẹ́. Nítorí náà, nínú āyah àkọ́kọ́, Allāhu pe àkíyèsí wa sí ìgbéléwọ̀n láààrin ẹ̀ṣẹ̀ ọtí àti àǹfààní rẹ̀. Nínú āyah ìkejì, Allāhu ṣe é ní èèwọ̀ láti máa hunrírà lórí ìrun. Àmọ́ ènìyàn díẹ̀ ló gbọ́ ìdájọ́ náà yé sí pé ìhunrírà kò yẹni rárá nígbà kan kan. Allāhu sì fi āyah ìkẹta ṣe ìhunrírà tàbí mímu ọtí ní èèwọ̀ nínú èyíkéyìí àsìkò, yálà ní àsìkò ìrun kíkí tàbí ní àsìkò mìíràn, yálà ní ọ̀sán tàbí ní òru, yálà ní àsìkò ayọ̀ tàbí ní àsìkò ìbànújẹ́.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (219) سورة: البقرة
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق