ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (232) سورة: البقرة
وَإِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَبَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا تَعۡضُلُوهُنَّ أَن يَنكِحۡنَ أَزۡوَٰجَهُنَّ إِذَا تَرَٰضَوۡاْ بَيۡنَهُم بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ ذَٰلِكَ يُوعَظُ بِهِۦ مَن كَانَ مِنكُمۡ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۗ ذَٰلِكُمۡ أَزۡكَىٰ لَكُمۡ وَأَطۡهَرُۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ
Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn (padà), nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.¹
1. Láti ọ̀dọ̀ Hasan. Ó sọ pé, Mi‘ƙọl ọmọ Yasār sọ fún mi pé, Wọ́n sọ āyah yìí (sūrah al-Baƙọrah 2:232) kalẹ̀ lórí òun. Ó sọ pé: “Mo so yìgì arábìnrin mi kan fún ọkùnrin kan. Lẹ́yìn náà, ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ títí òǹkà ọjọ́ opó rẹ̀ fi parí. À fi bí ó ṣe tún padà wá bá mi láti bá obìnrin náà s’ọ̀rọ̀ ìfẹ́ (kitbah). Mo sì sọ fún un pé, mo fún ọ lóbìnrin fẹ́ láya, mo ṣe é fún ọ ni ìtẹ́ (ìgùn), mo fi pọ́n ọ lé. Lẹ́yìn náà, o kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, o tún wá bá mi pé o fẹ́ bá a s’ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láti fẹ́ ẹ. Rárá, mo fi Allāhu búra, kò níí padà sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́ láéláé.” - Ènìyàn gidi sì ni arákùnrin yìí, obìnrin náà sì fẹ́ padà sí ọ̀dọ̀ arákùnrin yìí.- Báyìí ni Allāhu sọ āyah kalẹ̀. Waliyyu (alámòjúútó) obìnrin yìí sọ pé: “Ní báyìí mo máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ Òjíṣẹ́ Allāhu.” Ó sì so yìgì rẹ̀ padà fún un. (al-Bukọ̄riy, kitāb an-Nikāh, bāb mọn ƙọ̄l: Lā nikāh ’illā bi waliy)
Yàtọ̀ sí pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ń pàrọwà fún aláṣẹ obìnrin láti fọwọ́ wọ́nú lórí ìkọ̀sílẹ̀ ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ìkọ̀sílẹ̀ ẹ̀ẹ̀ kejì, pé kí ó tún yọ̀ǹda obìnrin tí ó jẹ́ alásẹ fún láti padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ bá ti wọ̀ padà láààrin ọkùnrin àti obìnrin náà, Imām Bukọ̄riy wulẹ̀ lo ìsẹ̀lẹ̀ náà láti fi rinlẹ̀ pé, jíjẹ́ dandan kí ọkùnrin tó jẹ́ alásẹ fún obìnrin fi àṣẹ sí lílọ́kọ obìnrin kò fi ìgbà kan kan kúrò lórí obìnrin, kódà obìnrin náà ìbáà jẹ́ adélébọ̀.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (232) سورة: البقرة
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق