ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (4) سورة: البقرة
وَٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبۡلِكَ وَبِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ يُوقِنُونَ
àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹ¹ àti àwọn tó ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.²
1. Ìgbàkígbà tí àwọn nasọ̄rọ̄ bá ka irú āyah yìí nínú al-Ƙur’ān, wọ́n a wí pé: “Al-Ƙur’ān gan-an sọ pé àwa mùsùlùmí gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú bíbélì!” Ní àkọ́kọ́ ná, Allāhu kò dárúkọ bíbélì nínú al-Ƙur’ān. Orúkọ àwọn tírà mímọ́ tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ nípa wọn nínú al-Ƙur’ān ni Zabūr, Suhuf, Taorāt àti ’Injīl.
Lẹ́yìn náà, ìkọ̀ọ̀kan àwọn tírà wọ̀nyẹn ló wà fún ìjọ Ànábì tí Allāhu fún nìkan, kò sì kan ìjọ mìíràn lẹ́yìn wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ pé ìjọ yẹn nìkan ni Allāhu rán Ànábì tí ọ̀rọ̀ kàn sí.
Lẹ́yìn náà, Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi rinlẹ̀ nínú al-Ƙur’ān pé kò sí ojúlówó àwọn tírà náà mọ́ níta, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú sūrah al-Baƙọrah; 2:75 & 79, sūrah an-Nisā’; 4:46 àti sūrah al-Mọ̄’idah; 5:13. Lóde òní yìí, bíbélì ti lé ní oríṣi ọgbọ̀n! Wàyí, níwọ̀n ìgbà tí ó sì ti rinlẹ̀ pé Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - sọ àwọn tírà kan kalẹ̀ fún àwọn Ànábì kan tó ṣíwájú Ànábì wa - kí ìkẹ́ Allāhu máa bá gbogbo wọn -, mùsùlùmí gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé Allāhu fún àwọn Ànábì kan ní tírà, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé mùsùlùmí yóò sọ tírà náà di ohun tí yóò máa kà áḿbọ̀sìbọ́sí pé yóò tẹ̀lé wọn. Nítorí náà, al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé ni tírà ìkẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ Allāhu fún gbogbo ẹ̀dá. Kò sí òmíràn mọ́.
2. Kíyè sí i! Āyah kẹ́ta àti ìkẹrin ló ń túmọ̀ “àwọn olùbẹ̀rù Allāhu” tí ó jẹyọ ní ìparí āyah kejì. Bákan náà, ìkọ̀ọ̀kan àwọn ìròyìn márààrún wọ̀nyí “ìgbàgbọ́ òdodo nínú ìkọ̀kọ̀, ìrun kíkí, nínáwó sí ọ̀nà ẹ̀tọ́, ìgbàgbọ́ òdodo nínú gbogbo àwọn tírà sánmọ̀ àti àmọ̀dájú (ìgbàgbọ́ òdodo) nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn”, gbogbo ìwọ̀nyí gbọ́dọ̀ wà lára ẹni tí ó bá fẹ́ wà nínú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (4) سورة: البقرة
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق