ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني سورة: العنكبوت   آية:

سورة العنكبوت - Suuratul-An'kabuut

الٓمٓ
’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.
التفاسير العربية:
أَحَسِبَ ٱلنَّاسُ أَن يُتۡرَكُوٓاْ أَن يَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا وَهُمۡ لَا يُفۡتَنُونَ
Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lérò pé A óò fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ pé: “A gbàgbọ́”, tí A ò sì níí dán wọn wò?
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ فَتَنَّا ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَلَيَعۡلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْ وَلَيَعۡلَمَنَّ ٱلۡكَٰذِبِينَ
A kúkú ti dán àwọn tó ṣíwájú wọn wò. Nítorí náà, dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó sọ òdodo. Dájúdájú Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn òpùrọ́.
التفاسير العربية:
أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلسَّيِّـَٔاتِ أَن يَسۡبِقُونَاۚ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ
Àbí àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aburú lérò pé àwọn máa mórí bọ́ mọ́ Wa lọ́wọ́ ni? Ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.
التفاسير العربية:
مَن كَانَ يَرۡجُواْ لِقَآءَ ٱللَّهِ فَإِنَّ أَجَلَ ٱللَّهِ لَأٓتٖۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí ìpàdé Allāhu, dájúdájú àkókò Allāhu kúkú ń bọ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
التفاسير العربية:
وَمَن جَٰهَدَ فَإِنَّمَا يُجَٰهِدُ لِنَفۡسِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَنِيٌّ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìyànjú, ó ń gbìyànjú fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَنُكَفِّرَنَّ عَنۡهُمۡ سَيِّـَٔاتِهِمۡ وَلَنَجۡزِيَنَّهُمۡ أَحۡسَنَ ٱلَّذِي كَانُواْ يَعۡمَلُونَ
Àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa ha àwọn iṣẹ́ aburú wọn dànù fún wọn. Dájúdájú A ó sì san wọ́n lẹ́san pẹ̀lú èyí tó dára ju ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.
التفاسير العربية:
وَوَصَّيۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ بِوَٰلِدَيۡهِ حُسۡنٗاۖ وَإِن جَٰهَدَاكَ لِتُشۡرِكَ بِي مَا لَيۡسَ لَكَ بِهِۦ عِلۡمٞ فَلَا تُطِعۡهُمَآۚ إِلَيَّ مَرۡجِعُكُمۡ فَأُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
A pa á ní àṣẹ fún ènìyàn láti ṣe dáadáa sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Tí àwọn méjèèjì bá sì jà ọ́ lógun pé kí ó fi ohun tí ìwọ kò ní ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Mi, má ṣe tẹ̀lé àwọn méjèèjì.[1] Ọ̀dọ̀ Mi ni ibùpadàsí yín. Nítorí náà, Mo máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
1. Fífi ohun tí ẹ̀dá kò nímọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹbọ sí Allāhu - Ọba tí kò ní akẹgbẹ́ - túmọ̀ sí pé, sísọ n̄ǹkan kan di ọlọ́hun, olúwa àti olùgbàlà lẹ́yìn Allāhu, n̄ǹkan tí Allāhu kò fi ìmọ̀ nípa n̄ǹkan náà mọ àwa ẹ̀dá Rẹ̀ nínú àwọn Tírà Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “akẹgbẹ́ Rẹ̀”.
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَنُدۡخِلَنَّهُمۡ فِي ٱلصَّٰلِحِينَ
Àwọn tó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọ́n sínú àwọn ẹni rere.
التفاسير العربية:
وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ فَإِذَآ أُوذِيَ فِي ٱللَّهِ جَعَلَ فِتۡنَةَ ٱلنَّاسِ كَعَذَابِ ٱللَّهِۖ وَلَئِن جَآءَ نَصۡرٞ مِّن رَّبِّكَ لَيَقُولُنَّ إِنَّا كُنَّا مَعَكُمۡۚ أَوَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِأَعۡلَمَ بِمَا فِي صُدُورِ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “A gba Allāhu gbọ́.” Nígbà tí wọ́n bá sì fi ìnira kàn án nínú ẹ̀sìn Allāhu, ó máa mú ìnira àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyà ti Allāhu. (Ó sì máa padà sínú àìgbàgbọ́.) Tí àrànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ bá sì dé, dájúdájú wọn yóò wí pé: “Dájúdájú àwa wà pẹ̀lú yín.” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà gbogbo ẹ̀dá ni?
التفاسير العربية:
وَلَيَعۡلَمَنَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَيَعۡلَمَنَّ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ
Dájúdájú Allāhu máa ṣàfi hàn àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó sì máa ṣàfi hàn àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí.
التفاسير العربية:
وَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّبِعُواْ سَبِيلَنَا وَلۡنَحۡمِلۡ خَطَٰيَٰكُمۡ وَمَا هُم بِحَٰمِلِينَ مِنۡ خَطَٰيَٰهُم مِّن شَيۡءٍۖ إِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wí fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Ẹ tẹ̀lé ojú ọ̀nà tiwa nítorí kí á lè ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Wọn kò sì lè ru kiní kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.
التفاسير العربية:
وَلَيَحۡمِلُنَّ أَثۡقَالَهُمۡ وَأَثۡقَالٗا مَّعَ أَثۡقَالِهِمۡۖ وَلَيُسۡـَٔلُنَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ عَمَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ
Dájúdájú wọn yóò ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn àti àwọn ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ kan mọ́ ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn. Àti pé dájúdájú A óò bi wọ́n léèrè ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.[1]
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah an-Nahl; 16:25
التفاسير العربية:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا نُوحًا إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ فَلَبِثَ فِيهِمۡ أَلۡفَ سَنَةٍ إِلَّا خَمۡسِينَ عَامٗا فَأَخَذَهُمُ ٱلطُّوفَانُ وَهُمۡ ظَٰلِمُونَ
Dájúdájú A rán (Ànábì) Nūh níṣẹ́ sí ìjọ rẹ̀. Ó gbé láààrin wọn fún ẹgbẹ̀rún ọdún àfi àádọ́ta ọdún. Ẹ̀kún-omi sì gbá wọn mú nígbà tí wọ́n jẹ́ alábòsí.
التفاسير العربية:
فَأَنجَيۡنَٰهُ وَأَصۡحَٰبَ ٱلسَّفِينَةِ وَجَعَلۡنَٰهَآ ءَايَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ
A sì la òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.[1]
1. Ǹjẹ́ ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - di olúwa àti olùgbàlà nítorí pé Allāhu sọ nípa rẹ̀ pé “A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá”? Rárá. Kí ló wá rọ́lu àwọn kan tí wọ́n sọ Ànábì Īsā di olùgbàlà?
التفاسير العربية:
وَإِبۡرَٰهِيمَ إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱتَّقُوهُۖ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ
(Rántí Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Kí ẹ sì páyà Rẹ̀. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.”
التفاسير العربية:
إِنَّمَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡثَٰنٗا وَتَخۡلُقُونَ إِفۡكًاۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَمۡلِكُونَ لَكُمۡ رِزۡقٗا فَٱبۡتَغُواْ عِندَ ٱللَّهِ ٱلرِّزۡقَ وَٱعۡبُدُوهُ وَٱشۡكُرُواْ لَهُۥٓۖ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Ẹ kàn ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Ẹ sì ń dá àdápa irọ́. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, wọn kò ní ìkápá arísìkí kan fún yín. Ẹ wá arísìkí sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Kí ẹ jọ́sìn fún Un. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
التفاسير العربية:
وَإِن تُكَذِّبُواْ فَقَدۡ كَذَّبَ أُمَمٞ مِّن قَبۡلِكُمۡۖ وَمَا عَلَى ٱلرَّسُولِ إِلَّا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ
Tí ẹ bá sì pe (òdodo) ní irọ́, àwọn ìjọ kan tó ṣíwájú yín kúkú ti pe (òdodo) ní irọ́. Kò sì sí ojúṣe kan fún Òjíṣẹ́ bí kò ṣe ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú.
التفاسير العربية:
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ كَيۡفَ يُبۡدِئُ ٱللَّهُ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥٓۚ إِنَّ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٞ
Tàbí wọn kò wòye sí bí Allāhu ti ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá ni? Lẹ́yìn náà, O máa dá a padà (sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀). Dájúdájú ìyẹn rọrùn fún Allāhu.
التفاسير العربية:
قُلۡ سِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَٱنظُرُواْ كَيۡفَ بَدَأَ ٱلۡخَلۡقَۚ ثُمَّ ٱللَّهُ يُنشِئُ ٱلنَّشۡأَةَ ٱلۡأٓخِرَةَۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ
Sọ pé: “Ẹ rìn kiri lórí ilẹ̀, kí ẹ wo bí Ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá (ní ìpìlẹ̀). Lẹ́yìn náà, Allāhu l’Ó máa mú ìṣẹ̀dá ìkẹ́yìn wá (fún àjíǹde). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”
التفاسير العربية:
يُعَذِّبُ مَن يَشَآءُ وَيَرۡحَمُ مَن يَشَآءُۖ وَإِلَيۡهِ تُقۡلَبُونَ
Ó ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Ó sì ń kẹ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.[1]
1. Fífẹ́bẹ́ẹ̀ Allāhu dúró sórí déédé àti ìmọ̀ Rẹ̀ tó rọkiriká gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀.
التفاسير العربية:
وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِۖ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ
Àti pé ẹ̀yin kò níí mórí bọ́ mọ́ Allāhu lọ́wọ́ lórí ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀. Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَلِقَآئِهِۦٓ أُوْلَٰٓئِكَ يَئِسُواْ مِن رَّحۡمَتِي وَأُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ
Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu àti ìpàdé Rẹ̀ (lọ́run), àwọn wọ̀nyẹn ti sọ̀rètí nù nínú ìkẹ́ Mi. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún.
التفاسير العربية:
فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوۡمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُواْ ٱقۡتُلُوهُ أَوۡ حَرِّقُوهُ فَأَنجَىٰهُ ٱللَّهُ مِنَ ٱلنَّارِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n wí pé: “Ẹ pa á tàbí kí ẹ sun ún níná.” Allāhu sì gbà á là nínú iná. Dájúdájú àwọn àmì kúkú wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́ ní òdodo.
التفاسير العربية:
وَقَالَ إِنَّمَا ٱتَّخَذۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡثَٰنٗا مَّوَدَّةَ بَيۡنِكُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ ثُمَّ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَكۡفُرُ بَعۡضُكُم بِبَعۡضٖ وَيَلۡعَنُ بَعۡضُكُم بَعۡضٗا وَمَأۡوَىٰكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن نَّٰصِرِينَ
Ó sì sọ pé: “Ẹ kàn mú àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu, ní ohun tí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí (láti jọ́sìn fún) láààrin ara yín nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Lẹ́yìn náà, ní Ọjọ́ Àjíǹde apá kan yin yóò tako apá kan. Apá kan yín yó sì ṣẹ́bi lé apá kan. Iná sì ni ibùgbé yín. Kò sì níí sí àwọn alárànṣe kan fún yín.”
التفاسير العربية:
۞ فَـَٔامَنَ لَهُۥ لُوطٞۘ وَقَالَ إِنِّي مُهَاجِرٌ إِلَىٰ رَبِّيٓۖ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
(Ànábì) Lūt sì gbà á gbọ́. (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Dájúdájú èmi yóò fi ìlú yìí sílẹ̀ nítorí ti Olúwa mi.[1] Dájúdájú Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
1. Ó fi ilẹ̀ ‘Irāƙ sílẹ̀. Ó sì wá sí ilẹ̀ Ṣām. Èyí ni a mọ̀ sí hijrah.
التفاسير العربية:
وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَجَعَلۡنَا فِي ذُرِّيَّتِهِ ٱلنُّبُوَّةَ وَٱلۡكِتَٰبَ وَءَاتَيۡنَٰهُ أَجۡرَهُۥ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَإِنَّهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
A fi ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ rẹ̀) ta á lọ́rẹ. A sì ṣe ipò jíjẹ́ Ànábì àti fífúnni ní tírà sínú àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀. A fún un ní ẹ̀san rẹ̀ ní ayé yìí. Dájúdájú ní ọ̀run, ó tún wà nínú àwọn ẹni rere.
التفاسير العربية:
وَلُوطًا إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ إِنَّكُمۡ لَتَأۡتُونَ ٱلۡفَٰحِشَةَ مَا سَبَقَكُم بِهَا مِنۡ أَحَدٖ مِّنَ ٱلۡعَٰلَمِينَ
(Rántí Ànábì) Lūt. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ń ṣe ìbàjẹ́ tí kò sí ẹnì kan nínú ẹ̀dá tí ó ṣe é rí ṣíwájú yín.
التفاسير العربية:
أَئِنَّكُمۡ لَتَأۡتُونَ ٱلرِّجَالَ وَتَقۡطَعُونَ ٱلسَّبِيلَ وَتَأۡتُونَ فِي نَادِيكُمُ ٱلۡمُنكَرَۖ فَمَا كَانَ جَوَابَ قَوۡمِهِۦٓ إِلَّآ أَن قَالُواْ ٱئۡتِنَا بِعَذَابِ ٱللَّهِ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ
Ṣé dájúdájú ẹ̀yin (ọkùnrin) yóò máa tọ àwọn ọkùnrin (ẹgbẹ́ yín) lọ (fún adùn ìbálòpọ̀), ẹ tún ń dánà, ẹ tún ń ṣe ohun burúkú nínú àkójọ yín? Èsì ìjọ rẹ̀ kò jẹ́ kiní kan àfi kí wọ́n wí pé[1]: “Mú ìyà Allāhu wá fún wa tí o bá wà nínú àwọn olódodo.”
1. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé, ìjọ rẹ̀ kì í sọ ọ̀rọ̀ mìíràn láti fi takò ó. Àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu wọ́n máa ń dá lérí “mú ìyà wá”.
التفاسير العربية:
قَالَ رَبِّ ٱنصُرۡنِي عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُفۡسِدِينَ
Ó sọ pé: “Olúwa mi, ṣàrànṣe fún mí lórí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
التفاسير العربية:
وَلَمَّا جَآءَتۡ رُسُلُنَآ إِبۡرَٰهِيمَ بِٱلۡبُشۡرَىٰ قَالُوٓاْ إِنَّا مُهۡلِكُوٓاْ أَهۡلِ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِۖ إِنَّ أَهۡلَهَا كَانُواْ ظَٰلِمِينَ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa sì mú ìró ìdùnnú dé bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, wọ́n sọ pé: “Dájúdájú àwa máa pa àwọn ará ìlú yìí run. Dájúdájú àwọn ará ìlú náà jẹ́ alábòsí.”
التفاسير العربية:
قَالَ إِنَّ فِيهَا لُوطٗاۚ قَالُواْ نَحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَن فِيهَاۖ لَنُنَجِّيَنَّهُۥ وَأَهۡلَهُۥٓ إِلَّا ٱمۡرَأَتَهُۥ كَانَتۡ مِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ
Ó sọ pé: “Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà níbẹ̀! Wọ́n sọ pé: “Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó wà níbẹ̀. Dájúdájú àwa yóò la òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ àfi ìyàwó rẹ̀ tí ó máa wà nínú àwọn tó máa ṣẹ́kù lẹ́yìn sínú ìparun.”
التفاسير العربية:
وَلَمَّآ أَن جَآءَتۡ رُسُلُنَا لُوطٗا سِيٓءَ بِهِمۡ وَضَاقَ بِهِمۡ ذَرۡعٗاۖ وَقَالُواْ لَا تَخَفۡ وَلَا تَحۡزَنۡ إِنَّا مُنَجُّوكَ وَأَهۡلَكَ إِلَّا ٱمۡرَأَتَكَ كَانَتۡ مِنَ ٱلۡغَٰبِرِينَ
Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ Wa dé ọ̀dọ̀ (Ànábì) Lūt, ó banújẹ́ nítorí wọn. Agbára rẹ̀ kò sì ká ọ̀rọ̀ wọn mọ́. Wọ́n sì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, má sì ṣe banújẹ́. Dájúdájú a máa la ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ àfi ìyàwó rẹ tí ó máa wà nínú àwọn olùṣẹ́kù-lẹ́yìn sínú ìparun.”
التفاسير العربية:
إِنَّا مُنزِلُونَ عَلَىٰٓ أَهۡلِ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِ رِجۡزٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ
Dájúdájú a máa sọ ìyà kan kalẹ̀ lé àwọn ará ìlú yìí lórí láti inú sánmọ̀ nítorí pé, wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.
التفاسير العربية:
وَلَقَد تَّرَكۡنَا مِنۡهَآ ءَايَةَۢ بَيِّنَةٗ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ
Dájúdájú A ti fi àmì kan tó fojú hàn lélẹ̀ nínú rẹ̀ fún ìjọ tó ní làákàyè.
التفاسير العربية:
وَإِلَىٰ مَدۡيَنَ أَخَاهُمۡ شُعَيۡبٗا فَقَالَ يَٰقَوۡمِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ وَٱرۡجُواْ ٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ
A tún ránṣẹ́ sí ará ìlú Mọdyan. (A rán) arákùnrin wọn, (Ànábì) Ṣu‘aeb (níṣẹ́ sí wọn). Ó sì sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ retí Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.”
التفاسير العربية:
فَكَذَّبُوهُ فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلرَّجۡفَةُ فَأَصۡبَحُواْ فِي دَارِهِمۡ جَٰثِمِينَ
Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, ohùn igbe líle tó mi ilẹ̀ tìtì gbá wọn mú. Wọ́n sì di ẹni tó dà lulẹ̀, tí wọ́n ti dòkú sínú ìlú wọn.
التفاسير العربية:
وَعَادٗا وَثَمُودَاْ وَقَد تَّبَيَّنَ لَكُم مِّن مَّسَٰكِنِهِمۡۖ وَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَعۡمَٰلَهُمۡ فَصَدَّهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَكَانُواْ مُسۡتَبۡصِرِينَ
(A tún ránṣẹ́ sí àwọn) ará ‘Ād àti ará Thamūd. (Ìparun wọn) sì kúkú ti fojú hàn kedere si yín nínú àwọn ibùgbé wọn. aṣ-Ṣaetọ̄n ṣe àwọn iṣẹ́ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Ó sì ṣẹ́rí wọn kúrò nínú ẹ̀sìn (Allāhu). Wọ́n sì jẹ́ olùríran (nípa ọ̀rọ̀ ayé).
التفاسير العربية:
وَقَٰرُونَ وَفِرۡعَوۡنَ وَهَٰمَٰنَۖ وَلَقَدۡ جَآءَهُم مُّوسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا كَانُواْ سَٰبِقِينَ
(A tún ránṣẹ́ sí àwọn) Ƙọ̄rūn, Fir‘aon àti Hāmọ̄n. Dájúdájú (Ànábì) Mūsā mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Wọ́n sì ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Wọn kò sì lè mórí bọ́ nínú ìyà.
التفاسير العربية:
فَكُلًّا أَخَذۡنَا بِذَنۢبِهِۦۖ فَمِنۡهُم مَّنۡ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِ حَاصِبٗا وَمِنۡهُم مَّنۡ أَخَذَتۡهُ ٱلصَّيۡحَةُ وَمِنۡهُم مَّنۡ خَسَفۡنَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ وَمِنۡهُم مَّنۡ أَغۡرَقۡنَاۚ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيَظۡلِمَهُمۡ وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ
A sì mú ìkọ̀ọ̀kan wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó wà nínú wọn, ẹni tí A fi òkúta iná ránṣẹ́ sí. Ó wà nínú wọn ẹni tí igbe líle gbá mú. Ó wà nínú wọn ẹni tí A jẹ́ kí ilẹ̀ ríri gbé e mì. Ó sì wà nínú wọn ẹni tí A tẹ̀rì sínú omi. Allāhu kò sì níí ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.
التفاسير العربية:
مَثَلُ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡلِيَآءَ كَمَثَلِ ٱلۡعَنكَبُوتِ ٱتَّخَذَتۡ بَيۡتٗاۖ وَإِنَّ أَوۡهَنَ ٱلۡبُيُوتِ لَبَيۡتُ ٱلۡعَنكَبُوتِۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ
Àpèjúwe àwọn tó mú àwọn (òrìṣà) ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Allāhu, ó dà bí àpèjúwe aláǹtàakùn tí ó kọ́ ilé kan. Dájúdájú ilé tí ó yẹpẹrẹ jùlọ ni ilé aláǹtàakùn, tí wọ́n bá mọ̀.
التفاسير العربية:
إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦ مِن شَيۡءٖۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ
Dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.
التفاسير العربية:
وَتِلۡكَ ٱلۡأَمۡثَٰلُ نَضۡرِبُهَا لِلنَّاسِۖ وَمَا يَعۡقِلُهَآ إِلَّا ٱلۡعَٰلِمُونَ
Àwọn àkàwé wọ̀nyí, À ń fún àwọn ènìyàn ni, kò sì sí ẹni tí ó máa ṣe làákàyè nípa rẹ̀ àfi àwọn onímọ̀.
التفاسير العربية:
خَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ
Allāhu ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àmì kan wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
التفاسير العربية:
ٱتۡلُ مَآ أُوحِيَ إِلَيۡكَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَۖ إِنَّ ٱلصَّلَوٰةَ تَنۡهَىٰ عَنِ ٱلۡفَحۡشَآءِ وَٱلۡمُنكَرِۗ وَلَذِكۡرُ ٱللَّهِ أَكۡبَرُۗ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تَصۡنَعُونَ
Ké ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú Tírà. Kí o sì kírun. Dájúdájú ìrun kíkí ń kọ ìwà ìbàjẹ́ àti aburú. Àti pé ìrántí Allāhu tóbi jùlọ. Allāhu sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe.[1]
1. Gbólóhùn yìí “ولذكر الله أكبر” kò túmọ̀ sí gbígbé sọlāt jù sílẹ̀ torí ṣíṣe adhikir.
التفاسير العربية:
۞ وَلَا تُجَٰدِلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡۖ وَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ إِلَيۡنَا وَأُنزِلَ إِلَيۡكُمۡ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمۡ وَٰحِدٞ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ
Ẹ má ṣe bá àwọn onítírà ṣàríyàn jiyàn àfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ (èyí ni lílo al-Ƙur’ān àti hadīth. Ẹ má sì ṣe jà wọ́n lógun) àfi àwọn tó bá ṣàbòsí nínú wọn.[1] Kí ẹ sì sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ẹ̀yin. Ọlọ́hun wa àti Ọlọ́hun yín, (Allāhu) Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”
1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé alábòsí wulẹ̀ ni gbogbo àwọn onítírà, àbòsí mìíràn ni Allāhu ń tọ́ka sí lára wọn nínú āyah yìí.
التفاسير العربية:
وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَۚ فَٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۖ وَمِنۡ هَٰٓؤُلَآءِ مَن يُؤۡمِنُ بِهِۦۚ وَمَا يَجۡحَدُ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَّا ٱلۡكَٰفِرُونَ
Báyẹn ni A ṣe sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ. Nítorí náà, àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n gbà á gbọ́.[1] Ó sì wà nínú àwọn wọ̀nyí (ìyẹn, àwọn ará Mọkkah), ẹni tó gbà á gbọ́. Kò sì sí ẹni tó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn aláìgbàgbọ́.
1. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí Allāhu sọ nípa wọn nínú sūrah al-Ƙọsọs; 28:52 - 55. -.
التفاسير العربية:
وَمَا كُنتَ تَتۡلُواْ مِن قَبۡلِهِۦ مِن كِتَٰبٖ وَلَا تَخُطُّهُۥ بِيَمِينِكَۖ إِذٗا لَّٱرۡتَابَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ
Ìwọ kò ké tírà kan rí ṣíwájú al-Ƙur’ān, ìwọ kò sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ kọ n̄ǹkan rí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, kí àwọn òpùrọ́ ṣeyèméjì (sí al-Ƙur’ān).
التفاسير العربية:
بَلۡ هُوَ ءَايَٰتُۢ بَيِّنَٰتٞ فِي صُدُورِ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَۚ وَمَا يَجۡحَدُ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَّا ٱلظَّٰلِمُونَ
Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó. al-Ƙur’ān), òhun ni àwọn āyah tó yanjú nínú igbá-àyà àwọn tí A fún ní ìmọ̀-ẹ̀sìn. Kò sì sí ẹni tó ń tako àwọn āyah Wa àfi àwọn alábòsí.
التفاسير العربية:
وَقَالُواْ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ ءَايَٰتٞ مِّن رَّبِّهِۦۚ قُلۡ إِنَّمَا ٱلۡأٓيَٰتُ عِندَ ٱللَّهِ وَإِنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٞ مُّبِينٌ
Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ àwọn àmì (ìyanu) kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà lọ́dọ̀ Rẹ̀. Àti pé olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni èmi.”
التفاسير العربية:
أَوَلَمۡ يَكۡفِهِمۡ أَنَّآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡكِتَٰبَ يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَرَحۡمَةٗ وَذِكۡرَىٰ لِقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ
Ṣé kò tó fún wọn (ní àmì ìyanu) pé A sọ tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ fún ọ, tí wọ́n ń ké e fún wọn? Dájúdájú ìkẹ́ àti ìrántí wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó gbàgbọ́.
التفاسير العربية:
قُلۡ كَفَىٰ بِٱللَّهِ بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡ شَهِيدٗاۖ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱلۡبَٰطِلِ وَكَفَرُواْ بِٱللَّهِ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ
Sọ pé: “Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin. Ó mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn tó gba irọ́ (òrìṣà) gbọ́, tí wọ́n sì ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu; àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.
التفاسير العربية:
وَيَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَلَوۡلَآ أَجَلٞ مُّسَمّٗى لَّجَآءَهُمُ ٱلۡعَذَابُۚ وَلَيَأۡتِيَنَّهُم بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Wọ́n sì ń kán ọ lójú nípa ìyà! Tí kò bá jẹ́ pé ó ti ní gbèdéke àkókò kan ni, ìyà náà ìbá kúkú dé bá wọn. (Ìyà) ìbá dé bá wọn ní òjijì sẹ́, tí wọn kò sì níí fura.
التفاسير العربية:
يَسۡتَعۡجِلُونَكَ بِٱلۡعَذَابِ وَإِنَّ جَهَنَّمَ لَمُحِيطَةُۢ بِٱلۡكَٰفِرِينَ
Wọ́n ń kán ọ lójú nípa ìyà! Dájúdájú iná Jahanamọ kúkú máa yí àwọn aláìgbàgbọ́ po.
التفاسير العربية:
يَوۡمَ يَغۡشَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِن فَوۡقِهِمۡ وَمِن تَحۡتِ أَرۡجُلِهِمۡ وَيَقُولُ ذُوقُواْ مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
(Rántí) ọjọ́ tí ìyà yóò bò wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn àti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, (Allāhu) sì máa sọ pé: “Ẹ tọ́ (ìyà) ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ wò.”
التفاسير العربية:
يَٰعِبَادِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّ أَرۡضِي وَٰسِعَةٞ فَإِيَّٰيَ فَٱعۡبُدُونِ
Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ilẹ̀ Mi gbòòrò. Nítorí náà, Èmi nìkan ni kí ẹ jọ́sìn fún.
التفاسير العربية:
كُلُّ نَفۡسٖ ذَآئِقَةُ ٱلۡمَوۡتِۖ ثُمَّ إِلَيۡنَا تُرۡجَعُونَ
Gbogbo ẹ̀mí l’ó máa tọ́ ikú wò. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni wọn yóò da yín padà sí.
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَنُبَوِّئَنَّهُم مِّنَ ٱلۡجَنَّةِ غُرَفٗا تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ نِعۡمَ أَجۡرُ ٱلۡعَٰمِلِينَ
Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, dájúdájú A máa fi wọn sínú àwọn ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì gígá kan nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ẹ̀san àwọn olùṣe-rere sì dára.
التفاسير العربية:
ٱلَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَلَىٰ رَبِّهِمۡ يَتَوَكَّلُونَ
(Àwọn ni) àwọn tó ṣe sùúrù. Olúwa wọn sì ni wọ́n ń gbáralé.
التفاسير العربية:
وَكَأَيِّن مِّن دَآبَّةٖ لَّا تَحۡمِلُ رِزۡقَهَا ٱللَّهُ يَرۡزُقُهَا وَإِيَّاكُمۡۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ
Mélòó mélòó nínú àwọn ẹranko tí kò lè dá bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀ gbé, tí Allāhu sì ń ṣe ìjẹ-ìmu fún àwọn àti ẹ̀yin. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.
التفاسير العربية:
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَسَخَّرَ ٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, tí Ó sì rọ òòrùn àti òṣùpá?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
التفاسير العربية:
ٱللَّهُ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦ وَيَقۡدِرُ لَهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ
Allāhu l’Ó ń tẹ́ ọrọ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ó sì ń díwọ̀n rẹ̀ fún ẹlòmíìràn. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
التفاسير العربية:
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّن نَّزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ مِنۢ بَعۡدِ مَوۡتِهَا لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۚ قُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ
Tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí Ó fi ta ilẹ̀ jí lẹ́yìn tí ó ti kú?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.”
التفاسير العربية:
وَمَا هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا لَهۡوٞ وَلَعِبٞۚ وَإِنَّ ٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَ لَهِيَ ٱلۡحَيَوَانُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ
Kí ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìranù àti eré ṣíṣe. Àti pé dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn sì ni ìṣẹ̀mí gbére tí wọ́n bá mọ̀.
التفاسير العربية:
فَإِذَا رَكِبُواْ فِي ٱلۡفُلۡكِ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ فَلَمَّا نَجَّىٰهُمۡ إِلَى ٱلۡبَرِّ إِذَا هُمۡ يُشۡرِكُونَ
Nígbà tí wọ́n bá gun ọkọ̀ ojú-omi, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1] Àmọ́ nígbà tí Ó bá gbà wọ́n là sí orí ilẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa ṣẹbọ
1. Ẹ wo sūrah Yūnus; 10:22 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀.
التفاسير العربية:
لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ وَلِيَتَمَتَّعُواْۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ
nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè jayékáyé. Nítorí náà, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
التفاسير العربية:
أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا جَعَلۡنَا حَرَمًا ءَامِنٗا وَيُتَخَطَّفُ ٱلنَّاسُ مِنۡ حَوۡلِهِمۡۚ أَفَبِٱلۡبَٰطِلِ يُؤۡمِنُونَ وَبِنِعۡمَةِ ٱللَّهِ يَكۡفُرُونَ
Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa ṣe Haram (Mọkkah) ni àyè ìfàyàbalẹ̀, tí wọ́n sì ń jí àwọn ènìyàn gbé lọ ní àyíká wọn? Ṣé irọ́ (òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, tí wọn yó sì ṣàì moore sí ìdẹ̀ra Allāhu?
التفاسير العربية:
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ كَذَّبَ بِٱلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُۥٓۚ أَلَيۡسَ فِي جَهَنَّمَ مَثۡوٗى لِّلۡكَٰفِرِينَ
Ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tàbí tó pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé inú iná Jahanamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni?
التفاسير العربية:
وَٱلَّذِينَ جَٰهَدُواْ فِينَا لَنَهۡدِيَنَّهُمۡ سُبُلَنَاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَمَعَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Àwọn tó gbìyànjú nípa Wa, dájúdájú A máa fi wọ́n mọ àwọn ọ̀nà Wa. Àti pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olúṣe-rere.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني سورة: العنكبوت
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق