ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (13) سورة: آل عمران
قَدۡ كَانَ لَكُمۡ ءَايَةٞ فِي فِئَتَيۡنِ ٱلۡتَقَتَاۖ فِئَةٞ تُقَٰتِلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَأُخۡرَىٰ كَافِرَةٞ يَرَوۡنَهُم مِّثۡلَيۡهِمۡ رَأۡيَ ٱلۡعَيۡنِۚ وَٱللَّهُ يُؤَيِّدُ بِنَصۡرِهِۦ مَن يَشَآءُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ
Àmì kúkú wà fún yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn lójú ogun). Ìjọ kan ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu (fún ààbò ẹ̀sìn). Aláìgbàgbọ́ sì ni ìjọ kejì tí ó ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú.¹ Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùríran.
1. Ní ojú ogun Badr ni àrànṣe Allāhu ti dé bá àwọn mùsùlùmí. Òǹkà àwọn mùsùlùmí jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́tàlá (313), òǹkà àwọn ọ̀ṣẹbọ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti àádọ́ta (950). Àmọ́ àwọn ọ̀ṣẹbọ ń rí òǹkà àwọn mùsùlùmí ní rírí ojú bí ìlọ́po méjì òǹkà wọn, ìyẹn ni pé, wọ́n ń rí òǹkà àwọn mùsùlùmí bí ẹgbẹ̀rún méjì.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (13) سورة: آل عمران
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق