ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (59) سورة: آل عمران
إِنَّ مَثَلَ عِيسَىٰ عِندَ ٱللَّهِ كَمَثَلِ ءَادَمَۖ خَلَقَهُۥ مِن تُرَابٖ ثُمَّ قَالَ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ
Dájúdájú irú ‘Īsā lọ́dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam; (Allāhu) dá a láti ara erùpẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì jẹ́ bẹ́ẹ̀.¹
1. Àwọn kan sọ pé, “Ìjọra mélòó gan-an l’ó wà láààrin ‘Īsā ọmọ Mọryam àti Adam tó fi tó sọ pé, ‘Dájúdájú irú ‘Īsā ní ọ̀dọ̀ Allāhu dà bí irú Ādam!” Èsì: Bí ó bá jẹ́ pé ìyàtọ̀ púpọ̀ wà láààrin Ànábì Ādam àti Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá àwọn méjèèjì -, Allāhu kò níí fi ìkíní wé ìkejì. Ṣebí ẹ̀dá Allāhu, ẹrú Allāhu àti Ànábì Allāhu ni àwọn méjèèjì. Àwọn méjèèjì kò sì dìjọ ní bàbá. Kódà Ànábì Ādam kò tún ní ìyá. Maryam sì ni ìyá ‘Īsa - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Àmọ́ sísọ tí àwọn nasọ̄rọ̄ sọ Ànábì ‘Īsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - di olúwa wọn, olùgbàlà wọn, ọmọ Ọlọ́hun àti ọlọ́hun ọmọ ní ti irọ́ àti ìparọ́mọ́ni ni wọ́n fi ń lérò pé irú Ànábì ‘Īsā kọ́ ni irú Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a '.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (59) سورة: آل عمران
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق