ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (79) سورة: النساء
مَّآ أَصَابَكَ مِنۡ حَسَنَةٖ فَمِنَ ٱللَّهِۖ وَمَآ أَصَابَكَ مِن سَيِّئَةٖ فَمِن نَّفۡسِكَۚ وَأَرۡسَلۡنَٰكَ لِلنَّاسِ رَسُولٗاۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدٗا
Ohunkóhun tó bá tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nínú oore, láti ọ̀dọ̀ Allāhu ni. Ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹlẹ̀ sí ọ nínú aburú, láti ọ̀dọ̀ ara rẹ ni. A rán ọ níṣẹ́ pé kí o jẹ́ Òjíṣẹ́ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.¹
1. Èbùbù, àyànmọ́ àti kádàrá ń túmọ̀ ara wọn. Ohun rere tí ó máa tẹ ẹ̀dá lọ́wọ́ àti aburú tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá láyé àti lọ́run pẹ̀lú ọ̀nà tí ó máa gbà ṣẹlẹ̀ ni kìkìdá kádàrá ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - l’Ó pébùbù fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Òun l’Ó yan àyànmọ́ fún wa. Láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni orísun gbogbo rẹ̀ ti ṣẹ̀ wá pẹ̀lú déédé Rẹ̀ àti ọlá Rẹ̀ lórí wa nítorí pé, kì í ṣe Ọba alábòsí. Kò sì ṣe é pè lẹ́jọ́. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń tọ́ka sí nínú āyah 78. Àmọ́ nígbà tí ẹ̀dá tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fún ní ẹ̀ṣà bá ṣẹ̀ṣà iṣẹ́ rere, ó máa dúpẹ́ fún Allāhu ni. Nígbà tí ẹ̀dá tí Allāhu fún ní ẹ̀ṣà bá sì ṣẹ̀ṣà iṣẹ́ aburú, òun fúnra rẹ̀ ló fọwọ́ ara rẹ̀ fa aburú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ dídá tó ṣà lẹ́ṣà. Èyí ni Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ń tọ́ka sí nínú āyah 79 àti nínú sūrah aṣ-Ṣūrọ̄; 42:30.
Bákan náà, Èṣù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lè ṣẹ̀ṣà láti nawọ́ aburú sí ènìyàn, ìyẹn sì ni ogun Èṣù. Èyí ni Allāhu ń tọ́ka sí nínú sūrah Sọ̄d; 38:41. Àmọ́ sá, kì í ṣe Èṣù ni a máa bẹ̀, kì í ṣe ìyọ́nú ayé tàbí ẹ̀bẹ̀ àwọn àgbà la máa ṣe bí kò ṣe wíwá ìyọ́nú Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nípa ìṣẹ̀ṣà ìtẹ̀lé àṣẹ Rẹ̀, ìdojú àdúà kọ Ọ́ àti wíwá ààbò ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Ní ṣókí, gbogbo ohun tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ti wà nínú kádàrá rẹ̀, àmọ́ ó lè ṣẹlẹ̀ tààrà láti ọ̀dọ̀ Allāhu sí ọ̀dọ̀ ẹ̀dá, tàbí kí Allāhu gbé e gba ọ̀nà sábàbí bíi àfọwọ́fà tàbí àkóbá láti ọ̀dọ̀ ẹ̀dá mìíràn. W-Allāhu-l-musta‘ān.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (79) سورة: النساء
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق