ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (128) سورة: الأنعام
وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا يَٰمَعۡشَرَ ٱلۡجِنِّ قَدِ ٱسۡتَكۡثَرۡتُم مِّنَ ٱلۡإِنسِۖ وَقَالَ أَوۡلِيَآؤُهُم مِّنَ ٱلۡإِنسِ رَبَّنَا ٱسۡتَمۡتَعَ بَعۡضُنَا بِبَعۡضٖ وَبَلَغۡنَآ أَجَلَنَا ٱلَّذِيٓ أَجَّلۡتَ لَنَاۚ قَالَ ٱلنَّارُ مَثۡوَىٰكُمۡ خَٰلِدِينَ فِيهَآ إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٞ
(Rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, (Ó máa sọ pé): “Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú, dájúdájú ẹ ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sọnù.” Àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú àwọn ènìyàn yóò wí pé: “Olúwa wa, apá kan wa gbádùn apá kan ni. A sì ti lo àsìkò wa tí O bù fún wa (láti lò).” (Allāhu) sọ pé: “Iná ni ibùgbé yín; olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀ àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́¹. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
1. Kíyè sí i, āyah yìí kò sọ pé “ إن شاء الله - tí Allāhu bá fẹ́ -.” Ohun tí ó sọ ni pé “إِلَّا مَا شَآءَ - àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́ -.” Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ìtúmọ̀ fún “àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́” :
(Ìkíní) àfi tí Allāhu bá fẹ́ so ìyà wọn rọ̀ fún ọ̀wọ́ àsìkò Àjíǹde láti inú sàréè àti ní àsìkò Ìdájọ́.
(Ìkejì) àfi tí Allāhu bá fẹ́ fi ìran ìyà mìíràn jẹ wọ́n pẹ̀lú ìyà Iná. (Ìkẹta) àfi tí Allāhu bá fẹ́ gba ìṣìpẹ̀ fún àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn kò bàjẹ́, ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n, tí wọ́n sì ti ipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ wà nínú Iná pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.
(Ìkẹrin) àfi tí Allāhu bá fẹ́ fi àánú Rẹ̀ nìkan la àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn kò bàjẹ́, ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n, tí wọ́n sì ti ipasẹ̀ bẹ́ẹ̀ wà nínú Iná pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.
Èyí wà ní ìbámu sí hadīth ’Anas, láti ọ̀dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, ó sọ pé: “Ọwọ́jà Iná yóò ba àwọn ènìyàn kan nípasẹ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tí wọ́n dá, (Iná yó sì jẹ́) ìyà (fún wọn). Lẹ́yìn náà, Allāhu yóò fi ìkẹ́ àjùlọ Rẹ̀ mú wọn wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n á sì máa pè wọ́n ni Jahanamiyyūn.” (al-Bukāriy;7012, Tafsīr al-Ƙurtubiy).
Nítorí náà, tí ó bá jẹ́ pé ohun tí āyah náà sọ ni pé “tí Allāhu bá fẹ́”, a ò bá sọ pé kò dájú pé gbére ni Iná ọ̀run fún àwọn aláìgbàgbọ́. Àmọ́ āyah náà kò sọ pé “tí Allāhu bá fẹ́.”
Bákan náà, “àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́” kò túmọ̀ sí pé kò níí sí olùṣegbére nínú Iná. Nítorí pé, o ti rinlẹ̀ nínú àwọn āyah mìíràn pé, kò sí àforíjìn Allāhu fún ẹni tí ó bá kú sórí ẹbọ ṣíṣe, àìgbàgbọ́ àti ìṣọ̀bẹ-ṣèlu, yálà nípasẹ̀ àṣepọ̀ láààrin ènìyàn àti àlùjànnú tàbí ní ọ̀nà mìíràn. Àwọn wọ̀nyí sì ni olùṣegbére nínú Iná. Ẹ ka àlàyé yìí síwájú sí i nínú ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Hūd 11; 108 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah as-Sajdah; 32:20.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (128) سورة: الأنعام
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق