ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية * - فهرس التراجم

PDF XML CSV Excel API
تنزيل الملفات يتضمن الموافقة على هذه الشروط والسياسات

ترجمة معاني آية: (36) سورة: التوبة
إِنَّ عِدَّةَ ٱلشُّهُورِ عِندَ ٱللَّهِ ٱثۡنَا عَشَرَ شَهۡرٗا فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ يَوۡمَ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ مِنۡهَآ أَرۡبَعَةٌ حُرُمٞۚ ذَٰلِكَ ٱلدِّينُ ٱلۡقَيِّمُۚ فَلَا تَظۡلِمُواْ فِيهِنَّ أَنفُسَكُمۡۚ وَقَٰتِلُواْ ٱلۡمُشۡرِكِينَ كَآفَّةٗ كَمَا يُقَٰتِلُونَكُمۡ كَآفَّةٗۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ
Dájúdájú òǹkà àwọn oṣù lọ́dọ̀ Allāhu ń jẹ́ oṣù méjìlá nínú àkọsílẹ̀ ti Allāhu ní ọjọ́ tí Ó ti dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Mẹ́rin ni oṣù ọ̀wọ̀ nínú rẹ̀.¹ Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀.² Nítorí náà, ẹ má ṣàbòsí sí ara yín nínú àwọn oṣù ọ̀wọ̀. Kí gbogbo yín sì gbógun ti àwọn ọ̀ṣẹbọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo wọn ṣe ń gbógun tì yín. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).
1. Àwọn oṣù ọ̀wọ̀ ni oṣù kìíní, Muharram; oṣú keje, Rajab; oṣù kọkànlá, Thul-Ƙọ‘dah àti oṣù kejìlá, Thul-Hijjah.
2. Ìyẹn ni pé, lára ẹ̀sìn àti ìjọ́sìn ’Islām ni lílo àwọn oṣù wọ̀nyí nítorí pé, oṣù náà ni à ń lò fún jíjọ́sìn fún Allāhu - subhānahu -. Bí àpẹ̀ẹrẹ, à ń kí ìrun Jum‘ah ní ọjọ́ Jum‘ah, à ń gba ààwẹ̀ Rọmọdọ̄n nínú oṣù Rọmọdọ̄n, a sì ń ṣe iṣẹ́ hajj nínú oṣù Thul-Hijjah.
التفاسير العربية:
 
ترجمة معاني آية: (36) سورة: التوبة
فهرس السور رقم الصفحة
 
ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - فهرس التراجم

ترجمة معاني القرآن الكريم إلى اللغة اليوربا، ترجمها الشيخ أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني. طبعة عام 1432هـ .

إغلاق