আল-কোৰআনুল কাৰীমৰ অৰ্থানুবাদ - ইউৰুবা অনুবাদ * - অনুবাদসমূহৰ সূচীপত্ৰ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

অৰ্থানুবাদ ছুৰা: ছুৰা আচ-চা-ফফা-ত   আয়াত:

Suuratu Sooffaat

وَٱلصَّٰٓفَّٰتِ صَفّٗا
Allāhu fi àwọn mọlāika tí ó ń tò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ búra.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَٱلزَّٰجِرَٰتِ زَجۡرٗا
Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń wọ́ ẹ̀ṣújò kiri tààrà bura.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَٱلتَّٰلِيَٰتِ ذِكۡرًا
Allāhu tún fi àwọn mọlāika tó ń ka ìrántí bura.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّ إِلَٰهَكُمۡ لَوَٰحِدٞ
Dájúdájú ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَرَبُّ ٱلۡمَشَٰرِقِ
Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Òun sì ni Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّا زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِزِينَةٍ ٱلۡكَوَاكِبِ
Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَحِفۡظٗا مِّن كُلِّ شَيۡطَٰنٖ مَّارِدٖ
àti ìṣọ́ kúrò níbi (aburú) gbogbo èṣù olóríkunkun.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
لَّا يَسَّمَّعُونَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰ وَيُقۡذَفُونَ مِن كُلِّ جَانِبٖ
(Àwọn èṣù) kò sì níí lè tẹ́tí sí ìjọ (mọlāika tó wà ní) àyè gíga jùlọ (nínú sánmọ̀. Bí wọ́n bá sì gbìyànjú láti yọ́ ọ̀rọ̀ gbọ́ láti sánmọ̀, àwọn mọlāika) yó sì máa kù wọ́n lókò (ẹ̀ta ìràwọ̀) ní gbogbo agbègbè (sánmọ̀).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
دُحُورٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٞ وَاصِبٌ
Wọ́n máa lé wọn dànù. Ìyà àìlópin sì wà fún wọn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا مَنۡ خَطِفَ ٱلۡخَطۡفَةَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٞ ثَاقِبٞ
(Wọn kò níí gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́) àyàfi ẹni tí ó bá rí ọ̀rọ̀ àjígbọ́ gbé, nígbà náà (ni mọlāika) yó sì fi ẹ̀ta ìràwọ̀ iná tó máa jó o tẹ̀lé e.¹
1. Àwọn èṣù àlùjànnú máa ń gbé ara wọn gunra wọn láti lè súnmọ́ etí sánmọ̀ ilé ayé. Bí wọ́n bá bá àwọn mọlāika lórí àwọn ìro kan tí Allāhu fi ránṣẹ́ sí wọn, wọ́n máa jí i gbọ́. Níkété tí àwọn mọlāika bá fura sí wọn, wọ́n máa fi adó olóró ẹta ìràwọ̀ tú wọn ká. Nígbà mìíràn, àwọn èṣù àlùjànnú yìí yóò ti ṣe àtagbà ìró náà síra wọn tán ṣíwájú kí wọ́n tó tú wọn ká. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó wà lókè pátápátá nínú wọn, kò níí tí ì ṣe àtagbà ìró sí àwọn yòókù rẹ̀ ṣíwájú kí wọ́n tó tú wọn ká. Èyí tí wọ́n bá jàjà rí jí gbé lọ, wọ́n máa lọ kọ bí àkùkọ sínú etí àwọn ẹni wọn nínú àwọn èṣù ènìyàn tí wọ́n yẹsẹ́ wò. Wọ́n sì máa fi irọ́ ọgọ́rùn-ún kún un fúnra wọn ní ọ̀dọ̀ àwọn tó ń pawọ́ dà, tí wọ́n ń yẹsẹ́ wò.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَهُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَم مَّنۡ خَلَقۡنَآۚ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّن طِينٖ لَّازِبِۭ
Bi wọ́n léèrè wò pé, ṣé àwọn (ènìyàn) ni ìṣẹ̀dá wọn lágbára jùlọ ni tàbí àwọn (n̄ǹkan mìíràn)¹ tí A dá? Dájúdájú Àwa dá àwọn (ènìyàn) láti ara ẹrẹ̀ tó lẹ̀ mọ́ra wọn.
1. Àwọn n̄ǹkan mìíràn bíi àwọn sánmọ̀, àwọn ilẹ̀, àwọn mọlāika àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
بَلۡ عَجِبۡتَ وَيَسۡخَرُونَ
Rárá (kò jọra wọn); ìwọ ṣèèmọ̀ (nípa al-Ƙur’ān), àwọn sì ń ṣe yẹ̀yẹ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِذَا ذُكِّرُواْ لَا يَذۡكُرُونَ
Àti pé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrántí fún wọn, wọn kò níí lo ìrántí.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِذَا رَأَوۡاْ ءَايَةٗ يَسۡتَسۡخِرُونَ
Nígbà tí wọ́n bá tún rí àmì kan, wọn yóò máa ṣe yẹ̀yẹ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَقَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٌ
Wọ́n sì wí pé: “Èyí kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبۡعُوثُونَ
Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَوَءَابَآؤُنَا ٱلۡأَوَّلُونَ
Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قُلۡ نَعَمۡ وَأَنتُمۡ دَٰخِرُونَ
Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀yin yó sì di ẹni yẹpẹrẹ.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٞ وَٰحِدَةٞ فَإِذَا هُمۡ يَنظُرُونَ
Nítorí náà, igbe ẹyọ kan mà ni. Nígbà náà ni wọn yóò máa wò sùn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَقَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا هَٰذَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ
Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Èyí ni Ọjọ́ ẹ̀san.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
هَٰذَا يَوۡمُ ٱلۡفَصۡلِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Èyí ni ọjọ́ Ìdájọ́ èyí tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
۞ ٱحۡشُرُواْ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ وَأَزۡوَٰجَهُمۡ وَمَا كَانُواْ يَعۡبُدُونَ
Ẹ kó àwọn tó ṣàbòsí jọ, àwọn ìyàwó wọn àti ohun tí wọ́n ń jọ́sìn fún
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
مِن دُونِ ٱللَّهِ فَٱهۡدُوهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطِ ٱلۡجَحِيمِ
lẹ́yìn Allāhu. Kí ẹ sì júwe wọn sí ojú ọ̀nà iná Jẹhīm.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَقِفُوهُمۡۖ إِنَّهُم مَّسۡـُٔولُونَ
Ẹ dá wọn dúró ná, dájúdájú wọ́n máa bi wọ́n léèrè ìbéèrè.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
مَا لَكُمۡ لَا تَنَاصَرُونَ
Kí ni kò jẹ́ kí ẹ ran ara yín lọ́wọ́?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
بَلۡ هُمُ ٱلۡيَوۡمَ مُسۡتَسۡلِمُونَ
Rárá, wọ́n ti juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ ní òní ni.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ
Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bi ara wọn léèrè ìbéèrè.¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:101.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَالُوٓاْ إِنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَأۡتُونَنَا عَنِ ٱلۡيَمِينِ
(Àwọn ènìyàn) wí pé: “Dájúdájú ẹ̀yin l’ẹ̀ ń gba ọ̀tún wọlé sí wa lára (láti ṣì wá lọ́nà).”¹
1. Gbígba ọ̀tún wọlé sí ni lára ni pé, wọ́n ń lo orúkọ ’Islām láti fi pe àwọn ènìyàn lọ síbi ìṣẹbọ dípò mímú Allāhu ní Ọ̀kan ṣoṣo. Àpẹ̀ẹrẹ àwọn wọ̀nyí ni àwọn àáfà tí wọ́n bá àwọn àlùjọ̀nnú dòwò pọ̀ tán, tí wọ́n sọra wọn di oníṣẹ́-ìyanu àti àwọn onibidiah bí ìjọ Ahmadiyyah àti ìjọ Tijāniyyah.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَالُواْ بَل لَّمۡ تَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ
(Àwọn àlùjànnú) wí pé: “Rárá o (àwa kọ́), ẹ̀yin ni ẹ kò jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَمَا كَانَ لَنَا عَلَيۡكُم مِّن سُلۡطَٰنِۭۖ بَلۡ كُنتُمۡ قَوۡمٗا طَٰغِينَ
Àti pé àwa kò ní agbára kan lórí yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ìjọ olùtayọ-ẹnu ààlà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَحَقَّ عَلَيۡنَا قَوۡلُ رَبِّنَآۖ إِنَّا لَذَآئِقُونَ
Ọ̀rọ̀ Olúwa wa sì kò lé wa lórí pé dájúdájú àwa yóò tọ́ Iná wò.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَأَغۡوَيۡنَٰكُمۡ إِنَّا كُنَّا غَٰوِينَ
Nítorí náà, a ṣì yín lọ́nà. Dájúdájú àwa náà sì jẹ́ olùṣìnà.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَإِنَّهُمۡ يَوۡمَئِذٖ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ
Dájúdájú ní ọjọ́ yẹn, akẹgbẹ́ ni wọ́n nínú Ìyà. (Wọ́n dìjọ máa wà nínú Iná.)
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَفۡعَلُ بِٱلۡمُجۡرِمِينَ
Dájúdájú báyẹn ni Àwa yóò ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهُمۡ كَانُوٓاْ إِذَا قِيلَ لَهُمۡ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱللَّهُ يَسۡتَكۡبِرُونَ
Dájúdájú nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé “Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu.”, wọn yóò máa ṣègbéraga.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَيَقُولُونَ أَئِنَّا لَتَارِكُوٓاْ ءَالِهَتِنَا لِشَاعِرٖ مَّجۡنُونِۭ
Wọ́n sì ń wí pé: “Ṣé a máa fi àwọn òrìṣà wa sílẹ̀ nítorí eléwì wèrè kan?”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
بَلۡ جَآءَ بِٱلۡحَقِّ وَصَدَّقَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Kò rí bẹ́ẹ̀. Ó mú òdodo wá ni. Ó sì ń jẹ́rìí sí òdodo àwọn Òjíṣẹ́ náà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّكُمۡ لَذَآئِقُواْ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَلِيمِ
Dájúdájú ẹ máa tọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro wò.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَمَا تُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
A kò níí san yín ní ẹ̀san kan àfi ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ رِزۡقٞ مَّعۡلُومٞ
Ti àwọn wọ̀nyẹn sì ni arísìkí tí wọ́n ti mọ̀;
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَوَٰكِهُ وَهُم مُّكۡرَمُونَ
àwọn èso. Àwọn sì ni alápọ̀n-ọ́nlé
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فِي جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ
nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
عَلَىٰ سُرُرٖ مُّتَقَٰبِلِينَ
Lórí àwọn ìtẹ́ ni wọn yóò ti kọjú síra wọn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
يُطَافُ عَلَيۡهِم بِكَأۡسٖ مِّن مَّعِينِۭ
Wọn yóò máa gbé ife ọtí mímọ́ láti inú odò kan tó ń ṣàn káà kiri ọ̀dọ̀ wọn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
بَيۡضَآءَ لَذَّةٖ لِّلشَّٰرِبِينَ
Funfun ni (ọtí náà). Ó ń dùn lẹ́nu àwọn tó máa mu ún.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
لَا فِيهَا غَوۡلٞ وَلَا هُمۡ عَنۡهَا يُنزَفُونَ
Kò sí ìpalára kan fún wọn nínú rẹ̀, wọn kò sì níí hunrírà lórí rẹ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ عِينٞ
Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, àwọn ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ yó sì wà lọ́dọ̀ wọn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
كَأَنَّهُنَّ بَيۡضٞ مَّكۡنُونٞ
Wọ́n dà bí ẹyin tí wọn kò ì bó èèpo rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.¹
1. Àwọn nasọ̄rọ̄, nínú ọ̀rọ̀ wọn kan tí wọ́n ń fi tàbùkù àwọn ìkẹ́ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, wọ́n sọ pé, “Nítorí ọ̀wọ́n èso ní erúkùsù ilẹ̀ Lárúbáwá ni Allāhu fi ṣàdéhùn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso fún àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn ọtí àmupara ni Allāhu fi bá wọn pèsè ọtí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ dè wọ́n nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀; nítorí pé àwọn Lárúbáwá fẹ́ràn àgbèrè ṣíṣe ni Allāhu fi bá wọn pèsè obìnrin ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sílẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn mùsùlùmí nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra Rẹ̀!”
Èsì: Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn nasọ̄rọ̄ wọ̀nyí, yàtọ̀ sí pé ó ń fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí aláwàdà kẹríkẹrì, ó tún jẹ́ kí á mọ̀ pé wọn kò retí ìkẹ́ kan kan lọ́run ní tiwọn. Tí ó bá jẹ́ pé, wọ́n ń retí ìkẹ́ kan ní ọ̀run, irú ìkẹ́ wo gan-an ni wọ́n ń retí nígbà náà?
Síwájú sí i, kì í kúkú ṣe Lárúbáwá nìkan ni mùsùlùmí. Gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ni mùsùlùmí. Àwọn nasọ̄rọ̄ ṣe wá ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé nítorí Lárúbáwá nìkan ni Allāhu fi dá Ọgbà Ìdẹ̀ra!
Ìgbádùn inú Ọgbà Ìdẹ̀ra wulẹ̀ pọ̀ tayọ èso, ọtí tí kì í pani àti obìnrin. Àmọ́ sá, kò wulẹ̀ sí ìgbádùn kan kan fún àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́run bí kò ṣe Iná gbére.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَأَقۡبَلَ بَعۡضُهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ يَتَسَآءَلُونَ
Apá kan wọn yóò dojú kọ apá kan, tí wọn yóò máa bira wọn léèrè ìbéèrè.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَالَ قَآئِلٞ مِّنۡهُمۡ إِنِّي كَانَ لِي قَرِينٞ
Òǹsọ̀rọ̀ kan nínú wọn yóò sọ pé: "Dájúdájú èmi ní ọ̀rẹ́ kan
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
يَقُولُ أَءِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُصَدِّقِينَ
tí ó ń wí pé, “Ṣé dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn onígbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Àjíǹde?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَءِذَا مِتۡنَا وَكُنَّا تُرَابٗا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَدِينُونَ
Ṣé nígbà tí a bá kú tán, tí a ti di erùpẹ̀ àti egungun, ṣé dájúdájú Wọn yóò san wá ní ẹ̀san ni?”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَالَ هَلۡ أَنتُم مُّطَّلِعُونَ
Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò yọjú wo (ẹni náà tí kò gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ àjíǹde)?”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَٱطَّلَعَ فَرَءَاهُ فِي سَوَآءِ ٱلۡجَحِيمِ
Ó yọjú wò ó. Ó sì rí i láààrin gbùngbùn nínú iná Jẹhīm.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَالَ تَٱللَّهِ إِن كِدتَّ لَتُرۡدِينِ
Ó (sì) sọ pé: “Mó fi Allāhu búra, ìwọ fẹ́ẹ̀ kó ìparun bá mi tán.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَلَوۡلَا نِعۡمَةُ رَبِّي لَكُنتُ مِنَ ٱلۡمُحۡضَرِينَ
Àti pé tí kì í bá ṣe ìdẹ̀ra Olúwa mi ni, èmi náà ìbá wà nínú ẹni tí wọ́n máa mú wá sínú Iná.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَفَمَا نَحۡنُ بِمَيِّتِينَ
Àwa kò sá níí kú mọ́ báyìí?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا مَوۡتَتَنَا ٱلۡأُولَىٰ وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ
Àfi ikú wa àkọ́kọ́. Wọn kò sì níí jẹ àwa níyà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ
Dájúdájú èyí, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
لِمِثۡلِ هَٰذَا فَلۡيَعۡمَلِ ٱلۡعَٰمِلُونَ
Nítorí irú èyí, kí àwọn olùṣẹ̀sìn máa ṣẹ̀sìn lọ.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَذَٰلِكَ خَيۡرٞ نُّزُلًا أَمۡ شَجَرَةُ ٱلزَّقُّومِ
Ǹjẹ́ ìyẹn l’ó lóore jùlọ ní ibùdésí ni tàbí igi zaƙūm (igi ẹlẹ́gùn-ún)?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّا جَعَلۡنَٰهَا فِتۡنَةٗ لِّلظَّٰلِمِينَ
Dájúdájú Àwa ṣe é ní àdánwò fún àwọn alábòsí.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهَا شَجَرَةٞ تَخۡرُجُ فِيٓ أَصۡلِ ٱلۡجَحِيمِ
Dájúdájú òhun ni igi kan tí ó máa hù jáde láti ìdí iná Jẹhīm.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
طَلۡعُهَا كَأَنَّهُۥ رُءُوسُ ٱلشَّيَٰطِينِ
Èso rẹ̀ dà bí orí àwọn èṣù.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَإِنَّهُمۡ لَأٓكِلُونَ مِنۡهَا فَمَالِـُٔونَ مِنۡهَا ٱلۡبُطُونَ
Dájúdájú wọn yóò máa jẹ nínú rẹ̀. Wọ́n sì máa jẹ ẹ́ ní àjẹyo bámúbámú.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
ثُمَّ إِنَّ لَهُمۡ عَلَيۡهَا لَشَوۡبٗا مِّنۡ حَمِيمٖ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò mu àwọnúwẹ̀jẹ̀ olómi gbígbóná tó gbóná parí lé e lórí.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
ثُمَّ إِنَّ مَرۡجِعَهُمۡ لَإِلَى ٱلۡجَحِيمِ
Lẹ́yìn náà, dájúdájú ibùpadàsí wọn ni iná Jẹhīm.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهُمۡ أَلۡفَوۡاْ ءَابَآءَهُمۡ ضَآلِّينَ
Dájúdájú wọ́n bá àwọn bàbá wọn ní olùṣìnà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَهُمۡ عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِمۡ يُهۡرَعُونَ
Àwọn náà sì ń yára tẹ̀lé orípa wọn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَلَقَدۡ ضَلَّ قَبۡلَهُمۡ أَكۡثَرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ti ṣìnà ṣíwájú wọn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا فِيهِم مُّنذِرِينَ
Dájúdájú A ti rán àwọn olùkìlọ̀ sí wọn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ
Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ti rí.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَلَقَدۡ نَادَىٰنَا نُوحٞ فَلَنِعۡمَ ٱلۡمُجِيبُونَ
Dájúdájú (Ànábì) Nūh pè Wá. A sì dára ní olùjẹ́pè.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ
A gba òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَجَعَلۡنَا ذُرِّيَّتَهُۥ هُمُ ٱلۡبَاقِينَ
A dá àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ sí lẹ́yìn rẹ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
A sì fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
سَلَٰمٌ عَلَىٰ نُوحٖ فِي ٱلۡعَٰلَمِينَ
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Nūh láààrin gbogbo ẹ̀dá.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ
Lẹ́yìn náà, A tẹ àwọn yòókù rì sínú agbami.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
۞ وَإِنَّ مِن شِيعَتِهِۦ لَإِبۡرَٰهِيمَ
Dájúdájú (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wà nínú ìjọ (tí ó tẹ̀lé ìlànà) rẹ̀.¹
1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀sìn Ànábì Nūh ni ẹ̀sìn Ànábì ’Ibrọ̄hīm - aleehimọ sọlātu wa salām -, ẹ̀sìn ’Islām.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِذۡ جَآءَ رَبَّهُۥ بِقَلۡبٖ سَلِيمٍ
(Ẹ rántí) nígbà tí ó dojú kọ Olúwa rẹ̀ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَاذَا تَعۡبُدُونَ
(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: "Kí ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَئِفۡكًا ءَالِهَةٗ دُونَ ٱللَّهِ تُرِيدُونَ
Ṣé ẹ̀ ń gbèrò láti sọ irọ́ di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَمَا ظَنُّكُم بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Kí sì ni èrò ọkàn yín sí Olúwa gbogbo ẹ̀dá?”¹
1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀san rere ni ẹ̀ ń retí ni tàbí ẹ̀san aburú?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَنَظَرَ نَظۡرَةٗ فِي ٱلنُّجُومِ
Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ ní wíwò kan.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٞ
Ó sì sọ pé: “Dájúdájú ó rẹ̀ mí.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَتَوَلَّوۡاْ عَنۡهُ مُدۡبِرِينَ
Nítorí náà, wọ́n pa á tì, wọ́n sì lọ.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَرَاغَ إِلَىٰٓ ءَالِهَتِهِمۡ فَقَالَ أَلَا تَأۡكُلُونَ
Nígbà náà, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òrìṣà wọn. Ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ kò níí jẹun ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
مَا لَكُمۡ لَا تَنطِقُونَ
Kí ni ó ṣe yín tí ẹ kò sọ̀rọ̀?”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَرَاغَ عَلَيۡهِمۡ ضَرۡبَۢا بِٱلۡيَمِينِ
Nígbà náà, ó dojú lílù kọ wọ́n pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún (ó sì rún wọn wómúwómú).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَأَقۡبَلُوٓاْ إِلَيۡهِ يَزِفُّونَ
(Àwọn abọ̀rìṣà) sáré wá dojú kọ ọ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَالَ أَتَعۡبُدُونَ مَا تَنۡحِتُونَ
Ó sọ pé: “Ṣé ẹ óò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí ẹ gbẹ́ kalẹ̀ lére ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَٱللَّهُ خَلَقَكُمۡ وَمَا تَعۡمَلُونَ
Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَالُواْ ٱبۡنُواْ لَهُۥ بُنۡيَٰنٗا فَأَلۡقُوهُ فِي ٱلۡجَحِيمِ
Wọ́n wí pé: “Ẹ mọ ilé kan fún un, kí ẹ sì jù ú sínú iná.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَأَرَادُواْ بِهِۦ كَيۡدٗا فَجَعَلۡنَٰهُمُ ٱلۡأَسۡفَلِينَ
Wọ́n gbèrò ète sí i. A sì sọ wọ́n di ẹni yẹpẹrẹ.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَقَالَ إِنِّي ذَاهِبٌ إِلَىٰ رَبِّي سَيَهۡدِينِ
Ó sọ pé: “Dájúdájú mo máa lọ sí (ìlú tí) Olúwa mi (pa mí láṣẹ láti lọ). Ó sì máa tọ́ mi sọ́nà (láti dé ibẹ̀).¹
1. Ìyẹn ìlú Ṣām.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
رَبِّ هَبۡ لِي مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
Olúwa mi, ta mí lọ́rẹ ọmọ nínú àwọn ẹni rere.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَبَشَّرۡنَٰهُ بِغُلَٰمٍ حَلِيمٖ
A sì fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan tí ó máa ní ìfaradà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَلَمَّا بَلَغَ مَعَهُ ٱلسَّعۡيَ قَالَ يَٰبُنَيَّ إِنِّيٓ أَرَىٰ فِي ٱلۡمَنَامِ أَنِّيٓ أَذۡبَحُكَ فَٱنظُرۡ مَاذَا تَرَىٰۚ قَالَ يَٰٓأَبَتِ ٱفۡعَلۡ مَا تُؤۡمَرُۖ سَتَجِدُنِيٓ إِن شَآءَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلصَّٰبِرِينَ
Nígbà tí (ọmọ náà) dàgbà, tí ó tó bá (bàbá rẹ̀) ṣe iṣẹ́, (bàbá rẹ̀) sọ pé: "Ọmọ mi, dájúdájú èmi lá àlá pé dájúdájú mò ń dúńbú rẹ. Nítorí náà, wòye sí i, kí ni o rí sí i." Ó sọ pé: “Bàbá mi, ṣe ohun tí Wọ́n pa láṣẹ fún ọ. O máa bá mi nínú àwọn onísùúrù, tí Allāhu bá fẹ́.”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَلَمَّآ أَسۡلَمَا وَتَلَّهُۥ لِلۡجَبِينِ
Nígbà tí àwọn méjèèjì juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀, tí (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sì dojú¹ (ọmọ) rẹ̀ bolẹ̀,
1. Ìtúmọ̀ “jẹbīn” ni iwájú orí.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَنَٰدَيۡنَٰهُ أَن يَٰٓإِبۡرَٰهِيمُ
A pè é (báyìí) pé, ’Ibrọ̄hīm,
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
قَدۡ صَدَّقۡتَ ٱلرُّءۡيَآۚ إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
o kúkú ti mú àlá náà ṣẹ. Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ ٱلۡبَلَٰٓؤُاْ ٱلۡمُبِينُ
Dájúdájú èyí, òhun ni àdánwò pọ́nńbélé.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَفَدَيۡنَٰهُ بِذِبۡحٍ عَظِيمٖ
A sì fi àgbò ńlá ṣèràpadà rẹ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
A tún fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِيمَ
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَبَشَّرۡنَٰهُ بِإِسۡحَٰقَ نَبِيّٗا مِّنَ ٱلصَّٰلِحِينَ
A tún fún un ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ’Ishāƙ, (ó máa jẹ́) Ànábì. (Ó sì máa wà) nínú àwọn ẹni rere.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَبَٰرَكۡنَا عَلَيۡهِ وَعَلَىٰٓ إِسۡحَٰقَۚ وَمِن ذُرِّيَّتِهِمَا مُحۡسِنٞ وَظَالِمٞ لِّنَفۡسِهِۦ مُبِينٞ
Àti pé A fún òun àti ’Ishāƙ ní ìbùkún. Ẹni rere àti alábòsí pọ́nńbélé (tó ń ṣàbòsí sí) ẹ̀mí ara rẹ̀ wà nínú àrọ́mọdọ́mọ àwọn méjèèjì.¹
1. Bẹ̀rẹ̀ láti āyah 100 títí dé āyah 113, ó ti hàn kedere pé:
(ìkíní) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni àkọ́bí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a -;
(ìkejì) Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a - ni ẹni tí Allāhu Ẹlẹ́dàá pa láṣẹ pé kí Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - pa láti fi jọ́sìn fún Òun;
(ìkẹta) Kò sí ohun tó jẹmọ́ ẹ̀jẹ́ àti ìmúṣẹ ẹ̀jẹ́ nínú àlá àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà; (ìkẹrin) Ìkíní kejì àwọn ọmọ méjèèjì náà ni ẹni ìbùkún. Àmọ́, àwọn nasọ̄rọ̄, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti àṣà wọn, orúkọ burúkú ni wọ́n ń fún Ànábì ’Ismā‘īl - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ẹ tún wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Hūd; 11:71.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ
Dájúdájú A ṣoore fún (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَنَجَّيۡنَٰهُمَا وَقَوۡمَهُمَا مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ
A gba àwọn méjèèjì àti ìjọ àwọn méjèèjì là kúrò nínú ìbànújẹ́ ńlá náà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَنَصَرۡنَٰهُمۡ فَكَانُواْ هُمُ ٱلۡغَٰلِبِينَ
A tún ṣàrànṣe fún wọn. Àwọn ni wọ́n jẹ́ olùborí (ọ̀tá wọn).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَءَاتَيۡنَٰهُمَا ٱلۡكِتَٰبَ ٱلۡمُسۡتَبِينَ
A sì fún àwọn méjèèjì ní Tírà tó yanjú.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَهَدَيۡنَٰهُمَا ٱلصِّرَٰطَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ
A tún fi àwọn méjèèjì mọ̀nà tààrà.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِمَا فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
A fún àwọn méjèèjì ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
سَلَٰمٌ عَلَىٰ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهُمَا مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú àwọn méjèèjì wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِنَّ إِلۡيَاسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dájúdájú (Ànábì) ’Ilyās wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦٓ أَلَا تَتَّقُونَ
(Ẹ rántí) nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù Allāhu ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَتَدۡعُونَ بَعۡلٗا وَتَذَرُونَ أَحۡسَنَ ٱلۡخَٰلِقِينَ
Ṣé ẹ óò máa pe òrìṣà kan, ẹ sì máa fi Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá sílẹ̀?¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:14.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
ٱللَّهَ رَبَّكُمۡ وَرَبَّ ءَابَآئِكُمُ ٱلۡأَوَّلِينَ
(ẹ̀ ń fi) Allāhu (sílẹ̀), Olúwa yín àti Olúwa àwọn bàbá yín, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ
Wọ́n sì pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, wọ́n máa mú wọn wá sínú Iná.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ
A fún un ní orúkọ rere láààrin àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِلۡ يَاسِينَ
Àlàáfíà kí ó máa bá (Ànábì) ’Ilyās.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ
Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ
Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِنَّ لُوطٗا لَّمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dájúdájú (Ànábì) Lūt wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِذۡ نَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ
(Ẹ rántí) nígbà tí A gba òun àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ là.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا عَجُوزٗا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ
Àyàfi arúgbóbìnrin kan tí ó wà nínú àwọn tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn (láààrin àwọn tí A parẹ́).¹
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah aṣ-Ṣu‘arọ̄’; 26:171.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ
Lẹ́yìn náà, A pa àwọn yòókù run.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِنَّكُمۡ لَتَمُرُّونَ عَلَيۡهِم مُّصۡبِحِينَ
Dájúdájú ẹ̀yin náà kúkú ń gba ọ̀dọ̀ wọn kọjá láàárọ̀-láàárọ̀
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَبِٱلَّيۡلِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ
àti ní alaalẹ́. Ṣé ẹ kò níí ṣe làákàyè ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dájúdájú (Ànábì) Yūnus kúkú wà nínú àwọn Òjíṣẹ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِذۡ أَبَقَ إِلَى ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ
(Ẹ rántí) nígbà tí ó sá lọ sínú ọkọ̀ ojú-omi tó kún (fún èrò).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُدۡحَضِينَ
Ó sì bá wọn ṣe kúríà papọ̀. Ó sì wà nínú àwọn tí kúrìá já.¹
1. Ìyẹn ni pé, nígbà tí ọkọ̀ ojú-omi fẹ́ yí dànù láààrin agbami odò nítorí èrò àkúnfàya, ọ̀rọ̀ jẹmọ́ kí ẹnì kan kúrò nínú rẹ̀ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wọn máa bá omi lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe ƙur‘ah. Ìyẹn ni pé, wọ́n kọ, bí àpẹ̀ẹrẹ, “orúkọ” olúkùlùkù sára n̄ǹkan kan ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n sì kó gbogbo rẹ̀ papọ̀ sínú n̄ǹkan kan bí igbá. Wọ́n sì yan ẹnì kan láààrin wọn pé kí ó mú ẹyọ kan péré nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹnukò wọn pé, ẹni tí wọ́n bá mú “orúkọ” rẹ̀ jáde ni wọ́n máa já jù sínú omi odò nítorí kí èrò ọkọ̀ lè fà fún ìtẹ̀síwájú lórí ìrìn náà. Èyí tí wọ́n kọ orúkọ Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - sí lára ní ọwọ́ ẹni náà bà. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n jù ú sínú odò. Ó sì ṣe wẹ́kú ẹnu ẹja.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَٱلۡتَقَمَهُ ٱلۡحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٞ
Nítorí náà, ẹja gbé e mì; ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَلَوۡلَآ أَنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُسَبِّحِينَ
Nítorí náà, tí kò bá jẹ́ pé ó wà nínú àwọn olùṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu,
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
لَلَبِثَ فِي بَطۡنِهِۦٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ
dájúdájú ìbá wà nínú ẹja títí di ọjọ́ tí wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
۞ فَنَبَذۡنَٰهُ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ سَقِيمٞ
Nítorí náà, A jù ú sí orí ilẹ́ gban̄sasa létí omi. Ó sì jẹ́ aláìlera.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَأَنۢبَتۡنَا عَلَيۡهِ شَجَرَةٗ مِّن يَقۡطِينٖ
A sì mú igi Yẹƙtīn hù jáde láti ṣíji bò ó.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَأَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ مِاْئَةِ أَلۡفٍ أَوۡ يَزِيدُونَ
A tún rán an níṣẹ́ sí ọ̀kẹ́ márùn-ún (ènìyàn) tàbí kí wọ́n lékún sí i.¹
1. Ọ̀kẹ́ márùn-ún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000). Wàyí, àwọn nasọ̄rọ̄ lérò pé, Allāhu kò nímọ̀ nípa pàtó òǹkà ìjọ Ànábì Yūnus - kí ọlà Allāhu máa bá a - l’Ó fi mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ wá pẹ̀lú “ ’ao” - “tàbí”. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:74 fún àlàyé lórí rẹ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَـَٔامَنُواْ فَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ
Wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo. A sì fún wọn ní ìgbádùn títí di ìgbà díẹ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَلِرَبِّكَ ٱلۡبَنَاتُ وَلَهُمُ ٱلۡبَنُونَ
Bi wọ́n léèrè wò pé: “Ṣé Olúwa rẹ l’ó ni àwọn ọmọbìnrin, tiwọn sì ni ọmọkùnrin?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَمۡ خَلَقۡنَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ إِنَٰثٗا وَهُمۡ شَٰهِدُونَ
Tàbí A dá àwọn mọlāika ní obìnrin, tí àwọn sì jẹ́ ẹlẹ́rìí?”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَلَآ إِنَّهُم مِّنۡ إِفۡكِهِمۡ لَيَقُولُونَ
Gbọ́, nínú irọ́ wọn ni pé dájúdájú wọ́n ń wí pé:
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَلَدَ ٱللَّهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ
“Allāhu bímọ.” Dájúdájú òpùrọ́ sì ni wọ́n.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَصۡطَفَى ٱلۡبَنَاتِ عَلَى ٱلۡبَنِينَ
Ṣé (Allāhu) ṣẹ̀ṣà àwọn ọmọbìnrin lórí àwọn ọmọkùnrin ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
مَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ
Kí l’ó ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Ṣé ẹ kò níí lo ìrántí ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَمۡ لَكُمۡ سُلۡطَٰنٞ مُّبِينٞ
Tàbí ẹ ní ẹ̀rí tó yanjú lọ́wọ́ ni?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَأۡتُواْ بِكِتَٰبِكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ
Ẹ mú tírà yín wà nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَجَعَلُواْ بَيۡنَهُۥ وَبَيۡنَ ٱلۡجِنَّةِ نَسَبٗاۚ وَلَقَدۡ عَلِمَتِ ٱلۡجِنَّةُ إِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ
Wọ́n tún fi ìbátan sáààrin (Allāhu) àti àlùjànnú! Àwọn àlùjànnú sì ti mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n kúkú máa mú àwọn wá sínú Iná ni.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
سُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ عَمَّا يَصِفُونَ
Mímọ́ ni fún Allāhu tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
Àfi àwọn ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَإِنَّكُمۡ وَمَا تَعۡبُدُونَ
Dájúdájú ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún (lẹ́yìn Allāhu),
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
مَآ أَنتُمۡ عَلَيۡهِ بِفَٰتِنِينَ
ẹ kò lè fi ṣi ẹnì kan kan lọ́nà
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِلَّا مَنۡ هُوَ صَالِ ٱلۡجَحِيمِ
àfi ẹni tí ó bá fẹ́ wọ inú iná Jẹhīm.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَمَا مِنَّآ إِلَّا لَهُۥ مَقَامٞ مَّعۡلُومٞ
Kò sí ẹnì kan nínú àwa (mọlāika) àfi kí ó ní ibùdúró tí wọ́n ti mọ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلصَّآفُّونَ
Dájúdájú àwa, a kúkú wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ni.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِنَّا لَنَحۡنُ ٱلۡمُسَبِّحُونَ
Àti pé dájúdájú àwa, àwa kúkú ni olùṣàfọ̀mọ́ (fún Allāhu).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِن كَانُواْ لَيَقُولُونَ
Wọ́n kúkú ń wí pé:
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
لَوۡ أَنَّ عِندَنَا ذِكۡرٗا مِّنَ ٱلۡأَوَّلِينَ
“Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú a bá ní (tírà) ìrántí kan nínú (àwọn tírà) àwọn ẹni àkọ́kọ́,
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
لَكُنَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ
dájúdájú àwa ìbá jẹ́ ẹrúsìn Allāhu, àwọn tí A ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo).”
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَكَفَرُواْ بِهِۦۖ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ
Ṣùgbọ́n wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú (Allāhu). Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَلَقَدۡ سَبَقَتۡ كَلِمَتُنَا لِعِبَادِنَا ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Dájúdájú ọ̀rọ̀ Wa ti ṣíwájú fún àwọn ẹrúsìn Wa, àwọn Òjíṣẹ́.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
إِنَّهُمۡ لَهُمُ ٱلۡمَنصُورُونَ
Dájúdájú àwọn, àwọn l’a kúkú máa ṣàrànṣe fún.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَإِنَّ جُندَنَا لَهُمُ ٱلۡغَٰلِبُونَ
Àti pé dájúdájú àwọn ọmọ ogun Wa, àwọn kúkú ni olùborí.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ
Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn fún ìgbà díẹ̀.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَأَبۡصِرۡهُمۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ
Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
أَفَبِعَذَابِنَا يَسۡتَعۡجِلُونَ
Ṣé ìyà Wa ni wọ́n ń wá pẹ̀lú ìkánjú?
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
فَإِذَا نَزَلَ بِسَاحَتِهِمۡ فَسَآءَ صَبَاحُ ٱلۡمُنذَرِينَ
Nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ sí gbàgede wọn, òwúrọ̀ ọjọ́ náà yó sì burú fún àwọn ẹni-akìlọ̀-fún.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَتَوَلَّ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ حِينٖ
Kúrò lọ́dọ̀ wọn títí di ìgbà kan ná.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَأَبۡصِرۡ فَسَوۡفَ يُبۡصِرُونَ
Àti pé máa wò wọ́n níran ná, àwọn náà ń bọ̀ wá ríran wò.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
سُبۡحَٰنَ رَبِّكَ رَبِّ ٱلۡعِزَّةِ عَمَّا يَصِفُونَ
Mímọ́ ni fún Olúwa rẹ, Olúwa (tó ni) agbára, tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَسَلَٰمٌ عَلَى ٱلۡمُرۡسَلِينَ
Kí àlàáfíà máa bá àwọn Òjíṣẹ́
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
আৰবী তাফছীৰসমূহ:
 
অৰ্থানুবাদ ছুৰা: ছুৰা আচ-চা-ফফা-ত
ছুৰাৰ তালিকা পৃষ্ঠা নং
 
আল-কোৰআনুল কাৰীমৰ অৰ্থানুবাদ - ইউৰুবা অনুবাদ - অনুবাদসমূহৰ সূচীপত্ৰ

ইউৰুবা ভাষাত আল-কোৰআনুল কাৰীমৰ অৰ্থানুবাদ। অনুবাদ কৰিছে, শ্বাইখ আবু ৰাহীমাহ মীকাঈল আইকুয়েনী চাহাবে। প্ৰকাশকালঃ ১৪৩২ হিজৰী।

বন্ধ