Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Yorubische Übersetzung * - Übersetzungen

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Übersetzung der Bedeutungen Vers: (1) Surah / Kapitel: At-Talâq

Suuratut-Tolaaq

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ وَأَحۡصُواْ ٱلۡعِدَّةَۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ رَبَّكُمۡۖ لَا تُخۡرِجُوهُنَّ مِنۢ بُيُوتِهِنَّ وَلَا يَخۡرُجۡنَ إِلَّآ أَن يَأۡتِينَ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖۚ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ ٱللَّهِ فَقَدۡ ظَلَمَ نَفۡسَهُۥۚ لَا تَدۡرِي لَعَلَّ ٱللَّهَ يُحۡدِثُ بَعۡدَ ذَٰلِكَ أَمۡرٗا
Ìwọ Ànábì, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.¹ Kí ẹ sì ṣọ́ òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ náà. Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu, Olúwa yín. Ẹ má ṣe mú wọn jáde kúrò nínú ilé wọn, àwọn náà kò sì gbọdọ̀ jáde àfi tí wọ́n bá lọ ṣe ìbàjẹ́ tó fojú hàn.² Ìwọ̀nyẹn sì ni àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀, o kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ kò sì mọ̀ bóyá Allāhu máa mú ọ̀rọ̀ titun kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn.
1. Ìyẹn ni pé, ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe “‘iddatu-ttọlāƙ” (opó ìkọ̀sílẹ̀) parí kí yìgì ààrin yín tó ó já. Lẹ́yìn náà, kí ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀. Bákan náà, a kì í sọ pé “mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀” ní àsìkò tí obìnrin bá ń ṣe héélà rẹ̀ lọ́wọ́ tàbí lẹ́yìn ìbálòpọ̀ tó wáyé lẹ́yìn ìmọ́ra níbi héélà.
2. Ìbàjẹ́ tó fojú hàn tí ó lè dínà kí obìnrin rí opó ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ ṣe nínú ilé ọkọ rẹ̀ pín sí bíi oríṣi mẹ́ta nínú àwọn tírà Tafsīr:
Ìbàjẹ́ kìíní: kí obìnrin ṣe zina.
Ìbàjẹ́ kejì: kí ẹnu obìnrin mú fún èébú bíbú, èpè ṣíṣẹ́ àti ariwo burúkú tí ó ń fi kó ìnira bá ọkọ rẹ̀ àti ará ilé ọkọ rẹ̀.
Ìbàjẹ́ kẹta: kí igun kìíní kejì wà nínú ẹ̀rù àti àìbalẹ̀-ọkàn síra wọn nípa aburú tí ó súnmọ́ kí wọ́n fi kanra wọn tàbí dúkìá wọn.
Láti lè dènà irúfẹ́ ìwọ̀nyí, obìnrin máa lọ ṣe opó ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀ ní àyè mìíràn. Fún àlàyé yòókù lórí tọlāƙ (kíkọ ìyàwó sílẹ̀), ẹ lọ ka sūrah al-Baƙọrah; 2: 228 - 232.
Arabische Interpretationen von dem heiligen Quran:
 
Übersetzung der Bedeutungen Vers: (1) Surah / Kapitel: At-Talâq
Suren/ Kapiteln Liste Nummer der Seite
 
Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Yorubische Übersetzung - Übersetzungen

Übersetzung der Quran-Bedeutung in Yoruba Sprache von Abu Rahima Mikhail Aikweiny in 1432 H.

Schließen