Check out the new design

ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល * - សន្ទស្សន៍នៃការបកប្រែ

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

ការបកប្រែអត្ថន័យ អាយ៉ាត់: (1) ជំពូក​: អាត់តឡាគ

At-Tolaaq

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَطَلِّقُوهُنَّ لِعِدَّتِهِنَّ وَأَحۡصُواْ ٱلۡعِدَّةَۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ رَبَّكُمۡۖ لَا تُخۡرِجُوهُنَّ مِنۢ بُيُوتِهِنَّ وَلَا يَخۡرُجۡنَ إِلَّآ أَن يَأۡتِينَ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖۚ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ ٱللَّهِ فَقَدۡ ظَلَمَ نَفۡسَهُۥۚ لَا تَدۡرِي لَعَلَّ ٱللَّهَ يُحۡدِثُ بَعۡدَ ذَٰلِكَ أَمۡرٗا
Ìwọ Ànábì, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.[1] Kí ẹ sì ṣọ́ òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ náà. Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu, Olúwa yín. Ẹ má ṣe mú wọn jáde kúrò nínú ilé wọn, àwọn náà kò sì gbọdọ̀ jáde àfi tí wọ́n bá lọ ṣe ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ìwọ̀nyẹn sì ni àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀, o kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ kò sì mọ̀ bóyá Allāhu máa mú ọ̀rọ̀ titun kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn.
[1] Ìyẹn ni pé, ẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe “‘iddatu-ttọlāƙ” (opó ìkọ̀sílẹ̀) parí kí yìgì ààrin yín tó ó já. Lẹ́yìn náà, kí ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀. Bákan náà, a kì í sọ pé “mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀” ní àsìkò tí obìnrin bá ń ṣe héélà rẹ̀ lọ́wọ́ tàbí lẹ́yìn ìbálòpọ̀ tó wáyé lẹ́yìn ìmọ́ra níbi héélà.
តាហ្វសៀរជាភាសា​អារ៉ាប់ជាច្រេីន:
 
ការបកប្រែអត្ថន័យ អាយ៉ាត់: (1) ជំពូក​: អាត់តឡាគ
សន្ទស្សន៍នៃជំពូក លេខ​ទំព័រ
 
ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល - សន្ទស្សន៍នៃការបកប្រែ

ការបកប្រែដោយលោកអាពូ​ រ៉ហុីម៉ះ​ មុីកាអុីល​ អៃក្វីនី។

បិទ