Check out the new design

Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael * - Translations’ Index

PDF XML CSV Excel API
Please review the Terms and Policies

Translation of the meanings Surah: An-Nahl   Ayah:
وَأَلۡقَىٰ فِي ٱلۡأَرۡضِ رَوَٰسِيَ أَن تَمِيدَ بِكُمۡ وَأَنۡهَٰرٗا وَسُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ
Ó sì fi àwọn àpáta tó dúró gbagidi sórí ilẹ̀ kí ó má baà mì mọ yín lẹ́sẹ̀ àti àwọn odò àti àwọn ojú-ọ̀nà nítorí kí ẹ lè dá ojú ọ̀nà mọ̀;
Arabic explanations of the Qur’an:
وَعَلَٰمَٰتٖۚ وَبِٱلنَّجۡمِ هُمۡ يَهۡتَدُونَ
àti àwọn àmì òpópónà (fún ìtọ́sọ́nà ìrìn ọ̀sán). Wọ́n tún ń fi ìràwọ̀ dá ojú ọ̀nà mọ̀ (lálẹ́).[1]
[1] Àwọn n̄ǹkan tí Allāhu - subhānahu wa ta'ālā - dá fún dídá ojú ọ̀nà mọ̀ wọ̀nyí dúró fún rírína rí ojú ọ̀nà, yálà ní alẹ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tàbí ní ọ̀sán pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ òòrùn àti àwọn atọ́ka òpópónà.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَفَمَن يَخۡلُقُ كَمَن لَّا يَخۡلُقُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ
Ǹjẹ́ Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá dà bí ẹni tí kò dá ẹ̀dá bí? Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِن تَعُدُّواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ لَا تُحۡصُوهَآۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ
Tí ẹ bá ṣòǹkà ìdẹ̀ra Allāhu, ẹ kò lè kà á tán. Dájúdájú Allāhu mà ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا تُسِرُّونَ وَمَا تُعۡلِنُونَ
Àti pé Allāhu mọ ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́ àti ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ
Àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn.
Arabic explanations of the Qur’an:
أَمۡوَٰتٌ غَيۡرُ أَحۡيَآءٖۖ وَمَا يَشۡعُرُونَ أَيَّانَ يُبۡعَثُونَ
Òkú (ni wọ́n), wọn kì í ṣe alààyè.[1] Wọn kò sì mọ àkókò tí A óò jí wọn dìde (nínú sàréè).
[1] Allāhu pe àwọn òrìṣà ní òkú nítorí pé, ère tí kò sí ẹ̀mí lára rẹ̀ ni àwọn òrìṣà náà. Ipò òkú, ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, ẹni tí kò lè ríran, ẹni tí kò lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ áḿbọ̀sìbọ́sí pé ó máa ran ẹlòmíìràn lọ́wọ́ ni ipò tí gbogbo ère òrìṣà wà.
Arabic explanations of the Qur’an:
إِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۚ فَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ قُلُوبُهُم مُّنكِرَةٞ وَهُم مُّسۡتَكۡبِرُونَ
Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àmọ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ni ọkàn wọn takò ó, tí wọ́n sì ń ṣègbéraga.
Arabic explanations of the Qur’an:
لَا جَرَمَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡتَكۡبِرِينَ
Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n, dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe àfihàn rẹ̀. Àti pé dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn onígbèéraga.
Arabic explanations of the Qur’an:
وَإِذَا قِيلَ لَهُم مَّاذَآ أَنزَلَ رَبُّكُمۡ قَالُوٓاْ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Kí ni Olúwa yín sọ̀kalẹ̀? Wọ́n á wí pé: “Àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ ni.”
Arabic explanations of the Qur’an:
لِيَحۡمِلُوٓاْ أَوۡزَارَهُمۡ كَامِلَةٗ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَمِنۡ أَوۡزَارِ ٱلَّذِينَ يُضِلُّونَهُم بِغَيۡرِ عِلۡمٍۗ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ
(Wọ́n sọ bẹ́ẹ̀) nítorí kí wọ́n lè ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tiwọn ní pípé pérépéré ní Ọjọ́ Àjíǹde àti (nítorí kí wọ́n lè rù) nínú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n ń ṣì lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Gbọ́, ohun tí wọn yóò rù ní ẹ̀ṣẹ̀, ó burú.[1]
[1] Kíyè sí i! Kò sí ìtakora láààrin āyah yìí àti sūrah an-Najm; 53:38. Āyah àkọ́kọ́ ń sọ nípa ìpín ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa wà fún onísábàbí iṣẹ́-aburú àti onísábàbí ìṣìnà. Ìyẹn ni pé, bí ìyà ṣe wà fún oníṣẹ́-aburú bẹ́ẹ̀ náà ni ìyà wà fún onísábàbí rẹ̀. Ní ti āyah ti sūrah an-Najm, ò ń sọ nípa bí kò ṣe níí sí àǹfààní fún ẹnikẹ́ni láti gbé àpapọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lọ́rùn rẹ̀ fún ẹlòmíìràn ní Ọjọ́ ẹ̀san. Nítorí náà, àròpọ̀ iṣẹ́ tí ẹ̀dá ṣe àti iṣẹ́ tí ó ṣe sábàbí rẹ̀ ló máa wà lọ́rùn rẹ̀, yálà ó jẹ́ iṣẹ́ rere tàbí iṣẹ́ aburú. Kò sì níí rí alábàárù-ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ ọrùn rẹ̀. Ẹ tún wo sūrah al-‘ankabūt; 29:12 àti 13.
Arabic explanations of the Qur’an:
قَدۡ مَكَرَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَأَتَى ٱللَّهُ بُنۡيَٰنَهُم مِّنَ ٱلۡقَوَاعِدِ فَخَرَّ عَلَيۡهِمُ ٱلسَّقۡفُ مِن فَوۡقِهِمۡ وَأَتَىٰهُمُ ٱلۡعَذَابُ مِنۡ حَيۡثُ لَا يَشۡعُرُونَ
Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú déte. Allāhu sì da ilé wọn wó látibi àwọn òpó ilé. Òrùlé sì wó lù wọ́n mọ́lẹ̀ láti òkè wọn. Àti pé ìyà dé bá wọn ní àyè tí wọn kò ti fura.
Arabic explanations of the Qur’an:
 
Translation of the meanings Surah: An-Nahl
Surahs’ Index Page Number
 
Translation of the Meanings of the Noble Qur'an - Yoruba translation - Abu Rahima Mikael - Translations’ Index

Translated by Sh. Abu Rahima Mikael Ekoyini

close